Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Oúnjẹ Aṣaralóore Ń Bẹ Níkàáwọ́ Rẹ

Oúnjẹ Aṣaralóore Ń Bẹ Níkàáwọ́ Rẹ

Oúnjẹ Aṣaralóore Ń Bẹ Níkàáwọ́ Rẹ

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ MẸ́SÍKÒ

ABÚLÉ kékeré kan tó wà ní ìpínlẹ̀ Oaxaca, ní Mẹ́síkò ni Angélica àti ìdílé rẹ̀ ẹlẹ́ni mẹ́wàá ń gbé. Wọn ò rí já jẹ, oúnjẹ wọn kò ju ṣapala, ẹ̀wà, omi ọbẹ̀ aláta, túwó ìrẹsì, búrẹ́dì aládùn àti tíì lọ. Angélica sọ pé: “A kò rí rùmúrùmú bó ṣe yẹ. Ńṣe la rí jáńjálá, a ò sì lẹ́ran lára. A máa ń ṣàìsàn lọ́pọ̀ ìgbà, bí inú rírun, aràn àti òtútù.”

Angélica àti ìdílé rẹ̀ ta mọ́ra pé àwọn á ṣí lọ sí Ìlú Mexico, èrò wọn ni pé àwọn á ríṣẹ́ tá á jẹ́ káwọn rówó lò báwọn ṣe fẹ́. Ní báyìí, ó rò pé oúnjẹ àwọn dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ nítorí pé wọ́n ti ń jẹ ẹyin, mílíìkì, ọ̀rá wàrà, ẹ̀fọ́ díẹ̀ àtàwọn oúnjẹ tí wọ́n ti yí padà. Àmọ́ ṣé lóòótọ́ ni oúnjẹ wọn ti wá ń ṣara lóore ju ti tẹ́lẹ̀ lọ?

Oúnjẹ Tí Kì Í Ṣara Lóore, Báwo Làwọn Tó Ń Jẹ Ẹ́ Ṣe Pọ̀ Tó?

Kárí ayé, ó ṣeé ṣe kí àìrí oúnjẹ tó ń ṣara lóore jẹ ṣekú pa èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rin [800] mílíọ̀nù. Gẹ́gẹ́ bí Ìròyìn Nípa Ìlera Àgbáyé tí Àjọ Ìlera Àgbáyé gbé jáde lọ́dún 1998, nǹkan bí ìdá àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ tí wọn kò tíì pé ọdún márùn-ún tó ń kú ló jẹ́ àìjẹ oúnjẹ tó ń ṣara lóore ló pa wọ́n. Àwọn tó bá sì rù ú là pàápàá kì í yéé ṣàìsàn.

Ní ìdàkejì èyí, àwọn kan sọ pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rin [800] mílíọ̀nù èèyàn ló ṣeé ṣe kí oúnjẹ àjẹjù ṣekú pa. Ẹni tí kò bá jẹ oúnjẹ tó ń ṣara lóore lè ní àwọn àrùn burúkú bíi kó sanra jù, àrùn tó ń mú kí ọ̀rá kóra jọ sínú ibi tí ẹ̀jẹ̀ ń gbà ṣàn káàkiri ara, ẹ̀jẹ̀ ríru, àtọ̀gbẹ, àrùn ẹ̀dọ̀ àti onírúurú àrùn jẹjẹrẹ. Àjọ Ìlera Àgbáyé wá kó gbogbo rẹ̀ pọ̀ pé: “Oúnjẹ tí kì í ṣara lóore tipa báyìí pín sí oríṣiríṣi ọ̀nà, ó lè jẹ́ èyí tí kì í ṣara lóore rárá, ó sì lè jẹ́ èyí táwọn èròjà kan kò sí nínú rẹ̀ tàbí kó jẹ́ pé àwọn èròjà inú rẹ̀ ti pọ̀ jù; ó ń pààyàn, ó ń sọ èèyàn di akúrẹtẹ̀, kì í jẹ́ kára gbé kánkán, ó ń sọ èèyàn di arọ, ó ń fọ́ èèyàn lójú, kì í sì í jẹ́ kéèyàn dàgbà sókè bó ṣe yẹ.”

