Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ilẹ̀ Sísẹ̀ Àti Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Ṣe Kàn Ọ́

Bí Ilẹ̀ Sísẹ̀ Àti Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Ṣe Kàn Ọ́

Bí Ilẹ̀ Sísẹ̀ Àti Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Ṣe Kàn Ọ́

ṢÁÁJÚ ikú Jésù, ó sàsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ tá á fi hàn pé ayé yìí ti wà ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Ó sọ pé lára àwọn nǹkan tó máa sàmì sí àkókò ọ̀hún ni àjàkálẹ̀ àrùn, àìtó oúnjẹ àti ogun ńláǹlà. Ó tún mẹ́nu kan “ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà” pé ó máa ṣẹlẹ̀ “láti ibì kan dé ibòmíràn.” (Mátíù 24:3, 7; Lúùkù 21:10, 11) Ṣé àkókò tiwa ni Jésù ń sọ?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́. Ohun tí wọ́n ṣáà ń tẹnu mọ́ ni pé ìsẹ̀lẹ̀ kò tíì fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ lẹ́nu ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí. Kódà, Ibùdó Ìsọfúnni Nípa Ìsẹ̀lẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé ìsẹ̀lẹ̀ tó wọn 7.0 àti jù bẹ́ẹ̀ lọ lórí òṣùwọ̀n Richter “kò fi bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀” jálẹ̀ ọ̀rúndún ogún. a

Àmọ́ ṣá o, kíyè sí i pé ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jésù kò ní kí iye ìsẹ̀lẹ̀ tó ń wáyé pọ̀ sí i tàbí kó lágbára sí i. Ohun tí Jésù sọ ni pé ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà á wà láti ibì kan dé ibòmíràn. Síwájú sí i, ó sọ pé àwọn nǹkan wọ̀nyí ló máa jẹ́ “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà.” (Mátíù 24:8) Kì í ṣe iye ilẹ̀ sísẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ tàbí bí wọ́n ṣe gbéwọ̀n tó lórí òṣùwọ̀n Richter ló máa fi bí ìsẹ̀lẹ̀ ṣe le tó hàn, àmọ́ ipa tó ní lórí àwọn èèyàn.

Kò sírọ́ níbẹ̀ pé ilẹ̀ sísẹ̀ ti fa wàhálà tó pọ̀ lákòókò wa. Àní, ní ọ̀rúndún ogún, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ṣòfò ẹ̀mí tàbí táwọn àjálù wọ̀nyí sọ dẹni tí kò nílé lórí. Àwọn ògbógi sọ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kú yìí kì bá ti máà kú. Ìròyìn orí rédíò BBC sọ pé: “Láwọn orílẹ̀ èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ kọbi ara sáwọn ìlànà ìkọ́lé, àwọn ò mọ̀ ju kí wọ́n ti kọ́lé olówó pọ́ọ́kú káwọn èèyàn tó ń rọ́ lọ sáwọn ìlú ńlá lè ríbi gbé.” Nígbà tí Ben Wisner, tó jẹ́ ọ̀mọ̀ràn kan nípa àjálù ìlú ńlá ń sọ̀rọ̀ nípa àjálù méjì tó ṣẹlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó sọ pé: “Ilẹ̀ sísẹ̀ kọ́ ló pa àwọn èèyàn yìí o. Àṣìṣe ẹ̀dá, ìdágunlá, ìwà ìbàjẹ́ àti ìwọra ló pa wọ́n.”

Bẹ́ẹ̀ ni o, ohun tó máa ń gbẹ̀mí èèyàn nígbà míì tí ilẹ̀ bá sẹ̀ ni ìmọtara-ẹni-nìkan àti àìka-ǹkan-sí ẹ̀dá ènìyàn. Kẹ́ ẹ sì wáá wò ó, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mìíràn nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan yìí mẹ́nu ba irú àwọn ìwà yìí. Bíbélì sọ pé ní àkókò yẹn, àwọn èèyàn á di “anìkànjọpọ́n, olùfẹ́ owó,” àti “aláìnígbatẹnirò.” (2 Tímótì 3:1-5, The Amplified Bible) Ńṣe ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí àti àwọn ọ̀rọ̀ Jésù nípa òpin ètò àwọn nǹkan, fún wa ní ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Ọlọ́run máa tó fún ẹ̀dá ènìyàn tí wàhálà ti bá ní ìtura kúrò lọ́wọ́ gbogbo nǹkan tó ń fa ìrora àti ìjìyà lọ́wọ́ tá a wà yìí, títí kan ilẹ̀ sísẹ̀.—Sáàmù 37:11.

Ṣé wà á fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìrètí tá a gbé karí Bíbélì yìí? Kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àdúgbò rẹ, tàbí kó o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tá a tò sójú ìwé 5.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn kan sọ pé ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tó ń ròkè sí i ló ń jẹ́ ká máa gbọ́ àwọn ìròyìn pé ìsẹ̀lẹ̀ túbọ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí i, nítorí pé òun ló ń mú káwọn ìmìtìtì ilẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ wá sójú táyé.