Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ Olùkọ́—Ohun Tó Ń Náni Àtàwọn Ewu Tó Wà Ńbẹ̀

Iṣẹ́ Olùkọ́—Ohun Tó Ń Náni Àtàwọn Ewu Tó Wà Ńbẹ̀

Iṣẹ́ Olùkọ́—Ohun Tó Ń Náni Àtàwọn Ewu Tó Wà Ńbẹ̀

“Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn èèyàn fẹ́ káwọn olùkọ́ máa ṣe, bẹ́ẹ̀ sì rèé àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ . . . gbóríyìn fún àwọn olùkọ́ tó ń ṣiṣẹ́ wọn bí iṣẹ́ láwọn ilé ẹ̀kọ́ wa.”—Ken Eltis, Yunifásítì Sydney, ní Ọsirélíà.

A KÒ gbọ́dọ̀ jiyàn rẹ̀ pé iṣẹ́ tí wọ́n pè ní “iṣẹ́ tó dára jù lọ” yìí ń kojú onírúurú ìṣòro. Látorí owó oṣù tí kò tó nǹkan dórí iyàrá ìkàwé tí kò dára tó; látorí ìwé àkọọ̀kọtán dórí àpọ̀jù akẹ́kọ̀ọ́ nínú kíláàsì; àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí kì í bọ̀wọ̀ fún olùkọ́ tí wọ́n sì máa ń hùwà ipá, tí àwọn òbí náà yóò sì máa hùwà kò-kàn-mí. Báwo làwọn olùkọ́ kan ṣe kojú àwọn ìṣòro wọ̀nyí?

Àìbọ̀wọ̀fúnni

A béèrè lọ́wọ́ àwọn olùkọ́ mẹ́rin nílùú New York pé kí lohun tí wọ́n rò pé ó jẹ́ olórí ìṣòro nílé ẹ̀kọ́. Párá táwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin máa dáhùn, wọ́n ní: “Àìbọ̀wọ̀fúnni ni.”

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí William ọmọ Kẹ́ńyà sọ, ọ̀rọ̀ ò rí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ ní Áfíríkà pàápàá tó bá di ọ̀ràn bíbọ̀wọ̀ fúnni. Ó sọ pé: “Àwọn ọmọ kò lẹ́kọ̀ọ́ ilé bí i ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Nígbà tí mo wà léwe [ó ti lé lẹ́ni ogójì ọdún báyìí], àwọn olùkọ́ wà lára àwọn táwọn èèyàn ń wárí fún jù lọ ní ilẹ̀ Áfíríkà. Tọmọdé tàgbà ló máa ń ka àwọn olùkọ́ sí ẹni téèyàn ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Àmọ́ ọ̀wọ̀ yìí kò dà bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Àṣà àwọn aláwọ̀ funfun ló kù táwọn èwe wa ń kó, kódà láwọn ìgbèríko Áfíríkà. Sinimá, fídíò àtàwọn ìwé ti sọ àìbọ̀wọ̀ fún àṣẹ di ohun tó wuyì.”

Giuliano, tó ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní Ítálì kédàárò pé: “Ẹ̀mí ọ̀tẹ̀, ẹ̀mí agídí àti ìwà àìgbọràn ti ran àwọn ọmọ, àwọn ìwà wọ̀nyí ló sì ń jà ràn-ìn láwùjọ.”

Oògùn Olóró àti Ìwà Ipá

Ó bani nínú jẹ́ pé oògùn olóró ti di ìṣòro láwọn ilé ẹ̀kọ́, ìṣòro náà sì ga débi tí LouAnne Johnson tó jẹ́ olùkọ́ àti òǹkọ̀wé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fi kọ̀wé pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ilé ẹ̀kọ́ ló ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nípa kíkáwọ́ oògùn olóró, bẹ̀rẹ̀ láti iléèwé jẹ́lé-ó-sinmi. [Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.] Àwọn ọmọdé mọ̀ nípa oògùn olóró . . . ju àwọn àgbàlagbà lọ.” Ó tún sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn ò dára wọn lójú, tó dà bí ẹni pé àwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ wọn, tí wọ́n nìkan wà, tí nǹkan ń sú tàbí tó dà bí ẹni pé wọn ò láàbò bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró.”—Two Parts Textbook, One Part Love.

