Mímú Kí Ibi Iṣẹ́ Rẹ Jẹ́ Aláìléwu
Mímú Kí Ibi Iṣẹ́ Rẹ Jẹ́ Aláìléwu
PẸ̀LÚ gbogbo òfin tí wọ́n ṣe pé kí ewu lè dín kù lẹ́nu iṣẹ́ kí ààbò sì wà, jàǹbá àti ikú lẹ́nu iṣẹ́ kò yéé ṣẹlẹ̀, èyí sì jẹ́ ìṣòro ńlá síbẹ̀. Ó ṣe kedere nígbà náà pé, ọ̀rọ̀ ààbò lẹ́nu iṣẹ́ kì í ṣe ohun tí òfin nìkan lè yanjú. Àti agbanisíṣẹ́ àti òṣìṣẹ́ ló gbọ́dọ̀ wá nǹkan ṣe nítorí ààbò ara wọn àti ti àwọn ẹlòmíràn.
Nítorí náà gbogbo àwọn tó jẹ́ òṣìṣẹ́ pátá ló yẹ kí wọ́n fara balẹ̀ wo bí nǹkan ṣe ń lọ sí níbi iṣẹ́ àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe iṣẹ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o ti kíyè sí i bóyá lóòótọ́ ni kò séwu níbi tó o ti ń ṣiṣẹ́? Ṣé èròjà tó lè ṣekú pani wà lára nǹkan tó o fi ń ṣiṣẹ́? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ààbò tó dájú wà fún ọ? Ṣé ọ̀pọ̀ ìgbà ni iṣẹ́ rẹ máa ń mú ara ni ọ́? Ṣé o máa ń ṣiṣẹ́ kọjá ààlà àkókò tí òfin béèrè?
Ìdáhùn rẹ sí àwọn ìbéèrè bí irú ìwọ̀nyí lè sọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa bí ààbò ṣe wà fún ọ tó níbi iṣẹ́ rẹ.
Máa Rántí Nígbà Gbogbo Pé Ewu Ńbẹ
Ewu ńbẹ nínú kéèyàn máa ṣiṣẹ́ bí aago. Lẹ́yìn tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Lawson Savery ti Yunifásítì Australia’s Curtin àti olùwádìí mìíràn kan ṣàyẹ̀wò àbájáde ìwádìí tí wọ́n ṣe fún àwọn òṣìṣẹ́ tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta ààbọ̀ [3,600,000], àti ibi iṣẹ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógójì ó lé igba [37,200], wọ́n tẹ ìwé ìwádìí kan jáde tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní, “Ṣíṣiṣẹ́ fún Ọ̀pọ̀ Wákàtí: Ǹjẹ́ Ó Léwu, Ṣé Àwọn Èèyàn Sì Gbà Pé Bẹ́ẹ̀ Ló Rí?” Láìdéènà pẹnu, bẹ́ẹ̀ ni, ni ìdáhùn sí ìbéèrè alápá méjì yìí.
Kò sírọ́ ńbẹ̀ pé àwọn òṣìṣẹ́ tí àárẹ̀ bá mú kì í lè ṣiṣẹ́ dáadáa wọ́n sì máa ń ṣe ọ̀pọ̀ àṣìṣe. Ọ̀jọ̀gbọ́n Savery sọ nínú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Ọsirélíà náà, The Sun-Herald pé: “Ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ ló máa ń rọ àwọn òṣìṣẹ́ láti máa ṣiṣẹ́ lọ bí aago, wọ́n á fojú wá àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ lọ ní rabidun, wọ́n á sì dá wọn lọ́lá.” Àbájáde èyí lè burú jáì. Bóyá la lè rí ibòmíràn
tí ìṣòro yìí ti wọ́pọ̀ ju ìdí iṣẹ́ ọkọ̀ wíwà lọ. Wọ́n máa ń rọ àwọn awakọ̀ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ mú wọn ní tipátipá láti wakọ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí láìsí pé wọ́n ń dúró sinmi, òfin sì kà á léèwọ̀ láwọn ilẹ̀ kan.Ewu mìíràn tún ni kí ibi téèyàn ti ń ṣiṣẹ́ máà bójú mu, kí gbogbo ibẹ̀ rí jákujàku kó má sì sí ìmọ́tótó. Dída irinṣẹ́ sílẹ̀ káàkiri tàbí sísọ wáyà iná sílẹ̀ níbi táwọn èèyàn wà máa ń fa jàǹbá àti ikú. Bákan náà tún ni dídágunlá sí àwọn ìlànà ààbò nígbà téèyàn bá ń lo àwọn irinṣẹ́ àti ẹ̀rọ tó ń lo iná. Ohun mìíràn tó tún ń fa ewu ni ṣíṣàìnu ilẹ̀ nígbà ti nǹkan bá dà sílẹ̀, pàápàá àwọn nǹkan tó lóró nínú. Ọ̀pọ̀ jàǹbá ló ti ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ yọ̀ tẹ̀rẹ́ lórí ilẹ̀ ti epo tàbí omi dà sí. Nítorí náà, a lè sọ pé, òfin àkọ́kọ́ fún ṣíṣe iṣẹ́ tó dára ni jíjẹ́ onímọ̀ọ́tótó àti ẹni tó wà létòlétò.
Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ láti dágunlá sí àwọn ìlànà ààbò. Ìwé ìròyìn Monthly Labor Review sọ pé: “Tí iṣẹ́ bá pọ̀ lọ́wọ́, èèyàn lè bẹ̀rẹ̀ sí i ronú pé àfi kí òun gba ọ̀nà àbùjá kí òun lè parí gbogbo iṣẹ́ náà.” Àwọn kan lè máa ronú pé, ‘Gbogbo ìgbà tí mi ò pa òfin ààbò mọ́, láburú kankan kò ṣẹlẹ̀.’ Nígbà tí máníjà ilé iṣẹ́ kan ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro yìí, ó sọ pé: “Ọ̀kan lára ohun tó burú jù lọ tó o lè máa ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ni kó o máa dágunlá sí ìlànà ààbò kó o sì máa mú un jẹ!” Kí nìdí? Nítorí pé èyí máa ń jẹ́ kéèyàn dára rẹ̀ lójú ju bó ṣe yẹ lọ kí ó sì di aláìbìkítà, èyí tá á wá yọrí sí jàǹbá tó pọ̀. Ìbúgbàù tó ṣẹlẹ̀ ní ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ Chernobyl ní ilẹ̀ Ukraine lọ́dún 1986 ni wọ́n ń pè lọ́pọ̀ ìgbà ní “jàǹbá atọ́míìkì tó tíì burú jù lọ lágbàáyé.” Kí ló fa jàǹbá yìí? Ìròyìn kan nípa àjálù náà sọ pé “ẹ̀rí jaburata ló wà nípa ṣíṣàìbìkítà fún ọ̀nà tó tọ́ láti gbà ṣe àwọn nǹkan” àti “mímọ̀ọ́mọ̀ ṣàìka àwọn ìlànà ààbò sí.”
Àwọn agbanisíṣẹ́ àtàwọn òṣìṣẹ́ lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti tètè mọ àwọn ohun tó lè fa jàǹbá. Òwe ọlọgbọ́n kan nínú Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Bẹ́ẹ̀ ni, ẹni tó gbọ́n máa ń kíyè sí ohun tó lè fa ewu, á sì wá ọ̀nà láti dáàbò bo ara rẹ̀ àtàwọn ẹlòmíràn.
Nígbà tí àwọn agbanisíṣẹ́ bá ṣe èyí, yóò ṣe àwọn fúnra wọn àtàwọn òṣìṣẹ́ wọn láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, ilé iṣẹ́ kan tó tún ọ́fíìsì wọn ṣe kí “àìsàn tí ilé ń fà” má bàa ṣe àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ rí i pé, kò pẹ́ rárá lẹ́yìn náà ti ohun táwọn òṣìṣẹ́ ń mú jáde pọ̀ sí i, ìfọ̀kànbalẹ̀ tó sì dé bá àwọn òṣìṣẹ́ náà kì í ṣe kékeré. Wọ́n tún rí i pé àwọn tó ń pa ibi iṣẹ́ jẹ nítorí àìsàn dín kù. Kì í ṣe pé gbígba ti ìlera àwọn ẹlòmíràn rò bí irú èyí máa ń mú kí àjọṣe tó dán mọ́rán wà láàárín agbanisíṣẹ́ àti òṣìṣẹ́ nìkan ni, àmọ́ ó tún lè ṣàǹfààní fún ọrọ̀ ajé wọn pẹ̀lú bí a ti rí i nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí.
Gẹ́gẹ́ bi a ti ṣàkíyèsí nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ìwà ipá ti tàn dé ẹnu iṣẹ́ báyìí o. Kí lo lè ṣe láti dáàbò bo ara rẹ ?
Àwọn Ohun Tó O Lè Ṣe
A ti rí i tí ìwà òfínràn lẹ́nu iṣẹ́, èyí tó lè máà kọ́kọ́ lágbára níbẹ̀rẹ̀, wá gbèèràn di fífòòró ẹni ṣáá. Ìwé ìròyìn Harvard Business Review pèsè ìmọ̀ràn tó yẹ ká ronú lé yìí pé: “Tó o bá fẹ́ dáwọ́ ìwà ipá tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ dúró, rántí pé àwọn èèyàn tó máa ń fínràn díẹ̀díẹ̀ náà ló sábà máa ń hu ìwà jàgídíjàgan tó burú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.”
