Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Pàdánù Ọmọ Tí Mi Ò Tíì Bí

Mo Pàdánù Ọmọ Tí Mi Ò Tíì Bí

Mo Pàdánù Ọmọ Tí Mi Ò Tíì Bí

ỌJỌ́ tó tuni lára ni ọjọ́ Monday, April 10, 2000, oòrùn rọra ń ta yẹ́ẹ́, èyí mú kí n jáde láti lọ ṣe àwọn nǹkan kan tó yẹ ní ṣíṣe. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ pé oṣù mẹ́rin tí oyún dúró sí mi lára ni, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara mi kò fi bẹ́ẹ̀ gbé kánkán tẹ́lẹ̀, inú mi dùn pé mo lè najú jáde. Bí mo ṣe dúró lórí ìlà pé kí n sanwó nílé ìtajà kan báyìí, bẹ́ẹ̀ ló dà bí i pé nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ sí mi.

Nígbà ti mo délé, ohun tó ń já mi láyà gan-an ló ṣẹlẹ̀. Ńṣe ni ẹ̀jẹ̀ ń dà lára mi, nǹkan tí kò ṣẹlẹ̀ sí mi nínú oyún méjèèjì tí mo ti kọ́kọ́ ní, èyí sì kó jìnnìjìnnì bá mi gan-an! Mo pe dókítà mi, àmọ́ ó ní kí n jẹ́ kó di ọjọ́ kejì kí n tó wá. Ìgbà yẹn náà ló kúkú yẹ kí n lọ rí i. Kí èmi àti ọkọ mi tó ó mú àwọn ọmọ wa méjèèjì lọ sùn lálẹ́ ọjọ́ yẹn, a gbàdúrà pa pọ̀, a bẹ Jèhófà pé kó fún wa lókun ní ọ̀nàkọnà tá a ti máa nílò rẹ̀. Nígbà tó yá, oorun gbé mi lọ.

Àmọ́ ní nǹkan bí aago méjì òru, ìrora burúkú kan jí mi. Díẹ̀díẹ̀, ìrora náà bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sílẹ̀, àmọ́ bí oorun ṣe tún ń mú mi lọ báyìí ló bá tún dé, lákòókò yìí, ó wá ń wá lemọ́lemọ́. Bẹ́ẹ̀ lẹ̀jẹ̀ túbọ̀ ń dà lára mi, mo sì wá á rí i pé ọmọ ló ń mú mi. Ọkàn mi kò balẹ̀ bí mo ti ń gbìyànjú láti ronú ohun tí mo ṣe tí irú nǹkan báyìí fi ń ṣẹlẹ̀, àmọ́ mi ò lè sọ pé nǹkan kan báyìí tí mo ṣe ló fà á.

Nígbà tó di aago márùn-ún ìdájí, mo mọ̀ pé mo gbọ́dọ̀ forí lé ọ̀nà ọsibítù. Nígbà tí èmi àti ọkọ mi débẹ̀, ará tù wá bá a ṣe bá àwọn òṣìṣẹ́ pàjáwìrì tí wọ́n ṣèèyàn, tí wọ́n ń ranni lọ́wọ́ tí wọ́n sì gba tiwa rò pàdé. Wákàtí méjì lẹ́yìn ìgbà náà, dókítà sọ ohun tí ẹ̀rú ń bà wá láti gbọ́ fún wa: Oyún mi ti bà jẹ́.

Nítorí àwọn àmì tí mo ti rí tẹ́lẹ̀, mo ti múra de ohun tó sọ yìí, mo sì ṣara gírí nígbà tí mo gbọ́ ọ. Láfikún sí ìyẹn, ọkọ mi kò fi mí sílẹ̀ ní gbogbo àkókò yìí, gbágbáágbá ló dúró tì mí. Àmọ́ ní báyìí tá ò ní gbé ọmọ dání lọ sílé, a bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé kí la máa sọ fún àwọn ọmọ wa méjèèjì, Kaitlyn, ọmọ ọdún mẹ́fà àti David, ọmọ ọdún mẹ́rin.

