Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Abiyamọ Wàhálà Àṣekúdórógbó Tí Wọ́n Ń Ṣe

Àwọn Abiyamọ Wàhálà Àṣekúdórógbó Tí Wọ́n Ń Ṣe

Àwọn Abiyamọ Wàhálà Àṣekúdórógbó Tí Wọ́n Ń Ṣe

Kò rọrùn rárá láti jẹ́ ìyá, àmọ́ èèyàn máa ń gbádùn rẹ̀. Àwọn abiyamọ máa ń gbádùn àkókò ọmọ títọ́, tí sáà yìí bá sì ti kọjá lọ, ó parí nìyẹn. Síbẹ̀, nígbà míì, ẹ̀mí àwọn ìyá mìíràn máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́. Helen fi ìgbésí ayé rẹ̀ wé eré ìje kan tó ní kòtò àti gegele. Ó sì dà bí ẹni pé bí àkókò ṣe ń lọ làwọn kòtò àti gegele yìí ń pọ̀ sí i.

Àwọn ìyá lè yááfì àkókò wọn àtèyí tó pọ̀ lára àkókò tí wọ́n fi ń gbádùn pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ wọn nítorí àtibójútó àwọn ọmọ wọn dáadáa. Esther, tó jẹ́ ìyá ọlọ́mọ márùn-ún sọ pé: “Mo gbọ́dọ̀ wà nítòsí ní gbogbo ìgbà nítorí àwọn ọmọ mi. Bí mo bá fẹ́ wẹ̀, mi ò lè pẹ́ ní balùwẹ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Mi ò lè ṣe àwọn oúnjẹ tó máa ń gba àkókò púpọ̀ mọ́, oúnjẹ àjápa ló kù tí mò ń ṣe. Mi ò lè rìnrìn àjò púpọ̀, mi ò lè lọ mọ ọ̀pọ̀ ibi tí mo fẹ́ẹ́ mọ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan sì ni mi ò lè ṣe. Àmọ́ aṣọ fífọ̀ ò gbélẹ̀ o, màá fọṣọ máà sì ká wọn pẹ́-pẹ́ẹ́-pẹ́!”

Síbẹ̀, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn abiyamọ kò tún ní í ṣàì sọ ìdùnnú àti ayọ̀ tí wọ́n ń rí bí wọ́n ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ wọn. Esther sọ pé: “Bí ọmọ náà ṣe ń rẹ́rìn-ín músẹ́ sí ọ, bó ṣe ń sọ pé ‘Ẹ ṣeun Mọ́mì,’ àti bó ṣe ń dì mọ́ ọ, gbogbo èyí á máa múnú rẹ dùn kò sì ní jẹ́ kó sú ọ.” a

Àwọn Abiyamọ Bẹ̀rẹ̀ sí Ṣiṣẹ́ Oúnjẹ Òòjọ́

Ìṣòro ńlá kan tí kò tún jẹ́ kí nǹkan rọrùn fáwọn ìyálọ́mọ ni pé, bí ọ̀pọ̀ lára wọn ṣe ń bójú tó àwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe nínú ilé ni wọ́n tún ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ láti rówó ṣètìlẹ́yìn fún ìdílé. Ibi tí ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin wọ̀nyí ti ń ṣiṣẹ́ jìnnà sílé, kì í kúkú ṣe pé ó wù wọ́n bẹ́ẹ̀ àmọ́ ó di dandan kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé táwọn bá jókòó sílé, ìdílé àwọn, pàápàá jù lọ àwọn ọmọ wọn, kò ní í ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó yẹ wọ́n. Ipa tí owó oṣù wọn ń kó kò kéré, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó sábàá máa ń kéré ju tàwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ ń ṣe irú iṣẹ́ kan náà lọ.

Bí àpẹẹrẹ, nílùú São Paulo, ní ilẹ̀ Brazil, ìdá méjìlélógójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èèyàn tó ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ló jẹ́ obìnrin. Ìwé ìròyìn kan níbẹ̀ sọ pé àwọn ìyá tí kì í ṣiṣẹ́ mìíràn ju kí wọ́n máa tọ́jú ọmọ lọ “ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú tán.” Láwọn ìgbèríko Áfíríkà, ibi gbogbo lèèyàn ti ń rí àwọn ìyá tó pọn ọmọ tí wọ́n á sì tún ru ẹrù igi sórí.

