Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀jẹ̀ Ríru—Bá A Ṣe Lè Dènà Rẹ̀ àti Bá A Ṣe Lè Kápá Rẹ̀

Ẹ̀jẹ̀ Ríru—Bá A Ṣe Lè Dènà Rẹ̀ àti Bá A Ṣe Lè Kápá Rẹ̀

Ẹ̀jẹ̀ Ríru—Bá A Ṣe Lè Dènà Rẹ̀ àti Bá A Ṣe Lè Kápá Rẹ̀

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ BRAZIL

JÌNNÌJÌNNÌ bo Marian! Ńṣe ni ẹ̀jẹ̀ kàn ṣàdédé ń dà ní imú rẹ̀. Ó sọ pé: “Mí ò mọ̀ pé mo lè rù ú là.” Dókítà kan sọ fún Marian pé àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru ló fa ẹ̀jẹ̀ tó ń dà ní imú rẹ̀. Àmọ́ Marian dá a lóhùn pé: “Kò sóhun tó ń ṣe mí kẹ̀.” Dókítà wá sọ fún un pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í mọ̀ pé àwọn ní àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru nítorí pé koko lara wọ́n le.”

Báwo ni ìfúnpá rẹ ṣe rí? Ṣé ọ̀nà tó ò ń gbà gbé ìgbésí ayé rẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ kò lè mú kó o ní àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru lọ́jọ́ iwájú? Kí lo lè ṣe láti má ṣe jẹ́ kí ìfúnpá rẹ ga ju bó ṣe yẹ lọ? a

Bí agbára tí ẹ̀jẹ̀ fi ń ṣàn kiri iṣan ara bá ṣe pọ̀ tó ló máa pinnu bí ìfúnpá èèyàn ṣe máa ga tó. Láti mọ bí ìfúnpá èèyàn ṣe ga to, èèyàn ní láti lo rọ́bà alátẹ́gùn kan tí wọ́n máa ń wé mọ́ apá tí wọ́n á sì so ó mọ́ ẹ̀rọ kan tó ń sọ ìwọ̀n ìfúnpá èèyàn. Oríṣi nọ́ńbà méjì ni ẹ̀rọ yìí máa ń gbé jáde. Àpẹẹrẹ rẹ̀ rèé: 120/80. Nọ́ńbà àkọ́kọ́ ni wọ́n ń pè ní systolic blood pressure, ìyẹn ni pé òun ló ń fi bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ń kiri nínú ara nígbà tí ọkàn bá ń lù kìkì hàn. Wọ́n ń pe nọ́ńbà kejì ní diastolic blood pressure, èyí ló ń fi bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ń kiri nínú ara hàn nígbà tí ọkàn kò bá lù kìkì. Mìlímítà ni wọ́n fi ń díwọ̀n ìfúnpá èèyàn. Bí ìfúnpá ẹnì kan bá sì ti wọ̀n kọjá 140/90, àwọn oníṣègùn ti ka onítọ̀hún sí alárùn ẹ̀jẹ̀ ríru nìyẹn.

Báwo tiẹ̀ ni ìfúnpá ṣe máa ń ga? Ńṣe lọ̀rọ̀ yìí dà bí ìgbà téèyàn bá ń ṣí omi ẹ̀rọ. Bó o bá ṣe túbọ̀ ṣí ẹ̀rọ náà sí ni omi á ṣe túbọ̀ máa dà yàà sí, bó o bá sì tì í, omi náà á tún fẹ́ fi agbára jáde. Bọ́ràn ẹ̀jẹ̀ ríru ṣe rí gan-an nìyẹn, bí agbára tí ẹ̀jẹ̀ fi ń ṣàn bá pọ̀ sí i, tàbí tí ohun kan bá ń dí i lọ́wọ́ tí kò ráyè ṣàn, ìwọ̀nyí lè mú kí ìfúnpá èèyàn ga. Kí ló ń fa kí ìfúnpá máa ga? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè fà á.

