Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ipò Tó Yẹ Ká Fi Iṣẹ́ Sí

Ipò Tó Yẹ Ká Fi Iṣẹ́ Sí

Ipò Tó Yẹ Ká Fi Iṣẹ́ Sí

ÒṢÌṢẸ́ ológun kan ṣiṣẹ́, ṣiṣẹ́ débi pé kò ráyè fún ìsinmi ọ̀sán, kó bàa lè parí iṣẹ́ tí ọ̀gá rẹ̀ nílò ní kánjúkánjú. Nígbà tí àwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ padà dé láti ibi tí wọ́n ti lọ jẹun ọ̀sán, wọ́n rí i tó dojú délẹ̀ sórí iṣẹ́ tó ń ṣe lọ́wọ́ lórí tábìlì rẹ̀—ó ti kú fin-ín-fin-ín.

Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nígbà tí ọ̀gá wọn pátápátá fóònù ní èyí tí kò pé wákàtí méjì lẹ́yìn náà tó sì sọ pé: “Ó dùn mi gan-an fún———, àmọ́ ẹ gbọ́dọ̀ fi ẹlòmíràn rọ́pò rẹ̀ fún mi láàárọ̀ ọ̀la!” Gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ló ń ṣe háà pé, Ṣé pé gbogbo ìwúlò òṣìṣẹ́ yìí lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ kò kọjá iṣẹ́ tó ń ṣe fún-un?

Ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lóòótọ́ yìí jẹ́ ká rí kókó kan—pé lọ́pọ̀ ìgbà, ohun kan ṣoṣo tí wọ́n máa ń fi díwọ̀n bí ẹnì kan ṣe ṣe pàtàkì tó ni bó ṣe wúlò fún agbanisíṣẹ́ rẹ̀ tó. Èyí lè wá sún ẹnì kan láti béèrè pé: Ṣé torí iṣẹ́ nìkan ni mo ṣe wà láàyè, àbí torí kí n lè bójú tó ara mi ni mo ṣe ń ṣiṣẹ́? Àwọn nǹkan wo nínú ìgbésí ayé mi ni mò ń yááfì nítorí iṣẹ́ tí mò ń ṣe?

Ṣíṣe Ìpinnu Tó Bọ́gbọ́n Mu

Méjì lára ohun táwọn kan kà sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé náà ni wọ́n sábà máa ń fi ìwàǹwára pinnu rẹ̀, ìyẹn yíyan ẹni téèyàn máa fẹ́ àti iṣẹ́ téèyàn máa ṣe. Nígbà kan, ohun tó gbọ́dọ̀ wà títí lọ làwọn èèyàn ka iṣẹ́ àti ìgbéyàwó sí. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń fara balẹ̀ dáadáa kí wọ́n tóó yan èyíkéyìí nínú méjèèjì. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n á gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn tó jù wọ́n lọ tàbí lọ́dọ̀ àwọn òbí.

Àmọ́ lóde òní, ó jọ pé fúnra ọ̀pọ̀ ni wọ́n ń yan ẹni tí wọ́n máa fẹ́ láìtiẹ̀ ní í fi lọ ẹnikẹ́ni, tí ìrísí ẹni náà bá ṣáà ti fani mọ́ra, tí wọ́n á sì máa ní in lọ́kàn pé, tí ìgbéyàwó náà kò bá rí bí àwọ́n ṣe rò, ẹnu kí àwọn wá ẹlòmíràn fẹ́ ni. Lọ́nà kan náà, ọ̀pọ̀ ló ń yan iṣẹ́ wọn kìkì nítorí iyì tí wọ́n rò pé ó ní láìro ìpalára tó ṣeé ṣe kó tibẹ̀ yọ. Tàbí kẹ̀, wọ́n lè yára gbé ìrònú nípa ìṣòro tó lè yọjú kúrò lọ́kàn wọn nípa sísọ pé, ‘màá kápá wọn.’

Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn obìnrin ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò rọ́wọ́ mú sábà máa ń múra tán láti lọ síbòmíràn lọ ṣe àwọn iṣẹ́ tí wọ́n gbọ́ pé á mú ìgbésí ayé oníyọ̀tọ̀mì wá. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, bí wọ́n bá ṣe ń gúnlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè mìíràn báyìí, ilé aṣẹ́wó ni wọ́n á ti bára wọn, ìgbésí ayé aṣẹ́wó tí wọ́n wá ń gbé báyìí á wá burú ju bí ayé wọn ṣe wà tẹ́lẹ̀ lọ. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn World Press Review sọ pé, ìsìnrú ayé òde òní yìí tó túbọ̀ ń burú sí i tó sì ń dáyà foni jẹ́ “àrùn burúkú tí kò ní í lọ.”

Ṣé wọ́n tún lè tan àwọn èèyàn gba iṣẹ́ tó bójú mu àmọ́ tó jẹ́ pé bí ẹrú ni wọ́n á wá dà níkẹyìn? Irú nǹkan yìí ti ṣẹlẹ̀ rí o! Bí àpẹẹrẹ, àwọn iléeṣẹ́ kan máa ń pèsè àwọn nǹkan afẹ́ tó gọntíọ fún àǹfààní àwọn òṣìṣẹ́ wọn. Lára irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ pípèsè ilé ìjẹun tí ẹbí àti ọ̀rẹ́ wọn lè lò, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n lè lò nígbàkigbà àti bíbá wọn fọ aṣọ wọn, gbígba oníṣègùn eyín sínú ọgbà tí wọ́n ń gbé, lílo gbọ̀ngàn eré ìmárale lọ́fẹ̀ẹ́ tàbí fífún wọn ní àǹfààní láti lọ jẹun ní ilé àrójẹ tó gbówó lórí.

