Báwo Ni Mo Ṣe Lè Wàásù fún Àwọn Ọmọ Iléèwé Mi?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Wàásù fún Àwọn Ọmọ Iléèwé Mi?
“Lọ́jọ́ kan, mo wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe kòńgẹ́ ẹnì kan tí mo mọ̀. Ńṣe nìdí mi domi! Ọpẹ́lọpẹ́ ẹni tá a jọ ṣiṣẹ́ ló gbà mí kalẹ̀, òun ló sọ̀rọ̀ dípò mi.”—Alberto.
“Mo mọ̀ pé ọmọ kíláàsì mi kan ń gbé òpópónà yìí, mo bá ní kí ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin bá gbogbo àwọn tá à ń bá pàdé sọ̀rọ̀. Nígbà tó yá, ọ̀rọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ni ín lára ló bá ní kí n sọ̀rọ̀ ní ilé tó kàn. Ni mo bá kanlẹ̀kùn, káàsà, ọmọ kíláàsì mi yẹn ló yọ sí mi gan-n-boro! Ńṣe làyà mi là gààrà!”—James.
ÀWỌN ọ̀dọ́ sábàá máa ń rò pé kì í ṣe ohun tó “gbayì” láti máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ìsìn. Àmọ́ àwọn tó jẹ́ ọ̀dọ́ láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ mọrírì àǹfààní ńláǹlà tí Ọlọ́run fún wọn láti sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fún àwọn mìíràn. Ìdí rèé tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kópa nínú wíwàásù láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà. Àmọ́ tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù láwọn kan ń ṣe é o, ìbẹ̀rù pé àwọn lè lọ pàdé ẹnì tí àwọ́n mọ̀ níléèwé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣe díẹ̀ tí Jennifer ti jáde ilé ìwé gíga, síbẹ̀ ó sọ pé: “Ojora ṣì máa ń mú mi tí mo bá bá àwọn tá a jọ lọ síléèwé pàdé.”
Bó o bá jẹ́ ọ̀dọ́ Kristẹni, ó lè máa ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ó dájú pé kò sẹ́nì kankan nínú wa tó fẹ́ káwọn èèyàn fojú tí kò dára wo òun, nítorí náà ó lè ṣẹlẹ̀ dáadáa pé kẹ́rù bà wá díẹ̀ tó bá di pé ká bá ọmọ iléèwé wa kan sọ̀rọ̀ nípa ìsìn. a Àmọ́ kò bọ́gbọ́n mu rárá kó o jẹ́ kí ìbẹ̀rù sọ ọ́ di nǹkan míì. Ṣé o rántí ọkùnrin kan tí Bíbélì pè ní “Jósẹ́fù láti Arimatíà”? Ó gba àwọn nǹkan tó kọ́ lọ́dọ̀ Jésù gbọ́. Síbẹ̀, Bíbélì pe Jósẹ́fù ní “ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ṣùgbọ́n ọ̀kan tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀ nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ fún àwọn Júù.” (Jòhánù 19:38) Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ ná ká ló o ní ọ̀rẹ́ kan tí kì í fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹ jọ ń ṣọ̀rẹ́? (Lúùkù 12:8, 9) Abájọ nígbà náà tí Ọlọ́run fi fẹ́ kí gbogbo àwọn Kristẹni ṣe “ìpolongo ní gbangba” nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́. (Róòmù 10:10) Ìyẹn kan bíbá àwọn ọmọ iléèwé rẹ sọ̀rọ̀.
Jósẹ́fù ara Arimatíà borí ìbẹ̀rù rẹ̀ o, ó kéré tán, ó lọ gba àṣẹ láti sin òkú Jésù. Báwo nìwọ náà ṣe lè borí ìbẹ̀rù rẹ?
