Iṣẹ́ Abiyamọ Bí O Ṣe Lè Ṣe É Láṣeyanjú
Iṣẹ́ Abiyamọ Bí O Ṣe Lè Ṣe É Láṣeyanjú
Tó bá jẹ́ lóòótọ́ làwọn ọmọdé òní jẹ́ àgbà ọ̀la, nígbà náà ó yẹ ká bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin tó tọ́ wọn, ìyẹn àwọn ìyá wọn, ká bọlá fún wọn ká sì tì wọ́n lẹ́yìn gbágbáágbá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn èèyàn ń gbà wo iṣẹ́ ọmọ títọ́ lóde ìwòyí, ohun tí Bíbélì sọ ni pé ẹ̀bùn tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá làwọn ọmọ jẹ́, ó sì lè jẹ́ orísun ayọ̀ fún àwọn òbí. (Sáàmù 127:3-5) Síbẹ̀, kì í ṣe pé Ìwé Mímọ́ ń kóyán iṣẹ́ àwọn abiyamọ kéré. Bíbélì sọ púpọ̀ lára àwọn ìpèníjà tó wé mọ́ jíjẹ́ abiyamọ.
Ìpinnu táwọn òbí bá ṣe nípa ọmọ títọ́ àti ṣíṣe iṣẹ́ abiyamọ máa ń nípa lórí ìgbésí ayé àti ìwà àwọn ọmọ wọn gan-an. Àwọn ìpinnu yìí lè yí ìgbésí ayé àwọn òbí padà, ìdí rèé tó fi yẹ kí wọ́n fara balẹ̀ ṣe àwọn ìpinnu náà. Wọ́n ní nínú àwọn ìbéèrè bíi: Ṣé ó yẹ kí ìyá máa lọ síbi iṣẹ́? Tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, báwo ni àkókò tá á máa lò á ṣe pọ̀ tó? Ta ló máa bójú tó àwọn ọmọ nígbà tí ìyá bá lọ síbi iṣẹ́? Olórí gbogbo rẹ̀ ni pé, àwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo nǹkan tí wọ́n mọ̀ pé ó yẹ fún àwọn ọmọ wọn kí wọ́n sì ṣe ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run.
Aísáyà 40:11, tó fi hàn pé Ọlọ́run ò kóyán àwọn abiyamọ àtàwọn ọmọ kéékèèké kéré, ó sì “máa rọra dà” wọ́n bí olùṣọ́ àgùntàn ti ń da agbo ẹran. Ọlọ́run fi ìfẹ́ yìí hàn nípa fífún àwọn abiyamọ ní àwọn ìtọ́sọ́nà nínú Bíbélì tó lè mú kí wọ́n gbádùn títọ́mọ kí wọ́n sì ṣe àṣeyọrí.
Àmọ́ o, kò yẹ káwọn ìyá máa lérò pé ṣíṣe ìpinnu tó dára jẹ́ ẹrù tí àwọn á máa dá gbé. Wọ́n lè rí ìtùnú ńlá nínú ọ̀rọ̀ tó wà nínú❖ Máa lo òye: Ó yẹ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé àwọn Kristẹni máa ń lo òye. (Fílípì 4:5) Janet Penley, tó jẹ́ òǹkọ̀wé àti abiyamọ rí i pé ìlànà yìí dára gan-an. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo di abiyamọ, ohun tí mò ń retí pọ̀ gan-an. Mo rò pé ọ̀nà tí màá gbà ṣe abiyamọ tèmi á jẹ́ èyí tí kò tíì sẹ́ni tó ṣe irú rẹ̀ rí. Onírúurú ìwé ni mo kà, mo sì tẹ́tí sáwọn ọ̀mọ̀ràn. Àmọ́ èyí tí inú mi ì bá fi dùn pé mo ṣàṣeyọrí, ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí ṣe mí bí ẹni pé n kì í ṣe ìyá tó múná dóko, ara ò sì rọ̀ mí.” Ó sọ pé “téèyàn bá ń wo aago aláago ṣiṣẹ́, tó jẹ́ àwọn ìlànà ‘tí ò ṣe é bá’ ló ń sáré lé, ńṣe ni gbogbo nǹkan á wá sú olúwa rẹ̀, ara rẹ̀ kò ní balẹ̀, ọkàn rẹ̀ á sì máa dá a lẹ́bi.”
