Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rúndún Tó Kún Fún Ìwà Ipá

Ọ̀rúndún Tó Kún Fún Ìwà Ipá

Ọ̀rúndún Tó Kún Fún Ìwà Ipá

ALFRED NOBEL ronú pé àlàáfíà á jọba táwọn orílẹ̀-èdè bá ní àwọn ohun ìjà aṣekúpani tí wọ́n lè fi run àwọn aríjàgbá ráúráú. Ó kọ ọ́ pé: “Èyí kò ní jẹ́ kí ogun ṣẹlẹ̀ rárá.” Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Nobel ní lọ́kàn, kò sí orílẹ̀-èdè kan tó mọnúúrò tó máa dá ogun sílẹ̀ nígbà tó mọ̀ pé àtúbọ̀tán rẹ̀ kò ní dára fóun. Àmọ́ kí ló ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún tó kọjá?

Kò pé ogún ọdún lẹ́yìn tí Nobel kú tí Ogun Àgbáyé Kìíní fi ṣẹlẹ̀. Àwọn àkọ̀tun ohun ìjà aṣekúpani ni wọ́n fi ja ogun yìí. Lára wọn ni àwọn ìbọn arọ̀jò-ọta, gáàsì olóró, àwọn ohun ìjà tó ń rọ̀jò iná, ọkọ̀ ogun alágbàá, ọkọ̀ òfuurufú àti ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi ń jagun. Àwọn sójà tó bógun lọ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́wàá, ó sì lé ní ìlọ́po méjì iye yẹn tó fara pa. Ọṣẹ́ tí Ogun Àgbáyé Kìíní ṣe mú káwọn èèyàn tún sọ pé àlàáfíà làwọn ń fẹ́. Èyí ló mú wọn dá ẹgbẹ́ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀. Ààrẹ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, Woodrow Wilson tó kópa tó jọjú nínú ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́ yìí ló gba Ẹ̀bùn Nobel ti Àlàáfíà lọ́dún 1919.

Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, gbogbo ìrètí táwọn èèyàn ní pé ogun á dópin títí láé wọmi ní 1939, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà, ogun yìí burú ju ti àkọ́kọ́ lọ. Àkókò ogun yìí ni Adolf Hitler túbọ̀ mú ilé iṣẹ́ Nobel tó wà ní ìlú Krümmel gbòòrò sí i, ó sì wá di ọ̀kan lára àwọn ilé iṣẹ́ ohun ìjà tó tóbi jù lọ ní Jámánì. Àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án. Àmọ́ nígbà tí ogun parí, ọkọ̀ òfuurufú ẹgbẹ́ ogun Olùgbèjà rọ̀jò bọ́ǹbù tó lé lẹ́gbẹ̀rún sórí ilé iṣẹ́ Nobel, wọ́n sì pa á rẹ́ ráúráú. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé àwọn àwárí tí Nobel fúnra rẹ̀ ṣe ni wọ́n fi ṣe àwọn bọ́ǹbù náà.

Ogun àgbáyé méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé ikú Nobel, bẹ́ẹ̀ sì tún ni àìmọye rògbòdìyàn mìíràn ti tẹ̀ lé e. Ní gbogbo àkókò yìí, ńṣe làwọn ohun ìjà ń pọ̀ sí i, lára wọn sì túbọ̀ ń di olóró sí i. Wo díẹ̀ lára àwọn ohun ìjà táwọn ológun ń lò tó ti wá pọ̀ gan-an láwọn ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé ikú Nobel.

Àwọn ohun ìjà kéékèèké àtàwọn ohun ìjà tó rọrùn-ún lò. Èyí ní nínú àwọn ìbọn ìléwọ́, ìbọn àgbéléjìká, àwọn bọ́ǹbù kéékèèké, àwọn ìbọn arọ̀jò ọta àtàwọn ohun ìjà kéékèèké mìíràn. Pọ́ọ́kú lowó àwọn ohun ìjà wọ̀nyí, wọ́n dùn-ún bójú tó, kódà wọn ò ṣòro lò.

