Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Abiyamọ Iṣẹ́ Tí Wọ́n Ń Ṣe Pọ̀ Púpọ̀

Àwọn Abiyamọ Iṣẹ́ Tí Wọ́n Ń Ṣe Pọ̀ Púpọ̀

Àwọn Abiyamọ Iṣẹ́ Tí Wọ́n Ń Ṣe Pọ̀ Púpọ̀

Ní aago márùn-ún ku ìṣẹ́jú mẹ́wàá ìdájí, ọmọ kékeré náà Alex, tí oorun ṣì wà lójú rẹ̀ á máa kígbe á sì máa rá gun orí ìyá rẹ̀ Helen. Àwọn ọmọ méjì tó kù, Penny (ọmọ ọdún márùn-ún), Joanna (ọmọ ọdún méjìlá) àti bàbá wọn Nick ṣì ń sùn ní tiwọn. Helen á gbé Alex mọ́ra lórí bẹ́ẹ̀dì, á sì fún un lọ́mú. Helen ò ní lè padà sùn mọ́.

Tó bá di aago mẹ́fà ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún òwúrọ̀, Helen á yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ilé ìgbọ́únjẹ, á po kọfí, á sì kàwé.

Láàárín aago mẹ́fà kọjá ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí aago méje kọjá ogún ìṣẹ́jú, Nick á jí. Helen á sì jí Penny àti Joanna, á gbọ́únjẹ àárọ̀, á sì ṣe àwọn iṣẹ́ ilé díẹ̀. Tó bá di aago méje kọjá ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, Nick á gbọ̀nà ibi iṣẹ́, á mú Joanna dé ilé ìwé. Ìyá Helen náà á dé láti wá bójú tó ọmọ-ọmọ rẹ̀, Alex.

Tó bá di aago méje ààbọ̀ òwúrọ̀, Helen á mú Penny lọ sí ilé ìwé jẹ́lé-ó-sinmi tó ń lọ. Ìgbà tí Helen bá wà lọ́nà ibi iṣẹ́ ló máa ń ráyè ronú pé lóòótọ́ kò rọrùn láti jẹ́ abiyamọ. Ó sọ pé: “Òun ni iṣẹ́ tó ṣòro jù lọ tí mo tíì ṣe rí láyé mi.”

Ní aago mẹ́jọ kọjá ìṣẹ́jú mẹ́wàá òwúrọ̀, onírúurú ohun tí Helen máa ṣe á ti kún orí tábìlì rẹ̀ jaburata níbi iṣẹ́. Ọkàn rẹ̀ ò sì balẹ̀ bó ṣe ń ronú pé tóun bá lọ lóyún mìíràn pẹ́nrẹ́n, iṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ òun. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìdílé rẹ̀ nílò owó tó ń ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wọlé.

Ní aago mọ́kànlá ku ìṣẹ́jú mẹ́tàdínlógún òwúrọ̀, ẹnì kan fóònù Helen, ó sì bá a sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ rẹ̀. Bó ṣe gbé tẹlifóònù sílẹ̀, Nancy, obìnrin kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í tù ú nínú ó sì tún ń yìn ín pé: “Ọ̀nà tó o gbà ń bá àwọn ọmọ rẹ lò kò lẹ́lẹgbẹ́.” Pòròpòrò lomijé ń dà lójú Helen.

Ní aago méjìlá kọjá ìṣẹ́jú márùn-ún ọ̀sán, Helen á yára wá nǹkan fi panu bẹ́ẹ̀ lá á bẹ̀rẹ̀ sí í rántí ọjọ́un àná, kó tó bí ọmọbìnrin rẹ̀ àkọ́bí. Nígbà yẹn, ó láwọn nǹkankan tó ti pinnu pé òun á máa fi àkókò “tí ọwọ́ òun bá dilẹ̀” ṣe. Ó wá rò ó lọ́kàn pé, ‘àṣé mo kàn ń tanra mi jẹ ni!’

Tó bá di aago mẹ́ta kọjá ìṣẹ́jú mẹ́wàá ọ̀sán, lẹ́yìn tí wọ́n ti pè é lórí tẹlifóònù lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà tí wọ́n sì ti sọ fún un nípa bí ọmọ rẹ̀ Alex, ṣe ń ta pọ́n-ún-pọ́n-ún, Helen á sọ pé àjọṣe àárín òun àtàwọn ọmọ òun gún régé gan-an. Ó sọ pé: “Mi ò tíì ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ fún ẹlòmíràn rí.” Ìdùnnú ńláǹlà yìí ló jẹ́ kó lè borí àwọn ìnira tó ti kọ́kọ́ ń ní tẹ́lẹ̀.

Ní aago márùn-ún kọjá ìṣẹ́jú mẹ́wàá ìrọ̀lẹ́, Helen á lọ mú Joanna, á sì yà lọ́nà ṣe àwọn nǹkankan tó yẹ ní ṣíṣe. Á fóònù Nick láti rán an létí pé òun ló kàn láti lọ mú Penny wálé.

Nínú ilé wọn, ní aago mẹ́fà sí aago méje ààbọ̀, Helen á gbaṣẹ́ lọ́wọ́ Màmá àgbà, ìyẹn ‘bíbójú tó Alex,’ á ṣiṣẹ́ tó ní í ṣe nínú ilé, á sì gbọ́únjẹ alẹ́. Nígbà tá a béèrè lọ́wọ́ Helen nípa ohun tí ọmọ ọwọ́ kan nílò jù lọ, ó sọ pé: “Ohun tí ọmọ ọwọ́ kan nílò ni gbogbo ara ìyá rẹ̀: apá ìyá rẹ̀, ara àti ọyàn ìyá rẹ̀ kó sì tún gba oorun lójú ìyá rẹ̀.”

Ní aago mẹ́jọ ààbọ̀ sí aago mẹ́wàá alẹ́, Helen á bá Joanna ṣe iṣẹ́ tí wọ́n ní kó ṣe wá láti ilé ìwé, á sì tún fún Alex ní ọyàn. Nick ní tirẹ̀ á kàwé fún Penny fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, Helen á sì tún ṣe àwọn iṣẹ́ ilé mìíràn.

Lẹ́yìn tí Penny àti Joanna ti lọ sùn ní aago mọ́kànlá kọjá ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún alẹ́, Alex ò tíì sùn, ó ṣì wà lọ́wọ́ ìyá rẹ̀, àmọ́ tó bá ṣe díẹ̀ oorun á gbé e lọ. Nick náà ti ń tòògbé, Helen á sì sọ fún un pé: “Ó dà bí pé ó ti tó àsìkò láti gbé e lọ sórí bẹ́ẹ̀dì.”