Iṣẹ́ Oúnjẹ Òòjọ́ Àṣekúdórógbó

Ohun mìíràn tó tún ń pa kún ìṣòro náà ni bó ṣe di dandan pé káwọn ìyálọ́mọ máa lo ọ̀pọ̀ wákàtí lẹ́nu iṣẹ́. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún kò tán síbẹ̀ o. Nígbà tí Maria tó ń gbé ní ilẹ̀ Gíríìsì ríṣẹ́ síbì kan, ọ̀gá rẹ̀ ní kó fọwọ́ síwèé kan tí Maria á fi sọ pé òun ò ní lóyún fún odidi ọdún mẹ́ta gbáko. Tó bá lè lóyún pẹ́nrẹ́n, ó máa san owó ìtanràn. Maria kúkú buwọ́ lu ìwé náà. Àmọ́ kò ju ọdún kan àtààbọ̀ lọ tóyún fi dé. Ọ̀gá rẹ̀ fi ìwé tó fọwọ́ sí tẹ́lẹ̀ hàn án, àmọ́ Maria gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí ilé ẹjọ́ pé ohun tí ilé iṣẹ́ òun ń ṣe kò dáa, ó sì ń retí àbájáde ọ̀rọ̀ náà báyìí.

Nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn agbanisíṣẹ́ lè sọ fún abiyamọ pé tí wọ́n bá ti bímọ tán ni kí wọ́n tètè padà sẹ́nu iṣẹ́ o. Wọn kì í sì í dín iye wákàtí tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ kù táwọn obìnrin wọ̀nyí bá padà sẹ́nu iṣẹ́. Fún ìdí yìí, wọn kì í gba ti àwọn ìyálọ́mọ yìí rò pé wọ́n ní ẹrù iṣẹ́ ńláǹlà lórí ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí. Wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ gba ìsinmi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ nítorí pé ó máa pa owó oṣù wọn lára. Àwọn ìyálọ́mọ tún lè ní láti kojú ìṣòro àìsí àwọn ilé womọdèmí tó péye àti owó àjẹmọ́nú tí ò tó nǹkan tí ìjọba ń san.

Tá a bá gba ibòmíràn wo ọ̀ràn náà, kì í ṣe torí owó làwọn abiyamọ míì ṣe ń ṣiṣẹ́, àmọ́ kínú wọn ṣáà lè dùn pé àwọn náà níṣẹ́ lọ́wọ́ ni. Bí Sandra ṣe ń bí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára ọmọ méjì tó ní tán ló padà sẹ́nu iṣẹ́. Ó rántí pé nígbà tóun bá nìkan wà nínú ilé pẹ̀lú ìkókó, òun á “dìde nígbà mìíràn òun á sì yọjú látojú wíńdò, tóun á sì máa ṣe kàyéfì nípa ohun tí gbogbo àwọn èèyàn ń ṣe.” Ibẹ̀ ló sì ti jẹ́ pé másùnmáwo ìdílé làwọn ìyá mìíràn ń sá fún tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́. Ìwé ìròyìn Daily Telegraph ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Àwọn òbí kan máa ń fẹ́ lo wákàtí púpọ̀ sí i níbi iṣẹ́, níbi tó ti dà bíi pé ọkàn wọn balẹ̀ ju kí wọ́n wà nílé lọ. Ńṣe ni èyí túbọ̀ ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ burú sí i, nítorí wọn ò ní lè lo àkókò tó tó pẹ̀lú àwọn ọmọ tí kì í ka ìbáwí sí, tí wọ́n jẹ́ oníjàgídíjàgan, tí wọ́n sì máa ń hùwà tí kò bójú mu.”