Ǹjẹ́ wíwà tí àwọn ohun ìjà yìí wà àti jàǹbá tí wọ́n ń ṣe fáwọn èèyàn ti mú kí ogun yéé ṣẹlẹ̀? Kò rí bẹ́ẹ̀ o! Michael Klare kọ ọ́ nínú ìwé ìròyìn Bulletin of the Atomic Scientists, pé àwọn ohun ìjà kéékèèké ti di “lájorí ohun ìjà tí wọ́n fi ń ja ogun tó pọ̀ jù lọ lẹ́yìn tí Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lé parí.” Kódà, nǹkan bí ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ṣòfò ẹ̀mí nínú àwọn ogun àìpẹ́ yìí ni ikú wọn ò ṣẹ̀yìn àwọn ohun ìjà kéékèèké àtàwọn ohun ìjà tó rọrùn-ún lò wọ̀nyí. Láwọn ọdún 1990 nìkan, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rin èèyàn táwọn ohun ìjà yìí gba ẹ̀mí wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, àwọn èwe tí wọn ò kọ́ṣẹ́ ogun tí wọn kì í sì í pa àwọn òfin ogun jíjà mọ́ ló máa ń lo àwọn ohun ìjà wọ̀nyí.

Àwọn ohun abúgbàù tí wọ́n ń rì mọ́lẹ̀. Nígbà tí ọ̀rúndún ogún fi máa parí, nǹkan bí àádọ́rin èèyàn ní ìpíndọ́gba ni àwọn ohun abúgbàù tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ ń sọ di amúkùn-ún tàbí pa lójoojúmọ́! Èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn ni kì í ṣe ológun o, aráàlú ni wọ́n. Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í ṣe tìtorí àtigba ẹ̀mí èèyàn ni wọ́n ṣe ń ri àwọn ohun abúgbàù mọ́lẹ̀, àmọ́ láti sọ àwọn èèyàn di abirùn kí ìpayà sì bá àwọn tó bá kàgbákò ọṣẹ́ tó ń ṣe.

Òótọ́ ni pé akitiyan ńláǹlà làwọn èèyàn ti ṣe láwọn ọdún àìpẹ́ yìí láti hú àwọn ohun abúgbàù tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ yìí jáde. Àmọ́ àwọn kan sọ pé tí wọ́n bá fi máa hú ohun abúgbàù kan jáde, àwọn èèyàn mìíràn á ti ri ogún mọ́lẹ̀ àti pé ó ṣeé ṣe kí ohun abúgbàù táwọn èèyàn ti rì mọ́lẹ̀ káàkiri ayé tó nǹkan bí ọgọ́ta mílíọ̀nù. Bí àwọn ohun abúgbàù yìí kò ṣe mọ̀yàtọ̀ láàárín àwọn ológun àtàwọn ọmọdé tó ń ṣeré lórí pápá kò ní kí àwọn tó ń ṣe àwọn ohun èlò ọlọ́ṣẹ́ yìí àtàwọn tó ń lò wọ́n jáwọ́.

Àwọn ohun ìjà runlérùnnà. Pẹ̀lú àwárí àwọn bọ́ǹbù runlérùnnà tí wọ́n ti ṣe, wọ́n lè pa odidi ìlú kan run láàárín ìṣẹ́jú àáyá mélòó kan láìjẹ́ pé àwọn sójà bára wọn jà rárá. Bí àpẹẹrẹ, wo bí nǹkan ṣe bà jẹ́ lọ bẹẹrẹbẹ nígbà tí wọ́n ju àwọn bọ́ǹbù átọ́míìkì sílùú Hiroshima àti Nagasaki ní 1945. Ìmọ́lẹ̀ bọ́ǹbù yìí ju agbára èèyàn lọ, ó sì fọ́ àwọn kan lójú. Ìtànṣán bọ́ǹbù yìí sọ àwọn mìíràn dìdàkudà. Iná rara àti ooru rẹ̀ sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀. Wọ́n ní iye èèyàn tó kú ní ìlú méjèèjì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000]!

Lóòótọ́, àwọn kan lè sọ pé rírun tí wọ́n fi bọ́ǹbù run ìlú méjèèjì mú kí iye èèyàn tí ì bá kú ká ní wọn ò lo àwọn bọ́ǹbù runlérùnnà dín kù. Síbẹ̀, rírí táwọn kan rí i bí ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ṣòfò ti mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rọ àwọn olóṣèlú àtàwọn sànmọ̀rí káàkiri àgbáyé láti fòpin sí lílo ohun ìjà ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ yìí. Kódà, ọ̀pọ̀ èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù pé ẹ̀dá èèyàn ti fọwọ́ ara rẹ̀ ṣe ohun tó máa pa á run.

