Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Ń fa Ilẹ̀ Sísẹ̀

Ohun Tó Ń fa Ilẹ̀ Sísẹ̀

Ohun Tó Ń fa Ilẹ̀ Sísẹ̀

“ILẸ̀ AYÉ TÁ A Ń GBÉ YÌÍ KÌ Í MÌ SỌ́TÙN-ÚN SÓSÌ, Ó SÌ TI MỌ́ WA LÁRA, ÈYÍ LÓ Ń MÚ ỌKÀN WA PÒRÚURÙU TÍ Ó BÁ ṢÀDÉDÉ BẸ̀RẸ̀ SÍ MÌ JÌGÌJÌGÌ.”—“THE VIOLENT EARTH.”

“ÌSẸ̀LẸ̀ wà lára àwọn ohun tó lágbára jù lọ tó sì máa ń ba nǹkan jẹ́ jù lọ tó máa ń ṣàdédé ṣẹlẹ̀ láìjẹ́ pé ẹnì kan fà á,” gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà The World Book Encyclopedia ṣe sọ. Àsọdùn kọ́ lọ̀rọ̀ yìí o nítorí bí ìsẹ̀lẹ̀ kan bá rinlẹ̀ dáadáa, bó ṣe máa ń lágbára tó máa ń fi ìgbà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ju ti bọ́ǹbù átọ́míìkì tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe jáde lọ! Ohun tó tún mú kí ìpayà náà túbọ̀ pọ̀ ni pé, ilẹ̀ sísẹ̀ kò mọ ibì kan yàtọ̀, ó sì lè ṣẹlẹ̀ nígbàkigbà àti ní àkókò èyíkéyìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ lè lóye díẹ̀ nípa ibi tó ṣeé ṣe kí ilẹ̀ ríri ti wáyé, wọn kò lè sọ ìgbà tó máa ṣẹlẹ̀.

Ìgbà táwọn arabaríbí òkúta tó wà lábẹ́ ilẹ̀ bá ń papò dà ni ilẹ̀ máa ń sẹ̀. Gbogbo ìgbà sì lèyí máa ń ṣẹlẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, kì í milẹ̀ púpọ̀ débi táwọn tó wà lórí ilẹ̀ ayé á fi mọ̀ ọ́n lára, àmọ́ wọ́n lè mọ̀ kí wọ́n sì ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ tí wọ́n bá lo ohun èlò kan tí wọ́n ń pè ní seismograph. a Ìgbà mìíràn sì rèé, ńṣe lọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ òkúta máa fọ́ kúrò lára ara wọn èyí á sì mú kí ilẹ̀ ayé mì jìgìjìgì.

Ẹ gbọ́ ná, kí ló fà á tí ojú ilẹ̀ ayé kò fi dúró sójú kan? Ibùdó Ìsọfúnni Nípa Ilẹ̀ Sísẹ̀ sọ pé: “Mímọ̀ nípa bí ìpele ilẹ̀ tó wà nísàlẹ̀ ṣe rí kọ́lọkọ̀lọ lè ṣàlàyé rẹ̀ fún wá, èròǹgbà yìí sì ti yí ohun táwọn èèyàn ronú lórí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa Ilẹ̀ Ayé padà.” Ó fi kún un pé: “A ti wá mọ̀ báyìí pé ìpele méje ni abala ilẹ̀, a sì tún pín wọn sọ́nà kéékèèké bíi mélòó kan. Gbogbo wọn ló ń yí ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ ní gbogbo ìgbà, iye ìgbà tí wọ́n sì ń yí lọ́dún jẹ́ nǹkan bíi mìlímítà mẹ́wàá sí àádóje.” Ibùdó yìí wá sọ pé ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ríri ni kì í kọjá àwọn ibi kọ́lọ́fín tó pààlà sí àwọn abala ilẹ̀ náà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ibí yìí ni ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún ìsẹ̀lẹ̀ ti máa ń wáyé.

Bó Ṣe Pọ̀ Tó àti Bó Ṣe Rinlẹ̀ Tó

Bí ọṣẹ́ tí ìsẹ̀lẹ̀ kan ṣe bá ṣe pọ̀ tó tàbí bó bá ṣe rinlẹ̀ tó ni wọ́n fi ń díwọ̀n rẹ̀. Láwọn ọdún 1930, Charles Richter ṣe òṣùwọ̀n kan tí wọ́n fi ń wọn bí ilẹ̀ ṣe sẹ̀ tó. Bí ibùdó seismograph ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe onírúurú òṣùwọ̀n tó dà bíi ti Richter. Bí àpẹẹrẹ, èyí tí wọ́n ń pè ní òṣùwọ̀n tí wọ́n fi ń díwọ̀n bí ilẹ̀ ríri kan ṣe rinlẹ̀ tó máa ń díwọ̀n bí iná tó jáde ní orísun ibi tí ilẹ̀ ti sẹ̀ náà lábẹ́ ilẹ̀ lọ́hùn-ún ṣe pọ̀ tó.