Akọ̀ròyìn Richard Reeves sọ pé: “Iléeṣẹ́ kan tiẹ̀ ti sanwó sílẹ̀ níbì kan táwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tó ń lò nílò omi òjò lè mú àfẹ́sọ́nà wọn lọ láti lọ ṣe fàájì.” Àmọ́ ṣọ́ra o! Ó ṣàlàyé pé: “Àwọn iléeṣẹ́ yìí ṣe àwọn ètò láti mú ìgbésí ayé rẹ rọrùn, àmọ́ orí ohun kan ni wọ́n gbé e kà, ìyẹn ni pé wàá gbà kó jẹ́ pé àwọn ni wọ́n á máa ṣàkóso ìgbésí ayé rẹ; pé wàá máa ṣiṣẹ́ wákàtí méjìdínlógún lójúmọ́ àti ní òpin ọ̀sẹ̀, pé ọ́fíìsì ni wàá ti máa jẹun, ṣeré, tí wàá tiẹ̀ máa sùn síbẹ̀ pàápàá torí bóyá wọ́n lè nílò ẹ fún èrè tara wọn.”

Bó O Ṣe Lè Yan Iṣẹ́ Tó Sàn

Òwe àtijọ́ kan sọ pé: “Ààyè ajá sàn ju òkú kìnnìún lọ.” (Oníwàásù 9:4) Irú òwe báyìí gbé ìbéèrè náà dìde pé, Ṣé ó yẹ kí n ba ìgbésí ayé mi tàbí ìlera mi jẹ́ nítorí iṣẹ́ mi? Ní ìdáhùn sí ìyẹn, ọ̀pọ̀ ti tún ipò wọn gbé yẹ̀ wò dáadáa wọ́n sì ti ṣàwárí ọ̀nà tí wọ́n fi lè máa gbọ́ bùkátà ara wọn lọ́nà tó bójú mu, títí kan ti ìdílé wọn pẹ̀lú, bó bá jẹ́ onídìílé ni wọ́n, wọ́n sì tún ṣàwárí ọ̀nà tí wọ́n fi lè máa gbé ìgbésí ayé tó ní ayọ̀ tó sì nítumọ̀.

Lóòótọ́, èyí sábà máa ń béèrè pé kéèyàn mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, ó sì tún lè béèrè ṣíṣe ìpinnu àwọn ohun téèyàn dìídì nílò dípò àwọn ohun téèyàn fẹ́ àmọ́ tí kò ṣe pàtàkì. Àwọn tó ń fẹ́ ipò ọlá àti iyì lè máà tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tó mọ níwọ̀n, kódà wọ́n lè máa ka àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ sí arìndìn. Àmọ́ kí lohun náà gan-an tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé? Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti séra ró díẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí láti ronú lórí èyí?

Bóyá lá rí ẹ̀dá èèyàn kankan tó tíì ní nǹkan tára tó ọlọgbọ́n ọba Sólómọ́nì tó kọ òwe tá a fa yọ lókè yìí. Àmọ́ nígbà tó ń ṣàkópọ̀ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì lóòótọ́, ó kọ̀wé lábẹ́ ìmísí Ọlọ́run pé: “Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.”—Oníwàásù 12:13.

Lẹ́sẹ̀ kan náà, Sólómọ́nì kò ṣàìmọ bí iṣẹ́ ti ṣe pàtàkì tó. Ó kọ̀wé pé: “Kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí [èèyàn] máa jẹ kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì jẹ́ kí ọkàn òun rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.” (Oníwàásù 2:24) Bákan náà, bíi ti Bàbá rẹ̀ ọ̀run, Jésù Kristi tí í ṣe Sólómọ́nì Títóbi Jù náà mọ ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́. Ó sọ pé: “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí, èmi náà sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́.”—Jòhánù 5:17; Mátíù 12:42.

Síbẹ̀, ìgbésí ayé téèyàn ń gbé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí kúrú jọjọ. (Sáàmù 90:10) Àmọ́ o, Kristi mọ̀ pé àwọn èèyàn á gbádùn ìgbésí ayé tí kò lópin lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba náà tó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà fún. Ìdí rèé tó fi pàrọwà nínú Ìwàásù rẹ̀ olókìkí lórí Òkè pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”—Mátíù 6:9, 10, 33.

Ní ti ìgbésí ayé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba yẹn, Bíbélì ṣèlérí pé: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; . . . iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—Aísáyà 65:21, 22.

Ìrètí yìí mà kúkú ga lọ́lá o, ìyẹn ìrètí gbígbádùn ìgbésí ayé títí lọ, níbi téèyàn á tún ti máa ṣe iṣẹ́ tó nítumọ̀ tó sì léré nínú! Gbígbé ipò tiwa fúnra wa yẹ̀ wò dáadáa lónìí lè jẹ́ ká rí i bóyá a nílò àtúnṣe láwọn apá ibì kan nínú iṣẹ́ wa, ká bàa lè yẹra fún àwọn ewu tó lè ṣàkóbá fún àǹfààní wa láti gbádùn “ìyè tòótọ́,” ìyẹn ìgbésí ayé ọjọ́ iwájú lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (1 Tímótì 6:19) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi hàn nínú iṣẹ́ wa tàbí nínú ohunkóhun tá a bá ń ṣe pé, á bọ̀wọ̀ fún Ẹni náà tó fún wa ní ìwàláàyè.—Kólósè 3:23.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]

Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, àwọn èèyàn yóò gbádùn ṣíṣe iṣẹ́ tí kò léwu nínú tó sì lérè