Ṣé “Àdábọwọ́ Ìsìn” Ló Máa Yanjú Ọ̀rọ̀ Náà?
Ṣé “Àdábọwọ́ Ìsìn” Ló Máa Yanjú Ọ̀rọ̀ Náà?
BÍ Ọ̀GỌ̀Ọ̀RỌ̀ èèyàn ṣe ń dẹ̀yìn lẹ́yìn ètò ìsìn, kò yani lẹ́nu pé púpọ̀ wọn ló máa lọ gbé èrò tara wọn kalẹ̀ nípa ìjọsìn. Àmọ́ o, àwọn ìbéèrè tí èyí gbé dìde ni pé, Ṣé ìyẹn lè paná ebi tẹ̀mí tó ń pa ẹnì kan? Ṣé “àdábọwọ́ ìsìn” ló máa yanjú ọ̀rọ̀ náà?
Láti dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, á dára ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò bóyá ìsìn tá a fúnra wa gbé kalẹ̀ lè pèsè ohun tá a nílò lóòótọ́ tá a bá fi “agbára ìmọnúúrò” wa, ìyẹn ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn títóbi jù lọ tí ẹ̀dá èèyàn ní ṣàyẹ̀wò rẹ̀ kínníkínní.—Róòmù 12:1.
Ẹnì kan tó mọnúúrò kò ní tẹ́wọ́ gba ohunkóhun tó bá ta kora. Àmọ́, nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Sweden nípa gbígba ohunkóhun tó bá ṣáà ti wuni gbọ́, wọ́n ní ńṣe làwọn èèyàn máa ń “pa oríṣiríṣi èrò (ó lè má fi ibi kankan bára mu o) nípa ìgbésí ayé pọ̀ mọ́ra láìronú jinlẹ̀ tí wọ́n á sì wáá fi èrò tiwọn kún un.”
Bí àpẹẹrẹ, ìdá méjì péré nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó pera wọn ní “Kristẹni lọ́nà tara wọn” ló gbà gbọ́ pé Jésù gbé ayé rí. Síbẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo wọn ló mẹ́nu kan àtúnwáyé. Nígbà náà, ṣe kì í ṣe ohun tó ta kora ni kéèyàn pera ẹ̀ ní ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi síbẹ̀ kó ṣàìka ìgbésí ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ sí, kó sì tún jẹ́ pé àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá ohun tí Kristi fi kọ́ni mu páàpáà ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń dìrọ̀ mọ́? a
Bákan náà, ọ̀nà tí à ń gbà ronú kì í jẹ́ ká tẹ́wọ́ gba ohun tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tàbí tí kò ṣe é ṣàlàyé. Àmọ́ nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò bóyá wọ́n gbà pé “Ọlọ́run tàbí ohun kan tó lágbára bí Ọlọ́run wà,” èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn dáhùn pé, “Ó ṣeé ṣe kí irú nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀ wà.” Ọ̀kan nínú wọn tiẹ̀ sọ pé: “Mo gbà pé nǹkan alágbára kan wà àmọ́ mi ò rò pé Ọlọ́run ni ohun náà.” Àwọn tó sì gbà gbọ́ nínú Ọlọ́run sọ pé “àwọn kò rò pé ó fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú ìgbésí ayé àwọn.” Ìròyìn yìí wá sọ pé “èrò tí kò lójútùú rárá” ni àdábọwọ́ ìsìn. Ó wá fi ọ̀kan lára àwọn ìdáhùn tó wọ́pọ̀ jù lọ parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Mo mọ̀ pé mo gbà nǹkan kan gbọ́, àmọ́ mi ò lè sọ pé ohun báyìí ni.”
Ohun kan náà ló fojú hàn nígbà tí wọ́n ṣèwádìí àdábọwọ́ ìsìn nílẹ̀ Kánádà. Ìwé ìròyìn Alberta Report sọ pé: “A ti ń rí i tí gbígba ohunkóhun tó bá ṣáà ti wu èèyàn gbọ́ ń ròkè sí i, àmọ́ a ò rí ibì kankan tó gbà bọ́gbọ́n mu. Nígbà tá a sì gbìyànjú láti mọ irú ìtọ́sọ́nà táwọn àdábọwọ́ ìsìn yìí ń fún àwọn èèyàn nígbèésí ayé, kò sí ọ̀kankan páàpáà. Wọ́n ò ní ohun kan pàtó tó ń tọ́ wọn láti hùwà rere. Fún ìdí yìí, èrò náà pé bó ṣe wuni là á ṣègbàgbọ́ ẹni kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ rárá.” Ìwé ìròyìn náà sọ nípa “ọlọ́run tó
pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ” nítorí pé ńṣe làwọn tó di irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ mú máà “ń já díẹ̀ níbí já díẹ̀ lọ́hùn-ún látinú àwọn ìlànà ṣọ́ọ̀ṣì tó ti wà tipẹ́.” Ṣé ìwọ́ rò pé ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀, títí kan ìrètí èèyàn nípa ọjọ́ ọ̀la ka irú èrò aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀, tí kò ṣe é ṣàlàyé tó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ bẹ́ẹ̀?A Máa Ń Fẹ́ Láti Jọ́sìn Pẹ̀lú Àwọn Mìíràn
Ọjọ́ pẹ́ táwọn onígbàgbọ́ ti máa ń fẹ́ láti bá àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn kẹ́gbẹ́ pọ̀, kí wọ́n jẹ́ apá kan ẹgbẹ́ ará kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan. (Ìṣe 2:42, 46) Àmọ́ nígbà tó jẹ́ pé àdábọwọ́ ìsìn kò ní àwọn nǹkan wọ̀nyí nínú, báwo ló ṣe lè pèsè wọn?
