Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Mo Bá Lọ Pàdé Ọmọ Iléèwé Mi Ńkọ́?

Bí Mo Bá Lọ Pàdé Ọmọ Iléèwé Mi Ńkọ́?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Bí Mo Bá Lọ Pàdé Ọmọ Iléèwé Mi Ńkọ́?

“Àtipadà síléèwé lọ́jọ́ Monday kì í rọgbọ fún mi rárá. Tí èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀rẹ́ mi bá ti rí mi níbi tí mo ti ń wàásù, mo ti mọ irọ́ mọ̀ràn-ìn-mọran-in tí mo máa ń pa. Bí àpẹẹrẹ, màá sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ mi pé ńṣe ni mò ń bá Ẹgbẹ́ Òṣìṣẹ́ Ìjọba gba owó kiri.”—James, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

“Yẹ̀yẹ́ làwọn tó bá rí mi máa ń lọ fi mí ṣe níléèwé. Nǹkan tí wọ́n ń fojú mi kàn kò kéré.”—Débora, Brazil.

KÍ LÓ mú kí ẹ̀rù pé àwọn lè pàdé àwọn ọ̀rẹ́ wọn máa ń ba àwọn ọ̀dọ́ yìí tó bẹ́ẹ̀? Ṣé nǹkan èèwọ̀ kan ni wọ́n ń ṣe ni? Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ tó dára jù lọ tó sì ṣe pàtàkì jù lọ láyé lónìí ni wọ́n mà ń ṣe o. Ìyẹn iṣẹ́ tí Jésù pa láṣẹ nígbà tó sọ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”—Mátíù 28:19, 20.

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ti fi hàn, ó lé ní ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́langba tó gba Ọlọ́run gbọ́. Nǹkan bí ìdajì lára wọn ló ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ṣọ́ọ̀ṣì, irú bí wíwà nínú ẹgbẹ́ akọrin, ìwọ̀nba díẹ̀ lára wọn ló máa ń bá àwọn ọmọ iléèwé wọn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run. Àmọ́ o, káàkiri ayé ni wọ́n mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún iṣẹ́ ìwàásù wọn láti ilé dé ilé. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ló sì ń kópa nínú iṣẹ́ yìí.

Bó o bá jẹ́ ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí, ó dájú pé ìwọ náà á ti máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù yìí. Àmọ́ èyí kò túmọ̀ sí pé ó rọrùn fún ẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bíi tàwọn ọ̀dọ́ tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀, ìrònú pé ọmọ iléèwé rẹ kan lè lọ jáde sí ẹ lẹ́nu ọ̀nà lè kó ọ lọ́kàn sókè. Ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ Jennie jẹ́wọ́ pé: “Ohun tí mo kórìíra jù lọ ni pé kí ọ̀kan lára àwọn ọmọléèwé mi rí mi kí n múra dáadáa, kí n wọ síkẹ́ẹ̀tì, kí n wá gbé àpò lọ́wọ́, kí ìmúra mi sì kọjá bí mo ṣe máa ń múra lọ síléèwé.”

Ẹ̀rù pé àwọn lè pàdé ọmọléèwé àwọn kan máa ń ba àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni kan débi pé, ńṣe ni wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í ta ọgbọ́nkọ́gbọ́n. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Leon sọ pé: “Mo mọ ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ pé aṣọ tó ṣeé fà bojú ló máa ń wọ̀ tó bá wà lóde ẹ̀rí, nítorí kó lè fà á bo ojú rẹ̀ tó bá ṣèèṣì bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ilé ìwé pàdé.” Síbẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ mìíràn kì í tiẹ̀ dé àwọn àdúgbò kan wàásù rárá. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Simon sọ pé: “Mo rántí pé mo máa ń gbàdúrà pé ká má lọ ṣiṣẹ́ láwọn àdúgbò kan, torí mo mọ̀ pé àwọn ọmọ iléèwé wa ló kún ibẹ̀.”

Kì í ṣohun tójú ò rí rí pé kí ìdààmú bá ọ díẹ̀ tó o bá ṣèèṣì pàdé ẹnì kan tó o mọ̀ níbi tó o ti ń wàásù. Àmọ́ o, ńṣe ni gbígba irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ láyè á wulẹ̀ ṣàkóbá fún ọ. Ọ̀dọ́ ọmọ ilẹ̀ Jámánì kan tó ń jẹ́ Alicia jẹ́wọ́ pé: “Iṣẹ́ ìwàásù máa ń kó mi nírìíra débi pé, ó kó bá ipò tẹ̀mí mi.”