Kí La Máa Sọ fún Àwọn Ọmọ Wa?

Kí àwọn ọmọ yìí tó lọ sùn, wọ́n ti fura pé nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀, àmọ́ báwo la ṣe fẹ́ sọ fún wọn pé ẹni tó yẹ kó jẹ́ àbúrò wọn ti kú? A pinnu pé ńṣe la máa sọ ojú abẹ níkòó àá sì jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó ṣẹlẹ̀. Màmá mi ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe èyí nípa sísọ fún àwọn ọmọ náà pé a ò ní gbé ọmọ wálé o. Nígbà tá a délé, wọ́n sáré wá pàdé wa, wọ́n dì mọ́ wa wọ́n sì fẹnu kò wá lẹ́nu. Ìbéèrè tí wọ́n kọ́kọ́ béèrè ni pé, “Ṣé nǹkankan kò ṣe ọmọ o?” Mi ò lè dáhùn, àmọ́, ọkọ mi fọwọ́ gbá gbogbo wa mọ́ra ó sì sọ pé: “Ọmọ ti kú.” A dì mọ́ra wa a sì sunkún, èyí jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ sí í borí ìbànújẹ́ yìí díẹ̀díẹ̀.

Àmọ́ o, a ò retí pé àwọn ọmọ wa lè ṣe àwọn ohun tí wọ́n ṣe lẹ́yìn náà. Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn tí oyún walẹ̀ lára mi, wọ́n ṣèfilọ̀ nínú ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí à ń lọ pé Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ àgbàlagbà tó sì tún jẹ́ ọ̀rẹ́ ìdílé wa tímọ́tímọ́ ti dolóògbé. Ńṣe ni David, ọmọ ọdún mẹ́rin bẹ̀rẹ̀ sí sunkún àsun-ùndábọ̀, ọkọ mi sì gbé e jáde. Lẹ́yìn tí ara rẹ̀ wálẹ̀, David béèrè pé kí ló dé tí ọ̀rẹ́ òun fi kú. Lẹ́yìn náà ó tún béèrè ìdí tí ọmọ tí wọn ò tíì bí náà fi kú. Ó wá béèrè lọ́wọ́ bàbá rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ̀yin náà máa kú ni?” Ó tún fẹ́ mọ ìdí tí Jèhófà Ọlọ́run kò fi tíì pa Sátánì run kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í “ṣàtúnṣe àwọn nǹkan.” Ká sòótọ́, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wa pé bó ṣe kéré mọ, ó lè máa ronú tó bẹ́ẹ̀ yẹn.

Kaitlyn náà béèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè. Tó bá ń fi àwọn ọmọlangidi rẹ̀ ṣeré, ó sábà máa ń fi ọ̀kan ṣe ẹni tí ara rẹ̀ kò yá tí àwọn ọmọláńgidi tó kù á sì jẹ́ àwọn nọ́ọ̀sì tàbí mọ̀lẹ́bí. Ó fi páálí kan ṣe ọsibítù àwọn ọmọlangidi, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, á máa ṣe bí ẹni pé ọ̀kan lára àwọn ọmọlangidi rẹ̀ ti kú. Àwọn ìbéèrè táwọn ọmọ wa béèrè àtàwọn eré tí wọ́n ń ṣe fún wa ní àǹfààní gan-an láti kọ́ wọn ní àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì nípa ìgbésí ayé àti bí Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò. A tún rán wọn létí ìpinnu Ọlọ́run láti sọ ayé di Párádísè ẹlẹ́wà, níbi tí kò ti ní sí ìjìyà tàbí ìrora mọ́, tí ikú pàápàá kò ní sí mọ́.—Ìṣípayá 21:3, 4.

