Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ńjẹ́ Ọlọ́run Fọwọ́ Sí Ogun Jíjà?

Ńjẹ́ Ọlọ́run Fọwọ́ Sí Ogun Jíjà?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ńjẹ́ Ọlọ́run Fọwọ́ Sí Ogun Jíjà?

LỌ́PỌ̀ ìgbà, àwọn ọ̀gágun, àwọn alákòóso, tó fi dórí àwọn àlùfáà pàápàá ti fọwọ́ sí ogun jíjà nípa pípe orúkọ Ọlọ́run sí i! Ní 1095, Póòpù Urban Kejì fọwọ́ sí Ogun Ẹ̀sìn Kìíní tí wọ́n ní wọ́n fẹ́ fi gba “Ìlú Mímọ́” náà Jerúsálẹ́mù, kó lè padà sọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́sìn Kristi, ó sì ṣètìlẹ́yìn fún un. Àmọ́ kọ́wọ́ wọn tó o ba ohun tí wọ́n fẹ́, àwọn ará Turkey tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn Ìsìláàmù ti pa agbo kan lára àwọn Ológun Ẹ̀sìn náà run ráúráú. Bí ìgbàgbọ́ àwọn tó kó Ogun Ẹ̀sìn wá ṣe gbóná nínú Mẹ́talọ́kan ni ìtara àwọn ẹlẹ́sìn Ìsìláàmù yìí fún Allah náà ṣe gbóná girigiri.

Ní August 1914, ohun ti ọ̀dọ́mọkùnrin ọmọ ilẹ̀ Jámánì kan kọ láti ibùdó tó wà nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní ni pé: “Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ló ń darí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ẹ̀dá—ó ṣì dá mi lójú pé òun ni—nítorí náà àwa lá máa jáwé olúborí.” Oṣù yẹn kan náà ni Czar Nicholas Kejì fún àwọn ọmọ ogun Rọ́ṣíà láṣẹ láti dìde ogun sí ilẹ̀ Jámánì. Ó sọ pé: “Mo fi tọkàntọkàn kí i yín, ẹ̀yin akíkanjú ọmọ ogun mi, àtàwọn ẹni iyì tó ń fẹ́ tiwa. Ọlọ́run ń bẹ lẹ́yìn wa gbágbáágbá!”

Látàrí bí wọ́n ṣe ń ki àwọn sójà láyà yìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ wọn ló ti lọ sógun, ọkàn wọn sì balẹ̀ dẹ́dẹ́ pé Ọlọ́run ń bẹ lẹ́yìn àwọn. Ọ̀pọ̀ gbà gbọ́ pé Ọlọ́run fọwọ́ sí irú ogun báyìí káwọn lè ní òmìnira, wọ́n sì máa ń fi àwọn ogun tí Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù (tí wọ́n sábà ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé) sọ̀rọ̀ nípa wọn ti ara wọn lẹ́yìn. Àmọ́ ṣé ọ̀nà tí wọ́n gbà lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yìí tọ̀nà?

Àwọn Ogun Tí Ísírẹ́lì Ayé Ọjọ́un Jà

Jèhófà Ọlọ́run pàṣẹ pé kí Ísírẹ́lì fi ogun pa àwọn ará Kénáánì oníwàkiwà rẹ́ kúrò ní Ilẹ̀ Ìlérí. (Léfítíkù 18:1, 24-28; Diutarónómì 20:16-18) Ọlọ́run tipa báyìí lo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì bí idà láti pa àwọn èèyàn yìí run gẹ́gẹ́ bó ṣe fi ìkún omi pa àwọn ẹni búburú run láyé Nóà àti bó ṣe fi iná pa àwọn ẹni ibi ìlú Sódómù àti Gòmórà run.—Jẹ́nẹ́sísì 6:12, 17; 19:13, 24, 25.

Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ja àwọn ogun mìíràn lábẹ́ ìdarí Ọlọ́run, ohun tó sì fà á ni pé ó fẹ́ dẹ́kun mọ̀huru-mọ̀huru tí àwọn ọ̀tá ń dún mọ́ wọn. Bí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì bá fi ti Jèhófà ṣe, wọ́n máa ń jáwé olúborí nínú ogun tí wọ́n bá lọ. (Ẹ́kísódù 34:24; 2 Sámúẹ́lì 5:17-25) Àmọ́ ohun tó máa ń fa àjálù bá wọn ni bí wọ́n bá ṣàyà gbàǹgbà pé àwọn fẹ́ lọ jagun láìjẹ́ pé Ọlọ́run ní kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jèróbóámù Ọba yẹ̀ wò. Ó kọ etí dídi sí ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run fún un, ó ní kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun òun lọ kógun bá Júdà. Nígbà tí ogun náà parí, ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] ọmọ ogun Jèróbóámù ló ṣòfò ẹ̀mí. (2 Kíróníkà 13:12-18) Kódà, ìgbà kan wà tí Jòsáyà Ọba lọ ja ogun tí kò yẹ kó jà. Ìpinnu tó fi ìwàǹwára ṣe yìí ló mú kó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.—2 Kíróníkà 35:20-24.

