Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Retí Pé Kí Ọlọ́run Yọ Wọ́n Nínú Gbogbo Ewu?

Ṣé Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Retí Pé Kí Ọlọ́run Yọ Wọ́n Nínú Gbogbo Ewu?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Retí Pé Kí Ọlọ́run Yọ Wọ́n Nínú Gbogbo Ewu?

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Bíbélì máa ń sọ̀rọ̀ nípa agbára tí Ọlọ́run ní láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ ewu. Dáfídì Ọba sọ pé: “Gbà mí sílẹ̀, Jèhófà, lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú; kí o fi ìṣọ́ ṣọ́ mi àní lọ́wọ́ oníwà ipá.” (Sáàmù 140:1) Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn olùjọ́sìn Ọlọ́run ló jẹ́ pé díẹ̀ báyìí ló máa ń kù kí àwọn oníwà ipá tàbí àwọn ọ̀daràn ṣe wọ́n ní ṣùtá tàbí kí àjálù bá wọn. Àwọn mìíràn tiẹ̀ máa ń wò ó pé ó ní láti jẹ́ pé ọ̀nà ìyanu ni Ọlọ́run fi kó àwọn yọ, nítorí pé àwọn ìgbà mìíràn wà tí àjálù ti bá àwọn èèyàn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ọṣẹ́ ṣe wọ́n, kódà àwọn mìíràn kú ikú gbígbóná pàápàá.

ǸJẸ́ Jèhófà Ọlọ́run máa ń kó àwọn kan yọ nínú ewu tí kì í sì í kó àwọn mìíràn yọ? Ṣé ó yẹ ká retí pé Ọlọ́run á yọ wá lọ́nà àrà nígbà tí wàhálà tàbí àjálù bá ṣẹlẹ̀ lónìí?

Ààbò Lọ́nà Ìyanu Tí Bíbélì Ṣàkọsílẹ̀ Rẹ̀

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkọsílẹ̀ ló wà nínú Bíbélì nípa bí Ọlọ́run ṣe dáàbò bo àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lọ́nà àrà. (Aísáyà 38:1-8; Ìṣe 12:1-11; 16:25, 26) Ìwé Mímọ́ sì tún sọ àwọn àkókò mìíràn tí láburú ṣẹlẹ̀ sáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. (1 Ọba 21:1-16; Ìṣe 12:1, 2; Hébérù 11:35-38) Nígbà náà, ó ṣe kedere pé ìgbàkigbà tó bá wu Jèhófà, ó lè pèsè ààbò nítorí ìdí kan. Nítorí náà, tí àdánwò bá dé bá àwọn Kristẹni, tí kò sì lọ, kí wọ́n máà ronú pé ńṣe ni Ọlọ́run kọ àwọn sílẹ̀ o. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kó wà lọ́kàn wa digbí pé àwọn nǹkan búburú á ṣẹlẹ̀, kódà á ṣẹlẹ̀ sáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà pàápàá. Kí ló dé tọ́ràn fi rí bẹ́ẹ̀?

Ìdí Tí Àwọn Nǹkan Búburú Fi Ń Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Olóòótọ́ Ìránṣẹ́ Ọlọ́run

Ìdí kan ni pé gbogbo wa la ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé látọ̀dọ̀ Ádámù àti Éfà. Fún ìdí yìí, ìrora, ìjìyà àti ikú lè dé bá wa. (Róòmù 5:12; 6:23) Ìdí mìíràn ni pé àkókò òpin la wà. Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn tó ń gbé ní àkókò wa á jẹ́ “aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere.” (2 Tímótì 3:1-5) Bí ìwà ìfipábáni-lòpọ̀, jíjí-èèyàn-gbé, ìṣìkàpànìyàn àtàwọn ìwà ọ̀daràn mìíràn ṣe ń gbilẹ̀ sí i jẹ́rìí sí èyí.

Àárín àwọn èèyàn oníwà ipá ni ọ̀pọ̀ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń gbé tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́. Àwọn ẹni ibi wọ̀nyí tiẹ̀ máa ń dájú sọ wọ́n nígbà mìíràn. A lè kàgbákò nígbà mìíràn kìkì nítorí pé a rìn sí àsìkò tí láabi ṣẹlẹ̀. Bákan náà, ohun tí Sólómọ́nì sọ tún máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa, ó sọ pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.”—Oníwàásù 9:11.

