Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ogun Ló Ń Gbé Lárugẹ Ni Àbí Àlàáfíà?

Ṣé Ogun Ló Ń Gbé Lárugẹ Ni Àbí Àlàáfíà?

Ṣé Ogun Ló Ń Gbé Lárugẹ Ni Àbí Àlàáfíà?

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ SWEDEN

Lọ́dọọdún, àwọn èèyàn tàbí àwọn àjọ tó ti ṣe gudugudu méje láti mú kí ìgbésí ayé àwọn èèyàn sunwọ̀n sí i ní onírúurú ọ̀nà máa ń gba ẹ̀bùn Nobel. Ìgbà wo ni àṣà yìí bẹ̀rẹ̀, àjọṣe wo ló wà nínú àṣà yìí àti bí aráyé ṣe ń wá àlàáfíà lójú méjèèjì?

ORÚKỌ rẹ̀ kì í gbẹ́yìn níbi tí wọ́n bá ti ń sọ̀rọ̀ nípa mímú kí ìgbésí ayé ọmọ ẹ̀dá dára sí i, síbẹ̀, ohun ìjà ogun ló tà títí tó fi dolówó rẹpẹtẹ. Ta lẹni yìí? Alfred Bernhard Nobel, ọmọ ilẹ̀ Sweden tó tún jẹ́ onímọ̀ nípa kẹ́míkà lóríṣiríṣi ni. Àwọn èèyàn ti ṣe sàdáńkátà fún Nobel nítorí ó jẹ́ olójú àánú, tó ń ṣoore fáwọn èèyàn, àmọ́ òun kan náà làwọn kan tún pè ní “oníṣòwò ikú.” Kí ló fà á? Ìdí ni pé Nobel ló ṣàwárí àwọn àdó olóró tó máa ń bú gbàù, àwọn àdó olóró tó ń pani wọ̀nyí ló ń ṣe tó sì ń tà nígbà ayé rẹ̀ tó fi lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀.

Àmọ́ lẹ́yìn tí Nobel kú ní 1896, àwọn èèyàn rí ohun kan tó mú wọn kọ háà. Ó sọ nínú ìwé ìhágún rẹ̀ pé kí wọ́n ya mílíọ̀nù mẹ́sàn-án dọ́là sọ́tọ̀, pé ọdọọdún ni kí wọ́n máa kó èrè orí rẹ̀ fún àwọn èèyàn tó bá ṣe àṣeyọrí tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ nínú ìmọ̀ físíìsì, ìmọ̀ kẹ́mísìrì, ìmọ̀ ìṣègùn, ìmọ̀ lítíréṣọ̀ àti ọ̀ràn àlàáfíà.

Ìyàlẹ́nu gbáà lọ̀rọ̀ yìí kọ́kọ́ jẹ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Wọ́n ń ṣe kàyéfì pé báwo ni ẹnì kan tí kò níṣẹ́ míì ju kó máa ṣe àdó panipani lọ ṣe wá di onínúure ọ̀sán gangan tó tún ń fáwọn èèyàn lẹ́bùn àlàáfíà? Àwọn kan sọ pé ẹ̀rí ọkàn ló ń na Nobel ní pàṣán nítorí àwọn àdó olóró tó gbélé ayé ṣe ti ṣọṣẹ́ jìnnà. Àmọ́ ṣá, ohun táwọn mìíràn sọ ni pé àlàáfíà ni Nobel fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ wá. Ká sòótọ́, ó dà bí ẹni pé èrò rẹ̀ ni pé bí àwọn ohun ìjà ṣe ń di olóró sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ogun á máa lọ sílẹ̀. A tiẹ̀ gbọ́ pé ó sọ fún òǹkọ̀wé kan pé: “Ó ṣeé ṣe káwọn ilé iṣẹ́ mi tètè fòpin sí ogun ju ìjọba àtàwọn aṣòfin yín lọ.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Lọ́jọ́ tí àwọn ẹgbẹ́ ogun méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bá run ara wọn láàárín ìṣẹ́jú àáyá kan, ó ṣeé ṣe kí jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ọ̀làjú ti bá kí wọ́n sọ pé káwọn jagunjagun àwọn kógbá ogun wọlé.”

Ǹjẹ́ ohun tí Nobel sọ tẹ́lẹ̀ yìí rí bẹ́ẹ̀? Àwọn ẹ̀kọ́ wo la ti rí kọ́ láwọn ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé ikú Nobel?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]

“Ó wù mí kí n ṣe kẹ́míkà kan tàbí ẹ̀rọ kan tí agbára rẹ̀ á kàmàmà, tó máa lè ba nǹkan jẹ́ lọ bí ilẹ̀ bí ẹní, èyí ni kò ní jẹ́ kí ogun wáyé mọ́ títí láé”ALFRED BERNHARD NOBEL

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Ojú ìwé 2: Ohun ìjà ogun: Fọ́tò U.S. Navy; ilé tó ti di àlàpà: FỌ́TÒ UN 158178/J. Isaac; ojú ìwé 3: Nobel: © Nobelstiftelsen