Bí Mo Ṣe Fara Da Àdánù Náà

Nígbà tí mo kọ́kọ́ dé sílé láti ọsibítù, ńṣe ni mo rọ kalẹ̀ tí ọkàn mi sì pòrúurùu. Àwọn nǹkan tó yẹ kí n ṣe kúnlẹ̀ àmọ́ mi ò mọ ibi tí ǹ bá ti bẹ̀rẹ̀. Mo ké sí àwọn ọ̀rẹ́ mi kan tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí, wọ́n sì tù mí nínú gan-an. Ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n kan fi òdòdó ránṣẹ́ sí wa ó sì sọ pé òún á kó àwọn ọmọ tira títí di ìrọ̀lẹ́. Mo dúpẹ́ gan-an fún inú rere tó fi hàn àti ìrànwọ́ tó ṣe!

Mo tún àwọn fọ́tò ìdílé wa tò sínú álíbọ́ọ̀mù. Mo yẹ àwọn aṣọ tí ìkókó náà kò fi kan ọrùn wò mo sì kó wọn lọ́wọ́, èyí tó jẹ́ ohun ìrántí kan ṣoṣo nípa ọmọ tí mo pàdánù náà. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀, ara mi kò lélẹ̀. Láwọn ọjọ́ mìíràn, ẹkún ni màá máa sun ṣáá, láìka bí ìdílé mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi ṣe ń ṣèrànwọ́ fún mi sí. Nígbà míì, ńṣe ló máa dà bíi pé orí mi fẹ́ dàrú. Ìgbà tí mo bá wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi tó lóyún lọ̀rọ̀ ọ̀hún máa ń burú jù. Èrò mi tẹ́lẹ̀ ni pé ìṣẹ́nú “kì í ṣe nǹkan bàbàrà” kan nínú ìgbésí ayé obìnrin, pé nǹkan téèyàn kàn lè mọ́kàn kúrò lórí ẹ̀ láìsí wàhálà ni. Àṣé mi ò mọ nǹkankan nígbà yẹn! a

Ìfẹ́—Oògùn Tó Dára Jù Lọ

Bí àkókò ti ń lọ ara bẹ̀rẹ̀ sí í tù mí, síbẹ̀ oògùn tó ṣíṣẹ́ jù lọ ni ìfẹ́ tí ọkọ mi àtàwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ mi fi hàn sí mi. Ẹlẹ́rìí kan lọ se oúnjẹ wá fún wa. Alàgbà kan nínú ìjọ Kristẹni àti ìyàwó rẹ̀ mú òdòdó àti káàdì ìkíni onífẹ̀ẹ́ wá fún wa, wọ́n sì wà lọ́dọ̀ wa ní gbogbo ìrọ̀lẹ́ náà. A mọ̀ pé ọwọ́ wọn máa ń dí gan-an èyí sì mú kí aájò wọn wú wa lórí púpọ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ wa mìíràn fi káàdì tàbí òdòdó ránṣẹ́ sí wa. Gbólóhùn ṣókí náà pé “A ò gbàgbé yín” ní ìtumọ̀ sí wa lọ́pọ̀lọpọ̀! Ẹnì kan láti ìjọ wa kọ gbólóhùn yìí sí wa pé: “Ojú tí Jèhófà fi ń wo ìwàláàyè làwa náà fi ń wò ó, pé ó jẹ́ ohun ṣíṣeyebíye gan-an. Bí ó bá mọ ìgbà tí ológoṣẹ́ kan já bọ́ sílẹ̀, ó dájú pé ó máa ń mọ̀ tí oyún inú bá ṣẹ́.” Ẹbí mi kan kọ̀wé pé: “Iṣẹ́ ìyanu ńlá ni ọmọ bíbí àti ìwàláàyè jẹ́ lójú wa, síbẹ̀ ó tún máa ń yà wá lẹ́nu nígbà tí oyún inú náà bá bà jẹ́.”