Àwọn Ohun Tó Ń Fà Á Téèyàn Ò sì Lè Dọ́gbọ́n Sí

Àwọn olùwádìí ti ṣàwárí pé tí ẹnì kan bá ní mọ̀lẹ́bí tó ní àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru, àfàìmọ̀ kí onítọ̀hún máà ní àrùn náà. Àkọsílẹ̀ oníṣirò táwọn kan ṣe ti fi hàn pé àwọn ìbejì tí wọ́n jọra dáadáa máa ń ní àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru ju àwọn ìbejì tí kò jọra lọ. Ìwádìí táwọn kan ṣe sọ pé “wọ́n lè rí àwọn àbùdá tó ń fa àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru nínú ara,” èyí tá á fi hàn pé ńṣe ni ẹnì kan jogún àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru. Bí àgbà ṣe ń dé sí èèyàn lè mú kéèyàn ní àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru, èyí sì máa ń wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọkùnrin aláwọ̀ dúdú.

Àwọn Ohun Tó Ń Fà Á Téèyàn Lè Dọ́gbọ́n Sí

Máa kíyè sí irú oúnjẹ tó ò ń jẹ! Iyọ̀ lè mú kí ìfúnpá àwọn mìíràn yára lọ sókè, àgàgà àwọn tó lárùn àtọ̀gbẹ, àwọn tí ẹ̀jẹ̀ ríru ń dà láàmú gan-an, àwọn tó ti darúgbó àtàwọn aláwọ̀ dúdú. Tí ọ̀rá bá pọ̀ jù nínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀, èyí lè mú kí èròjà cholesterol lọ dí àwọn òpójẹ̀ inú ara, àwọn òpójẹ̀ náà ò ní lè ṣiṣẹ́ dáadáa, èyí á sì mú kí ìfúnpá ga. Àwọn èèyàn tí wọ́n fi nǹkan bí ìdá ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún tóbi ju bó ṣe yẹ lọ lè ní àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru. Àwọn ìwádìí kan fi hàn pé téèyàn bá ń jẹ èròjà potassium àti èròjà káṣíọ̀mù dáadáa, èyí lè jẹ́ kí ìfúnpá lọ sílẹ̀.

Sìgá mímu lè jẹ́ kó o lárùn atherosclerosis, ìyẹn kí ọ̀rá pọ̀ nínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀, àrùn àtọ̀gbẹ, àrùn ọkàn àti àrùn ẹ̀gbà. Nítorí náà, téèyàn bá lárùn ẹ̀jẹ̀ ríru tó tún wá ń mu sìgá, ó lè ní àrùn òpójẹ̀ àti ọkàn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀rí tó wà kò tíì bára mu, èròjà kaféènì tó wà nínú kọfí, tíì, ọtí ẹlẹ́rìndòdò, kéèyàn máa ní másùnmáwo àti kéèyàn máa ṣe wàhálà àṣekúdórógbó lè mú kí ìfúnpá lọ sókè. Ní àfikún, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sọ pé mímu ọtí líle ní àmujù àti àìkìíṣe eré ìmárale lè mú kí ìfúnpá èèyàn ga.

Ìgbésí Ayé Tó Ń Fúnni Nílera

Àṣìṣe ńlá gbáà ló máa jẹ́ kéèyàn jẹ́ kó dìgbà tóun ní àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru kó tó máa wá oògùn rẹ̀. Àtìgbà òwúrọ̀ ló yẹ kéèyàn ti máa gbé ìgbésí ayé tó lè fúnni nílera. Béèyàn bá bójú tó ara rẹ̀ nígbà òwúrọ̀, ìgbésí ayé rẹ̀ á túbọ̀ dára sí i lọ́jọ́ alẹ́.

Níbi Àpérò Kẹta Táwọn Oníṣègùn Brazil Ṣe Nípa Títọ́jú Àrùn Ẹ̀jẹ̀ Ríru, wọ́n sọ béèyàn ṣe lè yí bó ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀ padà kí àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru tó ní bàa lè lọ sílẹ̀. Àwọn ohun tí wọ́n sọ wúlò gan-an fún àwọn tó ní àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru.

