Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kíkojú Àbájáde Rẹ̀

Kíkojú Àbájáde Rẹ̀

Kíkojú Àbájáde Rẹ̀

“ÀTÀÁRỌ̀ LA TI Ń FẸSẸ̀ RÌN. Ẹ̀MÍ WA LÀ Ń SÁ FÚN. A Ò RÓMI MU, A Ò RÓÚNJẸ JẸ. GBOGBO ILÉ LÓ TI WÓ TÁN.”—HARJIVAN, Ó YÈ BỌ́ NÍNÚ ÌSẸ̀LẸ̀ TÓ WÁYÉ NÍ ÍŃDÍÀ TÓ RINLẸ̀ TÓ 7.9 LÓRÍ ÒṢÙWỌ̀N RICHTER.

ÀYÀ èèyàn máa ń já burúkú burúkú bí ilẹ̀ bá sẹ̀ ní sàkáání èèyàn. Ẹnì kan tó rù ú là nígbà tí ilẹ̀ sẹ̀ ní Taiwan lọ́dún 1999 sọ pé: “Ńṣe làwọn ìwé ń já bọ́ lọ́tùn-ún lósì látinú àpótí tó ga tó ẹsẹ̀ bàtà mẹ́jọ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibùsùn mi. ‘Akoto tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rà tí mo máa ń dé lórí alùpùpù mi bọ́ látorí àpótí tí mo fi sí, ó sì bọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ orí mi lórí ibùsùn.’” Ó fi kún un pé, ‘ì bá ti pa mí.’

Lẹ́yìn Téèyàn Ti Yè É Bọ́

Àyà èèyàn máa ń já gan-an tó bá wà níbi tí ilẹ̀ bá ti sẹ̀, béèyàn bá sì yè é bọ́, onítọ̀hún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni. Láàárín àwọn wákàtí tó tẹ̀ lé ìṣẹ̀lẹ̀ náà, pẹ̀lú ìgboyà làwọn òṣìṣẹ́ tó ń pèsè ìrànlọ́wọ́ fi máa ń wá àwọn tó ṣèṣe kiri tí wọ́n á sì tọ́jú wọn. Jìnnìjìnnì máa ń bo àwọn náà lọ́pọ̀ ìgbà tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ọkùnrin kan tó ronú láti gbẹ́ àwókù ilé tó bo aládùúgbò rẹ̀ mọ́lẹ̀ nígbà tí ilẹ̀ sẹ̀ láìpẹ́ yìí ní El Salvador sọ pé: “A gbọ́dọ̀ fi tìṣọ́ratìṣọ́ra ṣe é. Nítorí bí ilẹ̀ bá tún mì pẹ́nrẹ́n, wíwó làwọn ògiri tó kù yìí á wó.”

Ẹ̀mí ìfara-ẹni rúbọ gbáà làwọn ènìyàn máa ń lò nígbà míì láti ran àwọn tí àjálù bá lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ilẹ̀ sísẹ̀ ńlá kan ṣẹlẹ̀ ní Íńdíà níbẹ̀rẹ̀ 2001, Manu tó jẹ́ àgbàlagbà, tó ń gbé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà báyìí padà sí ìlú rẹ̀. Ó sọ pé: “Ó di dandan kí n lọ, kì í ṣe láti lọ ran kìkì àwọn ìbátan mi lọ́wọ́, àmọ́ láti ran gbogbo àwọn tó ń jìyà lọ́wọ́.” Manu rí i pé bí ipò nǹkan ṣe rí láwọn ibi tó lọ kò bọ́ sí i rárá. Síbẹ̀, ó sọ pé: “Ìgboyà táwọn èèyàn ní kò lẹ́gbẹ́.” Akọ̀ròyìn kan kọ ọ́ pé: “Gbogbo àwọn tí mo mọ̀ ló fi ohunkóhun tí wọ́n lè fi tọrẹ tọrẹ, gbogbo owó tó wọlé fáwọn mìíràn lóòjọ́, lọ́sẹ̀, kódà odindi owó oṣù kan, tàbí lára owó tí wọ́n fi pa mọ́ tàbí ohunkóhun tó bá ṣáà ti wà lágbára wọn ni wọ́n fi ṣèrànwọ́.”