❖ Mú nǹkan rọrùn: Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé: “Ohun tó ṣeé ṣe káwọn ìdílé sọ nù pẹ̀lú ìgbésí ayé oníkòókòó jàn-ánjàn-án tí wọ́n ń gbé yìí ni ojúlówó ìrírí ìgbà ọmọdé àti ayọ̀ ìgbésí ayé ìdílé.” Ìdí rèé tí ọ̀pọ̀ ìyálọ́mọ fi ń fẹ́ gbé ìgbésí ayé tó túbọ̀ rọrùn. Báwo lo ṣe lè ṣe èyí? Lákọ̀ọ́kọ́, gbé àwọn ohun kan kalẹ̀ tó jẹ́ àkọ́múṣe, kó o wá gbájú mọ́ “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” títí kan àkókò àti ìtọ́jú táwọn ọmọ rẹ nílò. (Fílípì 1:10, 11) Èkejì, ronú lórí bó o ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ. O lè pa àwọn ìgbòkègbodò àtàwọn ohun ìní kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.
Kí ló ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ? Ṣé kó o ti ní gbogbo nǹkan lẹ́ẹ̀kan ni, tàbí o lè pa àwọn ohun kan tó o fẹ lé bá tì ná kọ́wọ́ rẹ bàa lè tẹ òmíràn? Abiyamọ ni Carolyn, kò sì fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ. Ó sọ ọgbọ́n tó ta sí ipò àìní rẹ̀ pé: “Mo mú káwọn nǹkan rọrùn mo sì dín àwọn ìnáwó kù.” Gloria, tó ní ọmọ mẹ́ta sọ pé: “A ò lówó láti ra àwọn aṣọ ìgbàlódé olówó ńlá, àmọ́ mo máa ń rán aṣọ fáwọn ọmọ màá sì sọ fún wọn pé àkànṣe láwọn aṣọ náà nítorí kò sẹ́ni tó tún ní irú rẹ̀.”
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ẹni “tí ń fi ìṣọ́ ṣọ́ ìfòyemọ̀ yóò rí ire.” (Òwe 19:8) Èèyàn nílò ìfòyemọ̀ láti mọ èyí tó yẹ láàárín onírúurú fàájì, ohun èèlò lóríṣiríṣi àtàwọn àṣà tó pọ̀ lọ jàra, táwọn òbí àtàwọn ọmọ dojú kọ. Ìyá kan tó ń jẹ́ Judith ní Gúúsù Áfíríkà sọ pé: “Àtìgbàdégbà làwọn nǹkan àkọ̀tun àkọ̀tun ń dé, ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tó dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ àti ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan mìíràn!” Ẹ wo bí Angela, ìyá ọlọ́mọ mẹ́rin ní Jámánì ṣe kojú ìpèníjà náà, ó ní: “Ńṣe lo máa yan àwọn ohun tó ṣe pàtàkì tó sì máa wúlò fún ọ, kó o sì ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti ṣe bákan náà.”
Òwe 3:21, Contemporary English Version) Ká ní ibi tó o ti ń ṣiṣẹ́ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ jìnnà sílé, ṣé owó tó ń wọlé fún ọkọ rẹ lè tó ìdílé yín ná? Kó o tó lè dáhùn ìbéèrè yìí, wo iye tí owó rẹ máa ń kù lẹ́yìn tó o bá ti yọ owó orí, owó tẹ́ ẹ fi tọ́jú ọmọ, owó tó o fi ń wọ ọkọ̀ lọ síbi iṣẹ́, owó aṣọ, owó tó o fi ń ra oúnjẹ jẹ níta àtàwọn ìnáwó mìíràn. Bákan náà, bí àpapọ̀ owó tó ń wọlé fún ìwọ àti ọkọ rẹ bá fi yín ságbo àwọn tówó gọbọi ń wọlé fún, èyí lè mú kí owó orí tí ọkọ rẹ á máa san pọ̀ gan-an. Ó máa yà ẹ́ lẹ́nu láti rí i pé iye tó máa ṣẹ́ kù kò tó nǹkan.
❖ Ṣe àwọn àyípadà tó o bá lè ṣe: Bíbélì gbani nímọ̀ràn pé: “Lo làákàyè kí o sì ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu.” (Ohun táwọn kan ṣe ni pé, ìwọ̀nba wákàtí díẹ̀ ni wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ tàbí kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nítòsí ilé. Owó tá á wọlé fún wọn lè máà tó nǹkan àmọ́ wọ́n á lè lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Ká ní iṣẹ́ rẹ ṣe pàtàkì sí ọ nítorí iyì tó ń fún ọ àti nítorí àwọn ohun tó ò ń ṣe láṣeyọrí, àmọ́ síbẹ̀ o pinnu láti fi iṣẹ́ ọ̀hún sílẹ̀ ńkọ́? Ó yẹ kó o wá ọ̀nà bó o ṣe máa ní iyì àti àṣeyọrí nígbà tí o ò bá lọ ṣiṣẹ́ níta mọ.