Ken, tó ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní Ọsirélíà béèrè pé: “Báwo làwọn olùkọ́ wa ṣe máa kọ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án tó jẹ́ pé àwọn òbí rẹ̀ gan-an ló kọ́ ọ ní bí wọ́n ṣe ń lo oògùn olóró, tóun náà sì ti wá di ìjìmì sínú rẹ̀?” Michael ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún, ilé ẹ̀kọ́ gíga kan ní Jámánì ló ti ń ṣiṣẹ́ olùkọ́. Ó kọ ọ́ pé: “Ní ti ọ̀ràn oògùn olóró, à mọ̀ dáadáa pé ó wà ní ilé ìwé; àmọ́ ó ṣòro láti rí wọn.” Ó tún sọ̀rọ̀ lórí ìwà àìgbọ́ràn, ó sì sọ pé òun ni ohun “tó ń mú káwọn akẹ́kọ̀ọ́ fẹ́ràn láti máa bá gbogbo nǹkan jẹ́.” Ó fi kún un pé: “Wọ́n ti dọ̀tí àwọn tábìlì àti ògiri, wọ́n sì ti ba àwọn àga jẹ́. Àwọn ọlọ́pàá ti mú lára àwọn ọmọ tí mò ń kọ́ nítorí pé wọ́n lọ ṣàfọwọ́rá nílé ìtajà tàbí àwọn nǹkan mìíràn tó jọ èyí. Abájọ tí ìwà gbéwiri fi wọ́pọ̀ nílé ẹ̀kọ́!”

Ìpínlẹ̀ Guanajuato, ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ni Amira ti ń ṣiṣẹ́ olùkọ́. Ó sọ pé: “À ń kojú ìṣòro ìwà ipá àti lílo oògùn olóró nínú ìdílé, èyí sì ń nípa lórí àwọn ọmọ. Àyíká tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ rírùn àtàwọn ìwà abèṣe lóríṣiríṣi ni wọ́n wà, èyí sì ń nípa lórí wọn. Ìṣòro ńlá mìíràn tún ni ipò òṣì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ wà níbí, àwọn òbí ṣì ní láti ra ìwé, kí wọ́n ra bírò àtàwọn nǹkan èèlò mìíràn. Àmọ́ oúnjẹ làkọ́kọ́.”

Tìbọn Ti Jẹ́ Nílé Ẹ̀kọ́?

Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìbọn yíyìn láwọn ilé ẹ̀kọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí ti fi hàn pé ìwà ipá tó jẹ mọ́ ti ìbọn ti kúrò lọ́ràn kékeré ní orílẹ̀-èdè náà. Ìròyìn kan sọ pé: “Wọ́n fojú bù ú pé ọ̀kẹ́ mẹ́fà ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [135,000] ìbọn ni wọ́n ń kó wọ àwọn ilé ìwé ìjọba tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún ó lé márùnlélọ́gọ́fà [87,125] tó wà lórílẹ̀ èdè náà lójoojúmọ́. Nítorí àtidín iye ìbọn táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń kó wọ ilé ìwé kù làwọn aláṣẹ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn ohun èèlò tó ń ṣàwárí nǹkan tó bá ní mẹ́táàlì, àwọn kámẹ́rà tó ń ṣọ́ àyíká, àwọn ajá tí wọ́n dìídì kọ́ láti mọ ibi tí ìbọn wà, wọ́n tún máa ń yẹ àpótí táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń kówèé wọn sí wò, wọ́n ń lo káàdì ìdánimọ̀, wọ́n sì ṣòfin pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ò gbọ́dọ̀ fi báàgì kó ìwé wọn wá sílé ẹ̀kọ́.” (Teaching in America) Àwọn ìgbésẹ̀ yìí tó jẹ́ nítorí ààbò mú kéèyàn béèrè pé, Ṣé ilé ẹ̀kọ́ là ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni àbí ọgbà ẹ̀wọ̀n? Ìròyìn ọ̀hún fi kún un pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ti lé dà nù nítorí pé wọ́n mú ìbọn wá sílé ẹ̀kọ́ ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà!