Máa Hára Gàgà Láti Wàásù
Dájúdájú, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kò tijú láti sọ ohun tó gbà gbọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Nínú Róòmù 1:15, ó sọ pé òun máa ń hára gàgà láti polongo ọ̀rọ̀ Bíbélì. Kí ló mú kó máa hára gàgà bẹ́ẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ tó wà ní ẹsẹ ìkẹrìndínlógún ṣe sọ, ó sọ pé: “Èmi kò tijú ìhìn rere; ní ti tòótọ́, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà sí gbogbo ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́.” Ìwọ náà ńkọ́? Ṣé o ti mú òtítọ́ da ara rẹ lójú ? (Róòmù 12:2) Ṣé ìwọ fúnra rẹ gbà gbọ́ pé “agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà” ni ọ̀rọ̀ inú Bíbélì jẹ́?
Pé ò ń tẹ̀ lé àwọn òbí rẹ lọ sípàdé ìjọ nìkan kò tó o. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Deborah sọ pé: “Tó bá jẹ́ ti lílọ sípàdé ni, ìyẹn kò le rárá nítorí pé àwọn òbí rẹ ló ń sọ pé kó o lọ. Àmọ́ táwọn èèyàn bá bi mí níbèérè nípa Bíbélì, n kì í mọ bí màá ṣe dá wọn lóhùn.” Ohun kan náà ni ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Mi Young sọ, ó ní: “Àwa fúnra wa gbọ́dọ̀ mú un dá ara wa lójú pé eléyìí gan-an ni òtítọ́.”
Kí ló máa sún ọ láti máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ Bíbélì tó o ní? Dídá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Sean sọ pé: “Nígbà tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnra rẹ, ìgbà yẹn lo máa tó ó lè sọ òtítọ́ di tìrẹ. Torí tara rẹ lo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́.” Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló lẹ́bùn ìkẹ́kọ̀ọ́. Shevon sọ pé: “Ìwé kì í wù mí í kà. Ìyẹn mú kó ṣòro fún mi níbẹ̀rẹ̀ láti máa ka Ilé Ìṣọ́ àti Jí! kí n sì tún máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Àmọ́ bí àkókò ti ń lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kà wọ́n.”
Kí ló máa jẹ́ àbájáde fífi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.” (Róòmù 10:17) Bí ìgbàgbọ́ rẹ àti ìdánilójú rẹ ti ń lágbára sí i, ó dájú pé ìṣesí rẹ á yí padà. Ọ̀dọ́ ọmọ ilẹ̀ Brazil kan tó ń jẹ́ Elisângela sọ pé: “Nǹkan iyì ni kí èèyàn jẹ́ Kristẹni, kì í ṣe ohun ìtìjú.” Àní, bí ìgbàgbọ́ rẹ ti ń fẹsẹ̀ múlẹ̀ sí i bẹ́ẹ̀ ni wàá rí i pé á máa wù ọ́ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, títí kan àwọn ọmọ kíláàsì rẹ. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwa . . . lo ìgbàgbọ́ àti nítorí náà a sọ̀rọ̀.” (2 Kọ́ríńtì 4:13) Yàtọ̀ síyẹn, báwo ni “ọrùn” rẹ ṣe fẹ́ “mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀” àwọn ẹlòmíràn tó o bá ń fawọ́ ìmọ̀ tí ń fúnni ní ìyè sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó ò ń rí lójoojúmọ́?—Ìṣe 20:26, 27.
Àmọ́ àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ kan máa ń sọ pé àwọn kò mọ ohun tí àwọ́n lè bá àwọn mìíràn sọ nípa Bíbélì. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Joshua sọ pé: “Tó ò bá mọ ohun tó o máa sọ, o ò lè gbádùn iṣẹ́ ìwàásù rárá.” Níbí yìí náà, níní òye tó jinlẹ̀ nípa Bíbélì á jẹ́ kó o lè lò ó bó ti tọ́ àti bó ti yẹ. (2 Tímótì 2:15) Nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ọ̀dọ́ lè lọ bá àwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn àwọn lọ́wọ́ láti mú ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àwọn sunwọ̀n sí i. Matthias, ọ̀dọ́ ọmọ ilẹ̀ Jámánì kan sọ pé: “Ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ dáadáa ni mo tó ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù, yàtọ̀ sígbà tó jẹ́ ńṣe ni mo kàn máa fìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọni lásán.”