Ṣé ṣíṣe àwọn ohun ìjà runlérùnnà yìí ti mú kí àlàáfíà jọba? Àwọn kan sọ pé bẹ́ẹ̀ ni. Wọn sọ pé àwọn èèyàn ò tíì fi àwọn ohun ìjà alágbára yìí jagun fún ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún báyìí. Àmọ́ èyí ó wù kó jẹ́, èrò Nobel pé àwọn ohun ìjà runlérùnnà á jẹ́ kí ogun yéé ṣẹlẹ̀ kò tíì ṣẹ o, nítorí pé àwọn èèyàn ṣì ń fi àwọn ohun ìjà kéékèèké jagun. Yàtọ̀ síyẹn, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ìlànà Ohun Ìjà Runlérùnnà sọ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ohun ìjà runlérùnnà ló wà ní sẹpẹ́ fún lílò nígbàkigbà. Lásìkò tá a wà yìí, tó jẹ́ pé gbogbo èèyàn lọ̀rọ̀ àwọn apániláyà ń kódààmú bá, ńṣe lọ̀pọ̀ ń bẹ̀rù pé ìṣẹ̀lẹ̀ láabi gbáà ló máa ṣẹlẹ̀ tí àwọn ohun tí wọ́n fi ń ṣe àwọn nǹkan ìjà wọ̀nyí bá bọ́ sọ́wọ́ àwọn apániláyà. Ká tiẹ̀ ní kò bọ́ sọ́wọ́ àwọn apániláyà pàápàá, ewu ṣì ń bẹ pé táwọn kan bá ṣèèṣì yìn ín, ó lè kó gbogbo ayé sí yọ́ọ́yọ́ọ́. Ó hàn gbangba pé, tá a bá ń sọ nípa àwọn ohun ìjà runlérùnnà, àlàáfíà tí Nobel rò pé ó máa dé kò dé o.

Àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn àtàwọn ohun ìjà oníkẹ́míkà. Wọ́n máa ń fi àwọn kòkòrò bakitéríà tó lè pani ja ogun, irú bí èyí tí wọ́n ń pè ní anthrax, tàbí àwọn kòkòrò fáírọ́ọ̀sì, irú èyí tó ń fa ìgbóná. Ti ìgbóná yìí léwu gan-an nítorí pé ó tètè máa ń tàn kálẹ̀. Ewu àwọn ohun ìjà oníkẹ́míkà náà tún wà níbẹ̀, irú bí àwọn gáàsì olóró. Oríṣiríṣi làwọn èròjà onímájèlé yìí. Òótọ́ ni pé wọ́n ti fòfin dè wọ́n fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún sẹ́yìn, síbẹ̀ àwọn èèyàn ṣì ń lò wọ́n.

Ǹjẹ́ àwọn ohun ìjà ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ yìí àti ọṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ti jẹ́ káwọn èèyàn ṣe bí Nobel ṣe sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣe, ìyẹn ni pé ‘jìnnìjìnnì á bo gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀làjú wọ́n á sì sọ pé káwọn jagunjagun àwọn kógbá ogun wọlé’? Rárá o, kàkà kí ọ̀ràn rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n túbọ̀ ń mú káwọn èèyàn máa jáyà pé ọjọ́ kan lè jọ́kan táwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa àwọn ohun ìjà wọ̀nyí á lọ lò wọ́n. Ó lé ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn báyìí tí olùdarí Àjọ Tó Ń Rí sí Dídín Ohun Ìjà Ogun Kù ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí èèyàn kankan tí kò lè ṣe àwọn ohun ìjà oníkẹ́míkà ní ẹ̀yìnkùlé rẹ̀, bó bá sáà ti kọ́ ẹ̀kọ́ kẹ́mísìrì díẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ gíga.”

