Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ Olùkọ́—Iṣẹ́ Tó Ń Tẹni Lọ́rùn Tó sì Ń Fúnni Láyọ̀

Iṣẹ́ Olùkọ́—Iṣẹ́ Tó Ń Tẹni Lọ́rùn Tó sì Ń Fúnni Láyọ̀

Iṣẹ́ Olùkọ́—Iṣẹ́ Tó Ń Tẹni Lọ́rùn Tó sì Ń Fúnni Láyọ̀

“Kí ló mú kí n ṣì máa ṣiṣẹ́ olùkọ́? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ olùkọ́ ṣòro tó sì máa ń tánni lókun, bí mo ṣe ń rí i tínú àwọn ọmọ ń dùn nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ àti bí mo ṣe ń rí i pé wọ́n ń tẹ̀ síwájú ni mo fi sọ pé mi ò ní fi iṣẹ́ náà sílẹ̀.”—Leemarys, iṣẹ́ olùkọ́ ló ń ṣe nílùú New York.

LÁÌKA àwọn ìpèníjà, ìdíwọ́ àti ọ̀pọ̀ ìjákulẹ̀ sí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùkọ́ kárí ayé ni wọ́n sọ pé àwọn ò ní fi iṣẹ́ yìí sílẹ̀. Àmọ́ kí ló mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa sapá kí wọ́n bàa lè di olùkọ́ nígbà tí wọ́n mọ̀ pé àwọn èèyàn lè má fi bẹ́ẹ̀ kà wọ́n sí nídìí iṣẹ́ náà? Kí ló mú kí wọ́n ṣì máa ṣiṣẹ́ yìí?

Inna, tó ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní Rọ́ṣíà sọ pé: “Inú èèyàn máa ń dùn tó bá rí i tí àwọn tó kọ́ nílé ìwé ti di géńdé, tí wọ́n sì ń sọ pé ohun tí olùkọ́ náà kọ́ àwọn wúlò gan-an ni. Ó máa ń wú èèyàn lórí táwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí bá sọ pé àwọn gbádùn àkókò tí olùkọ́ náà fi kọ́ àwọn gan-an ni.”

Giuliano, ìyẹn olùkọ́ tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú sọ pé: “Béèyàn bá mọ̀ pé ó ti ṣeé ṣe fún òun láti mú káwọn akẹ́kọ̀ọ́ nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ kan pàtó, ó jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó máa ń múnú èèyàn dùn jù lọ. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí mo sọ ìtàn kan tán, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: ‘Ẹ máà dánu dúró o. A fẹ́ gbọ́ sí i!’ Irú ọ̀rọ̀ báyìí tó wá látọkàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè mú kára èèyàn yá gágá tó bá wà níléèwé nítorí pé olúwarẹ̀ ti mú kínú àwọn èwe yìí dùn nípa sísọ ohun tí wọn ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ fún wọn. Inú èèyàn á dùn nígbà tó bá rí i táwọn ọmọ wọ̀nyí ń yọ̀ ṣìnkìn nítorí pé wọ́n ti lóye iṣẹ́ kan.”

Elena, tó ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní Ítálì sọ pé: “Ní tèmi o, àwọn ohun kéékèèké téèyàn ń ṣe lójoojúmọ́ àtàwọn àṣeyọrí kéékèèké táwọn akẹ́kọ̀ọ́ bá ṣe ló máa ń fún èèyàn ní ìtẹ́lọ́rùn, kì í ṣe àwọn nǹkan kàbìtì kàbìtì tó jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni wọ́n máa ń ṣẹlẹ̀.”

Ará Ọsirélíà ni Connie, ó ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún. Ó sọ pé: “Ó máa ń múnú èèyàn dùn gan-an nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ tẹ́ ẹ ti jọ mọwọ́ ara yín gan-an nígbà tó wà nílé ẹ̀kọ́ bá kọ lẹ́tà sí èèyàn, tó fi dúpẹ́ fún akitiyan téèyàn ṣe lórí rẹ̀.”

Bákan náà ló ṣe rí lára Oscar, ọmọ ìlú Mendoza, ní Ajẹntínà. Ó sọ pé: “Mo máa ń nímọ̀lára pé ẹni ẹ̀yẹ ni mí nígbà táwọn ọmọ tí mò ń kọ́ bá pàdé mi ní pópó tàbí níbòmíràn tí wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ mi fún àwọn nǹkan tí mo ti kọ́ wọn” Angel, tó wà nílùú Madrid ní Sípéènì sọ pé: “Ohun tó máa ń múnú mi dùn jù lọ ni pé bí mo ṣe fi apá kan ìgbésí ayé mi ṣe iṣẹ́ alárinrin tó sì tún ṣòro yìí, kí n rí àwọn tí mo kọ́ pé wọ́n di èèyàn àtàtà, tó sì jẹ́ pé akitiyan tí mo ṣe wà lára ohun tó mú kí wọ́n dà bẹ́ẹ̀.”

Leemarys tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lókè, sọ pé: “Ó dá mi lójú pé èèyàn àrà ọ̀tọ̀ làwọn olùkọ́ jẹ́. Èèyàn tó dà bíi wa, tó lè ṣe iṣẹ́ ńláǹlà báyìí ṣọ̀wọ́n. Àmọ́ bó o bá lè ṣe é, tó o tún ìgbésí ayé ọmọ bíi mẹ́wàá tàbí ẹyọ kan ṣoṣo pàápàá ṣe, iṣẹ́ ribiribi lo ṣe, ohun tó sì dára jù lọ nìyẹn. Tayọ̀tayọ̀ ni wàá máa fi ṣe iṣẹ́ rẹ.”