Ó rọrùn díẹ̀ láti palẹ̀ àwọn àwókù ilé mọ́ àti láti tọ́jú àwọn tó fara pa; àmọ́ kò rọrùn láti mú àtúnṣe bá ìgbésí ayé àwọn èèyàn tí ìpayà òjijì náà ti sọ dìdàkudà. Wo ti obìnrin kan tó ń jẹ́ Delores, tí ilẹ̀ tó sẹ̀ ní El Salvador ba ilé rẹ̀ jẹ́. Ó sọ pé: “Èyí burú ju ogun tó jà wá tẹ́lẹ̀ lọ. Ó ṣe kò ṣe, a ní ibi tá a ń gbé nígbà ogun náà.”

Gẹ́gẹ́ bá a ti sọ ọ́ nínú àpilẹ̀kọ wa àkọ́kọ́, ohun táwọn èèyàn nílò gan-an nígbà míì ju àwọn nǹkan agbẹ́mìíró nìkan lọ, wọ́n tún nílò àtìlẹ́yìn ní ti èrò inú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ sọ ìlú Àmẹ́níà tó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Kòlóńbíà di báṣubàṣu níbẹ̀rẹ̀ 1999, ẹ̀mí tó lọ sí i lé ní ẹgbẹ̀rún kan, jìnnìjìnnì àti àìsírètí sì bo àìmọye èèyàn. Roberto Estefan, oníṣègùn ọpọlọ tí àjálù ọ̀hún ba ilé òun náà jẹ́ sọ pé: “Ibikíbi tó o bá lọ, igbe ẹ ràn wá lọ́wọ́ làwọn èèyàn ń ké. Mo lọ sílé àrójẹ kan pé kí n lọ jẹun, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó ń kí mi ló ń lo àkókò náà láti sọ fún mi nípa bí wọn ò ṣe lè sùn àti ìbànújẹ́ tó bá wọn.”

Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Estefan náà ṣe mọ̀, wàhálà tí ilẹ̀ sísẹ̀ máa ń kó bá èrò inú lè sọ èèyàn dìdàkudà. Obìnrin kan tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti bá wọn kọ́ àgọ́ tí wọ́n ti ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí jàǹbá ṣe kíyè sí i pé àwọn kan tí wọ́n níṣẹ́ lọ́wọ́ sọ pé àwọn ò lọ síbi iṣẹ́ mọ́ torí àwọn mọ̀ pé àwọn ò ní pẹ́ kú.

Ṣíṣèrànwọ́ fún Àwọn Tí Kò Nírètí

Láwọn àkókò wàhálà bẹ́ẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá láti ran àwọn tó rù ú là lọ́wọ́ nípa tara, nípa tẹ̀mí àti ti èrò inú. Bí àpẹẹrẹ, ní kété tí ìsẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní Kòlóńbíà tá a mẹ́nu bà ṣáájú ṣẹlẹ̀, ni ọ́fíìsì ẹ̀ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ ti gbé ìgbìmọ̀ pàjáwìrì kan dìde. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí jákèjádò orílẹ̀-èdè náà kó oúnjẹ àti owó sílẹ̀. Kò sì pẹ́ tí wọ́n fi fi àádọ́rin tọ́ọ̀nù oúnjẹ ṣọwọ́ sí ibi tí jàǹbá náà ti ṣẹlẹ̀.

Àtìlẹ́yìn nípa tẹ̀mí ló ṣe pàtàkì jù lọ́pọ̀ ìgbà. Láàárọ̀ ọjọ́ kan lẹ́yìn tí ilẹ̀ ríri ṣẹlẹ̀ ní Kòlóńbíà, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kíyè sí obìnrin kan táyé ti sú tó kàn ń fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri ojú títì nílùú Armenia tó ti dìdàkudà. Ó lọ bá obìnrin táyé ti sú yìí ó sì fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú kan tó ní àkọlé náà, Ireti Wo ni Ó Wà fun Awọn Ololufẹ Tí wọn Ti Kú? a