Àwọn kan lè máà rí oúnjẹ tó ń ṣara lóore jẹ tó káwọn mìíràn tí wọ́n jọ ń gbé ní orílẹ̀-èdè kan náà sì sanra jọ̀kọ̀tọ̀. Nínú ìdílé kan náà sì rèé, ìṣòro àwọn ọmọdé lè jẹ́ àìrí oúnjẹ tó ní èròjà aṣaralóore nínú nígbà tí tàwọn àgbàlagbà sì lè jẹ́ sísanra tí wọ́n sanra jọ̀kọ̀tọ̀. Nígbà míì pàápàá, ó lè jẹ́ ẹni tí kò jù náṣán-náṣán nítorí àìrí oúnjẹ gidi jẹ nígbà tó wà lọ́mọdé ló máa wá sanra jọ̀kọ̀tọ̀ nígbà tó dàgbà. Ìyẹn lè ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti ìgbèríko ṣí lọ sílùú ńlá.

Ọ̀pọ̀ ni kò mọ̀ pé ìlera wọn ní í ṣe pẹ̀lú irú oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ. Bóyá nítorí pé ipa tí àìrí oúnjẹ tó dáa jẹ ń ní lórí ìlera kì í tètè fara hàn ni kò jẹ́ kí wọ́n mọ̀. Àmọ́ oúnjẹ tó ń ṣara lóore lè dènà àìmọye àrùn. Kódà, Àjọ Ìlera Àgbáyé fojú bù ú pé nǹkan bí ìdá ogójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ní àrùn jẹjẹrẹ ni wọn kì bá ní i ká ní wọ́n ń jẹ oúnjẹ tó dáa tí wọ́n sì ń ṣeré ìmárale. Àmọ́ báwo ni o ṣe lè mú kí oúnjẹ rẹ túbọ̀ ṣara lóore?

Bó O Ṣe Lè Mú Kí Oúnjẹ Rẹ Túbọ̀ Ṣara Lóore

Àwọn kan sọ pé ọ̀nà mẹ́ta loúnjẹ pín sí. Àkọ́kọ́ ni àwọn oúnjẹ tó ń wá látinú hóró ọkà bí àgbàdo, àlìkámà, ìrẹsì, oat, ọkà rye, ọkà báálì àti ọkà bàbà pẹ̀lú oríṣi mìíràn bí ànàmọ́ àti iṣu. Àwọn oúnjẹ onítáàṣì wọ̀nyí máa ń fún èèyàn ní okun. Oríṣi kejì ni ẹ̀wà lóríṣiríṣi, bí ẹ̀wà sóyà, ẹ̀wà lẹ́ńtìlì, chick-peas, awújẹ àtàwọn nǹkan tó ń tara ẹran jáde bí ẹran, ẹja, ẹyin, wàrà àtàwọn nǹkan tí wọ́n ń fi wàrà ṣe. Àwọn wọ̀nyí máa ń fún èèyàn ní èròjà protein, èròjà iron, èròjà zinc àti oríṣiríṣi fítámì. Oríṣi kẹta ni ẹ̀fọ́ àti àwọn èso. Àwọn wọ̀nyí ń fún èèyàn ní àwọn fítámì tó ṣe kókó àti èròjà mineral. Èèyàn tún máa ń rí ṣákítí nínú wọn, wọ́n sì ń fún ara lókun, àwọn tún ni orísun èròjà fítámì C àbáláyé.

Dókítà Héctor Bourges, ọ̀gá àgbà nípa ẹ̀kọ́ oúnjẹ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ìṣègùn àti Ẹ̀kọ́ Nípa Oúnjẹ Tó Ń Ṣara Lóore ní ìlú Salvador Zubirán ní Mẹ́síkò sọ pé, àwọn èròjà wọ̀nyí gbọ́dọ̀ wà nínú oúnjẹ tó máa ṣara lóore, oúnjẹ náà gbọ́dọ̀ tó, káwọn èròjà inú rẹ̀ sì pé. Ó dá a lábàá pé kí oúnjẹ téèyàn á jẹ níjokòó ẹ̀ẹ̀kan “jẹ́ látinú oríṣi mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yìí kéèyàn sì máa lú wọn mọ́ra, bákan náà ni kéèyàn máa pawọ́ bó ṣe ń sè wọ́n dà.”

Wo María bí àpẹẹrẹ. Òun àti ìdílé rẹ̀ ń gbé ní Atopixco, ìgbèríko kan ní ìpínlẹ̀ Hidalgo ní Mẹ́síkò. Wọn ò rí já jẹ, olórí oúnjẹ wọn kò ju ṣapala, ẹ̀wà, oúnjẹ alápòpọ̀, ìrẹsì àti ata lọ. Tiwọn yàtọ̀ sí ti ìdílé Angélica tá a mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀, nítorí oúnjẹ wọn ní nínú èso squash, èso chayotes, olú àtàwọn ẹ̀fọ́ bí èyí tí wọ́n ń pè ní purslane àti pigweed. Ìgbèríko ni wọ́n ti ń rí ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀fọ́ yìí. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n máa ń gbìyànjú láti jẹ èso dáadáa lásìkò wọn. Ìsapá wọn yìí mú kí ara wọn túbọ̀ jí pépé sí i.