Bí mo ṣe wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ní ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan lẹ́yìn ìgbà náà, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe mí bíi pé kí n máa sunkún, ni mo bá jáde síta bó ṣe kù díẹ̀ kí ìpàdé bẹ̀rẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́bìnrin ọ̀wọ́n méjì tí wọ́n kíyè sí i pé ńṣe ni mo sunkún jáde wá jókòó tì mí nínú ọkọ̀, wọ́n dì mí lọ́wọ́ mú, wọ́n sì dẹ́rìn-ín pa mí. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà làwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọlé padà. Nǹkan ayọ̀ gbáà mà ló jẹ́ o láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tó sún mọ́ni “tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ”!—Òwe 18:24.

Bí àwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó yà mí lẹ́nu láti mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn ti fojú winá irú ohun kan náà rí. Kódà, àwọn kan tá ò fi bẹ́ẹ̀ mọra tẹ́lẹ̀ sọ̀rọ̀ ìtùnú fún mi wọ́n sì fún mi níṣìírí. Ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ wọn lásìkò tí mo nílò rẹ̀ rán mi létí gbólóhùn inú Bíbélì kan tó sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—Òwe 17:17.

Ìtùnú Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé ìgbà tí oyún mi bà jẹ́ ni Ìṣe Ìrántí ikú Kristi. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, bá a ṣe ń ka àkọsílẹ̀ Bíbélì tó sọ nípa àwọn ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé, ńṣe ni kókó kan ṣàdéédéé sọ sí mi lọ́kàn pé: ‘Jèhófà mọ bó ṣe máa ń dunni tó téèyàn bá pàdánù nǹkan. Òun náà pàdánù ọmọ tirẹ̀!’ Nítorí pé ọ̀run ni Bàbá wa, Jèhófà, ń gbé, mo máa ń gbàgbé nígbà míì pé ó lóye wa gan-an àti pé ó mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Bí ìyẹn ṣe sọ sí mi lọ́kàn báyìí, ìtura ńlá kan dé sí mi. Mo wá rí i pé mo túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

Mo tún rí ìtùnú púpọ̀ látinú àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé karí Bíbélì, pàápàá jù lọ àwọn ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó ti kọjá tí wọ́n dá lórí bá a ṣe lè fara dà á tí èèyàn wa bá kú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí “Didojukọ Adanu Ọmọ Kan” nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti February 8, 1988 ṣèrànwọ́ gan-an ni, bákan náà sì tún ni ìwé pẹlẹbẹ náà, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú. b

Ìbànújẹ́ Máa Dópin

Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, mo mọ̀ pé ara mi ti ń bọ̀ sípò, nítorí mo ti lè rẹ́rìn-ín láìròó pé kí ló ń dùn nínú mi, mo sì tún lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ láìmẹ́nu lọ síbi ọ̀rọ̀ ọmọ mi tí kò sí náà. Síbẹ̀, àwọn ìgbà kọ̀ọ̀kan ṣì wà tí mo máa ń kárí sọ nítorí ìbànújẹ́, bí irú ìgbà tí mo bá pàdé àwọn kan tí wọn ò tíì gbọ́ nípa àdánù náà tàbí nígbà tí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ tuntun bá wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa.

Ńṣe ni mo jí ní àárọ̀ ọjọ́ kan, ti mo sì rí i pé ìbànújẹ́ náà ti wábi gbà. Kí n tiẹ̀ tó la ojú mi rárá ló ti jọ pé ara mi ti yá, àlááfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn tó ti fò mí ru fún ọ̀pọ̀ oṣù sẹ́yìn sì dé sí mi. Àmọ́, nígbà tí mo lóyún mìíràn ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tí oyún bà jẹ́ lára mi, ńṣe ni èrò pé oyún tún lè bà jẹ́ mọ́ mi lára bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí mi lọ́kàn. Ṣùgbọ́n, inú mi dùn púpọ̀ nígbà tí mo bí ọmọkùnrin làǹtì-lanti kan ní October 2001.