Àwọn olùwádìí sọ pé kí àwọn tó bá sanra jù máa jẹ àwọn oúnjẹ tí kò ní èròjà kálórì púpọ̀ nínú, kí wọ́n yéé jẹ àwọn oúnjẹ tí wọ́n ń sè pá-pà-pá àtàwọn oúnjẹ “ajẹ́bíidán” tí wọ́n fi ń dín sísanra kù, kí wọ́n sì máa ṣeré ìmárale tí kò le jù déédéé. Àwọn olùwádìí náà tún sọ pé kí wọ́n má jẹ ju iyọ̀ ṣíbí ìpotíì kan ṣoṣo lójúmọ́. b Ohun tí gbogbo èyí túmọ̀ sí ni pé ìwọ̀nba iyọ̀ díẹ̀ ni kí wọ́n máa fi sí oúnjẹ, kí wọ́n dín oúnjẹ alágolo, ẹran bíbọ̀, ẹran díndín, àwọn oúnjẹ tí wọ́n ti fi oògùn sí láti pa á mọ́ àtàwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n máa ń jẹ kù. Láti lè dín iyọ̀ tí wọ́n ń jẹ kù, kí wọ́n yéé fi iyọ̀ sínú oúnjẹ tí wọ́n bá ń jẹun lọ́wọ́, kí wọ́n máa kíyè sí àwọn oúnjẹ tí wọ́n ti fi ẹ̀rọ yí padà tí wọ́n bá fẹ́ rà láti mọ bí iyọ̀ tó wà nínú rẹ̀ ṣe pọ̀ tó.

Wọ́n tún dá a lábàá níbi Àpérò Àwọn Oníṣègùn Brazil náà pé káwọn tó lárùn ẹ̀jẹ̀ ríru máa jẹ èròjà potassium tó pọ̀ nítorí ó máa ń “gbéjà ko àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru.” Nítorí náà, oúnjẹ tó lè fúnni nílera ní láti jẹ́ èyí “tí èròjà sodium inú rẹ̀ kò tó nǹkan, àmọ́ tí èròjà potassium inú rẹ̀ pọ̀ púpọ̀.” Irú bí ẹ̀wà, àwọn ẹ̀fọ́ tó ṣe ṣèréṣèré, ọ̀gẹ̀dẹ̀, ẹ̀gúsí, kárọ́ọ̀tì, ewébẹ̀ beet, tòmátì àti ọsàn. Ó tún ṣe pàtàkì kéèyàn dín ọtí líle tó ń mu kù. Àwọn olùwádìí kan sọ pé àwọn ọkùnrin tí wọ́n lárùn ẹ̀jẹ̀ ríru kò gbọ́dọ̀ mu kọjá gàásì kan ọtí líle lóòjọ́; pé àwọn obìnrin tó lárùn náà àtàwọn obìnrin tí ò tóbi tó bó ṣe yẹ kò gbọ́dọ̀ mu kọjá ìlàjì gàásì lójúmọ́. c

Ibi tí Àpérò Àwọn Oníṣègùn Brazil parí ọ̀rọ̀ sí ni pé ṣíṣe eré ìmárale déédéé kì í jẹ́ kí ìfúnpá ga ju bó ṣe yẹ lọ kì í sì í jẹ́ kéèyàn ní àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru. Eré ìmárale tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, bíi kéèyàn rìn káàkiri, kéèyàn wa kẹ̀kẹ́ kiri tàbí kéèyàn lúwẹ̀ẹ́ fún nǹkan bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta, ní ẹ̀ẹ̀mẹta sí ẹ̀ẹ̀marùn-ún lọ́sẹ̀ máa ń ṣara láǹfààní. d Àwọn ohun mìíràn tó lè mú kéèyàn gbé ìgbésí ayé tó ń fúnni nílera ni kéèyàn jáwọ́ sìgá mímu, kéèyàn máà jẹ́ kí ọ̀rá sẹgẹdẹ sínú ẹ̀jẹ̀, kéèyàn má fàyè gba àrùn àtọ̀gbẹ, kéèyàn máa jẹ èròjà káṣíọ̀mù àti èròjà magnesium tó pọ̀, kéèyàn ṣọ́ra fún sísá sókè sódò ju bó ṣe yẹ lọ, kó sì yẹra fún ìdààmú ọkàn. Àwọn oògùn kan wà tó lè mú kí ìfúnpá èèyàn ròkè, àwọn bí oògùn tí kì í jẹ́ kí imú dí, àwọn oògùn tí èròjà sodium pọ̀ nínú wọn tí wọ́n fi ń gbogun ti ásíìdì, àwọn oògùn tó ń febi pani àtàwọn oògùn apàrora tí wọ́n ń lò fún túúlu, tó ní èròjà kaféènì nínú.

