Ṣé Ohun Tó Burú Ni Kí Ẹ̀rí Ọkàn Máa Dá Èyàn Lẹ́bi?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Ohun Tó Burú Ni Kí Ẹ̀rí Ọkàn Máa Dá Èyàn Lẹ́bi?
Ọ̀PỌ̀ èèyàn lónìí ló sọ pé ohun tí kò dára rárá ni kí ẹ̀rí ọkàn máa dá èèyàn lẹ́bi. Èrò wọn dà bí ti onímọ̀ ọgbọ́n orí ọmọ ilẹ̀ Jámánì náà Friedrich Nietzsche, tó sọ pé: “Kí ẹ̀rí ọkàn máa dá èèyàn lẹ́bi ni àrùn tó burú jù téèyàn ò lè kápá.”
Àmọ́ ọ̀tọ̀ ni ohun táwọn olùwádìí kan wá sọ báyìí o. Gbajúmọ̀ oníṣègùn, àti òǹkọ̀wé náà, Susan Forward, sọ pé: “Ẹ̀bi jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì láti mú kéèyàn jẹ́ ẹni tó máa ń mọ nǹkan lára, ó sì tún fi hàn pé èèyàn jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Ọmọ ìyá lòun àti ẹ̀rí ọkàn jẹ́.” Nígbà náà, ṣé ohun tó burú ni pé kí ẹ̀rí ọkàn máa dá èèyàn lẹ́bi? Ǹjẹ́ àwọn àkókò kan lè wà tó máa dára kí ẹ̀rí ọkàn dá èèyàn lẹ́bi?
Kí Ló Ń Jẹ́ Ẹ̀bi?
Ẹ̀rí ọkàn máa ń dá èèyàn lẹ́bi nígbà tá a bá rí i pé a ti ṣàìdáa sí ẹnì kan tá a fẹ́ràn tàbí nígbà tá ò bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà tá a rò pé ó yẹ ká tẹ̀ lé. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ẹ̀bi jẹ́ “níní ìmọ̀lára pé èèyàn jẹ gbèsè nítorí pé kò ṣe ohun kan tó yẹ kó ṣe, tàbí nítorí pé ó ti ṣe láìfí, hùwà ipá tàbí nítorí pé ó ti dẹ́ṣẹ̀.”
Nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù, tí ọmọ Ísírẹ́lì kan kò bá pa Òfin Ọlọ́run mọ́, ó lè máa nímọ̀lára ẹ̀bi. A mẹ́nu ba èyí tó pọ̀ jù lọ nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ nínú ìwé Léfítíkù àti Númérì. Ó yẹ fún àfiyèsí pé a ò fi bẹ́ẹ̀ mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ yìí nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì. Àmọ́ láwọn ibi díẹ̀ tá a ti mẹ́nu kàn án, ohun kan náà ló tọ́ka sí. Ìyẹn ni àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo táwọn kan dá sí Ọlọ́run.—Máàkù 3:29; 1 Kọ́ríńtì 11:27.
Àmọ́ ó dunni pé, ẹ̀rí ọkàn wa lè máa dá wa lẹ́bi nígbà míì láìjẹ́ pé a dìídì ṣe ohun kan tó burú ní ti gidi. Bí àpẹẹrẹ, béèyàn bá jẹ́ aṣefínnífínní dóríi bíńtín, tó jẹ́ pé àwọn ohun tí kò lè bá ló máa ń lé, gbogbo ìgbà tí kò bá lè bá àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ á bẹ̀rẹ̀ sí dá a lẹ́bi tí kò pọn dandan. (Oníwàásù 7:16) Bákan náà, a lè ṣe àwọn ohun kan tó kù díẹ̀ káàtó, ká sì wá jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa máa dà wá láàmú kọjá bó ṣe yẹ. Nígbà náà, oore wo ni kí ẹ̀rí ọkàn máa dá èèyàn lẹ́bi lè ṣe?