❖ Wá ìrànlọ́wọ́: Léraléra ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé ‘igbe fún ìrànlọ́wọ́’ lè sèso rere. (Ẹ́kísódù 2:23, 24; Sáàmù 34:15) Ó yẹ kí ọkọ lè ran ìyàwó rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tí ìyàwó bá nílò rẹ̀. Bí ọkọ rẹ bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ, ẹ ó lè jọ ṣètò bí ẹ óò ṣe máa pín iṣẹ́ ilé ṣe, àkókò á sì wà láti bá ohun tẹ́yin méjèèjì ń lé, irú bíi wíwà pẹ̀lú àwọn ọmọ yín. Tó bá tún ṣeé ṣe, ó yẹ kí ìyá tún wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ àwọn èèyàn mìíràn, títí kan àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ gidi, tí wọ́n fẹ́ràn ohun tí obìnrin náà fẹ́ràn tí wọ́n sì jọ ní ohun kan náà tí wọ́n ń lépa.
Ọ̀pọ̀ abiyamọ ń rí ìrànlọ́wọ́ tó wúlò lọ́dọ̀ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn nínú ìjọ Kristẹni tí wọ́n wà. María, tó lọ́mọ mẹ́ta sọ pé “sísún mọ́ àwọn tó wà nínú ìjọ” jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí “Ọlọ́run gbà ń fi ìfẹ́ àti àánú hàn sí wa, ó sì tún ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn wá pé òun kì í fi ọ̀ràn wa ṣeré rárá.”
❖ Ara ń fẹ́ ìsinmi: Kódà, Jésù gan-an tó jẹ́ èèyàn pípé tó sì lókun nínú dáadáa sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí ‘àwọ́n lọ ní àwọn nìkan sí ibi tí ó dá, kí àwọ́n sì sinmi díẹ̀.’ (Máàkù 6:30-32) Láti lè jẹ́ abiyamọ tó ṣàṣeyọrí, ó yẹ kí o lókun nínú kí o lè rí nǹkan lò nígbà tí ìṣòro bá dé. Òótọ́ ni pé àwọn ọmọ fẹ́ kó o wà pẹ̀lú àwọn nígbà gbogbo, àmọ́ wọ́n tún fẹ́ máa rí ọ kí inú rẹ máa dùn kó o má sì ṣàníyàn. Ara rẹ ń fẹ́ ìsinmi tí ó tó.
Angela tá a mẹ́nu kàn ṣáájú, sọ ètò tó ṣe fún ìsinmi. Ó ní: “Mo ya àkókò kan sọ́tọ̀ nídàájí. Mò ń lo, ó kéré tán, ọgbọ̀n ìṣẹ́jú fún ara mi. Èmi àti ọkọ mi sì tún ní alẹ́ kan tàbí méjì láàárín ọ̀sẹ̀ nígbà táwọn ọmọ máa lọ sápá ibòmíràn nínú ilé, tí wọ́n á wà níbẹ̀ tí wọ́n á sì máa rọra ṣe àwọn nǹkan láìsí ariwo. Èyí á jẹ́ kí èmi àti ọkọ mi lè lo wákàtí kan fún ara wa.”
❖ Fí àwọn nǹkan tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́: A ti kíyè sí i pé àìfi ìdí téèyàn fi ń ṣe abiyamọ sọ́kàn àti àìfi àwọn ohun tó ṣe pàtàkì sí ipò iwájú ló ń fa ìṣòro àwọn abiyamọ. Bí àwọn ìdílé Kristẹni bá pawọ́ pọ̀ fi Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn, ayọ̀ ló máa ń tìdí rẹ̀ jáde. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Fífọkànsin Ọlọ́run ṣàǹfààní fún ohun gbogbo, bí ó ti ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀.” (1 Tímótì 4:8) Ìdílé tó bá ń fọkàn sin Ọlọ́run tó tún tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀ tó wà nínú Bíbélì á ní ayọ̀. Kódà, bó jẹ́ ẹnì kan péré nínú ìdílé ló ń fi àwọn ìlànà inú Bíbélì sílò, nǹkan máa ń sàn dáadáa ju ìgbà tí ẹni kankan kò ṣe bẹ́ẹ̀ lọ.