Oyún tó wálẹ̀ lára mi ṣì ń máa ń bà mí nínú jẹ́. Àmọ́ o, ńṣe ni gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí mú kí n túbọ̀ ní ìmọrírì tó pọ̀ sí i fún ìwàláàyè, fún ìdílé mi, fun àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ mi àti fún Ọlọ́run, ẹni tó ń tù wá nínú. Ohun tó ṣẹlẹ̀ náà túbọ̀ fìdí òtítọ́ tí kò rọrùn náà múlẹ̀ pé Ọlọ́run kọ́ ló ń gba àwọn ọmọ wa, àmọ́ pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo [wa].”—Oníwàásù 9:11.

Mò ń wọ̀nà lójú méjèèjì de àkókò náà tí Ọlọ́run máa mú gbogbo ìbànújẹ́, ẹkún àti ìrora ọkàn kúrò, títí kan ìrora àti ẹ̀dùn ọkàn tí ìṣẹ́nú ń fà! (Aísáyà 65:17-23) Nígbà yẹn, gbogbo ẹ̀dá èèyàn tó jẹ́ onígbọràn á lè sọ pé: “Ikú, ìjagunmólú rẹ dà? Ikú, ìtani rẹ dà?”—1 Kọ́ríńtì 15:55; Aísáyà 25:8.—A kọ ọ́ ránṣẹ́.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwádìí fi hàn pé tí oyún bá bà jẹ́ lára obìnrin, ọkàn tí kálukú fi ń gbà á yàtọ̀ síra. Ńṣe ni ìdààmú ọkàn máa bá àwọn kan, àwọn mìíràn á wò ó pé ìrètí àwọn ti já sófo tí ìbànújẹ́ á sì gbé àwọn mìíràn mì ráúráú. Àwọn olùwádìí sọ pé ìwà ẹ̀dá ni pé kéèyàn bọkàn jẹ́ tí òfò ńlá bá ṣẹlẹ̀, irú bí ìṣẹ́nú, èyí sì jẹ́ ara ọ̀nà téèyàn fi ń borí ìbànújẹ́ náà díẹ̀díẹ̀.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

Bí Ìṣẹ́nú Ṣe Wọ́pọ̀ Tó àti Ohun Tó Ń Fà Á

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ìwádìí fi hàn pé ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ogún nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo oyún tó ti fara hàn ló máa ń bà jẹ́. Àmọ́ ọ̀sẹ̀ méjì àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí obìnrin bá fẹ́ra kù (lóyún) ló ṣeé ṣe kí ìṣẹ́nú ṣẹlẹ̀ jù lọ, ìyẹn àkókò kan tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ obìnrin ni kì í mọ̀ pé àwọn ti lóyún.” Ìwé ìwádìí mìíràn sọ pé ó ju “ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ìṣẹ́nú tó máa ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ méjìlá àkọ́kọ́,” èyí tá a ronú pé ìdajì nínú wọn ó kéré tán ló ní i ṣe pẹ̀lú àwọn àbùkù tí ọlẹ̀ náà ní. Àwọn àbùkù látinú àbùdá ìyá tàbí ti bàbá kọ́ ló ń fa àwọn àbùkù wọ̀nyí.