Iris, tó jẹ́ olùkọ́ ní ìlú New York sọ fún Jí! pé: “Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń fọgbọọgbọ́n mú nǹkan ìjà wọ ilé ẹ̀kọ́. Àwọn ohun èèlò tó ń ṣàwárí nǹkan tó bá ní mẹ́táàlì kò sì lè kápá àwọn nǹkan ìjà náà. Ìwà bàsèjẹ́ nílé ẹ̀kọ́ tún jẹ́ ìṣòro mìíràn.

Pẹ̀lú gbogbo yánpọnyánrin yìí, àwọn olùkọ́ tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ ṣì ń sapá láti kọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ àti ìwà tó dáa. Abájọ tí ọ̀pọ̀ àwọn olùkọ́ fi máa ń soríkọ́ tí gbogbo nǹkan sì máa ń sú wọn. Rolf Busch, tó jẹ́ ọ̀gá àgbà Ẹgbẹ́ Àwọn Olùkọ́ nílùú Thuringia, ní Jámánì sọ pé: “Nǹkan bí ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn olùkọ́ ní Jámánì ló ń ṣàìsàn nítorí másùnmáwo tó bá wọn. Iṣẹ́ náà ti sú wọn pátápátá.”

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Tó Ń Bímọ

Olórí ìṣòro mìíràn tún ni ìwà ìbálòpọ̀ láàárín àwọn èwe. George S. Morrison, tó kọ ìwé Teaching in America sọ nípa orílẹ̀-èdè náà pé: “Nǹkan bíi mílíọ̀nù kan àwọn ọmọ tí kò tíì pé ogún ọdún (ìdá mọ́kànlá nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mọ́kàndínlógún) ló ń gboyún lọ́dọọdún.” Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà làwọn ọ̀dọ́langba ti ń gboyún jù lọ nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà.

Iris gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, ó sọ pé: “Gbogbo nǹkan táwọn ọ̀dọ́langba ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ kò ju ìbálòpọ̀ àti lílọ sóde àríyá lọ. Wọ́n ti fi ba ara wọn jẹ́. Íńtánẹ́ẹ̀tì sì ti tún wà lórí àwọn kọ̀ǹpútà tó wà níléèwé báyìí! Ìyẹn á tún fún wọn láyè láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì wọ́n á sì lè wo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè.” Angel, tó wà nílùú Madrid ní Sípéènì sọ pé: “Ìwà pálapàla takọtabo ń wáyé láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dáadáa. A ti rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tọ́jọ́ orí wọn ṣì kéré gan-an tí wọ́n lóyún.”

“Àwọn Tó Ń Tọ́jú Ọmọdé”

Àròyé mìíràn táwọn olùkọ́ kan máa ń ṣe ni pé ọ̀pọ̀ òbí ni kì í ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nílé. Àwọn olùkọ́ ronú pé àwọn òbí ló yẹ kó kọ́kọ́ kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ilé sì la ti ń kó ẹ̀ṣọ́ ròde. Èyí ló mú kí Sandra Feldman, tó jẹ́ ààrẹ Ẹgbẹ́ Àpapọ̀ Àwọn Olùkọ́ ní Amẹ́ríkà sọ pé “ojú táwọn . . . èèyàn fi ń wo àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ mìíràn ló yẹ kí wọ́n máa fi wo àwọn olùkọ́, kì í ṣe pé kí wọ́n kàn máa wò wọ́n bí àwọn tó ń tọ́jú ọmọdé.”

Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn òbí kì í fara mọ́ ìbáwí táwọn olùkọ́ ń fún àwọn ọmọ nílé ìwé. Leemarys, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí sọ fún Jí! pé: “Tó o bá lọ sọ̀rọ̀ àwọn ọmọ tó ya pòkíì fún ọ̀gá ilé ìwé pẹ́nrẹ́n, ohun tó o kàn máa rí ni pé àwọn òbí ọmọ náà á wá gbógun tì ọ́!” Busch, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ọwọ́ tí wọ́n fi ń mú àwọn oníyọnu ọmọ: “Àwọn òbí kì í tọ́ ọmọ wọn dáadáa mọ́. O ò lè sọ mọ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ló wá láti ilé rere, tí wọ́n sì tọ́ wọn dáadáa.” Estela tó wá láti ìlú Mendoza ní orílẹ̀-èdè Ajẹntínà, sọ pé: “Ẹ̀rù àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń ba àwa olùkọ́. Bá a bá fún wọn ní ipò tó rẹ̀yìn díẹ̀, òkò ni wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í sọ lù wá tí wọ́n á sì gbógun tì wá. Bá a bá ní ọkọ̀ pẹ́nrẹ́n, wọ́n á bà á jẹ́.”

