Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìmọ́lẹ̀ Ọ̀sán Máa Ń Jẹ́ Kéèyàn Sùn Dáadáa Lóru

Ìmọ́lẹ̀ Ọ̀sán Máa Ń Jẹ́ Kéèyàn Sùn Dáadáa Lóru

Ìmọ́lẹ̀ Ọ̀sán Máa Ń Jẹ́ Kéèyàn Sùn Dáadáa Lóru

ṢÉ Ó máa ń ṣòro fún ọ láti rí oorun sùn? Ó lè jẹ́ pé àìkì í sí níbi tí ìmọ́lẹ̀ wà dáadáa lọ́sàn-án ló ń fà á, pàápàá tó o bá jẹ́ àgbàlagbà. Láìpẹ́ yìí, àwọn olùwádìí ní ilẹ̀ Japan ṣe ìwádìí kan nípa àwọn arúgbó tí wọn kì í rí oorun sùn dáadáa ní ilé ìtọ́jú wọn. Wọ́n rí i pé ìṣòro náà jẹ́ nítorí pé àwọn èèyàn náà kì í fi bẹ́ẹ̀ sí níbi tí ìmọ́lẹ̀ wà lọ́sàn-án. Bákan náà, àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ṣe fún àwọn arúgbó náà fi hàn pé èròjà melatonin, tí omi ara tó n súnni ṣe nǹkan máa ń mú jáde, lọ sílẹ̀ gan-an lára wọn.

Ẹṣẹ́ kan tó ń jẹ́ pineal nínú ọpọlọ ló máa ń mú èròjà melatonin jáde. Ìwé ìròyìn The Journal of Clinical Endocrinology & Metabolism sọ pé tí ara èèyàn bá wà bó ṣe yẹ, èròjà melatonin tí ẹṣẹ́ yìí máa ń pèsè sínú ẹ̀jẹ̀ lójoojúmọ́ máa ń “pọ̀ gan-an lóru tá á sì lọ sílẹ̀ gan-an lọ́sàn-án.” Àmọ́ o, bí àwọn àgbàlagbà kò bá fi bẹ́ẹ̀ sí níbi tí ìmọ́lẹ̀ wà lọ́sàn-án, ńṣe ni èròjà melatonin inú ẹ̀jẹ̀ wọn máa ń lọ sílẹ̀. Ó dà bí ẹni pé tí ìmọ́lẹ̀ kò bá pọ̀ tó, ńṣe ló máa ń dabarú ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọ̀sán àti òru nínú ara, èyí táwọn olùwádìí gbà pé òun ló ń ṣèdíwọ́ fún rírí oorun sùn.

Ìròyìn náà sọ pé, nígbà tí wọ́n fi àwọn arúgbó tí kì í rí oorun sùn dáadáa síbi tí ìmọ́lẹ̀ wà fún wákàtí mẹ́rin nígbà tí oòrùn ti yọ (láti aago mẹ́wàá sí méjìlá ọ̀sán àti aago méjì di aago mẹ́rin) fún ọ̀sẹ̀ mẹ́rin, èròjà melatonin tí ara wọn mú jáde ròkè “sí iye kan náà pẹ̀lú ti àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n lò nínú àyẹ̀wò náà.” a Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n túbọ̀ rí oorun sùn dáadáa.

Àwọn àbájáde yìí mú kí àwọn olùwádìí “gbà pé àwọn arúgbó, pàápàá àwọn arúgbó tí kì í rí oorun sùn, tó jẹ́ pé inú ilé ni wọ́n máa ń wà láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, kì í gba ìmọ́lẹ̀ tí ó tó sára débi tára wọn á fi lè ṣiṣẹ́ níbàámu pẹ̀lú aago inú ara.” Nítorí pé àwọn àgbàlagbà kan máa ń lo àfikún èròjà melatonin kí wọ́n lè rí oorun sùn, ìròyìn náà sọ pé: “Tèèyàn bá ro aburú tí lílo oògùn melatonin lálòjù lè ṣe fún ara, wíwà nínú ìmọ́lẹ̀ ọjọ́kanrí lè pèsè ohun tí ara nílò fún àwọn arúgbó tí èròjà melatonin ti ara wọn ń pèsè kéré jọjọ. Èròjà tí ìmọ́lẹ̀ pèsè náà gbéṣẹ́, kò léwu, èèyàn sì lè dá a lò fún ara rẹ̀.”

Nítorí náà, tó bá jẹ́ pé inú ilé lo máa ń wà láti àárọ̀ ṣúlẹ̀ tó o sì níṣòro àìróorunsùn tó, kí ló dé tóò gbìyànjú láti máa lo àkókò púpọ̀ sí i níta gbangba. Tàbí kẹ̀, ó kéré tán kó o jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ tó pọ̀ gan-an máa wọ inú ilé rẹ ní ọ̀sán kó o sì jẹ́ kí yàrá tó ò ń sùn máa ṣókùnkùn tó bá ti di alẹ́. Wà á rí i pé ìmọ́lẹ̀ ọ̀sán máa ń jẹ́ kéèyàn sùn dáadáa lóru.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ẹgbẹ́ méjì ni wọ́n lò fún ìwádìí yìí: àwọn ọ̀dọ́ mẹ́wàá àtàwọn arúgbó mẹ́wàá tí ara wọn le dáadáa, tí àwọn àtàwọn arúgbó tí kì í rí oorun sùn jọ ń gbé ilé ìtọ́jú kan náà.