Iṣẹ́ Wọn Pọ̀ Rẹpẹtẹ

Kéèyàn máa ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ilé kò rọrùn rárá. Ìyá kan ní Netherlands sọ bó ṣe máa ń rí fún ọ̀pọ̀ àwọn ìyá, ó ní: “Ńṣe ló máa rẹ èèyàn tẹnutẹnu. Rírẹ̀ ló máa ń rẹ̀ mí bí mo bá jí pàápàá. Bí mo bá tibi iṣẹ́ dé, rírẹ̀ ló máa rẹ̀ mí gbáà. Àwọn ọmọ tiẹ̀ ti ń sọ pé, ‘Gbogbo ìgbà ló máa ń rẹ mọ́mì,’ èyí sì máa ń mú kó dà bí ẹni pé mi ò ṣe tó bó ṣe yẹ. Mi ò fẹ́ di ìsáǹsá níbi iṣẹ́, mo sì fẹ́ jẹ́ ìyá tó ń kóni mọ́ra tó sì ń ṣe gbogbo nǹkan tó yẹ kó ṣe. Àmọ́ mi ò tíì di ẹni àwòṣàpẹẹrẹ tó wù mí láti jẹ́.”

Obìnrin yìí jẹ́ ọ̀kan lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn abiyamọ tó ń ṣiṣẹ́, tí wọ́n máa ń rò ó pé báwọn ò bá tiẹ̀ sí lọ́dọ̀ àwọn ọmọ àwọn lọ́pọ̀ ìgbà, bí ìwọ̀nba àkókò táwọn lò bá jẹ́ èyí tó ‘wúlò gan-an,’ àbùṣe bùṣe. Àmọ́ wọ́n ti wáá rí i pé èrò yìí kù díẹ̀ káàtó. Ọ̀pọ̀ ìyálọ́mọ lónìí ló ti sọ pé másùnmáwo ibi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti tinú ilé ń mú kí wàhálà náà fẹ́ẹ́ ju ẹ̀mí àwọn lọ. Wọ́n ní ó ń mú káwọn lo ara àwọn ju bó ṣe yẹ lọ, owó táwọn sì ń rí kò tó nǹkan.

Tí àwọn òbí bá ń lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí níta, àwọn ọmọ kì í lè rí ohun tí wọ́n nílò jù lọ gbà, ìyẹn àkókò àti àfiyèsí ìyá wọn. Fernanda A. Lima, tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú nípa àwọn ọmọdé ní ilẹ̀ Brazil sọ pé kò sí èèyàn mìíràn tó lè rọ́pò ìyá. Ó sọ pé: “Ọdún méjì àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé ọmọ ló ṣe pàtàkì jù lọ. Ọmọ náà kò tíì dàgbà tó láti lóye ohun tó fà á tí ìyá òun kò fi sí lọ́dọ̀ òun.” Ẹnì kan tó ń bójú tó ọmọ ọwọ́ kàn lè ṣe àwọn ohun kan tí ìyá máa ṣe lásán ni, àmọ́ kò lè dà bí ìyá ọmọ náà láéláé. Lima sọ pé: “Ọmọ kékeré náà mọ̀ pé àbójútó onífẹ̀ẹ́ ti ìyá òun kò sí.”

Kathy ń ṣiṣẹ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀, ó sì lọ́mọbìnrin kékeré kan. Ó sọ pé: ‘Ọkàn mi máa ń dá mi lẹ́bi gan-an, ńṣe ló ń dà bí ẹni pé mo kàn pa ọmọ yìí tì sí [ilé ìtọ́jú àwọn ọmọdé]. Kì í dùn mọ́ èèyàn nínú tó bá mọ̀ pé òun kò ní àǹfààní láti rí bí ọmọ òun ṣe ń dàgbà, ó sì ń bani lọ́kàn jẹ́ pé ọmọ náà ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú ilé ìtọ́jú àwọn ọmọdé ju èyí tó ní pẹ̀lú olúwa rẹ̀ lọ.’ Obìnrin kan tó ń bójú tó àwọn èrò nínú ọkọ̀ òfuurufú ní Mẹ́síkò sọ pé: “Nígbà tó bá yá, ọmọ rẹ kò ní mọ̀ ọ́ mọ́, kò sì ní bọ̀wọ̀ fún ọ nítorí pé ìwọ kọ́ lò ń tọ́ ọ. Wọn mọ̀ pé ìwọ ni ìyá wọn o, àmọ́ tó bá yá, wàá kàn rí i pé ó tẹ́ wọn lọ́rùn láti wà pẹ̀lú obìnrin tó ń tọ́jú wọn ni.”