Ǹjẹ́ nǹkan bàbàrà ni pé àwọn orílẹ̀-èdè kan wà tí kò ti sí àwọn olùkọ́ tó tó? Vartan Gregorian, tó jẹ́ ààrẹ Ẹgbẹ́ Carnegie ti ìlú New York, sọ pé: “Àwọn ilé ẹ̀kọ́ wa [Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà] máa nílò tó mílíọ̀nù méjì àtààbọ̀ olùkọ́ ní ẹ̀wádún tó ń bọ̀.” Àwọn ìlú ńlá kan lórílẹ̀-èdè náà “ń wá àwọn olùkọ́ lójú méjèèjì láti ilẹ̀ Íńdíà, West Indies, Gúúsù Áfíríkà, Yúróòpù àtàwọn ibòmíràn tí wọ́n ti lè rí àwọn olùkọ́ tó dáńgájíá.” Èyí sì lè mú káwọn àgbègbè tí wọ́n ti ń wá olùkọ́ yìí máà ní olùkọ́ tó pọ̀ tó bó bá yá.

Kí Ló Dé Táwọn Olùkọ́ Ò Fi Pọ̀ Tó?

Yoshinori, ọmọ ilẹ̀ Japan tó ti ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ fún ọdún méjìlélọ́gbọ̀n sọ pé “iṣẹ́ tó gbayì tó gbẹ̀yẹ ni iṣẹ́ olùkọ́ ní Japan, wọ́n máa ń ṣe kóríyá fáwọn tó ń ṣe é wọ́n sì tún máa ń wárí fún wọn.” Àmọ́ ó ṣe, ibi gbogbo kọ́ ni wọ́n ti ń ṣe báyìí. Gregorian, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lókè tún sọ nípa àwọn olùkọ́ pé àwọn èèyàn “kì í bọ̀wọ̀ fún wọn, wọn kì í kà wọ́n sí tàbí fún wọn láwọn àjẹmọ́nú tó tọ́ sí wọn. . . . Iṣẹ́ olùkọ́ ni owó rẹ̀ kéré jù lọ nínú gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ń fi oyè yunifásítì ṣe ní ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ [ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà].”

Ken Eltis, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ kọ ọ́ pé: “Kí ló máa ṣẹlẹ̀ táwọn olùkọ́ bá mọ̀ pé owó táwọn tí ò kàwé tó àwọn ń gbà níbi àwọn iṣẹ́ kan pọ̀ ju tàwọn lọ? Tàbí tí wọ́n bá mọ̀ pé àwọn ọmọ tí wọ́n kọ́ ní oṣù méjìlá sẹ́yìn . . . ti bẹ̀rẹ̀ sí í gba owó tó ju èyí tí àwọn ń gbà lọ tàbí tó tiẹ̀ ju iye táwọn máa gbà ní odidi ọdún márùn-ún sí àkókò yìí? Ó dájú pé irú nǹkan báyìí máa ń mú káwọn olùkọ́ lérò pé àwọn ò tiẹ̀ níyì eléépìnnì.”

William Ayers kọ ọ́ pé: “Wọn kì í sanwó tó jọjú fáwọn olùkọ́ . . . Ní ìpíndọ́gba, ìdámẹ́rin owó táwọn amòfin ń gbà ni wọ́n ń fún wa, ìlàjì iye táwọn olùṣírò owó ń gbà, kò sì tó iye táwọn tó ń wa ọkọ̀ akẹ́rù àtàwọn tó ń ṣe ọkọ̀ òkun ń gbà. . . . Kò sí iṣẹ́ mìíràn tó la wàhálà púpọ̀ lọ bí iṣẹ́ olùkọ́ tó sì jẹ́ pé owó táṣẹ́rẹ́ ni wọ́n ń san fáwọn tó ń ṣe é.” (To Teach—The Journey of a Teacher) Lórí ọ̀rọ̀ yìí kan náà, Janet Reno, tó jẹ́ amòfin àgbà tẹ́lẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ ní November 2000 pé: “A ń rán àwọn èèyàn lọ sínú òṣùpá. . . . Owó tàbùà tabua là ń san fáwọn eléré ìdárayá wa. Kí wá ló dé tá ò lè sanwó tó jọjú fáwọn olùkọ́ wa?”

