Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Àwọn Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Abilà Fi Ń Nílà Lára?

Kí Nìdí Tí Àwọn Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Abilà Fi Ń Nílà Lára?

Kí Nìdí Tí Àwọn Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Abilà Fi Ń Nílà Lára?

Àwọn tó gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́ kò mọ báwọn á ṣe ṣàlàyé ilà tó wà lára kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà. Àwọn kan sọ pé ó jẹ́ àmì tó fi ń lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ da nù. Àmọ́, ẹ̀rí ti fi hàn pé àwọn ilà tó rí kàlákìní yìí kò tó nǹkan tó lè ṣẹ̀rù ba kìnnìún àtàwọn ẹranko mìíràn tó máa ń pa ẹran jẹ.

Àwọn mìíràn sọ pé ìjẹ́pàtàkì ilà yìí ni láti fi fa àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mọ́ra fún ìbálòpọ̀. Àmọ́ ṣá, kò dà bí ẹni pé òótọ́ ni èyí nítorí bákan náà ní ilà ara gbogbo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà ṣe rí, ì báà jẹ́ akọ tàbí abo.

Èrò mìíràn tún ni pé ilà funfun àti dúdú yìí kì í jẹ́ kí ẹranko yìí mọ àlá ooru tí oòrùn gbígbóná janjan ilẹ̀ Áfíríkà máa ń fà. Ká ní bẹ́ẹ̀ ni, kí ló wá dé táwọn ẹranko mìíràn ò fi ní irú ilà kan náà?

Ohun kan tó wọ́pọ̀ táwọn èèyàn tún máa ń sọ ni pé ète arúmọjẹ làwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà máa ń lo ilà tó wà lára wọn fún. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti wádìí, wọ́n sì ti rí i pé ìtànṣán oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà kò pa àwọ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà dà, kò sì sọ pé kí wọ́n má rí i látòkèèrè. Arúmọjẹ yìí ò tiẹ̀ lè ṣiṣẹ́ lójú kìnnìún tó jẹ́ olórí elénìní kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà tá á ti jẹ́ kí ẹranko yìí sún mọ́ tòsí dáadáa kó tó kì í mọ́lẹ̀.

Àwọn kan tún sọ pé bí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà bá ń sá gìrọ́gìrọ́ kiri, àwọ̀ wọn tó jọra kò ní jẹ́ káwọn kìnnìún tó fẹ́ pa wọ́n jẹ́ ní ọ̀kan pàtó lọ́kàn láti pa jẹ́. Àmọ́ ká sòótọ́, ìwádìí táwọn èèyàn ṣe nípa àwọn ẹranko inú igbó fi hàn pé bí àwọn kìnnìún kì í ṣeé bà á tì bí wọ́n bá fẹ́ pa àwọn ẹranko mìíràn jẹ náà ni wọn kì í ṣeé bà á tì tí wọ́n bá fẹ́ pa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà jẹ.

Ohun tó túbọ̀ mú kí ìbéèrè náà dojú rú ni pé àwọn ilà ara kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà máa ń ṣàkóbá fún un gan-an ni. Tí òṣùpá bá ń ràn lóru, ilà funfun àti dúdú tó wà lára kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà máa ń mú kó rọrùn láti rí ju àwọn ẹranko mìíràn tí àwọ̀ wọn dọ́gba délẹ̀ lọ. Ìgbà tó sì jẹ́ pé òru ni kìnnìún máa ń ṣọdẹ, ó jọ pé èyí á mú kí ewu tó ń wu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà ju tàwọn ẹranko mìíràn lọ.

Nígbà náà, ibo ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà ti rí àwọn ilà dúdú-funfun tó wà lára rẹ̀? Ohun kan ṣoṣo tó lè mú ká lóye rẹ̀ ni gbólóhùn ṣókí náà pé: “Ọwọ́ Jèhófà ni ó ṣe èyí.” (Jóòbù 12:9) Bẹ́ẹ̀ ni o, Ẹlẹ́dàá náà dá àwọn ẹ̀dá orí ilẹ̀ ayé lọ́nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ó sì fún wọn láwọn ànímọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó lè mú kí wọ́n gbádùn ìgbésí ayé wọn dọ́ba. Ẹ̀dá èèyàn lè máà mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìdí tí Ọlọ́run fi ṣe èyí. Àwọn ọnà àgbàyanu tí Ọlọ́run tún ṣe sára àwọn ohun alààyè ń ṣiṣẹ́ mìíràn. Ó ń fún ẹ̀dá èèyàn ní ayọ̀, ìtẹ́lọ́rùn, ó sì ń múnú wa dùn. Àní, ẹwà tí ìṣẹ̀dá ní ló mú kí ọ̀pọ̀ lónìí sọ irú ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nígbà pípẹ́ sẹ́yìn pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn ni o fi ọgbọ́n ṣe. Ilẹ̀ ayé kún fún àmújáde rẹ.”—Sáàmù 104:24.