Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìtùnú fún Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀

Ìtùnú fún Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀

Ìtùnú fún Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀

KÍKỌLÙ táwọn apániláyà kọlu ìlú New York àti ìlú Washington, D.C., ní September 11, 2001 kó ìpayà bá àwọn èèyàn kárí ayé. Lọ́jọ́ kan ṣoṣo, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ṣòfò ẹ̀mí. Èyí ní nínú ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn akíkanjú panápaná, àwọn ọlọ́pàá àtàwọn oníṣègùn.

Látìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lápapọ̀ ti ń ṣe gugudu méje láti tu àwọn tí èèyàn wọn kú nínú àjálù náà nínú. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe èyí jẹ́ “láti di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn” àti “láti tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.”—Aísáyà 61:1, 2.

Látọjọ́ pípẹ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí i pé àwọn téèyàn wọn bá kú sábàá máa ń bi ara wọn láwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí. Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè náà. O ò ṣe kúkú wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí nínú Bíbélì rẹ?

Tí ẹnì kan bá kú, ṣé Ọlọ́run ló kádàrá rẹ̀ bẹ́ẹ̀?

Bíbélì sọ nínú Oníwàásù 9:11 pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” (“èṣì,” Bibeli Yoruba Atọ́ka) ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo èèyàn. Tó bá jẹ́ lóòótọ́ ni Ọlọ́run kádàrá èèyàn láti kú, kí ló dé tí Bíbélì fi sọ pé ká máa ṣọ́ra ká má bàa ṣèṣe?—Bí àpẹẹrẹ, wo Diutarónómì 22:8.

Èé ṣe tá a fi ń kú?

Inú Párádísè orí ilẹ̀ ayé la fi tọkọtaya àkọ́kọ́ ìyẹn Ádámù àti Éfà sí. Ká ní wọ́n ṣègbọràn ni, wọn kì bá tí kú. Kìkì bí ẹ̀dá èèyàn bá ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run nìkan ni wọ́n máa kú. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15-17) Ó mà ṣe o, Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ẹlẹ́dàá wọn. Èyí sì yọrí sí ikú fún wọn. Ìgbà tó sì jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ádámù àti Éfà ni gbogbo ẹ̀dá èèyàn ti ṣẹ̀ wá, gbogbo wọn ló ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Bíbélì sọ pé: ‘Ẹ̀ṣẹ̀ tipasẹ̀ ènìyàn kan [Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.’—Róòmù 5:12.

Ipò wo làwọn òkú wà?

Lẹ́yìn tí Ádámù ti ṣọ̀tẹ̀, Ọlọ́run sọ pé: “Ìwọ yóò . . . padà sí ilẹ̀, nítorí láti inú rẹ̀ ni a ti mú ọ jáde. Nítorí ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Nítorí náà, ẹni tó bá ti kú kò mọ ohunkóhun mọ́, kódà kò sí níbì kankan mọ́. Bíbélì sọ pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Bíbélì tún sọ pé tí ẹnì kan bá kú, ńṣe ni “ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.”Sáàmù 146:3, 4.

Ṣebí téèyàn bá kú ọkàn rẹ̀ kì í kú?

Ohun tí Bíbélì fi kọ́ wa ni pé ìwọ fúnra rẹ ni ọkàn, kì í ṣe ohun ọ̀tọ̀ kan tó máa wà láàyè lẹ́yìn tó o bá kú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Òwe 2:10; Jeremáyà 2:34) Nítorí náà, a lè sọ pé nígbà tí ẹnì kan bá kú, ọkàn kan ló kú yẹn. Bíbélì sọ ọ́ kedere pé: “Ọkàn [ìyẹn èèyàn] tí ń dẹ́ṣẹ̀ . . . yóò kú.”—Ìsíkíẹ́lì 18:4.

Ìrètí wo ló wà fáwọn tó ti kú?

Bíbélì sọ pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe ni pé, ní àkókò àjíǹde, ó máa jí àwọn òkú dìde sórí ilẹ̀ ayé tó ti di Párádísè, níbi tí kò ti ní sí àìsàn àti ikú mọ́. Jésù sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29; Ìṣípayá 21:1-4.

Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó kú, ìyẹn Lásárù, ó fi ikú wé ìgbà téèyàn bá sùn. (Jòhánù 11:11-13) Síwájú sí i, lẹ́yìn tí Jésù jí Lásárù dìde, kò sọ ohunkóhun tó jẹ mọ́ pé òun ti wà níbì kan tóun ti ń jìyà tàbí tóun ti ń gbádùn níwọ̀nba àkókò tó fi kú náà. (Jòhánù 11:37-44) Èyí kò rúni lójú nítorí pé àwọn òkú kò mọ ohunkóhun. Kò sí pé wọ́n ń joró níbì kankan, ńṣe ni wọ́n dúró de “wákàtí” náà tí a óò jí wọn dìde. Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ńbẹ̀ ni pé, jíjí tí Jésù jí Lásárù dìde fi hàn pé àwọn òkú lè padà wà láàyè. Àní, ńṣe ni Jésù lo iṣẹ́ ìyanu tó ṣe yìí láti jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. (Ìṣe 24:15) Ìtùnú ńlá mà lèyí o fún àwọn téèyàn wọn kú lákòókò oníwàhálà tá a wà yìí!