Obìnrin kan lè máà ní in lọ́kàn láti pe àfiyèsí àwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ sí ara rẹ̀, àmọ́ tí ìmúra rẹ̀, ìsọ̀rọ̀ rẹ̀, àti ìṣesí rẹ̀ kò bá wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, àwọn èèyàn lè máa wò ó pé oníranù ni. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn ìgbà kan wà tí ìwà táwọn èèyàn hù láìṣe pé 1 Tímótì 2:9.
wọ́n ní èròkérò lọ́kàn ti dá wàhálà ńlá sílẹ̀, lára rẹ̀ ni ṣíṣọ́ni kiri láti ṣeni ní ṣùtá, fífipá báni lòpọ̀ tàbí ìpànìyàn pàápàá. Nítorí náà, máa ronú lórí bí ìmúra rẹ àti ìṣesí rẹ ṣe ń nípa lórí àwọn ẹlòmíràn. Ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Bíbélì náà pé: ‘Fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú.’—Ìwé ìròyìn Monthly Labor Review tún jẹ́ ká mọ ohun mìíràn tó lè kóni sínú ewu, ó sọ pé: “Ẹ̀rù ń báni nítorí àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n máa ń dá ṣiṣẹ́ alẹ́ láwọn àgbègbè téèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ sí.” Nítorí náà, rò ó wò ná: Ṣé ó bọ́gbọ́n mu láti kó ara rẹ séwu ìwà ipá, àgàgà èyí tó sábàá ń ṣẹlẹ̀ téèyàn bá ń dá nìkan ṣiṣẹ́ tílẹ̀ bá ti ṣú gan-an? Ṣé owó tó o máa rí níbẹ̀ tó ohun tó ò ń fẹ̀mí ara rẹ wewu lé lórí?
Ó tún ṣe pàtàkì pé ká ṣọ́ bá a ṣe ń ṣe sí àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa tí nǹkan kò fara rọ fún, tí wọ́n máa ń kanra tí wọn ò sì mọ eré. Kí la lè ṣe láti pẹ̀tù sí wàhálà tó ṣeé ṣe kó fa ewu? Òwe Bíbélì kan dámọ̀ràn pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1) Dájúdájú, bó o bá jẹ́ onínúure tó o sì ń fọ̀wọ̀ wọ àwọn ẹlòmíràn, o lè dín wàhálà kù jọjọ tí ìjà kò sì ní ṣẹlẹ̀.
Láyé tára ń ni àwọn èèyàn níbi iṣẹ́ yìí, ìwà ká máa kanra mọ́ni ká sì máa bínú síni ti wá wọ́pọ̀ gan-an. Nígbà tó bá dà bíi pé àwa gan-an ni wọ́n dájú sọ, ó lè jẹ́ pé wàhálà àti ìjákulẹ̀ tẹ́ni yẹn ń bá fínra ló ń mú un hùwà lọ́nà bẹ́ẹ̀. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni àwa kàn lọ ṣe kòńgẹ́ ìbínú rẹ̀. Nítorí náà, ọ̀nà tí à ń gbà dáhùn ṣe kókó. Ó lè mú ọ̀rọ̀ náà rọlẹ̀ tàbí kó mú un burú sí i.
Bóyá kẹ̀, àìgbọ́ra-ẹni-yé lohun tó fà á. Ìwé Resolving Conflicts at Work ṣe àkíyèsí tó lè ranni lọ́wọ́ yìí pé: “Nígbà táwa àti ẹnì kan bá ní gbólóhùn-asọ̀, . . . a kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣàlàyé ọ̀rọ̀ látọkàn wá. Àlàyé nípa ohun tó mú wa hùwà lọ́nà kan kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ ṣe kedere.” Kí ló lè fa ìyẹn? Ìwé náà ń bá a lọ pé: “Wàhálà tó wà láàárín wa lè dà wá lọ́kàn rú
tàbí kó ra wá níyè, á sì jẹ́ ká máa wò ó pé ká jọ dà á rú fúnra wa nìkan ló lè yanjú rẹ̀.”Kí wá ni ojútùú rẹ̀? TẸ́TÍ SÍLẸ̀! Ìwé tá a fa ọ̀rọ̀ yọ nínú rẹ̀ lókè sọ pé: “Nípa fífi tọkàntọkàn tẹ́tí sílẹ̀ sí àwọn èèyàn tọ́rọ̀ wa kì í bára mu . . . , ìbínú ọkàn wa á rọlẹ̀, à ó sì rí ojútùú sí i.” Àmọ̀ràn gidi rèé o láti má ṣe jẹ́ kí aáwọ̀ tàbí àìgbọ́ra-ẹni-yé gbèèràn débi tó máa wa di ìjà rẹpẹtẹ.
Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti wá ọ̀nà tó bójú mu láti dáàbò bo ara rẹ. Èyí kan jíjẹ́ ẹni tó ń fi tọkàntọkàn pa àwọn òfin ààbò tí ìjọba àdúgbò ṣe mọ́. Ṣíṣe èyí lè wúlò gan-an fún mímú ibi iṣẹ́ rẹ jẹ́ ibi tí kò fi bẹ́ẹ̀ léwu.
Kókó mìíràn tún ni pé, ojú tá a fi ń wo ìwàláàyè, iṣẹ́ àti àkókò fàájì lè nípa lórí irú iṣẹ́ tá a yàn láti ṣe àti ojú tá a fi ń wo dídáàbò ara wa. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tó yẹ ká ṣe nípa àwọn kókó yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Nu gbogbo epo tó bá dà sílẹ̀ dáadáa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ lè pẹ̀tù sí ìṣòro tó le koko