Àwọn ohun mìíràn tó tún lè mú kí oyún wálẹ̀ lè ní í ṣe pẹ̀lú àìlera ìyá. Àwọn onímọ̀ ìṣègùn mẹ́nu kan ìṣòro nínú omi ara tó máa ń súnni ṣe nǹkan àti nínú agbára ìdènà àrùn ara ìyá, àkóràn àti kí ojú ọ̀nà sí ilé ọmọ àti ilé ọlẹ̀ ìyá má wà bó ṣe yẹ. Àwọn àrùn bárakú, irú bí àtọ̀gbẹ (tí wọ́n ò bá mójú tó o dáadáa) àti ẹ̀jẹ̀ ríru tún lè fà á.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn ògbógi ti sọ, kò fi dandan túmọ̀ sí pé ṣíṣe eré ìmárale, gbígbé àwọn ohun tó wúwo tàbí níní ìbálòpọ̀ ló ń jẹ́ kí oyún wálẹ̀. Kò dájú pé kéèyàn ṣubú, kí wọ́n rọra gbáni níkùn tàbí kí ẹ̀rù ṣàdédé ba èèyàn lè fa ìṣẹ́nú. Ìwé ìwádìí kan sọ pé: “Kò jọ pé jàǹbá kankan lè ṣe ọlẹ̀ inú ní ohunkóhun àyàfi tí jàǹbá náà bá le débi pé ẹ̀mí ìwọ alára fẹ́ lọ sí i.” Ẹ ò rí i pé ọ̀nà tí Ẹlẹ́dàá gbà dá ilé ọmọ ń jẹ́rìí sí i lọ́pọ̀lọpọ̀ pé ọlọgbọ́n àti onífẹ̀ẹ́ ni!—Sáàmù 139:13, 14.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Bí Àwọn Ẹbí àti Ọ̀rẹ́ Ṣe Lè Ṣèrànwọ́

Nígbà míì, ó máa ń ṣòro láti mọ nǹkan pàtó téèyàn lè sọ tàbí ṣe nígbà tí oyún bá bà jẹ́ lára ẹbí ẹni tàbí ọ̀rẹ́ ẹni kan. Tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, àwọn èèyàn máa ń rí ọkàn gbà á sí jura wọn lọ, ìdí rèé tá ò fi lè sọ pé ọ̀nà kan pàtó rèé láti fi tu èèyàn nínú tàbí láti ṣèrànwọ́. Àmọ́, gbé àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ yìí yẹ̀ wò. c

Àwọn nǹkan tó bọ́gbọ́n mu tó o lè ṣe láti fi ràn wọ́n lọ́wọ́:

◆ Sọ fún wọn pé o lè bá wọn bójú tó àwọn ọmọ tó ti dàgbà.

◆ Se oúnjẹ kó o sì gbé e wá fún ìdílé náà.

◆ Ṣèrànwọ́ fún bàbá ọmọ pẹ̀lú. Bàbá kan sọ pé, “ní irú ipò yìí, àwọn tó ń ṣe káàdì ìkíni kì í ṣe ti bàbá mọ́ ọn.”

Àwọn nǹkan tó o lè sọ tó lè ṣèrànwọ́:

“Ó dùn mí gan-an nígbà tí mo gbọ́ pé oyún bà jẹ́ lára rẹ.”

Ọ̀rọ̀ tó ṣe ṣókí yìí ní ìtumọ̀ gan-an, ó sì lè jẹ́ kó o mọ àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú mìíràn tó o lè sọ tẹ̀ lé e.

“Kò burú láti sunkún o.”

Láwọn ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ tí oyún wálẹ̀ lára ẹnì kan, ẹkún kì í jìnnà sí ẹni náà, ó tiẹ̀ lè máa bá a lọ fún ọ̀pọ̀ oṣù pàápàá. Jẹ́ kó mọ̀ pé ẹkún tó ń sun kò dín ọ̀wọ̀ tó o ní fún un kù.

“Ṣé mo lè fóònù ẹ́ tàbí kí n padà bẹ̀ ọ́ wò lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀ láti mọ bó o ṣe wà?”

Àwọn tí oyún wálẹ̀ lára wọn lè rí i tí ọ̀pọ̀ èèyàn wá bá wọn kẹ́dùn nígbà tó kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, àmọ́ bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́ tí ìbànújẹ́ wọn ò sì tíì lọ, wọ́n lè máa rò pé àwọn èèyàn ti gbàgbé àwọn. Ó dára kó o jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìrànwọ́ tó ò ń ṣe kò dáwọ́ dúró. Wọ́n ṣì lè máa ní ìbànújẹ́ ọkàn fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ tàbí ọ̀pọ̀ oṣù. Kódà, ìbànújẹ́ ọ̀hún ṣì lè yọjú lẹ́yìn tí wọ́n ti lóyún mìíràn tí wọ́n sì ti bí i.

“Mi ò kan tiẹ̀ mọ nǹkan tí mo lè sọ.”

Ó máa ń sàn kéèyàn kúkú sọ èyí ju pé kó má sọ nǹkan kan rárá lọ. Sísọ tó o sọ òótọ́ inú rẹ jáde àti wíwà tó o wà níbẹ̀ fi hàn pé o lánìíyàn.

Ohun tí kò yẹ kó o sọ:

“O ṣì lè bí ọmọ mìíràn.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, wọ́n lè kà á sí pé o ò ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. Àwọn òbí yìí kò fẹ́ ọmọ èyíkéyìí, ọmọ yẹn gan-an ni wọ́n fẹ́. Kí wọ́n tó máa ronú níní ọmọ mìíràn, ó dájú pé wọ́n á ṣì ṣọ̀fọ̀ èyí tí wọ́n pàdánù yìí ná.

“Ó ní láti jẹ́ pé ọmọ náà ní àìsàn ni.”

Èyí lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, àmọ́ kò tu èèyàn nínú páàpáà. Lọ́kàn ìyá ọmọ, ọmọ tára ẹ̀ pé ló lóyún rẹ̀.

“Ṣebí o ò kúkú rí ọmọ ọ̀hún sójú. Ká ní ẹ̀yìn tó o bí i ni èyí ṣẹlẹ̀ ni, ìyẹn ni ì bá burú jù.”

Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn obìnrin ló máa ń nífẹ̀ẹ́ ọmọ tí wọn ò tíì bí gan-an ní gbàrà tí wọ́n bá ti lóyún rẹ̀. Tí irú ọmọ bẹ́ẹ̀ bá wá kú, ìbànújẹ́ ló sábà máa ń tẹ̀ lé e. Ohun tó máa ń jẹ́ kí ìbànújẹ́ yìí légbá kan ni pé, kò sẹ́lòmíràn tó “mọ” ọmọ náà tó bí ìyá yẹn ṣe mọ̀ ọ́n.

“Ṣebí o ṣì ní àwọn ọmọ mìíràn.”

Lójú àwọn òbí tí ìbànújẹ́ bá, ọ̀rọ̀ yìí kò yàtọ̀ sí kéèyàn sọ fún ẹnì tí apá rẹ̀ kan tàbí ẹsẹ̀ rẹ̀ kan gé dà nù pé: “Ṣebí o ṣì ní apá àti ẹsẹ̀ mìíràn.”

Ó dájú pé, a gbọ́dọ̀ gbà pé àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ onínúure gan-an tí wọ́n sì máa ń fi òótọ́ inú sọ̀rọ̀ máa ń ṣì sọ nígbà mìíràn. (Jákọ́bù 3:2) Nípa bẹ́ẹ̀, ó dára kí àwọn olóye obìnrin tí oyún bà jẹ́ lára wọn fi ìfẹ́ Kristẹni hàn, kí wọ́n máà di àwọn èèyàn sínú nítorí pé wọ́n fi bí nǹkan ṣe rí lára wọn sọ̀rọ̀ àmọ́ lọ́nà tí kò bójú mu.—Kólósè 3:13.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

c A fa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí yọ látinú ìwé A Guide to Coping With Miscarriage tí àjọ Wellington ti ilẹ̀ New Zealand mú jáde, ìyẹn Ẹgbẹ́ Tó Ń Tu Àwọn Tí Oyún Bà Jẹ́ Lára Wọn Nínú.