Àmọ́ o, àwọn abiyamọ tó ń jókòó sílé látòwúrọ̀ ṣúlẹ̀ láti bójú tó àwọn ọmọ wọn sọ pé ńṣe ni wọ́n máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn láwùjọ tí wọn ti ń fojú ńlá wo ṣíṣe iṣẹ́ tó ń mówó wọlé. Láwọn àwùjọ kan, wọn ò ka jíjẹ́ ìyàwó ilé sí ohun ọ̀wọ̀. Èyí ló ń mú káwọn obìnrin náà fẹ́ ṣiṣẹ́, kódà bí wọn ò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ nílò owó tí wọ́n á máa rí.

Àwọn Ló Ń Dá Ṣe Gbogbo Wàhálà Ọ̀hún

Ohun tó tún ń pa kún wàhálà àwọn abiyamọ ni pé: Lẹ́yìn tí ìyá kan ti ṣiṣẹ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀ tó sì ti rẹ̀ ẹ́, kò sí ìsinmi tó bá délé, iṣẹ́ ilé á tún bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu. Yálà àwọn ìyálọ́mọ ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ o tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn ló sábà ń dá ṣe gbogbo iṣẹ́ inú ilé tí wọ́n sì ń bójú tó àwọn ọmọ.

Bí àwọn ìyá ṣe ń lo wákátì púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ tó, àwọn bàbá kì í fi bẹ́ẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìwé ìròyìn The Sunday Times tìlú London sọ pé: “Àwọn bàbá tí kì í gbélé ló kún ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe fi hàn pé nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré làwọn ọkùnrin ń lò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn lójúmọ́. . . . Ọ̀pọ̀ ọkùnrin ni kò fẹ́ràn lílo àkókò pẹ̀lú ìdílé wọn. . . . Tá a bá fi wọ́n wéra pẹ̀lú àwọn ìyá tó ń ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ìyá kan ń lo wákàtí kan ààbọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ lójúmọ́.”

Àwáwí àwọn ọkùnrin kan ni pé àwọn ìyàwó àwọn kì í jẹ́ káwọn ràn wọ́n lọ́wọ́ nítorí pé wọ́n máa ń fẹ́ káwọn ṣe ohun gbogbo lọ́nà tí wọ́n gbà ń ṣe é. Àwọn ọkọ ní “tó ò bá ti ṣe é bó ṣe ń ṣe é gẹ́lẹ́, o ò mọ̀ ọ́n ṣe nìyẹn.” Ó hàn gbangba pé tí ìyàwó kan tó ti rẹ̀ bá fẹ́ gbádùn ìrànwọ́ ọkọ rẹ̀, kò gbọ́dọ̀ ranrí pé bí òun ṣe ń ṣe àwọn iṣẹ́ ilé kan gẹ́lẹ́ ni ọkọ òun ṣe gbọ́dọ̀ ṣe wọ́n. Ọkọ náà ò sì gbọ́dọ̀ máa fi ìyẹn kẹ́wọ́ pé ìyẹn ni kò jẹ́ kóun ṣe ohunkóhun.

Ohun Tó Tún Ń Pa Kún Wàhálà Náà

Àwọn àṣà ìbílẹ̀ tó ti mọ́ àwọn èèyàn lára tún lè pa kún wàhálà náà. Ní Japan, àwọn èèyàn retí pé káwọn ìyá tọ́ ọmọ wọn lọ́nà kan náà táwọn mìíràn ń gbà tọ́ tiwọn. Táwọn ọmọ mìíràn bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun èèlò ìkọrin tàbí ẹ̀kọ́ nípa àwòrán yíyà, ìyá mìíràn á fẹ́ káwọn ọmọ tòun náà ṣe bákan náà. Àwọn ilé ìwé máa ń rọ àwọn òbí láti jẹ́ káwọn ọmọ wọn dára pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ mìíràn nínú onírúurú eré tí wọ́n ń ṣe tí wọ́n bá jáde ilé ẹ̀kọ́. Táwọn òbí ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ wọn lè bẹ̀rẹ̀ sí í fòòró ẹ̀mí wọn. Àwọn olùkọ́ ọmọ wọn, àwọn òbí bíi tiwọn àtàwọn ìbátan pàápàá máa ń fòòró àwọn òbí tí kò ṣe bíi ti àwọn òbí yòókù. Bó ṣe rí láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn náà nìyẹn.