Lákọ̀ọ́kọ́, kí ló dé tó o fi ní láti wàásù, pàápàá tí o ò bá gbádùn ṣíṣe bẹ́ẹ̀? Láti dáhùn, jẹ́ ká wo ìdí tí Ọlọ́run fi fi dandan lé e pé o gbọ́dọ̀ wàásù. Lẹ́yìn náà a óò wá fi hàn bó ṣe jẹ́ pé, pẹ̀lú ìsapá àti ìpinnu, o lè borí ìbẹ̀rù rẹ.

Àṣẹ Náà Láti Wàásù

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, tó o bá wò ó pé ṣíṣàlàyé ìgbàgbọ́ rẹ fún àwọn ẹlòmíràn kì í ṣe ohun tójú ò rí rí tàbí tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìyẹn lè ṣèrànwọ́. Àtìgbà láéláé làwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ohun táwọn èèyàn mọ Nóà mọ́ jù ni pé ó kan ọkọ̀ áàkì gìrìwò kan. (Jẹ́nẹ́sísì 6:14-16) Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí 2 Pétérù 2:5 ti sọ, ó tún jẹ́ “oníwàásù òdodo.” Nóà mọ̀ pé ó jẹ́ dandan kóun kìlọ̀ fún àwọn mìíràn nípa ewu tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí wọn.—Mátíù 24:37-39.

Lẹ́yìn ìgbà yẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò dìídì pàṣẹ fún àwọn Júù láti wàásù fún àwọn tí kì í ṣe Júù, ọ̀pọ̀ wọn ló sọ nípa ìgbàgbọ́ wọn fún àwọn mìíràn. Ìyẹn ló jẹ́ kí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè kan tó ń jẹ́ Rúùtù mọ̀ nípa Jèhófà. Rúùtù mọrírì ohun ti ìyá-ọkọ rẹ̀ Náómì, tí í ṣe Júù ṣe fún un, ó sì sọ fún un pé: “Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.” (Rúùtù 1:16) Nígbà tó tún yá, Sólómọ́nì Ọba sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Júù yóò wá gbọ́ nípa “orúkọ ńlá” Jèhófà wọn yóò sì wá jọ́sìn nínú tẹ́ńpìlì Rẹ̀.—1 Àwọn Ọba 8:41, 42.

Ó dára, tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yìí láyé ọjọ́un bá bá àwọn mìíràn sọ̀rọ̀ láìṣe pé àṣẹ kankan wà tó sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ò rí i pé ó yẹ kí àwọn Kristẹni ọjọ́ òní mú iṣẹ́ ìwàásù lọ́kùn-únkúndùn! Bẹ́ẹ̀ sì rèé, a pa á láṣẹ fún wa pé ká wàásù “ìhìn rere ìjọba yìí.” (Mátíù 24:14) A dà bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ti pé, a wà lábẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti wàásù ìhìn rere yìí. (1 Kọ́ríńtì 9:16) Ìgbàlà wa so mọ́ ọn. Róòmù 10:9, 10 sọ pé: “Bí ìwọ bá polongo ‘ọ̀rọ̀ yẹn tí ń bẹ ni ẹnu ìwọ alára’ ní gbangba, pé Jésù ni Olúwa, . . . a ó gbà ọ́ là. Nítorí ọkàn-àyà ni a fi ń lo ìgbàgbọ́ fún òdodo, ṣùgbọ́n ẹnu ni a fi ń ṣe ìpolongo ní gbangba fún ìgbàlà.”

Ibo lo ti lè ṣe “ìpolongo ní gbangba” yẹn? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wíwàásù lọ́nà tí kì í ṣe bí àṣà náà dára, iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà ṣì ni ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ láti dé ọ̀dọ̀ àwọn mìíràn. (Ìṣe 5:42; 20:20) Ṣé nítorí pé o jẹ́ ọmọdé, iṣẹ́ yẹn wá yọ ọ́ sílẹ̀? Rárá o. Bíbélì pa àṣẹ tó wà ní Sáàmù 148:12, 13 yìí pé: “Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin àti ẹ̀yin wúńdíá pẹ̀lú, ẹ̀yin arúgbó pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀yin ọmọdékùnrin. Kí wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà.”

