Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣíṣèrànwọ́ Fún Àwọn Tó Kàgbákò Ìsẹ̀lẹ̀

Ṣíṣèrànwọ́ Fún Àwọn Tó Kàgbákò Ìsẹ̀lẹ̀

Ṣíṣèrànwọ́ Fún Àwọn Tó Kàgbákò Ìsẹ̀lẹ̀

“MO WO Ọ̀TÚN MO WO ÒSÌ, MO RÍ I TÍ ILÉ Ń WÓ LULẸ̀ TÍ INÁ SÌ Ń SỌ KẸ̀Ù. BÍ MO ṢE Ń SÁ LỌ NI MÒ Ń GBỌ́ TÁWỌN ÈÈYÀN Ń FIGBE TA LỌ́TÙN-ÚN LÓSÌ, WỌ́N FIGBE ÀDÚRÀ BỌNU BẸ́Ẹ̀ NI WỌ́N Ń PARIWO PÉ KÁWỌN ÈÈYÀN WÁ RÀN ÀWỌN LỌ́WỌ́. MO RÒ PÉ AYÉ FẸ́ PA RẸ́ NI.”—G. R., ẸNI TÓ RÙ Ú LÀ NÍGBÀ TÍ ILẸ̀ SẸ̀.

ÀRÀÁDỌ́TA ọ̀kẹ́ ìsẹ̀lẹ̀ ló ń wáyé lọ́dọọdún ní ilé ayé wa tó ń yí bíríbírí yìí. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ nínú iye yẹn ni kì í fi bẹ́ẹ̀ lágbára. a Síbẹ̀, ní ìpíndọ́gba, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogóje ìsẹ̀lẹ̀ tó ń wáyé lọ́dọọdún tó burú gan-an débi tá a fi lè pín wọn sọ́nà mẹ́ta, èyí tó “ga,” èyí tó “ga jù” tàbí èyí tó “peléke.” Nínú ìtàn ẹ̀dá, àwọn ilẹ̀ sísẹ̀ tó burú tó báyìí ti gbẹ̀mí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ó sì ti ba dúkìá tí kò níye jẹ́.

Ilẹ̀ sísẹ̀ tún máa ń sọ àwọn tó bá rù ú là di òkú-òòró. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ilẹ̀ ríri méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ gbo ilẹ̀ El Salvador jìgìjìgì níbẹ̀rẹ̀ ọdún 2001, olùṣekòkárí ìgbìmọ̀ tó ń gbani nímọ̀ràn nípa ìlera ọpọlọ ti àjọ ìlera orílẹ̀-èdè náà sọ pé: “Àwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìṣòro ìrònú òun ìhùwà èyí tí ìbànújẹ́, àìsírètí àti ìbínú ń fà.” Kò yani lẹ́nu nígbà náà ìdí tí àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera ní ilẹ̀ El Salvador fi ròyìn pé iye èèyàn tí ìsoríkọ́ àti hílàhílo ń bá jà ti fi ìdá mẹ́tàléláàádọ́rin lé sí i. Kódà, ìwádìí fi hàn pé nínú àwọn nǹkan táwọn tó wà ní àgọ́ ìdáàbòbò nílò jù lọ, ìtọ́jú ọpọlọ ló wà ní ipò kejì sí omi.

Àmọ́ ohun tó wà nínú ọ̀ràn ilẹ̀ sísẹ̀ ju ikú, bíba nǹkan jẹ́ àti àìnírètí lọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn àjálù wọ̀nyí ti mú káwọn èèyàn fi ìfẹ́ hàn lọ́nà tó ga tí wọ́n sì tún fi ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ hàn. Àwọn kan tiẹ̀ ti ṣiṣẹ́ àṣekára láti ṣàtúnṣe àwọn ilé tó ti wó wọ́n sì ti ran àwọn èèyàn tí ìgbésí ayé wọn dojú rú lọ́wọ́. Irú àwọn ìrànlọ́wọ́ wọ̀nyẹn ti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n kàgbákò ilẹ̀ sísẹ̀ tí ń dáni níjì, gẹ́gẹ́ bí a ṣe máa rí i.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ilẹ̀ ríri tí kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára lè wà lára àwọn wọ̀nyí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn ló sì ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ojú ìwé 13: Bàbá kan tí ń dámúsò pé wọ́n rí ọmọbìnrin òun ọlọ́dún márùn-ún yọ

[Credit Line]

Fọ́tò AP/Dimitri Messinis