Àmọ́ o, gbogbo ìgbà kọ́ làwọn òṣùwọ̀n yìí máa ń sọ bí ìsẹ̀lẹ̀ kan ṣe ṣọṣẹ́ tó. Wo ti ìgbà tí ilẹ̀ sẹ̀ níhà àríwá Bolivia ní June 1994, tí pípọ̀ rẹ̀ jẹ́ 8.2 lórí òṣùwọ̀n Richter, wọ́n ròyìn pé kò pa ju èèyàn márùn-ún lọ. Ibẹ̀ ni èyí tó ṣẹlẹ̀ ní Tangshan, tó wà ní China lọ́dún 1976, tí pípọ̀ rẹ̀ kéré, tó jẹ́ 8.0 lórí òṣùwọ̀n Richter ti gbẹ̀mí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn!

Ńṣe ni àkọsílẹ̀ bí ìsẹ̀lẹ̀ ṣe rinlẹ̀ tó máa ń fi jàǹbá tó ti ṣe fún àwọn èèyàn, ilé àti àyíká hàn. Èyí ló túbọ̀ máa ń fi bí ìsẹ̀lẹ̀ náà ṣe nípa lórí ẹ̀dá ènìyàn tó hàn. Ó ṣe tán ìmìjìgìjìgì ilẹ̀ fúnra rẹ̀ kì í ṣèèyàn ní jàǹbá. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ohun tó ń fà, bíi kí ògiri wó, kí páìpù gáàsì fọ́, òpó wáyà tó wó, àwọn nǹkan tó ń ti òkè ré lulẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ló ń ṣèèyàn léṣe tó sì ń mú ẹ̀mí lọ.

Ọ̀kan lára ohun táwọn onímọ̀ nípa ilẹ̀ sísẹ̀ fẹ́ ṣe ni pé kí wọ́n lè tètè sọ fáwọn èèyàn pé ilẹ̀ máa sẹ̀ níbìkan o. Wọ́n ti ṣe ìlànà kan tó ń bá kọ̀ǹpútà ṣiṣẹ́ tí wọ́n pè ní Advanced Seismic Research and Monitoring System. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan lórí tẹlifíṣọ̀n CNN ti sọ, ìlànà yìí àti bó ṣe lè yára gba àwọn ìsọfúnni àtàwọn ìlànà alágbára mìíràn tí kọ̀ǹpútà máa ń lò yóò ran àwọn òṣìṣẹ́ yìí lọ́wọ́ láti lè “tètè mọ àwọn àgbègbè tí ilẹ̀ ríri tó lágbára ti ṣẹlẹ̀.” Èyí á jẹ́ kó rọrùn fáwọn aláṣẹ láti tètè pèsè ìrànwọ́ fáwọn èèyàn tọ́ràn kàn.

Òtítọ́ ni pé béèyàn bá múra sílẹ̀ de ìsẹ̀lẹ̀, ìpalára tó máa ṣe á dín kù, kò ní ba nǹkan jẹ́ púpọ̀, èyí tó sì ṣe pàtàkì jù ni pé ó máa dáàbò bo ọ̀pọ̀ ẹ̀mí. Àmọ́ ìsẹ̀lẹ̀ kò yéé ṣẹlẹ̀ o. Nítorí náà, ìbéèrè tó wá tibẹ̀ jáde ni pé: Báwo la ṣe ṣèrànwọ́ fún àwọn kan tó ti kàgbákò ìsẹ̀lẹ̀ kí wọ́n bàa lè kojú àbájáde rẹ̀?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Seismograph jẹ́ ohun èlò tí wọ́n fi ń díwọ̀n tí wọ́n sì fi ń ṣàkọsílẹ̀ bí ilẹ̀ ṣe mì tìtì tó nígbà tí ilẹ̀ bá sẹ̀. Ọdún 1890 ni wọ́n ṣe àkọ́kọ́ irú rẹ̀ jáde. Lónìí, ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ibùdó seismograph tó wà kárí ayé.

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 15]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Báwo Ni Ìsẹ̀lẹ̀ Tó Ń wáyé Ṣe Pọ̀ tó?

Bó Ṣe Tóbi Tó Bó Ṣe Rinlẹ̀ Tó Ìpíndọ́gba Lọ́dọọdún

Èyí Tó Peléke 8 lọ sókè 8 1

Èyí Tó Ga Lágajù 7 sí 7.9 18

Èyí Tó Lágbára 6 sí 6.9 120

Èyí Tí Kò Rinlẹ̀ Jù 5 sí 5.9 800

Èyí Tí Kò Ba Nǹkan Jẹ́ Jù 4 sí 4.9 6,200*

Èyí Tí Kò Fi Bẹ́ẹ̀ Lágbára 3 sí 3.9 49,000*

Èyí Tó Kàn Rọra Milẹ̀ <3.0 Èyí tí pípọ̀ rẹ̀ wọn 2 sí 3:

nǹkan bí 1,000 lójúmọ́

Èyí tí pípọ̀ rẹ̀ wọn 1 sí 2:

nǹkan bí 8,000 lójúmọ́

* Iye Tí Wọ́n Fojú Bù.

[Credit Line]

Látọwọ́: Ibùdó Ìsọfúnni Nípa Ìsẹ̀lẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà

Pẹ̀lú ìyọ̀ǹda USGS/Ibùdó Ìsọfúnni Nípa Ìsẹ̀lẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 15]

Àwòrán tó ń sọ bí ilẹ̀ ṣe mì tìtì tó ní ojú ìwé 14 àti 15: Àwọn nọ́ńbà inú rẹ̀ jẹ́ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Berkeley Seismological Laboratory