Leemarys sọ pé: “Gbogbo àwọn olùkọ́ ni owó tí wọ́n ń gbà kò tó bó ṣe yẹ. Pẹ̀lú gbogbo ọdún tí mo fi kàwé, gbogbo owó tí mò ń gbà lọ́dún kò tó nǹkan, tó sì tún jẹ́ ìlú New York ni mò ń gbé pẹ̀lú másùnmáwo àti wàhálà tó máa ń wà ní ìlú ńlá yìí.” Olùkọ́ kan nílùú St. Petersburg, ní Rọ́ṣíà, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Valentina sọ pé: “Tá a bá wo iye tí wọ́n ń san fáwọn olùkọ́, kò fi hàn pé àwọn èèyàn mọyì iṣẹ́ olùkọ́ rárá. Owó tí wọ́n ń san fún wọn kì í tó iye tí àwọn tówó oṣù wọn kéré jù lọ ń gbà.” Bákan náà lọ́rọ̀ ṣe rí lára Marlene, ọmọ ìlú Chubut ní Ajẹntínà. Ó sọ pé: “Owó oṣù tí kò tó nǹkan tá à ń gbà ló jẹ́ ká máa ṣiṣẹ́ níbi méjì tàbí mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àá wá máa sáré láti ibì kan sí ibòmíràn. Eléyìí kì í jẹ́ ká lè ṣiṣẹ́ wa bó ṣe yẹ.” Ọmọ ìlú Kẹ́ńyà ní Nairobi ni Arthur, iṣẹ́ olùkọ́ ló ń ṣe. Ó sọ fún Jí! pé: “Bí ètò ọrọ̀ ajé ṣe ń dẹnu kọlẹ̀ yìí, ìgbésí ayé mi ò rọrùn rárá pẹ̀lú iṣẹ́ olùkọ́ tí mò ń ṣe. Àwọn ẹlẹgbẹ́ mi lè jẹ́rìí sí i pé owó oṣù tí kò tó nǹkan tí wọ́n ń san fún wa ni kò jẹ́ káwọn èèyàn fẹ́ ṣe iṣẹ́ olùkọ́.”

Diana, ọmọ ìlú New York tó ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ ṣàròyé nípa iṣẹ́ orí bébà tó máa ń gba àkókò olùkọ́ gan-an. Olùkọ́ mìíràn kọ ọ́ pé, àròyé kan tó wọ́pọ̀ ni pé: “Iṣẹ́ orí bébà ti pọ̀ jù, olúwarẹ̀ á bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ lórí àwọn fọ́ọ̀mù lóríṣiríṣi, títí ọjọ́ á fi lọ.”

Àwọn Olùkọ́ Ò Tó, Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Pọ̀ Jù

Berthold, ọmọ ìlú Düren ní Jámánì sọ nípa àròyé mìíràn tó wọ́pọ̀: “Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti pọ̀ jù! Àwọn kíláàsì mìíràn níbí ní tó akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n. Èyí túmọ̀ sí pé a ò ní lè bójú tó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá níṣòro. Kò sẹ́ni tó máa mọ̀. Kò sẹ́ni tó máa bójú tó ìṣòro tí ọmọ kọ̀ọ̀kan ní.”

Leemarys, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lókè sọ pé: “Lọ́dún tó kọjá, ìṣòro mìíràn tí mo ní yàtọ̀ sí ti àwọn òbí tí wọn kì í bójú tó ọmọ wọn ni pé àwọn ọmọ márùnlélọ́gbọ̀n ló wà ní kíláàsì mi. Fojú inú wo bó ṣe máa rí, kéèyàn ní òun fẹ́ bójú tó àwọn ọmọ márùnlélọ́gbọ̀n tí wọ́n jẹ́ kìkìdá ọmọ ọlọ́dún mẹ́fà!”