Ǹjẹ́ kì í ṣe pé ńṣe ni ìsìn kóńkó jabele pẹ̀lú èrò náà pé “kí kálukú máa sin Ọlọ́run bó bá ṣe wù ú,” túbọ̀ ń dá kún yíyapa tí àwọn èèyàn ń yapa kúrò nínú ìsìn? Ìwé ìròyìn Alberta Report sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ìsìn ti wá di pé ohun tó bá wu kálukú ni kó gbà gbọ́ . . . , èyí sì ti sọ wá di orílẹ̀-èdè tí ohun tá a gbà gbọ́ kò mọ sí ọgọ́rùn-ún díẹ̀ àmọ́ ó ti wọ mílíọ̀nù.” Abájọ, nígbà náà táwọn èèyàn fi pe àdábọwọ́ ìsìn ní ìsìn yánpọnyánrin.
Ìwà Ọmọlúwàbí Ńkọ́?
Nígbà tí ìwé ìròyìn Svenska Dagbladet ń fọ̀rọ̀ wá Bíṣọ́ọ̀bù ọmọ ilẹ̀ Sweden náà, Martin Lönnebo lẹ́nu wò, ó sọ pé, “ká máa gba ohunkóhun tá a rí gbọ́ kò lè ṣe sànmánì wa ní oore kankan, kò sì sí bí àwọn ìlànà rẹ̀ ṣe lè wúlò fún ìran tó ń bọ̀.” Ohun kan tó wọ́pọ̀ nínú ọ̀nà tí àwọn òbí ní orílẹ̀-èdè Sweden ń gbà tọ́ àwọn ọmọ wọn jẹ́rìí gbé ọ̀rọ̀ yìí. Ìwé ìròyìn Svenska Dagbladet ṣàkópọ̀ ohun náà, ó sọ pé: “Ohun tó bá wù ẹ́ ni kó o gbà gbọ́! Má sì kàn án nípa fún àwọn ọmọ rẹ láti yan ọ̀kan. Àmọ́ nígbà tí wọ́n bá dàgbà, jẹ́ kí wọ́n yan èyí tó bá wù wọ́n.”
Ìwé ìròyìn náà sọ pé kíkọ́ àwọn ọmọ ní ìlànà ẹ̀sìn kò yàtọ̀ sí gbígbin ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ kan sí wọn lọ́kàn. Síbẹ̀, ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Kíkọ́ ọmọ ẹni láwọn ìlànà ẹ̀sìn lè ṣàǹfààní ó sì lè jẹ́ ọ̀nà kan ṣoṣo tí wọ́n . . . fi lè ṣe ìpinnu fúnra wọn.” Ká sòótọ́, ìṣòro tó ń kojú àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ fi hàn pé gbígba ohunkóhun tó wu èèyàn gbọ́ kò so àwọn ìdílé ṣọ̀kan tá a bá ń sọ nípa gbígbé àwọn ìlànà tó dára kalẹ̀, èyí tó lè wúlò fún àwọn ìran tó ń bọ̀.
Nígbà náà, ó jọ pé èrò ọkàn ẹni nìgbàgbọ́ ẹni kò lè pèsè àwọn ìdáhùn tó ṣe é gbára lé tó sì péye sí àwọn ìbéèrè tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbésí ayé, bẹ́ẹ̀ ni kò sì lè mú àwọn èèyàn ṣọ̀kan tàbí kó pèsè àwọn ìtọ́sọ́nà tí wọ́n nílò láti hùwà rere. Àpilẹ̀kọ tá a fa ọ̀rọ̀ yọ nínú rẹ̀ níṣàájú látinú ìwé ìròyìn Svenska Dagbladet sọ kókó yìí pé: “Tó bá jẹ́ orí gba tibí gbọ́ gba tọ̀hún gbọ́ ni ẹnì kan gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ kà, òfìfo ni irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀. Tí òmìnira téèyàn ní kò bá sì ní ààlà, ìyẹn kì í ṣe òmìnira.”
Ó ti wá ṣe kedere báyìí pé, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà, ìsìn gba-ohun-tó-wù-ẹ́-gbọ́ kò lè pèsè ohun táwọn èèyàn nílò nípa tẹ̀mí. Ní ti gidi, báwo lèèyàn ṣe lè retí pé kí ọ̀rọ̀ rí bẹ́ẹ̀ nígbà téèyàn bá ń mú ìgbàgbọ́ látinú onírúurú ìsìn, bí ìgbà téèyàn ń mú èyí tó wù ú nínú ọ̀pọ̀ oúnjẹ tí wọ́n tò kalẹ̀? Bákan náà, ó tún ti hàn kedere pé àwọn ẹ̀sìn tó ti wà tipẹ́ kò lè pèsè ohun táwọn èèyàn nílò nípa tẹ̀mí. Ibo ló kù tá a wá fẹ́ yíjú sí o?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Jésù kò kọ́ni pé àwọn òkú máa ń tún ayé wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó kọ́ni pé ńṣe ni wọ́n ń sùn nínú oorun ikú àti pé wọ́n ń dúró de àjíǹde lọ́jọ́ iwájú.—Jòhánù 5:28, 29; 11:11-14.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]
Ṣé ó yẹ ká máa wo ìsìn bí ọ̀pọ̀ oúnjẹ tí wọ́n tò kalẹ̀, ká máa ṣà ká sì máa yan ohunkóhun tó bá sáà ti wù wá láti gbà gbọ́?