Ṣé O Ti Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Àwọn Olùkọ́ Rẹ?

Yálà o jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tàbí òbí, ǹjẹ́ o ti fìgbà kan rí dúpẹ́ lọ́wọ́ olùkọ́ kan pé ó ṣeun fún àkókò tó yọ̀ǹda, ìsapá tó ṣe àti ìfẹ́ tó fi hàn? Ǹjẹ́ o ti fi káàdì pélébé kan ránṣẹ́ sí i láti fi dúpẹ́ tàbí kó o kọ lẹ́tà ìdúpẹ́ sí i? Arthur, ní ìlú Nairobi ní Kẹ́ńyà sọ kókó pàtàkì kan pé: “Béèyàn bá yin àwọn olùkọ́, wọ́n túbọ̀ máa ń jára mọ́ṣẹ́. Ó yẹ kí ìjọba, àwọn òbí àti akẹ́kọ̀ọ́ máa gbóríyìn fún wọn àti iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe.”

LouAnne Johnson, tó jẹ́ òǹkọ̀wé àti olùkọ́ kọ ọ́ pé: “Tí mo bá fi gba lẹ́tà kan tó sọ pé olùkọ́ kan kò ṣe dáadáa, màá ti gba ọgọ́rùn-ún lẹ́tà tó ń yin àwọn olùkọ́, èyí sì fi hàn pé àwọn olùkọ́ tó dára pọ̀ gan-an ju àwọn tí kò dára lọ.” Àní, àwọn kan tiẹ̀ máa ń háyà àwọn èèyàn láti “bá wọn wá olùkọ́ kan tó ti kọ́ wọn nígbà kan rí. Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ láti wá àwọn olùkọ́ wọn rí kí wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn.”

Àwọn olùkọ́ ló máa ń pilẹ̀ ẹ̀kọ́ èèyàn, èyí sì ṣe pàtàkì gan-an. Kódà, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tí wọ́n mọ̀wé gan-an láwọn yunifásítì tó lókìkí ni kì bá má ti ṣeé ṣe fún láti débẹ̀ bí kì í bá ṣe ti àwọn olùkọ́ tó mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n ní ìmọ̀ kí wọ́n sì ní òye. Arthur, nílùú Nairobi sọ pé: “Àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn láwọn ilé iṣẹ́ ìjọba àti ti aládàáni ni àwọn olùkọ́ ti kọ́ ní àkókò kan nínú ìgbésí ayé wọn.”

Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn wọ̀nyí lọ́kùnrin lóbìnrin, tí wọ́n jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ sí ṣíṣe àwárí lóríṣiríṣi, tí wọ́n dé ọkàn wa tí wọ́n sì kọ́ wa ní ọ̀nà tá a lè gbà wá ìmọ̀ kún ìmọ̀ àti òye kún òye!

Ó mà yẹ ká dúpẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Olùkọ́ni Ńlá náà, Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó mí sí àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 2:1-6, tó sọ pé: “Ọmọ mi, bí ìwọ yóò bá gba àwọn àsọjáde mi, tí ìwọ yóò sì fi àwọn àṣẹ tèmi ṣúra sọ́dọ̀ rẹ, láti lè dẹ etí rẹ sí ọgbọ́n, kí o lè fi ọkàn-àyà rẹ sí ìfòyemọ̀; jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí o bá ké pe òye, tí o sì fọ ohùn rẹ jáde sí ìfòyemọ̀, bí o bá ń bá a nìṣó ní wíwá a bíi fàdákà, tí o sì ń bá a nìṣó ní wíwá a kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin, bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lóye ìbẹ̀rù Jèhófà, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an. Nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n; láti ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.”

Kíyè sí ọ̀rọ̀ náà “bí” tó fara hàn nígbà mẹ́ta nínú ẹsẹ tó ń múni ronú jinlẹ̀ yìí. Ronú nípa rẹ̀ ná, bí a bá ṣe tán láti ṣe àwọn ohun tó yẹ ká ṣe, a ó “rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an”! Ó dájú pé ìyẹn ni ẹ̀kọ́ tó ju gbogbo ẹ̀kọ́ lọ.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]

Ìyá Kan Tí Ayọ̀ Rẹ̀ Kún

Olùkọ́ kan ní ìlú New York rí lẹ́tà tó wà nísàlẹ̀ yìí gbà:

“Mo ń fi tọkàntọkàn dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún ohun tó o ti ṣe fún àwọn ọmọ mi. Bó o ṣe bójú tó wọn, tó o fi inú rere àti òye tó o ní bá wọn lò ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbé àwọn ohun rere kan ṣe tó dá mi lójú pé bí kì í bá ṣe ìwọ ni kò ní ṣeé ṣe. O ti mú kí n lè fi àwọn ọmọ mi yangàn, mi ò sì jẹ́ gbàgbé rẹ̀ láé. Tìrẹ ní tòótọ́, S. B.”

Ṣé o mọ olùkọ́ kan tó o lè fún níṣìírí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

‘Inú èèyàn náà á dùn nígbà tó bá rí i táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń yọ̀ ṣìnkìn nítorí pé wọ́n ti lóye ohun kan.’—GIULIANO, ÍTÁLÌ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

‘Ó máa ń múnú èèyàn dùn gan-an nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ bá kọ lẹ́tà ìdúpẹ́ sí èèyàn.’—CONNIE, ỌSIRÉLÍÀ