Àwọn ìpolówó ọjà lóríṣiríṣi lè mú káwọn ọmọ máa fúngun mọ́ àwọn òbí láti ra àwọn nǹkan fún wọn. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, àwọn ìyá lè máa rò pé dandan ni káwọn ra ohun tọ́mọ wọn bá fẹ́ fún un nítorí pé àwọn ìyá mìíràn ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bí agbára wọn ò bá wá gbé e, wọ́n lè máa rò pé àwọn di aláṣetì.

Kò yẹ kí àlàyé tá a ti ṣe yìí nípa iṣẹ́ ọmọ títọ́ lóde òní mú wa gbójú fo iṣẹ́ ribiribi tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ìyá ń ṣe. Wọ́n ń yááfì àwọn ohun kan wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti kẹ́sẹ járí nínú ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ tó dára jù lọ, ìyẹn títọ́ ìran ọjọ́ iwájú dàgbà. Àǹfààní lèyí jẹ́ fún wọn o. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọmọ jẹ́ ìbùkún àti ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ ỌLỌ́RUN.” (Sáàmù 127:3, Contemporary English Version) Irú ìyá bẹ́ẹ̀ ni Miriam, tó lọ́mọ méjì jẹ́. Ó sọ pé: “Pẹ̀lú àwọn ìpèníjà tó wà nínú kéèyàn jẹ́ abiyamọ, ayọ̀ tí ò lẹ́gbẹ́ náà tún wà níbẹ̀. Ọkàn àwa ìyá máa ń balẹ̀ gan-an tá a bá rí i tí àwọn ọmọ wa gba ẹ̀kọ́ àti ìbáwí tá a fún wọn tí wọ́n sì wá di èèyàn àtàtà láwùjọ.”

Kí ló lè mú káwọn ìyá túbọ̀ gbádùn ẹ̀bùn wọn yìí? Àpilẹ̀kọ tó kàn á fún wa láwọn àbá tó wúlò.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn abiyamọ tó wà lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ làwọn àpilẹ̀kọ yìí ń bá wí o. Lọ́jọ́ iwájú, Jí! á sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìpèníjà táwọn ìyá anìkàntọ́mọ àtàwọn ìyá tí kò relé ọkọ ń kojú.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

“Ayẹyẹ Àyájọ́ Àwọn Ìyá”

Ipò òṣì paraku, àìmọ̀wé, àwọn ọkọ tí wọn ò ní láárí, ṣíṣe èèyàn níṣekúṣe àti àjàkálẹ̀ àrùn Éèdì ń fojú àwọn ìyá rí màbo ní apá gúúsù Áfíríkà. Níbi ayẹyẹ Àyájọ́ Àwọn Ìyá tó wáyé láìpẹ́ yìí, ìwé ìròyìn Gúúsù Áfíríkà náà The Citizen, sọ pé: “Lọ́jọ́ ayẹyẹ Àyájọ́ Àwọn Ìyá, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn obìnrin làwọn ọkọ wọn máa lù tàbí fi ìbálòpọ̀ fìtínà, àwọn míì á sì pàdánù ẹ̀mí wọn.” Àwọn ìṣòro yìí ló ń mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìyálọ́mọ ní Gúúsù Áfíríkà gbé àwọn ọmọ wọn sọ nù lọ́dọọdún. Ní ọdún méjì sẹ́yìn, àwọn ọmọ tí ìyá wọn ń gbé sọ nù fi ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i. Èyí tó tiẹ̀ tún burú ni ti bí iye àwọn obìnrin tó ń fọwọ́ ara wọn gbẹ̀mí ara wọn ṣe ń pọ̀ sí i. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, obìnrin kan ní àgbègbè kan táwọn akúṣẹ̀ẹ́ ti pọ̀ gan-an wa àwọn ọmọ rẹ mẹ́ta mọ́yà, ó sì lọ dúró sójú ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin. Gbogbo wọn ló ṣòfò ẹ̀mí. Àwọn ìyá mìíràn ti gbégbá aṣẹ́wó nítorí àtirí owó ra àwọn ohun tí wọ́n nílò, oògùn olóró làwọn mìíràn ń tà tàbí kí wọ́n máa gba àwọn ọmọbìnrin wọn níyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Ìròyìn sọ pé ní Hong Kong, ńṣe làwọn “ìyálọ́mọ kan tí wọn ò tíì dàgbà púpọ̀ máa ń pa ọmọ wọn tí wọ́n bá ti bí i tán tàbí kí wọ́n jù ú sínú gorodóòmù tí wọ́n ń da pàǹtírí sí. Ìdí ni pé wàhálà náà ti ju agbára wọn lọ.” Ìwé ìròyìn South China Morning Post, sọ pé àwọn tó kéré lọ́jọ́ orí tí wọ́n relé ọkọ ní Hong Kong “ti wà nínú másùnmáwo báyìí [débi pé] ọpọlọ wọn lè máà ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́ tí wọ́n á fi gbẹ̀mí ara wọn.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Bọ́ràn Àwọn Abiyamọ Ṣe Rí Láwọn Orílẹ̀-Èdè Kan

