Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àlàáfíà Kárí Ayé Kì í Ṣe Àlá Tí Kò Lè Ṣẹ o!

Àlàáfíà Kárí Ayé Kì í Ṣe Àlá Tí Kò Lè Ṣẹ o!

Àlàáfíà Kárí Ayé Kì í Ṣe Àlá Tí Kò Lè Ṣẹ o!

KÁ NÍ ó ṣeé ṣe fún Alfred Nobel láti mọ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún ogún ni, ǹjẹ́ á lè fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ pé àlàáfíà kárí ayé ń bọ̀ láìpẹ́? Kò sírọ́ ńbẹ̀ pé inú rẹ̀ á dùn pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fi tinútinú sáré sọ́tùn-ún sósì láti rí i pé kò sógun mọ́. Síbẹ̀, bí ipò nǹkan ṣe wá dà yìí á jọ ọ́ lójú púpọ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Hugh Thomas ò ṣì sọ nígbà tó wí pé: “Òótọ́ ni pé ìtẹ̀síwájú bá ọ̀ràn ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ní ọ̀rúndún ogún, ìjọba sì túbọ̀ ń mú ọ̀ràn ìgbésí ayé àwọn tí kò rí já jẹ ní ọ̀kúnkúndùn. Síbẹ̀, àwọn èèyàn lo ohun ìjà olóró lóríṣiríṣi nínú ọ̀rúndún ogún. Àwọn bí ìbọn arọ̀jò ọta, àwọn ọkọ̀ ogun alágbàá, ọkọ̀ òfuurufú tó ń rọ̀jò bọ́ǹbù, èyí tí wọ́n ń pè ní B-52, àwọn bọ́ǹbù runlérùnnà àtàwọn àfọ̀njá olóró mìíràn. Àwọn ogun tí ẹ̀mí tó bá a rìn ju ti ọ̀rúndún èyíkéyìí mìíràn lọ tún mú kí ọ̀rúndún ogún yàtọ̀.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Thomas fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bí olúkúlùkù bá ṣe rò ó sí ló máa pinnu bóyá lóòótọ́ la lè sọ pé ìtẹ̀síwájú dé bá ọ̀rúndún ogún tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.”

Ǹjẹ́ ìrètí àlàáfíà kárí ayé ti wá dájú ní báyìí tá a ti wọ ọ̀rúndún kọkànlélógún? Bẹ́ẹ̀ kọ́ o! Nígbà tí ìwé ìròyìn Newsweek ń sọ̀rọ̀ nípa báwọn apániláyà ṣe kọlu ìlú New York àti ìlú Washington, D.C., ní September 11, 2001, ó sọ pé: “Nínú ayé kan tí ọkọ̀ òfuurufú ńlá tí wọ́n fi ń kérò ti lè di ohun ìjà aṣenilọ́ṣẹ́ tó ṣe é gbélé ta bí ọfà, kò jọ pé ohun kan wà tí kò lè ṣeé ṣe. Èyí tó sì tún burú jù ni pé kò sóhun téèyàn lè ṣèdíwọ́ fún pé kó má ṣẹlẹ̀.”

Àwọn kan sọ pé kí àlàáfíà kárí ayé tó lè dé, nǹkan méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀: Àkọ́kọ́, ìyípadà ńláǹlà gbọ́dọ̀ wáyé nínú báwọn èèyàn ṣe ń ronú àti bí wọ́n ṣe ń hùwà; èkejì, gbogbo orílẹ̀-èdè gbọ́dọ̀ di òṣùṣù ọwọ̀ kí ìjọba kan ṣoṣo sì máa ṣàkóso wọn. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ tí àlàáfíà á wà kárí ayé, àmọ́ akitiyan ẹ̀dá èèyàn kọ́ ló máa mú èyí wá o. Sáàmù 46:9 sọ nípa Ẹlẹ́dàá náà, Jèhófà Ọlọ́run pe: “Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ṣe èyí? Ìjọba rẹ̀ ló máa lò, ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ọkàn ló sì ti gbàdúrà fún ìjọba yìí léraléra. Ìjọba yìí kì í ṣe ohun kan tí kò ṣe é ṣàlàyé tó wà nínú ọkàn èèyàn, ìjọba gidi kan ni, òun ni Ọlọ́run á sì lò láti fi mú àlàáfíà dé orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé. Wòlíì Aísáyà tí Ọlọ́run mí sí sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn tó máa jẹ́ ọmọ abẹ́ ìjọba yẹn kò ní “kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” (Aísáyà 2:4) Ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan tó ń wáyé ní gbogbo ayé ló máa kọ́ gbogbo èèyàn láti gbé ní àlàáfíà, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn.”

Àní lákòókò tá a wà yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi ẹ̀yà ni wọ́n ti wá tí wọ́n sì wà ní orílẹ̀-èdè tó lé ní igba, wọn kì í fi àwọn ohun ìjà ogun kọlu àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn. Ẹ̀rí tó fi èyí hàn ni pé wọn kì í dá sọ́tùn-ún tàbí dá sósì nínú ayé tí ogun ti bà jẹ́ yìí. Èyí ló fi hàn dájú pé àlàáfíà kì í ṣe àlá tí ò lè ṣẹ, ó ṣì ń bọ̀ wá jọba.

Ṣé wà á fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ìrètí ojúlówó àlàáfíà yìí tá a gbé karí Bíbélì? Jọ̀wọ́, kọ̀wé sáwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde nípa lílo àdírẹ́sì tó sún mọ́ ọ jù lọ lára àwọn tá a tò sí ojú ìwé 5, tàbí kó o kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àdúgbò rẹ.