Iris sọ pé: “Kò sí àwọn olùkọ́ tó pọ̀ tó nílùú New York níbí, àgàgà àwọn olùkọ́ ìṣirò àti ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì. Wọ́n lè rí iṣẹ́ tówó rẹ̀ pọ̀ níbòmíràn. Ni àwọn aráàlú bá lọ gba àwọn olùkọ́ tí wọn jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn.”

Kò sẹ́ni tí ò mọ̀ pé iṣẹ́ tó ní ọ̀pọ̀ wàhálà ni iṣẹ́ olùkọ́. Nígbà náà, kí ló mú káwọn olùkọ́ ṣì máa ṣe iṣẹ́ náà? Kí ló mú kí wọ́n máa bá a lọ kí wọ́n sì máa fara dà á? Àpilẹ̀kọ wa tó gbẹ̀yìn máa dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

Wọ́n fojú bù ú pé ọ̀kẹ́ mẹ́fà ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [135,000] ìbọn ni wọ́n ń kó wọ àwọn ilé ìwé tó wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lójoojúmọ́

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Kí Ló Ń Mú Kí Ẹnì Kan Jẹ́ Olùkọ́ Tó Múná Dóko?

Báwo lo ṣe máa ṣàpèjúwe olùkọ́ tó ń ṣiṣẹ́ rẹ̀ bí iṣẹ́? Ṣé ẹni tó bá lè mú kí ọmọ kan há àwọn ohun kan sórí kó sì yege nínú ìdánwò ni? Tàbí ẹnì kan tó ń kọ́ ọmọ láti béèrè ìbéèrè, kó sì ronú jinlẹ̀? Tàbí ẹnì kan tó tún ń ran ọmọ lọ́wọ́ láti di èèyàn àtàtà?

“Ìgbà táwa olùkọ́ bá mọ̀ pé ńṣe là ń ṣìkejì àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa nínú ìrìn àjò ìgbésí ayé tó gùn tó sì ṣòro, tá a bẹ̀rẹ̀ sí fún wọn ní iyì àti ọ̀wọ̀ tó tọ́ sí wọn bí ẹ̀dá ènìyàn, ìgbà náà la máa tó di olùkọ́ tó múná dóko. Àmọ́, bó ṣe rọrùn náà ló ṣe ṣòro o.”—To Teach—The Journey of a Teacher.

Olùkọ́ tó múná dóko máa ń mọ àwọn ànímọ́ rere tí akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan ní àti ọ̀nà tóun lè gbà mú kí akẹ́kọ̀ọ́ náà lo ànímọ́ yìí lọ́nà tó dára. William Ayers sọ pé: “A ní láti wá ọ̀nà tó túbọ̀ gbéṣẹ́, ọ̀nà tá a fi máa kọ́ àwọn ọmọ níbi tí okun wọn, ìrírí wọn, òye wọn àti agbára wọn mọ . . . Ó mú mi rántí ohun tí ìyá kan tó jẹ́ ará Àmẹ́ríńdíà sọ, táwọn èèyàn ti sọ pé ọmọkùnrin rẹ̀ ọlọ́dún márùn-ún ‘kò mọ̀wé,’ ó sọ pé: ‘Wind-Wolf mọ orúkọ àwọn ẹyẹ tó lé ní ogójì ó sì mọ bí wọ́n ṣe ń ṣí kiri. Ó mọ̀ pé ìyẹ́ mẹ́tàlá ló wà nídìí ẹyẹ idì tára rẹ̀ pé. Gbogbo ohun tọ́mọ yìí nílò ni olùkọ́ tó lóye ibi tágbára rẹ̀ mọ.’”

Kí olùkọ́ tó lè kọ́ ọmọ lọ́nà tó múná dóko, ó gbọ́dọ̀ mọ ohun tí ọmọ náà nífẹ̀ẹ́ sí àti ohun tó ń mú kí ọmọ náà ronú tàbí hùwà lọ́nà kan pàtó. Olùkọ́ tó múṣẹ́ rẹ̀ lọ́kùn-únkúndùn sì gbọ́dọ̀ fẹ́ràn àwọn ọmọdé.

[Credit Line]

Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè/Fọ́tọ̀ tí Saw Lwin yà

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]

Ṣé Gbogbo Ìgbà Ló Yẹ Kí Ẹ̀kọ́ Kíkọ́ Jẹ́ Àwàdà?