Dókítà Adolfo Chávez tó jẹ́ ọ̀gá àgbà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Nípa Oúnjẹ Tó Ń Ṣara Lóore ti ìlú Salvador Zubirán dámọ̀ràn pé ńṣe ló yẹ kéèyàn máa fi ẹran pẹ̀kún oúnjẹ, kò dáa kí ẹran jẹ́ olórí oúnjẹ téèyàn ń jẹ. Bí àpẹẹrẹ, èèyàn lè fi ẹyin bíi mélòó kan, ànàmọ́, ẹ̀fọ́ tàbí ẹ̀wà se oúnjẹ jẹ. Dókítà Chávez sọ pé: “Èyí ni [àwọn onímọ̀ nípa] oúnjẹ ń pè ní ‘mímú nǹkan pọ̀ sí i.’” Àmọ́ ìkìlọ̀ tó wà níbẹ̀ ni pé: Rí i pé o fọ àwọn èso àti ẹ̀fọ́ dáadáa, pàápàá jù lọ àwọn téèyàn ò ní sè kó tó jẹ wọ́n.

Oúnjẹ téèyàn ń jẹ tún gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó dára fún ara onítọ̀hún, èèyàn gbọ́dọ̀ wo ọjọ́ orí, bóyá ẹ̀yà akọ ni tàbí abo àti irú ìgbésí ayé tí olúwarẹ̀ ń gbé kó lè mọ irú oúnjẹ tó yẹ kó jẹ. Àwọn kan dámọ̀ràn pé káwọn àgbàlagbà jẹ́ kí ẹ̀fọ́ àti èso máa pọ̀ dáadáa nínú oúnjẹ wọn, kí wọ́n sì tún máa jẹ oríṣiríṣi ẹ̀wà àti àwọn oúnjẹ tó ń wá látinú hóró ọkà dáadáa. Wọ́n dámọ̀ràn pé ìwọ̀nba ni kí wọ́n máa jẹ ẹran mọ, tí wọ́n bá sì fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n jẹ ẹja, ẹran adìyẹ tí wọ́n ti bó awọ ara rẹ̀ àti ẹran tí kò ní ọ̀rá. Wọ́n tiẹ̀ tún sọ pé kí wọ́n rọra jẹ ọ̀rá àti ṣúgà.

Àwọn tí kò rí já jẹ pàápàá láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lè mú kí oúnjẹ wọn túbọ̀ ṣara lóore o. Lọ́nà wo? Nípa fífi àwọn oúnjẹ tó ń ṣara lóore lúra wọn, irú bíi kéèyàn máa jẹ onírúurú ẹ̀wà pa pọ̀ mọ́ àwọn oúnjẹ tó ń wá látinú hóró ọkà. Kéèyàn máa fi ẹran tàbí ẹyin díẹ̀ sínú oúnjẹ kó bàa lè túbọ̀ ṣara lóore. Kéèyàn máa jẹ àwọn ẹ̀fọ́ tó wà ládùúgbò rẹ̀ kó sì máa jẹ àwọn èso tó bá ń jáde.

Ẹlẹ́dàá wa ń mú kí “oúnjẹ jáde wá láti inú ilẹ̀” fún ìgbádùn ọmọ ènìyàn. (Sáàmù 104:14) Bíbélì sọ ọ́ nínú ìwé Oníwàásù 9:7 pé: “Máa lọ, máa fi ayọ̀ yíyọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ.” Ó dájú pé, béèyàn kò bá ti àṣejù bọ̀ ọ́, tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, á gbádùn àwọn oúnjẹ aládùn tó ń ṣara lóore tí Ẹlẹ́dàá wa ti pèsè fún wa.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

ORÍṢI ÀKỌ́KỌ́: àwọn oúnjẹ tó ń wá látinú hóró ọkà bí ìrẹsì àtàwọn oúnjẹ tó ń wá látinú ohun ọ̀gbìn ẹlẹ́ta bí iṣu

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

ORÍṢI KEJÌ: onírúurú ẹ̀wà, ẹran, ẹja, ẹyin, wàrà àtàwọn nǹkan tí wọ́n ń fi ṣe,

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

ORÍṢI KẸTA: àwọn èso àti ẹ̀fọ́