Kò sí àníàní pé àwọn ogun tó túbọ̀ ba nǹkan jẹ́ púpọ̀púpọ̀, tó ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀rúndún ogún pọ̀ ju ti sànmánì èyíkéyìí mìíràn lọ. Ní báyìí tá a ti wà níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkànlélógún, ńṣe ni ọ̀rọ̀ pé àlàáfíà ń bọ̀ wá jọba túbọ̀ ń dà bí àlá tí kò lè ṣẹ, àgàgà lẹ́yìn ọṣẹ́ tí àwọn apániláyà ṣe nílùú New York àti ìlú Washington, D.C., ní September 11, 2001. Steven Levy kọ ọ́ nínú ìwé ìròyìn Newsweek, pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹni tí kò mọ̀ báyìí pé dípò lílo ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ fún àǹfààní èèyàn, iṣẹ́ láabi ni wọ́n ń fi ṣe.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ta la lè sọ pé ó mọ ọgbọ́n tá a lè dá sí ọ̀rọ̀ náà? Ohun tí ẹ̀dá èèyàn ń ṣe látọjọ́ pípẹ́ ni pé kí wọ́n máa forí-fọrùn ṣe ohun tí wọ́n bá ti kà sí ìtẹ̀síwájú, ìgbà tí wọ́n bá ṣe é tán ni wọ́n á ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣàtúpalẹ̀ ọ̀rọ̀ náà. Ríronú tí a kì í ronú ṣáájú pé ìṣẹ̀lẹ̀ láabi lè ṣẹlẹ̀ ló ń mú ká bá ara wa nípò tó fi lè ṣẹlẹ̀ lóòótọ́.”

Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí, ìtàn ti fi kọ́ wa pé ṣíṣe àwọn ohun abúgbàù àtàwọn ohun ìjà tó ń gbẹ̀mí èèyàn kò mú àlàáfíà wá fún aráyé. Nígbà náà, ṣé àlá ti kò lè ṣẹ wá lọ̀rọ̀ àlàáfíà fún gbogbo aráyé ni?

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Pípẹ̀tù sí Agbára Kẹ́míkà Olóró

Ní 1846, onímọ̀ nípa kẹ́míkà náà Ascanio Sobrero, tó tún jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Ítálì ṣàwárí kẹ́míkà olóró kan tó dà bí epo rọ̀bì tó sì lè bú gbàù, nitroglycerin ni wọ́n ń pè é. Kẹ́míkà yìí lóró burúkú burúkú. Ìgbà tí kẹ́míkà olóró yìí dáhùn mọ́ Sobrero lọ́wọ́ nígbà tó fi ń ṣe àwọn ohun kan, tó sì dá ọgbẹ́ ńlá kan sí i níwájú orí ni kò lò ó mọ́. Ìyẹn nìkan kọ́, ìṣòro kan wà nínú ọ̀rọ̀ kẹ́míkà yìí tí Sobrero ò lè yanjú. Ìṣòro ọ̀hún ni pé, tí wọ́n bá da kẹ́míkà yìí sílẹ̀ tí wọ́n sì fi òòlù lù ú, apá ibi tí wọ́n fi òòlù lù nìkan ló máa gbaná, ohunkóhun ò sì ní ṣẹlẹ̀ sáwọn tó kù.

Nobel ló wá yanjú ìṣòro yìí nígbà tó ṣàwárí ohun èèlò kan tí wọ́n fi ń yin ohun àwọn ohun abúgbàù. Ó lo ìwọ̀nba díẹ̀ lára oríṣi kẹ́míkà kan tó máa ń bú gbàù tó lè tanná ran oríṣi kẹ́míkà mìíràn tóun náà ń bú gbàù. Nígbà tó wá di 1865, Nobel ṣe korobá tí wọ́n fi ń yin ohun abúgbàù. Bó ṣe ṣe é ni pé ó fi kẹ́míkà mercury tó ń bú gbàù sínú korobá kan ó sì dé e, ó wá fi korobá yìí sínú àgbá ńlá kan tí kẹ́míkà nitroglycerin wà, ó tanná ràn án, ìyẹn sì dáhùn.