Ní paríparí rẹ̀, gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fìgboyà sọ̀rọ̀. (Ìṣe 4:29) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí i pé Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn yìí. Nínú 1 Tẹsalóníkà 2:2 ó sọ pé: “[A] máyàle nípasẹ̀ Ọlọ́run wa láti sọ ìhìn rere Ọlọ́run fún yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìjàkadì.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìwádìí kan ti sọ, a lè tú ọ̀rọ̀ yìí sí, “Ọlọ́run mú ìbẹ̀rù kúrò lọ́kàn wa.” Nítorí náà, o ò ṣe gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó jọ̀ọ́ kó mú ìbẹ̀rù kúrò lọ́kàn rẹ?
Jẹ́ Kí Wọ́n Mọ̀ Pé Ajẹ́rìí Ni Ọ́
Níbàámu pẹ̀lú àdúrà yẹn, kó o wá gbégbèésẹ̀ akin ló kù. Chic, ọ̀dọ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan dámọ̀ràn pé: “Sọ fún àwọn ọmọ kíláàsì rẹ pé Ajẹ́rìí ni ọ́.” Nígbà tí kì í ṣe pé ‘ọmọ ẹ̀yìn ní ìkọ̀kọ̀’ lo fẹ́ jẹ́. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Rebecca sọ pé ẹ̀rù máa ń ba òun tẹ́lẹ̀ pé òún lè lọ pàdé ẹni tí òún mọ̀ nígbà tí òún bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́, ó ní òún rí i pé “tó o bá sọ fún wọn pé Kristẹni ni ọ́ àti pé o máa ń wàásù láti ilé dé ilé, nígbà míì, ńṣe ni wọ́n máa bi ẹ́ pé, ‘Ó dáa, ṣé wàá wá sílé wa lọ́jọ́ kan?’”
Àmọ́ kí ló dè tí wàá dúró dìgbà tẹ́ ẹ máa pàdé lójijì? Wá àwọn ọ̀nà tó o lè gbà sọ nípa ohun tó o gbà gbọ́ níléèwé. Rántí àwọn ìbéèrè tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Báwo . . . ni wọn yóò ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tí wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe gbọ́ láìsí ẹnì kan láti wàásù?” (Róòmù 10:14) Ìwọ lo láǹfààní jù lọ láti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ lọ́wọ́ láti gbọ́. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Iraida sọ pé: “Ilé ìwé jẹ́ ìpínlẹ̀ ìwàásù kan tó jẹ́ pé àwa tá a jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ nìkan la lè débẹ̀.” Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ fi ń gbá àǹfààní yìí mú tí wọ́n sì máa ń wàásù lọ́nà tí kì í ṣe bí àṣà.
Nígbà míì kẹ̀, wọ́n máa ń yan àwọn iṣẹ́ kan fúnni ní kíláàsì tó lè fún ọ láǹfààní láti sọ òtítọ́ Bíbélì fún àwọn mìíràn. Ọ̀dọ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ Jaimie sọ pé: “A ń jíròrò nípa ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ní kíláàsì lọ́jọ́ kan, mo sì sọ nípa ohun tí mo gbà gbọ́. Ni ọmọkùnrin kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò dákan mọ̀ kò sì yẹ kí wọ́n máa wà níléèwé. Àmọ́, kíá làwọn ọmọ tó kù ní kíláàsì ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbèjà mi.” Kò sí àní àní pé jíjẹ́ tí ọmọbìnrin yìí jẹ́ Kristẹni àwòfiṣàpẹẹrẹ ló jẹ́ kí wọ́n gbèjà rẹ̀ bẹ́ẹ̀. Jaimie wá fi kún un pé: “Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún mi láti fi ẹ̀dá kan ìwé náà, Is There a Creator Who Cares About You? fún ọmọ kíláàsì mi kan.” b
Micu, ọmọdébìnrin ọlọ́dún mẹ́rìnlá kan ní ilẹ̀ Romania náà sọ ìrírí kan tó jọ ìyẹn. Ó sọ pé: “Olùkọ́ mi sọ pé a máa ní ìjíròrò kan ní kíláàsì tó dá lórí ọtí líle, tábà àti oògùn olóró. Ni mo bá mú ìtẹ̀jáde Jí! ti April 8, 2000 tó sọ̀rọ̀ lórí kókó náà, ‘Bóo Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Sìgá Mímu’ lọ sí iléèwé. Ọmọ kíláàsì mi kan rí ìwé ìròyìn yìí, ló bá gbà á lọ́wọ́ mi kò sì dá a padà fún mi mọ́. Lẹ́yìn tó kà á, ó sọ pé òún máa rí i dájú pé òún jáwọ́ nínú sìgá mímu.”