William Ayers tó jẹ́ olùkọ́ ṣàkọsílẹ̀ èrò mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí kò tọ̀nà táwọn èèyàn ń ní nípa iṣẹ́ olùkọ́. Ọ̀kan lára wọn ni pé: “Àwọn olùkọ́ tó múná dóko máa ń mú kí ẹ̀kọ́ kíkọ́ dà bí ìgbà téèyàn ń ṣàwàdà.” Ó sọ síwájú pé: “Àwàdà ṣíṣe kì í jẹ́ kéèyàn lè pọkàn pọ̀, èèyàn á kàn máa rẹ́rìn-ín ni. Ẹ̀rín àrínlamilójú làwọn aláwàdà máa ń dá pa èèyàn. Àpárá wọn sì máa ń múni rẹ́rìn-ín àríntàkìtì. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ńṣe ló yẹ kí ẹ̀kọ́ kíkọ́ mú kéèyàn ronú, kóhun téèyàn kọ́ wọnú ọkàn rẹ̀, kó mú kéèyàn kọ háà pé tuntun tún lèyí, kó kọ́kọ́ dà bí àdììtú séèyàn, kéèyàn sì gbádùn rẹ̀. Tí ẹ̀kọ́ kíkọ́ bá jẹ́ àwàdà, kì í ṣe pé ó burú náà. Àmọ́ kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀.” Ó tún sọ pé: “Kíkọ́ni ń béèrè pé kéèyàn ní ìmọ̀ nípa onírúurú nǹkan kó sì lágbára láti ṣe é, kéèyàn ní ìfòyemọ̀ kó sì lóye, borí gbogbo rẹ̀, ó ń béèrè pé kéèyàn ronú jinlẹ̀ kó sì lè ṣaájò àwọn ẹlòmíràn.”—To Teach—The Journey of a Teacher.

Sumio tó wà nílùú Nagoya ní Japan sọ pé ìṣòro tóun kíyè sí láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ òun ni pé: “Kò sóhun tó dùn mọ́ ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama ju kí wọ́n máa ṣe àwàdà lọ àti ohun tí kò gba agbára.”

Rosa, tó máa ń fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nímọ̀ràn nílùú Brooklyn, New York, sọ pé: “Ohun tó wà lọ́kàn gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni pé ẹ̀kọ́ kíkọ́ máa ń súni. Pé olùkọ́ gan-an kì í ṣàwàdà. Èrò wọn ni pé ó yẹ kí gbogbo nǹkan jẹ́ kìkì àwàdà. Wọn ò mọ̀ pé bí ìsapá téèyàn bá ṣe láti kẹ́kọ̀ọ́ bá ṣe pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ náà ni àǹfààní téèyàn á jẹ níbẹ̀ á ṣe pọ̀ tó.”

Àwàdà ṣáá táwọn èwe máa ń ṣe kò jẹ́ kó rọrùn fún wọn mọ́ láti sapá gan-an kí wọ́n sì yááfì àwọn ohun kan. Sumio, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lókè sọ pé: “Ohun tó wà nídìí ọ̀rọ̀ yìí ni pé wọn ò lè ronú nípa ọjọ́ iwájú. Ìwọ̀nba díẹ̀ làwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ girama tó máa ń ronú pé táwọn bá ṣiṣẹ́ kára fún nǹkan lónìí, àwọn máa jèrè rẹ̀ lọ́la.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

DIANA, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

‘Wọ́n ń lo oògùn olóró káàkiri àmọ́ ó ṣòro láti rí wọn gbá mú.’—MICHAEL, JÁMÁNÌ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

“À ń kojú ìṣòro ìwà ipá àti lílo oògùn olóró nínú ìdílé.”—AMIRA, MẸ́SÍKÒ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

“Ojú táwọn . . . èèyàn fi ń wo àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ mìíràn ló yẹ kí wọ́n máa fi wo àwọn olùkọ́, kì í ṣe pé kí wọ́n kàn máa wò wọ́n bí àwọn tó ń tọ́jú ọmọdé.” —SANDRA FELDMAN, ÀÀRẸ ẸGBẸ́ ÀPAPỌ̀ ÀWỌN OLÙKỌ́ NÍ AMẸ́RÍKÀ