Kí làwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi hàn? Ó fi hàn pé ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, Ọlọ́run ló ń pinnu bóyá kí wọ́n jagun tàbí kí wọ́n má jagun. (Diutarónómì 32:35, 43) Ó máa ń jẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ jagun láti mú àwọn ète rẹ̀ kan ṣẹ ní pàtàkì. Àmọ́, ó ti mú àwọn ète náà ṣẹ nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Síwájú sí i, Jèhófà sọ tẹlẹ̀ pé, àwọn tá á máa jọ́sìn òun “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́” yóò “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀” wọn ò sì ní “kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” (Aísáyà 2:2-4) Ó hàn gbangba pé, àwọn ogun tí wọ́n jà nínú Bíbélì kò fi hàn pé èyí tí wọ́n ń jà lóde òní tọ̀nà, nítorí kò sí èyíkéyìí nínú tòde òní tí Ọlọ́run pàṣẹ pé kí wọ́n jà.

Agbára Tí Ẹ̀kọ́ Kristi Ní

Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi hàn wá bá a ṣe lè fi ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan rọ́pò ìkórìíra. Ó pàṣẹ pé: “Ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín.” (Jòhánù 15:12) Ó tún sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà.” (Mátíù 5:9) Nínú ohun tó sọ yìí, ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì fún “ẹlẹ́mìí àlàáfíà” ju pé kéèyàn jẹ́ ẹni jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́. Ó tún ní nínú kéèyàn fẹ́ràn àlàáfíà, kó sì máa ṣaápọn nígbà gbogbo láti jẹ́ ẹni rere.

Nígbà tí wọ́n fàṣẹ ọba mu Jésù, àpọ́sítélì Pétérù fi ohun ìjà tó lè ṣekú pani gbèjà rẹ̀. Àmọ́ ńṣe ni Ọmọ Ọlọ́run bá a wí, ó sọ fún un pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:52) Báwo làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe fi ọ̀rọ̀ yìí sílò? Ìwọ wo àwọn ọ̀rọ̀ tá a fà yọ nísàlẹ̀ wọ̀nyí.

“Àyẹ̀wò kínníkínní lórí gbogbo ìsọfúnni tó wà lọ́wọ́ [fi hàn] pé títí di àkókò Marcus Aurelius [121 sí 180 Sànmánì Tiwa], kò sí Kristẹni kankan tó di ológun; gbogbo àwọn tó sì jẹ́ ológun tẹ́lẹ̀ ló fiṣẹ́ ológun sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n di Kristẹni.”—The Rise of Christianity.

“Ìwà àwọn Kristẹni [àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀] yàtọ̀ sí tàwọn ará Róòmù gan-an. . . . Nítorí pé Kristi ti wàásù nípa àlàáfíà, wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun.”—Our World Through the Ages.

Àwọn ará Róòmù pa púpọ̀ lára àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi nítorí pé wọn ò wọnú ẹgbẹ́ ọmọ ogun olú ọba. Èé ṣe táwọn Kristẹni fi ṣe ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ sí yìí? Ìdí ni pé Jésù kọ́ wọn pé kí wọ́n jẹ́ èèyàn àlàáfíà.

Ogun Jíjà Lóde Òní

Fojú inú wo bó ṣe máa kó ìpayà báni tó ká ní àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi wà nínú ẹgbẹ́ ológun tó ń bára wọn jà, tí wọ́n ń para wọn. Irú èyí kò ní í bá àwọn ìlànà Kristẹni mu rárá. Ká sòótọ́, àwọn tó bá ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run tó ni Bíbélì kò ní ṣe ẹnikẹ́ni ní ṣùtá, ì báà tiẹ̀ jẹ́ àwọn ọ̀tá wọn pàápàá. aMátíù 5:43-45.

Ó hàn gbangba pé, Ọlọ́run ò lọ́wọ́ sí àwọn ogun táwọn èèyàn ń jà lóde òní tí wọ́n fi ń pààyàn nípakúpa. Ẹlẹ́mìí àlàáfíà làwọn Kristẹni tòótọ́, wọ́n sì ń polongo àlàáfíà tó máa gbalẹ̀ kárí ayé nínú Ìjọba Ọlọ́run.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bíbélì sọ nípa “Ha-Mágẹ́dọ́nì,” èyí tá a tún mọ̀ sí “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” Kì í ṣe ogun tí ẹ̀dá èèyàn ń jà ni èyí tọ́ka sí o, àmọ́ ó ń tọ́ka sí bí Ọlọ́run ṣe máa ṣa àwọn èèyàn búburú sọ́tọ̀ tá á sì pa wọ́n run. Nítorí náà, èèyàn ò lè fi ti Ha-Mágẹ́dọ́nì kẹ́wọ́ pé òun ló mú kí ogun tí wọ́n ń jà lóde òní tọ̀nà tàbí kéèyàn máa rò pé Ọlọ́run fọwọ́ sí àwọn ogun náà.—Ìṣípayá 16:14, 16; 21:8.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ọ̀gágun Francisco Franco ní Sípéènì, níbi tó ti bá ọ̀pọ̀ àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ya fọ́tò

[Credit Line]

Fọ́tò U.S. National Archives

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àwọn sójà táwọn àlùfáà Ọ́tódọ́ọ̀sì ilẹ̀ Gíríìkì ń gbàdúrà fún nígbà táwọn yẹn fẹ́ lọ sí Kosovo, ní June 11, 1999

[Credit Line]

Fọ́tò AP/Giorgos Nissiotis