Síbẹ̀, lílo kẹ́míkà nitroglycerin ṣì léwu púpọ̀ púpọ̀. Àpẹẹrẹ kan rèé: Nígbà tí kẹ́míkà kan bú gbàù nínú ilé iṣẹ́ Nobel ní 1864, lẹ́yìn òde ìlú Stockholm, odidi èèyàn márùn-ún ló ṣòfò ẹ̀mí, kódà Emil, àbúrò Nobel tó kéré jù wà lára àwọn márùn-ún náà. Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn kẹ́míkà abúgbàù yìí dáhùn nílé iṣẹ́ Nobel tó wà ní Krümmel, ní Jámánì, gbogbo ibẹ̀ ló sì bà jẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan ń fi kẹ́míkà elépo yìí tan iná àtùpà, wọ́n máa ń fi kun bàtà tàbí kí wọ́n fi pa àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọn, àmọ́ ọṣẹ́ tó ṣe fún wọn kò ṣe é fẹnu sọ. Kódà tí wọ́n bá fi fọ́ àwọn òkúta ńlá pàápàá, epo kẹ́míkà yìí lè ṣàn sínú àwọn àfọ́kù òkúta kó sì fa jàǹbá tó bá yá.

Ní 1867, Nobel yí kẹ́míkà elépo rọ̀bì yìí kúrò ní kẹ́míkà ṣíṣàn. Bó ṣe ṣe é ni pé ó po kẹ́míkà nitroglycerin mọ́ kẹ́míkà kan tí kì í bú gbàù, èyí tí wọ́n ń pè ní kieselguhr. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Nobel tún ṣe àwọn ohun abúgbàù mìíràn nígbà tó yá, èyí tó ṣe yìí làwọn èèyàn sọ pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àwárí tó ṣe pàtàkì jù lọ tó ṣe.

Ní tòótọ́, wọ́n ti lo àwọn ohun abúgbàù tí Nobel ṣàwárí rẹ̀ fún àwọn ohun mìíràn yàtọ̀ sí ogun o. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ohun tó ṣàwárí rẹ̀ yìí ló jẹ́ kí wọ́n lè kọ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ St. Gotthard (1872 sí 1882), òun ni wọ́n fi fọ́ àwọn òkúta omi abẹ́ ilẹ̀ tó wà ní East River nílùú New York (1876 àti 1885), òun náà ni wọ́n tún lò láti gbẹ́ Ọ̀nà Omi Abẹ́lẹ̀ ti Kọ́ríńtì ní Gíríìsì (1881 si 1893). Síbẹ̀, látìgbà tí wọ́n ti ṣàwárí ohun èèlò abúgbàù yìí, ohun èèlò ìparun àti ikú làwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí nílé lóko.

[Àwòrán]

Àgọ́ ọlọ́pàá tí àwọn ohun èèlò abúgbàù sọ di àlàpà ní Kòlóńbíà

[Credit Line]

© Reuters NewMedia Inc./CORBIS

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Kò pé ogun ọdún lẹ́yìn tí Nobel kú ni wọ́n fi àwọn àkọ̀tun ohun ìjà aṣekúpani ja Ogun Àgbáyé Kìíní

[Credit Line]

Fọ́tò U.S. National Archives

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn tí ohun abúgbàù tí wọ́n ń rì mọ́lẹ̀ ṣe lọ́ṣẹ́ ní ìlú Cambodia, Iraq àti Azerbaijan

[Àwọn Credit Line]

Fọ́tò UN/DPI 186410C tí P.S. Sudhakaran yà

Fọ́tò UN/DPI 158314C tí J. Isaac yà

Fọ́tò UN/DPI tí Armineh Johannes yà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ìlànà Ohun Ìjà Runlérùnnà sọ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ohun ìjà runlérùnnà ló wà ní sẹpẹ́ fún lílò nígbàkigbà

[Credit Line]

ÌPARAPỌ̀ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ/FỌ́TÒ TÍ SYGMA YÀ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Títú táwọn kan tú gáàsì olóró kan tí wọ́n ń pè ní “sarin” sáfẹ́fẹ́ ní ibùdó ọkọ̀ ojú irin kan ní Tokyo lọ́dún 1995 ló jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọṣẹ́ tó ń ṣe kọjá kèrémí

[Credit Line]

Asahi Shimbun/Sipa Press

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]

Fọ́tò UN/DPI 158198C tí J. Isaac yà