Kí Ẹ̀rí Ọkàn Máa Dá Èèyàn Lẹ́bi Lóore Tó Ń Ṣeni
Ó kéré tán, kí ẹ̀rí ọkàn máa dá èèyàn lẹ́bi lè ṣeni lóore ní ọ̀nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Èkíní, ó fi hàn pé a mọ ìlànà tó bójú mu. Ó fi hàn pé ẹ̀rí ọkàn wa ṣì ń ṣiṣẹ́. (Róòmù 2:15) Kódà, ìwé kan tí Àjọ Ìṣègùn Ọpọlọ ní Amẹ́ríkà tẹ̀ jáde sọ pé ohun burúkú tó lè ṣàkóbá fún àwùjọ ló jẹ́ tí ẹ̀rí ọkàn kì í báá dá àwọn èèyàn lẹ́bi. Àwọn èèyàn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò ṣiṣẹ́ dáadáa tàbí tó ti kú kì í lè rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó dára àtèyí tí kò dára, ewu ńláǹlà sì lèyí.—Títù 1:15, 16.
Ìkejì, ẹ̀rí ọkàn tó ń dá èèyàn lẹ́bi kò ní jẹ́ kéèyàn ṣe àwọn ohun tí kò dára. Bára bá ń ro wá, a máa ń mọ̀ pé àìsàn ń bọ̀ nìyẹn, bákan náà, dídà tí ẹ̀rí ọkàn ń dà wá láàmú á jẹ́ ká mọ̀ pé a ti hu ìwà kan tí kò dáa tàbí ṣe ohun kan tó kù díẹ̀ káàtó nípa tẹ̀mí tó yẹ ká tètè bójú tó. Tá a bá sì ti mọ àìdáa tá a ṣe náà, á túbọ̀ ṣeé ṣe fún wa láti má ṣe pa ara wa, àwọn èèyàn wa tàbí àwọn ẹlòmíràn lára lọ́jọ́ iwájú.—Mátíù 7:12.
Ìkẹta, jíjẹ́wọ́ ìwà tó kù díẹ̀ káàtó téèyàn hù á ran ẹni tó hùwà náà àti ẹni tó hù ú sí lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀dùn ọkàn ńláǹlà kọlu Dáfídì nígbà tó dẹ́ṣẹ̀. Ó kọ ọ́ pé: “Nígbà tí mo dákẹ́, egungun mi ti di gbígbó nítorí ìkérora mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” Àmọ́ nígbà tí Dáfídì Ọba jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún Ọlọ́run, tayọ̀tayọ̀ ló fi kọrin pé: “Ìwọ yóò fi igbe ìdùnnú yí mi ká lẹ́nu pípèsè àsálà.” (Sáàmù 32:3, 7) Kódà, béèyàn bá jẹ́wọ́ àìdáa tó ṣe, ó lè mú kí ẹni tó ṣe é sí ṣara gírí nítorí gbígbà tó gbà pé òún ti ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó á jẹ́ kí ẹni tó ṣàìdáa sí mọ̀ pé ó fẹ́ràn òun, pé ó kábàámọ̀ ìwà àìdáa tó hù.—2 Sámúẹ́lì 11:2-15.
Èrò Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Kéèyàn Nímọ̀lára Ẹ̀bi
Láti ní èrò tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa kéèyàn máa nímọ̀lára ẹ̀bi, wo ìyàtọ̀ tó wà láàárín irú ojú tí Jésù fi wo ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹlẹ́ṣẹ̀ àti irú ojú táwọn Farisí fi wò ó. Nínú ìwé Lúùkù 7:36-50, a kà nípa obìnrin oníwà pálapàla kan tó wọlé Farisí kan níbi tí Jésù ti ń jẹun lọ́wọ́. Obìnrin náà lọ sọ́dọ̀ Jésù, ó fi omijé rẹ̀ nu ẹsẹ̀ Jésù, ó sì fi òróró onílọ́fínńdà pa á.