Ó dájú pé tó o bá ní àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru, kò sí ẹlòmíràn tó tóótun bíi dókítà rẹ láti fún ọ nímọ̀ràn lórí àwọn oúnjẹ tó yẹ ọ́ àtàwọn àṣà tó yẹ kó o yẹra fún, lọ́nà tó bá ìlera rẹ mu. Àmọ́ ṣá, bó ṣe wù kí ìlera rẹ rí, àǹfààní kékeré kọ́ ló wà nínú kéèyàn ti ìgbà òwúrọ̀ máa gbé ìgbésí ayé tó ń fún ara lókun. Bí èyí ṣe dára fáwọn tó lárùn ẹ̀jẹ̀ ríru náà ló ṣe dára fún ìdílé lápapọ̀. Marian, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ṣe àwọn àyípadà kan nínú bó ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀. Ó ṣì ń lo egbòogi ní lọ́wọ́lọ́wọ́, àmọ́ ìgbésí ayé rẹ̀ kò yàtọ̀ sí tàwọn èèyàn tó kù bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní àìlera. Ìwọ náà ńkọ́? Bá a ti ń dúró de ìgbà tára gbogbo èèyàn á dá ṣáṣá tí “kò [ní] sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí,’” má ṣe jẹ́ kí ìfúnpá rẹ ga ju bó ṣe yẹ lọ o!—Aísáyà 33:24.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Jí! kò sọ pé irú ìtọ́jú báyìí ló dára láti gbà o, nítorí olúkúlùkù ló máa pinnu irú ìtọ́jú tóun fẹ́.

b Bó o bá ní àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru tàbí àrùn ọkàn, àrùn ẹ̀dọ̀ tàbí àrùn kíndìnrín, tó o sì ń lo oògùn ní lọ́wọ́lọ́wọ́, yáa lọ bá dókítà rẹ̀ kó sọ fún ọ nípa bí èròjà sodium àti èròjà potassium tí wàá máa jẹ lójúmọ́ ṣe gbọ́dọ̀ pọ̀ tó.

c Gàásì kan ògidì ọtí ògógóró jẹ́ ọgbọọgba pẹ̀lú gàásì méjì ọtí whiskey, vodka, ó tún jẹ́ ọgbọọgba pẹ̀lú gàásì mẹ́jọ ọtí wáìnì tàbí kọ́ọ̀pù ọtí bíà méjì

d Bá dókítà rẹ sọ̀rọ̀ láti mọ̀ bóyá eré ìmárale kan pàtó ló yẹ ọ́.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]

BÍ O ṢE LÈ GBÓGUN TI ÀRÙN Ẹ̀JẸ̀ RÍRU

1. Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Dènà Àrùn Ẹ̀jẹ̀ Ríru

• Má ṣe sanra jọ̀kọ̀tọ̀

• Dín iyọ̀ tó ò ń fi sí oúnjẹ kù

• Máa jẹ àwọn oúnjẹ tó ní èròjà potassium nínú dáadáa

• Dín ọtí líle tó ò ń mu kù

• Máa ṣe eré ìmárale déédéé

2. Àwọn Ohun Mìíràn Tí Kò Ní Jẹ́ Kí Ìfúnpá Rẹ Ga Ju Bó Ṣe Yẹ Lọ

• Máa jẹ àwọn ohun tó ní èròjà káṣíọ̀mù àti èròjà magnesium nínú

• Máa jẹ àwọn ẹ̀fọ́ tó ní ṣakiti nínú dáadáa

• Gba ìtọ́jú tí wọ́n fi ń dín másùnmáwo kù

3. Àwọn Ohun Mìíràn Tó O Tún Lè Ṣe

• Fi sìgá mímu sílẹ̀

• Dín èròjà cholesterol tó wà lára rẹ kù

• Wá ìtọ́jú sí àrùn àtọ̀gbẹ

• Má ṣe lo àwọn oògùn tó lè mú kí ìfúnpá rẹ lọ sókè

[Credit Line]

A fa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí yọ látinú ìwé lórí Àpérò Kẹta Táwọn Oníṣègùn Brazil Ṣe Nípa Títọ́jú Àrùn Ẹ̀jẹ̀ Ríru—Revista Brasileira de Clínica & Terapêutica.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ṣíṣe eré ìmárale déédéé àti jíjẹ oúnjẹ tó ń fún ara lókun lè ṣèrànwọ́ láti dènà àti láti tọ́jú àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru