Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 14. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)
1. Kí ló dé tí Aísáyà fi sọ̀rọ̀ nípa jíju àwọn ọlọ́run wúrà àti fàdákà sí àwọn àdán ní ọjọ́ Jèhófà? (Aísáyà 2:20)
2. Èé ṣe tí Ọlọ́run fi sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gbọ́dọ̀ kárúgbìn eteetí pápá wọn pátápátá? (Léfítíkù 19:9)
3. Lábẹ́ Òfin Mósè, kí ni òfin béèrè pé kí ọkùnrin tó bá ba ojú ẹrú rẹ̀ jẹ́ tàbí tó gbá eyín rẹ̀ yọ ṣe? (Ẹ́kísódù 21:26, 27)
4. Ìgbà wo ni ẹnì kan tó pààyàn láìmọ̀ọ́mọ̀ tó lè kúrò ní ìlú ààbò? (Númérì 35:25)
5. Báwo ni àkókò tó wà láàárín ìgbà tí Kọ̀nílíù gbàdúrà sí Ọlọ́run àti ìgbà tí Pétérù dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe gùn tó? (Ìṣe 10:30-33)
6. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ pé káwọn ará ṣe fún “àwọn tí ń fa ìpínyà àti àwọn àyè fún ìkọ̀sẹ̀”? (Róòmù 16:17)
7. Ọṣẹ́ wo ni Sátánì ṣe fún ìlera Jóòbù níbi tó ti ń gbìyànjú láti ba ìwà títọ́ Jóòbù jẹ́? (Jóòbù 2:7)
8. Ibo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ jẹ mánà tí wọn sì ti kọ́kọ́ pa òfin Sábáàtì mọ́? (Ẹ́kísódù 16:1)
9. Báwo ni Éhúdù ṣe pa Égílónì Ọba Móábù? (Onídàájọ́ 3:16)
10. Ẹkùn ilẹ̀ Róòmù wo làwọn ìjọ méje tí Jòhánù ránṣẹ́ sí wà? (Ìṣípayá 1:4)
11. Irú ẹranko wo la sábà ń fi Jésù wé, kí ló sì fà á? (Jòhánù 1:29)
12. Orúkọ wo la fi pe àgbájọ omi tó wà láyé èyí tó fi ìyàtọ̀ sáàárín rẹ̀ àti ilẹ̀ ayé? (Hábákúkù 2:14)
13. Ohun èlò wo ni Nóà lò fún ọkọ̀ áàkì náà kí omi má bàa wọ inú rẹ̀? (Jẹ́nẹ́sísì 6:14)
14. Kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́run lẹ́yìn tí Kristi gorí ìtẹ́? (Ìṣípayá 12:7)
15. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì wo ni Jésù rán lọ pé kí wọ́n lọ ṣètò sílẹ̀ fún ayẹyẹ Ìrékọjá rẹ̀ tó kẹ́yìn? (Lúùkù 22:7-13)
16. Irú ẹran wo la sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù máa gùn wọ Jerúsálẹ́mù? (Sekaráyà 9:9)
17. Àpẹẹrẹ kòkòrò wo la ní káwọn ọ̀lẹ tẹ̀ lé? (Òwe 6:6)
18. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Pétérù fi idà rẹ̀ gbèjà Jésù? (Jòhánù 18:10)
19. Kòkòrò wo làwọn Farisí máa ń fi tìṣọ́ratìṣọ́ra sẹ́ dà nù kó má bàa sọ wọ́n di aláìmọ́? (Mátíù 23:24)
20. Ta ni ẹni náà tá a sọ pé ó bọlá fún àwọn ọmọ rẹ̀ ju Jèhófà lọ? (1 Sámúẹ́lì 2:22, 29)
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Nítorí pé ibi òkùnkùn àti ibi àìmọ́ ló yẹ irú àwọn òrìṣà wọ̀nyẹn, kì í ṣe ibi tó lọ́lá tó sì gbayì
2. Kí àwọn tí ò rí já jẹ àtàwọn àtìpó lè rí nǹkan pèéṣẹ́
3. Kí ó dá ẹrú náà sílẹ̀
4. Ìgbà tí àlùfáà àgbà bá kú
5. Ọjọ́ mẹ́rin
6. Kí wọ́n máa kíyè sí wọn kí wọ́n sì yẹra fún wọn
7. Ó fi oówo afòòró-ẹ̀mí kọlu Jóòbù ní gbogbo ara
8. Nínú aginjù Sínì
9. Idà olójú méjì
10. Éṣíà
11. Ọ̀dọ́ àgùntàn. Nítorí ipá tí Jésù kó láti ṣe ìrúbọ
12. Òkun
13. Ọ̀dà bítúmẹ́nì
14. Ogun, nínú èyí tá a fi Sátánì sọ̀kò kúrò ní òkè ọ̀run
15. Pétérù àti Jòhánù
16. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
17. Èèrà
18. Ó gé etí ọ̀tún Málíkọ́sì, ẹrú àlùfáà àgbà
19. Kantíkantí
20. Élì Àlùfáà Àgbà