Ojú burúkú ni Farisí tó gbé ẹ̀sìn rù yìí fi wo obìnrin náà, pé kò yẹ lẹ́ni tóun lè gbọ́ tiẹ̀. Ó wá ń sọ nínú ara rẹ̀ pé: “Ọkùnrin yìí [Jésù], bí ó bá jẹ́ wòlíì ni, ì bá mọ ẹni àti irú obìnrin tí ẹni tí ń fọwọ́ kan òun jẹ́, pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.” (Lúùkù 7:39) Lójú ẹsẹ̀ ni Jésù ti tún èrò ọkùnrin yìí ṣe. Ó sọ fún un pé: “Ìwọ kò fi òróró pa orí mi; ṣùgbọ́n obìnrin yìí fi òróró onílọ́fínńdà pa ẹsẹ̀ mi. Fún ìdí yìí, mo sọ fún ọ, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀, a dárí wọn jì, nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ púpọ̀.” Kò sí tàbí ṣùgbọ́n pé irú ọ̀rọ̀ yìí fún obìnrin yìí níṣìírí ó sì mú kí ọkàn rẹ̀ fúyẹ́ gan-an.—Lúùkù 7:46, 47.
Kì í ṣe pé Jésù ń fi ojú kékeré wo ìwà pálapàla o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń kọ́ Farisí agbéraga yẹn pé ìfẹ́ ni olórí ohun tó ń sún èèyàn sin Ọlọ́run. (Mátíù 22:36-40) Ní tòótọ́, kò sóhun tó burú níbẹ̀ pé ẹ̀rí ọkàn obìnrin náà dá a lẹ́bi fún ìwà pálapàla tó ti hù sẹ́yìn. Àmọ́ ó hàn gbangba pé ó ti ronú pìwà dà nítorí pé ó sọkún, kò sì wí àwíjàre fún ìwà tí kò dáa tó ti hù sẹ́yìn, ó sì gbé ìgbésẹ̀ tó dára láti bọ̀wọ̀ fún Jésù ní gbangba. Èyí ni Jésù rí to fi sọ fún un pé: “Ìgbàgbọ́ rẹ ti gbà ọ́ là; máa bá ọ̀nà rẹ lọ ní àlàáfíà.”—Lúùkù 7:50.
Ní ti Farisí yẹn, ojú ẹlẹ́ṣẹ̀ ló ṣì fi ń wo obìnrin náà. Bóyá ó ń ronú pé òun á ‘jẹ́ kí obìnrin náà mọ̀ pé yóò jíhìn fún Ọlọ́run’ kó sì dójú tì í. Àmọ́, ìwà àìnífẹ̀ẹ́ ló jẹ́ béèyàn bá ń jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn àwọn èèyàn máa dà wọ́n láàmú nígbà gbogbo bí kò bá mọ́ wọn lára láti ṣe àwọn nǹkan lọ́nà tá a rò pé ó yẹ kí wọ́n gbà ṣe é, àbájáde rẹ̀ kì í sì í dára nígbẹ̀yìn. (2 Kọ́ríńtì 9:7) Títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù ló lè mú àbájáde tó dára jù lọ wá, ìyẹn ni pé kéèyàn máa fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀, kó máa fi tọkàntọkàn gbóríyìn fún àwọn èèyàn, kó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun gbọ́kàn lé wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà míì wà tí wọ́n máa nílò ìbáwí tàbí ìmọ̀ràn.—Mátíù 11:28-30; Róòmù 12:10; Éfésù 4:29.
Nítorí náà, ohun tó dára ni, ohun tó tiẹ̀ yẹ ni pàápàá pé kí ẹ̀rí ọkàn dá èèyàn lẹ́bi béèyàn bá ṣe ohun kan tó kù díẹ̀ káàtó. Òwe 14:9 (Bibeli Mimọ) sọ pé: “Aṣiwere nfi ẹbi-ẹ̀ṣẹ ṣẹsin.” Ẹ̀rí ọkàn tó ń dà wá láàmú á jẹ́ ká lè jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa ká sì ṣe àwọn ohun mìíràn tó yẹ ní ṣíṣe. Àmọ́ ṣá o, ìdí pàtàkì tá a fi ń sin Jèhófà gbọ́dọ̀ jẹ́ ìfẹ́, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹ̀bi. (Jóòbù 1:9-11; 2:4, 5) Bíbélì mú kó dá wa lójú pé tí èrò yìí bá ń fún àwọn èèyàn rere níṣìírí tó sì tù wọ́n nínú, wọ́n á lè ṣe gbogbo nǹkan tágbára wọn bá gbé. Èyí tó sì ṣe pàtàkì jù ni pé tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n á fi máa ṣe é.