Ìdí Tó Fi Ṣòro Láti Wàásù fún Ojúgbà Ẹni

Ká sòótọ́, ó lè máa tì ọ́ lójú tàbí kó jẹ́ ohun tí kò bá ọ lára mu pé kó o jáde lọ wàásù kó o sì pàdé ẹnì kan tó jẹ́ ọmọléèwé rẹ. Ó ṣe tán, kò sẹ́ni tí kò fẹ́ káwọn ẹlòmíràn gba tòun. Kò sẹ́ni tó fẹ́ kí wọ́n máa fi òun ṣẹ̀sín, kí wọ́n kẹ́gàn òun tàbí kí wọ́n máa bú òun. Bí ohun tí ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Tanya sọ pé, “àwọn ọmọ iléèwé lè fayé sú ọ!” Nítorí náà, o lè ti máa rò ó pé kí làwọn ọmọléèwé rẹ máa sọ ná bí wọ́n bá rí ẹ tó o múra dáadáa àmọ́ tó o wá gbé Bíbélì lọ́wọ́. Ó dunni láti sọ pé, ó ṣeé ṣe dáadáa pé yẹ̀yẹ́ ni wọ́n á máa fi ọ́ ṣe. Felipe tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Brazil sọ pé: “Ọmọkùnrin kan wà ní kíláàsì mi tá a jọ ń gbé ilé kan náà. Ńṣe lá máa sọ pé, ‘Ìwọ pẹ̀lú Bíbélì ẹ yìí ṣáá! Kí lo tiẹ̀ máa ń rí dì sínú àpò yẹn ná?’”

Fífini ṣe yẹ̀yẹ́ nírú ọ̀nà yìí kì í ṣe ohun ṣeréṣeré o. Bíbélì sọ fún wa pé Ísákì, ọmọkùnrin Ábúráhámù fojú winá ìfiniṣẹ̀sín tá a lè pè ní pípẹ̀gàn ẹni látọ̀dọ̀ Íṣímáẹ́lì tó jẹ́ ọbàkan rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 21:9) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kò fojú kékeré wo ìwàkiwà yìí. Àpọ́sítélì yìí sì tọ̀nà nígbà tó pè é ní “inúnibíni” nínú Gálátíà 4:29.

Bákan náà, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn kan á wà tí wọn kò ní nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn òun. Ó sọ pé: “Bí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé ó ti kórìíra mi kí ó tó kórìíra yín. Bí ẹ̀yin bá jẹ́ apá kan ayé, ayé yóò máa ní ìfẹ́ni fún ohun tí í ṣe tirẹ̀. Wàyí o, nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, ṣùgbọ́n mo ti yàn yín kúrò nínú ayé, ní tìtorí èyí ni ayé fi kórìíra yín.”—Jòhánù 15:18, 19.

Nítorí náà, bó o ti jẹ́ Kristẹni, ó yẹ kó o fi sọ́kàn pé wàá ní láti fara da inúnibíni díẹ̀. (2 Tímótì 3:12) Kódà ká tiẹ̀ ní o kò tíì bá àwọn ojúgbà rẹ sọ̀rọ̀ rí nípa Bíbélì, àwọn kan ṣì lè máa ṣe inúnibíni sí ọ kìkì nítorí pé ìwà rẹ dára gan-an tí o kì í sì í bá wọn lọ́wọ́ sí ìwàkiwà. (1 Pétérù 4:4) Bó ti wù kó rí, Jésù sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú yìí fún wa pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi.” (Mátíù 5:11) Báwo ni inú rẹ ṣe lè máa dùn bí wọ́n ti ń fi ẹ́ ṣẹ̀sín tàbí pẹ̀gàn rẹ? Nítorí o mọ̀ pé ò ń mú ọkàn Jèhófà Ọlọ́run yọ̀ ni! (Òwe 27:11) Bó o sì ṣe ń mú inú Ọlọ́run dùn, ńṣe lò ń fi hàn pé o fẹ́ ẹ́ gba èrè ìyè ayérayé!—Lúùkù 10:25-28.

A dúpẹ́ pé, kò lè jẹ́ gbogbo àwọn ọmọléèwé rẹ tàbí èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ló máa fi ọ́ ṣẹlẹ́yà nígbà tó o bá bá wọn pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ Angela sọ pé: “Tó o bá pàdé ọmọléèwé rẹ kan lẹ́nu ọ̀nà, ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn gan-an lara wọn ò ní balẹ̀ tó tìẹ!” Àní, ara àwọn kan tiẹ̀ lè ti wà lọ́nà pé kí lo fẹ́ sọ ná. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni ló ń ṣàṣeyọrí ńláǹlà nínú wíwàásù fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. Àpilẹ̀kọ tó máa tẹ̀ lé èyí nínú ọ̀wọ́ yìí yóò jíròrò àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí ìwọ náà lè gbà ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lẹ̀rù máa ń bà pé káwọn má lọ ṣe kòńgẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ àwọn kan lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Má ṣe jẹ́ kí ìfiṣẹ̀sín mú ọ tijú ìgbàgbọ́ rẹ láé