Kristẹni ni ìyá kan tó ń jẹ́ Adele, ó máa ń ṣiṣẹ́ látàárọ̀ di alẹ́, ó sì ti rí àǹfààní tó wà nínú fífi ọwọ́ pàtàkì mú nǹkan tẹ̀mí. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìlànà àtàwọn ìsọfúnni ló wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé karí Bíbélì, wọ́n sì ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun táwọn ọmọ wa ń dojú kọ àti bá a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Bó o ṣe ń rí i táwọn ọmọ rẹ ń fi àwọn ohun tẹ̀mí tó ò ń kọ́ wọn sílò á jẹ́ kó o nímọ̀lára pé o ò ṣàṣedànù. Bó o bá rí i pé wọ́n ń tẹ̀ síwájú díẹ̀díẹ̀ nínú ìwà wọn àti bí wọ́n ṣe ń ronú, wàá mọ̀ pé wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn ìsọfúnni àtàwọn ìlànà tó o fún wọn àti pé gbogbo ìsapá rẹ kò já sófo.” a
Bẹ́ẹ̀ ni o, èèyàn lè borí ohun ìdènà tó ń kojú àwọn abiyamọ dáadáa. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fúnni ní ìdánilójú tó ń tuni nínú náà pé gbogbo làálàá àwọn abiyamọ tó ń ṣiṣẹ́ wọn bí iṣẹ́ tí wọ́n tún ń yááfì àwọn ohun kan, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ wọn lé e kò ní já sí asán. Àwọn abiyamọ tí wọ́n ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ lè rí ìtura nínú ìlérí tó ṣe pé òun á “fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀.”—Aísáyà 40:29.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ àwọn ìwé mélòó kan tá a gbé karí Bíbélì fún títọ́ àwọn ọmọ. Lára wọn ni Iwe Itan Bibeli Mi, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, àti Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]
Ẹní Bíni Là Á Jọ
Gẹ́gẹ́ bí abiyamọ, o lè máa ṣe kàyéfì nígbà mìíràn nípa bí ìwà rẹ ṣe ń nípa lórí ìgbésí ayé ọmọ rẹ. Nígbà míì, ó lè dà bí ẹni pé ẹgbẹ́, àwọn olùkọ́, eré ìdárayá, eré orí fídíò àti orin ń nípa lórí ọmọ rẹ ju ìwọ fúnra rẹ lọ.
Gbé àpẹẹrẹ Jókébédì, ìyẹn ìyá Mósè yẹ̀ wò. Ó gbé ayé nígbà tí nǹkan nira gan-an kò sì láṣẹ lórí ohun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe fún ọmọ rẹ̀. Síbẹ̀, ó lo àǹfààní tó ní láti tọ́ ọ dàgbà. Lákọ̀ọ́kọ́, ó lo ìgbàgbọ́ kò sì bẹ̀rù, èyí ni kò jẹ́ kí wọ́n pa Mósè. Ọlọ́run san ẹ̀san ìgbàgbọ́ rẹ̀ yìí nípa dídáàbò bo ọmọ náà. Yàtọ̀ sí ìyẹn, Ọlọ́run tún ṣètò àwọn nǹkan débi tí Jókébédì fi wá di olùtọ́jú ọmọ náà, òun sì ni ìyá tó tọ́ ọ dàgbà.—Ẹ́kísódù 1:15, 16; 2:1-10.
Ẹ̀rí wà pé Mósè fìwà jọ ìyá rẹ̀. Pẹ̀lú bí Mósè ṣe sún mọ́ ọba Íjíbítì tó, nígbà tó di ọkùnrin tán, kò fi àjọṣe àárín òun àtàwọn Hébérù àti Ọlọ́run wọn ṣeré. Èyí fi hàn bí ìwà àwọn òbí rẹ̀ ṣe ràn án tó nígbà tó wà léwe.—Hébérù 11:24-26.
Kò sí tàbí ṣùgbọ́n pé ìwọ ìyá ní àǹfààní láti kọ́ ọmọ rẹ ju Jókébédì lọ. Ǹjẹ́ ò ń lo àǹfààní ìgbà èwe ọmọ rẹ láti fún un láwọn ìtọ́ni tó máa wà pẹ́ títí, tí Ọlọ́run sì fọwọ́ sí? Àbí àwọn àṣà tó lòde lò ń jẹ́ kó nípa lórí ọmọ rẹ bó ṣe ń dàgbà?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jẹ́ kí àwọn mìíràn náà lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ilé, wá àkókò tí wàá fi sinmi, kó o sì fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sípò kìíní