Kò tán síbẹ̀ o, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn Kristẹni gangan làwọn èèyàn á dojú inúnibíni kọ nítorí pé wọ́n ń sin Ọlọ́run. Ó ní: “Ní ti tòótọ́, gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tímótì 3:12) Ọ̀rọ̀ yìí ti rí bẹ́ẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè kan ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí.

Nítorí náà, pé èèyàn ń bẹ̀rù Ọlọ́run kò sọ pé kó má kàgbákò àwọn oníwà ipá, àwọn ọ̀daràn, àjálù tàbí ikú òjijì. Sátánì ti gbìyànjú láti mú kí èèyàn ní èrò náà pé Jèhófà ti fi ààbò kan sára àwọn èèyàn Rẹ̀ tó fi jẹ́ pé búburú kankan ò ní ṣẹlẹ̀ sí wọn nígbèésí ayé wọn. (Jóòbù 1:9, 10) Ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀ o. Síbẹ̀, ó dá wa lójú pé bí Jèhófà ò bá tiẹ̀ dáàbò bò wá lọ́nà àrà nígbà tí aburú kan bá ṣẹlẹ̀, ó ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀.

Bí Jèhófà Ṣe Ń Dáàbò Bo Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Lóde Òní

Jèhófà ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀. Jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí àti níní ìmọ̀ Bíbélì lè jẹ́ ká mọ bá a ti ń lo òye àti bá a ti ń ní èrò tó bójú mu. Èyí kò ní jẹ́ ká ṣe àwọn àṣìṣe tí kò yẹ, á sì tún jẹ́ ká ṣe àwọn ìpinnu tó lọ́gbọ́n nínú. (Sáàmù 38:4; Òwe 3:21; 22:3) Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àjálù ló ti fo àwọn Kristẹni dá nítorí pé wọ́n ń fi ìmọ̀ràn tí Bíbélì fúnni sílò láti yẹra fún ìṣekúṣe, ìwà ìwọra, ìbínú àti ìwà ipá. Bákan náà, tí a ò bá báwọn èèyànkéèyàn kẹ́gbẹ́, á ṣòro ká wà níbi tí nǹkan burúkú ti máa ṣẹlẹ̀, ìyẹn ni pé a ò ní wà níbi tí kò yẹ ká wà lásìkò tí láabi á ṣẹlẹ̀. (Sáàmù 26:4, 5; Òwe 4:14) Àwọn tó ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò máa ń gbádùn ìgbésí ayé, ìdààmú kì í sábà bá ọkàn wọn, ara wọn sì máa ń le.

Ohun tó máa ń fúnni ní ìtùnú jù lọ ni mímọ̀ pé ká tiẹ̀ ní Ọlọ́run fàyè gba nǹkan burúkú kó ṣẹlẹ̀, òun kan náà á pèsè okun táwọn olùjọ́sìn rẹ̀ nílò láti gba ohun tó ṣẹlẹ̀ náà mọ́ra. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú un dá wa lójú, ó sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.” (1 Kọ́ríńtì 10:13) Bíbélì tún ṣèlérí pé Ọlọ́run á fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” ká lè fara da àjálù èyíkéyìí.—2 Kọ́ríńtì 4:7.

Bó Ṣe Wu Ọlọ́run Ló Ń Ṣe Nǹkan Rẹ̀

Ṣé ó yẹ káwọn Kristẹni máa retí pé kí Ọlọ́run yọ wọ́n lọ́nà àrà nígbàkigbà tí ewu bá ń bọ̀? Ohun tó wà nínú Bíbélì kò ti èyí lẹ́yìn o.

Lóòótọ́, bó bá wu Jèhófà Ọlọ́run ó lè mú ewu tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ sí èyíkéyìí lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kúrò. Bí ẹnì kan bá sì sọ pé ọ̀nà àrà ni Ọlọ́run fi yọ òun nínú ewu, kò yẹ kí ẹnikẹ́ni bá a jiyàn. Àmọ́ nígbà tí Jèhófà bá gba ohun burúkú kan láyè láti ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn rẹ̀, wọn ò gbọ́dọ̀ ronú pé ńṣe ni Ọlọ́run kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

Ǹjẹ́ ká jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé ìṣòro èyíkéyìí táwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ Jèhófà bá dojú kọ, ó máa dáàbò bò wọn. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ló máa mú ìṣòro náà kúrò tàbí kó fún wa lókun láti fara dà á. Tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ìṣòro náà gba ẹ̀mí wa, Jèhófà á jí wa dìde sí ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun rẹ̀.—Sáàmù 37:10, 11, 29; Jòhánù 5:28, 29.