Obìnrin náà mú ìwé àṣàrò kúkúrú ọ̀hún relé ó sì fara balẹ̀ kà á. Ńṣe lobìnrin yìí tú kẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ nígbà tí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún lọ sí ilé rẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé tó kọ́ sí ìlù náà tó ń mówó wọlé fún un ni ilẹ̀ ríri náà ti bà jẹ́. Ní báyìí kò ní gá kò ní go. Kò tán síbẹ̀ o. Nígbà tí ilẹ̀ ríri náà ṣẹlẹ̀, ilé tí obìnrin yìí àti ọmọkùnrin rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ń gbé wó lulẹ̀ ó sì pa ọmọ rẹ̀ yìí. Obìnrin yìí sọ fún Ẹlẹ́rìí tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ pé òun ò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ ẹlẹ́sìn dé tẹ́lẹ̀, àmọ́ báyìí òun ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè láti béèrè. Ìwé àṣàrò kúkúrú náà ti fún un ní ìrètí tó jẹ́ ojúlówó. Kò pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ó dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lójú pé àkókò kan ń bọ̀ tí àwọn ìjábá, títí kan ilẹ̀ sísẹ̀ kò tún ní han ẹ̀dá ènìyàn léèmọ̀ mọ́. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e á ṣàlàyé bó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]

GBÁRA DÌ O!

◼ Rí i dájú pé àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ń mú omi gbóná wà ní dídè mọ́lẹ̀ pinpin, kẹ́ ẹ sì gbé àwọn ohun èlò tó bá wúwo sí ilẹ̀ẹ́lẹ̀ tàbí orí nǹkan tí kò ga púpọ̀.

◼ Kọ́ àwọn mẹ́ńbà ìdílé ní bí wọ́n ṣe lè paná ẹ̀lẹ́tíríìkì, bí wọ́n ṣe lè pa iná gáàsì kí wọ́n sì ti omi pa.

◼ Rí i pé o ní ohun èlò ìpaná àtàwọn èlò ìtọ́jú pàjáwìrì nínú ilé.

◼ Jẹ́ kí rédíò kékeré kan tó ní bátìrì tuntun máa wà nítòsí rẹ.

◼ Máa bá ìdílé rẹ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n lè ṣe bí iná bá ń jó, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti (1) má ṣe gbọ̀n jìnnìjìnnì, (2) láti pa sítóòfù àtàwọn ohun èlò tó ń mú omi gbóná, (3) láti dúró lẹ́nu ọ̀nà tàbí sá sábẹ́ tábìlì àti (4) láti jìnnà sí fèrèsé, àti láti jìnnà sí ibi tí dígí àti ààrò tó ń mú ilé móoru wà.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

ILẸ̀ SÍSẸ̀ NÍ ÍSÍRẸ́LÌ

Ọ̀jọ̀gbọ́n Amos Nur sọ pé, ilẹ̀ Ísírẹ́lì ló ní “àkọsílẹ̀ ilẹ̀ sísẹ̀ tó ti ń ṣẹlẹ̀ látọjọ́ pípẹ́ jù lọ tó sì tún ń bá a lọ nínú ìtàn gbogbo àgbáyé.” Ohun tó sì fà á ni pé lára Àfonífojì Ńlá náà, ìyẹn ibi tí ilẹ̀ ti lè ri láàárín ìpele Mẹditaréníà àti Arébíà, gba àárín Ísírẹ́lì kọjá, láti ìhà àríwá sí gúúsù.

Ó yẹ fún àfiyèsí pé àwọn awalẹ̀pìtàn kan gbà gbọ́ pé àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ayé ìgbà yẹn lo àwọn ọgbọ́n àkànṣe kan láti dín ọṣẹ́ tí ilẹ̀ sísẹ̀ ń ṣe kù. Èyí bá bí Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ọ̀nà tí Sólómọ́nì gbà ṣiṣẹ́ ìkọ́lé rẹ̀ mu, pé: “Ní ti àgbàlá títóbi náà, ẹsẹ mẹ́ta òkúta gbígbẹ́ àti ẹsẹ kan ìtì igi kédárì wà yí i ká; àti èyí pẹ̀lú fún àgbàlá inú lọ́hùn-ún ilé Jèhófà, àti fún gọ̀bì ilé náà.” (1 Ọba 6:36; 7:12) Ọ̀pọ̀ ibi la ti rí ẹ̀rí ọ̀nà ìgbàkọ́lé yìí tí wọ́n á ti fi àwọn ìtì igi sínú àwọn ilé tí wọ́n fi òkúta kọ́, lára wọn ni ti ẹnubodè Mẹ́gídò tó ṣeé ṣe kó ti wà látìgbà ayé Sólómọ́nì tàbí ṣáájú ìgbà yẹn. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà David M. Rohl sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ “nítorí kí ilẹ̀ sísẹ̀ má lè ba àwọn ilé náà jẹ́” ni wọ́n ṣe ń fi àwọn ìtì igi yìí sínú wọn.