Àkókò kò tó

❖ Ìwádìí kan ní Hong Kong fi hàn pé ìdá ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn abiyamọ tó ń ṣiṣẹ́ ni kì í lo àkókò tó tó pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Ìdá ogún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ tí wọ́n ti tó ọmọ ọdún mẹ́ta tí àwọn òbí wọn sì ń ṣiṣẹ́ ni kì í gbélé láàárín ọ̀sẹ̀. Ọ̀dọ̀ àwọn òbí àgbà ni wọ́n ń gbé.

❖ Àwọn obìnrin ìlú Mẹ́síkò máa ń pamọ jọ bí ẹdá ni, nǹkan bí ọdún mẹ́tàlá nínú ìgbésí ayé wọn ni wọ́n fi ń tọ́ ọmọ wẹ́wẹ́.

Àwọn abiyamọ àti iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́

❖ Ní Ireland, ìdá ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin ló máa ń wà nílé láti bójú tó àwọn ọmọ wọn. Ní Gíríìsì, Ítálì àti Sípéènì, nǹkan bí ìdá ogójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin ló ń ṣe bẹ́ẹ̀.

Bíbáni ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́-pẹ̀ẹ̀-pẹ́ nínú ilé

❖ Ní Japan, ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ìyàwó ilé ló sọ pé ì bá dùn mọ́ àwọn nínú ká ní ẹnì kan nínú ìdílé lè ran àwọn lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ ilé, àgàgà nígbà tí ara àwọn kò bá yá.

❖ Ní Netherlands, wákàtí méjì làwọn ọkùnrin ń lò lójúmọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ, èyí tí wọ́n sì fi ń ṣiṣẹ́ ilé kò tó wákàtí kan. Àwọn obìnrin ń lo wákàtí mẹ́ta pẹ̀lú àwọn ọmọ, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó wákàtí méjì tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ ilé.

Àwọn Ìyá tí másùnmáwo ń dà láàmú

❖ Ìdá àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ìyá ní Jámánì ni másùnmáwo ń bá fínra. Nǹkan bí ìdá mọ́kànléláàádọ́ta ló ń pariwo ẹ̀yìn dídùn. O ju ìdá kan nínú mẹ́ta wọn tó máa ń rẹ̀ tẹnutẹnu nígbà gbogbo wọ́n sì máa ń soríkọ́. Nǹkan bí ìdá ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún ni ẹ̀fọ́rí àti túúlu ń bá jà.

Àwọn ìyá tí wọ́n ń hùwà àìdáa sí

❖ Ní Hong Kong, ìdá mẹ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin tí wọ́n lò fún ìwádìí ló sọ pé ọkọ àwọn ti lu àwọn rí lásìkò tí àwọ́n lóyún.

❖ Ìwádìí kan tí ìwé ìròyìn Focus ṣe ní Jámánì fi hàn pé, nǹkan bí ìyá kan nínú ìyá mẹ́fà lo sọ pé ó kéré tán ọmọ àwọn ti kọjú ìjà sáwọn rí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Kò rọrùn rárá láti jẹ́ ìyá, nítorí ọ̀pọ̀ obìnrin ló máa ń sapá láti má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ wọn àti ìgbésí ayé ìdílé pa ara wọn lára