Gbogbo ìgbà kọ́ ni wàá máa bá irú ipò dídára bẹ́ẹ̀ yẹn pàdé o. Àmọ́ Oníwàásù 11:6 rọ̀ wá pé: “Ní òwúrọ̀, fún irúgbìn rẹ àti títí di ìrọ̀lẹ́, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ sinmi; nítorí ìwọ kò mọ ibi tí èyí yóò ti ṣe àṣeyọrí sí rere.” Ká tiẹ̀ ní nǹkan kò wá rí bó o ṣe lérò, sísọ ohun tó o gbà gbọ́ fún àwọn mìíràn níléèwé á jẹ́ kó rọrùn fún ọ lọ́jọ́ mìíràn láti bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa gbádùn mọ́ni ká ní o ṣèèṣì bá ọ̀kan nínú wọn pàdé nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Ọ̀dọ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ Jessica sọ pé: “Kò sóhun tó nira rárá nínú wíwàásù fún àwọn tó o mọ̀ níléèwé, nítorí pé ẹ kúkú ti mọra tẹ́lẹ̀.” Ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti rí bí ara àwọn ọmọ iléèwé rẹ kan á ṣe wà lọ́nà láti mọ̀ nípa ohun tó o gbà gbọ́.
Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo wọn ló máa gbà ọ́ tọwọ́tẹsẹ̀ o. Àmọ́ ìmọ̀ràn tó wúlò tí Jésù fúnni ni pé: “Ibi yòówù tí ẹnikẹ́ni kò bá ti gbà yín wọlé tàbí fetí sí ọ̀rọ̀ yín, nígbà tí ẹ bá ń jáde kúrò ní ilé yẹn . . . ẹ gbọn ekuru ẹsẹ̀ yín dànù.” (Mátíù 10:14) Lédè mìíràn, má ronú pé ìwọ ni wọ́n kọ̀. Rọra fibẹ̀ sílẹ̀ lálàáfíà kó o sì wá ẹlòmíràn tó máa nífẹ̀ẹ́ láti gbọ́. Bópẹ́ bóyá, wàá rí àwọn olóòótọ́ ọkàn tí ebi òtítọ́ ń pa tí wọ́n sì fẹ́ẹ́ gbọ́. Ǹjẹ́ inú rẹ kò ní í dùn tí ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí bá lọ jẹ́ ọmọ iléèwé rẹ? Tó bá lọ ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, wàá yọ̀ pé o borí ẹ̀rù tó ti ń bà ọ́ tẹ́lẹ̀ láti bá àwọn ọmọléèwé rẹ sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Bí Mo Bá Lọ Pàdé Ọmọ Iléèwé Mi Ńkọ́?,” nínú ìtẹ̀jáde March 8, 2002.
b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]
“Nígbà tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnra rẹ, ìgbà yẹn lo máa tó lè sọ òtítọ́ di tìrẹ.”—Sean.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Má bẹ̀rù láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé Ajẹ́rìí ni ọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ń yàn fúnni ní kíláàsì máa ń fúnni ní àǹfààní láti sọ nípa òtítọ́ Bíbélì