[Àwòrán]

Àwọn ilé tí ilẹ̀ sísẹ̀ wó ní Bet Sheʼan, ní Ísírẹ́lì

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

ÌPAYÀ ÌṢẸ́JÚ MÉJÌ PÉRÉ—OHUN TÍ ẸNÌ KAN TÓ RÙ Ú LÀ SỌ

Ìdílé wa ń ṣe kùkùkẹ̀kẹ̀ ìgbéyàwó mọ̀lẹ́bí mi kan tó ń bọ̀ lọ́nà ní ìlú Ahmadabad, tó wà ní Íńdíà. Jìgìjìgì tí ibi gbogbo ń mì ló jí mi ní January 26, 2001, kì í ṣe ìró aago. Mo ń gbọ́ táwọn àpótí ìkó-ǹkan-sí ń yẹ̀ sọ́tùn-ún sósì, ìgbà yẹn ni mo mọ̀ pé wàhálà kan ti ṣẹlẹ̀. Àbúrò bàbá mi ń pariwo, “Ẹ jáde síta o!” Bá a ṣe wà níta, a rí i tí ilé náà ń mì jìgìjìgì sọ́tùn-ún sósì. Ńṣe ló dà bí i pé àìmọye ọdún ló fi ṣẹlẹ̀. Àmọ́ ṣá, kò ju ìṣẹ́jú méjì péré lọ.

Làásìgbò ọ̀hún le kú nítorí pé wàràwéré ni gbogbo rẹ̀ ṣẹlẹ̀. A rí i dájú pé kò sí nǹkan tó ṣe ìdílé wa. Tẹlifóònù kò ṣiṣẹ́ mọ́, iná mànàmáná sì ti lọ, èyí kò jẹ́ ká tètè mọ ipò táwọn ẹbí wa láwọn ìlú tó yí wa ká wà. Lẹ́yìn wákàtí kan tí ọkàn wa ti wà lókè, la wá gbọ́ pé nǹkankan kò ṣẹlẹ̀ sí wọn. Kì í ṣe gbogbo èèyàn ni nǹkan ṣẹnuure fún bíi tiwa o. Bí àpẹẹrẹ, iye ilé tó dà wó ní Ahmadabad lé ní ọgọ́rùn-ún, iye tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ènìyàn sì pàdánù ẹ̀mí wọn.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀ ni gbogbo èèyàn fi wà nínú ìpayà. Báwọn èèyàn bá ń lọ sùn lálẹ́, ńṣe lẹ̀rù máa ń bà wọ́n pé ilẹ̀ tún máa sẹ̀ o nítorí àwọn kan ti sọ bẹ́ẹ̀. Ó gba ọ̀pọ̀ àkókò láti ṣàtúnṣe àwọn ohun tó bà jẹ́, ọ̀pọ̀ sì di aláìnílélórí. Ilẹ̀ tó sẹ̀ fún ìṣẹ́jú méjì péré ló fa gbogbo èyí, àmọ́ a kò lè gbàgbé rẹ̀ láéláé. —Gẹ́gẹ́ bí Samir Saraiya ṣe sọ ọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Ẹnì kan tó yè bọ́ nígbà ilẹ̀ ríri tó wáyé ní Íńdíà ní January 2001, níbi tó ti mú fọ́tò ìyá rẹ̀ tó kú tí wọ́n sì ń sun òkú rẹ̀ dání

[Credit Line]

© Randolph Langenbach/UNESCO (www.conservationtech.com)