Àwọn Ohun Tó Ń fa Ìṣòro—Láàárín Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì àti Ìsìn
Àwọn Ohun Tó Ń fa Ìṣòro—Láàárín Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì àti Ìsìn
“Ṣé bí àrùn kan tó ń gbèèràn, tó ń nípa lórí béèyàn ṣe ń ronú àti bó ṣe ń lóye ni ìsìn ṣe rí?”—Richard Dawkins, onímọ̀ nípa ohun alààyè.
NÍGBÀ mìíràn, àwọn èèyàn máa ń ronú pé ọ̀tá paraku ni ìsìn àti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì jẹ́. Àwọn mìíràn sì máa ń lérò pé ìjàkadì àárín àwọn méjèèjì kọjá kèrémí, pé ìjà ọ̀hún ò lè parí àyàfi bí ọ̀kan lára wọn ò bá sí mọ́.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan jẹ́ agbo kan láyè ara wọn, àwọn bíi Peter Atkins tó jẹ́ onímọ̀ nípa kẹ́míkà, tí wọ́n sì ń sọ pé ìsìn àti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì “ò lè” ṣọ̀kan “láéláé.” Atkins sọ pé “ohun ẹ̀gàn gbáà ni” kéèyàn “gbà pé Ọlọ́run kan wà, (ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti pé òun ló dá ohun gbogbo).”
Àwọn tí kò fẹ̀sìn ṣeré sì tún jẹ́ agbo mìíràn, tí wọ́n ń sọ pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ni ọ̀bàyéjẹ́ tó ba ìgbàgbọ́ àwọn ẹlẹ́sìn jẹ́. Irú àwọn èèyàn yìí gbà gbọ́ pé ẹ̀tàn gbáà ló wà nídìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní; pé àwọn àwárí rẹ̀ lè jẹ́ òótọ́, àmọ́ bí wọ́n ṣe túmọ̀ àwọn àwárí yìí lọ́nà òdì ń ṣèpalára fún ìgbàgbọ́ àwọn ẹlẹ́sìn. Bí àpẹẹrẹ, William Provine tó jẹ́ onímọ̀ nípa ohun alààyè sọ pé ẹ̀kọ́ èrò orí tí Darwin fi kọ́ni “kò ní ìpìlẹ̀ rere kankan fún ìlànà ìwà híhù; pé kò ní ìtumọ̀ kankan fún ìgbésí ayé.”
Bó ti wù ó rí, àwọn irọ́ tàbí ọ̀rọ̀ tí kò sí ẹ̀rí láti gbè é lẹ́yìn tó máa ń wá látọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn àtàwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló dá lára àwọn ìṣòro yìí sílẹ̀. Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn làwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti ń fi àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu tí ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ àtàwọn ẹ̀kọ́ ìsìn tó lábùkù kọ́ àwọn èèyàn. Àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí kò bá àwọn àwárí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní ti ṣe mu bẹ́ẹ̀ ni kò sì bá Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí mu. Bí àpẹẹrẹ, Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì dá Galileo lẹ́bi nítorí ó sọ pé ńṣe layé ń yí. Ohun tí Galileo sọ yìí kò tako Bíbélì lọ́nàkọnà o, àmọ́ ó ta ko ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ àwọn èèyàn nígbà yẹn. Yàtọ̀ síyẹn, àṣìṣe ńlá gbáà làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì náà ṣe nígbà tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn pé inú ohun kan tí kò lẹ́mìí ni ìwàláàyè ti wá, pé kì í ṣe látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò rí nǹkan kan fi ti àbá èrò orí yìí lẹ́yìn. Wọn yọ ṣùtì ètè sí ìgbàgbọ́ àwọn ẹlẹ́sìn pé kò bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu.
Nígbà náà, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti mú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìsìn ṣọ̀kan? Ó kúkú ṣeé ṣe. Ká sòótọ́, ńṣe ni ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ní ẹ̀rí gidi àti ìsìn tòótọ́ gbe ara wọn lẹ́yìn, wọn ò tako ara wọn rárá.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 2, 3]
Galileo fi òtítọ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kọ́ àwọn èèyàn, ìdí sì rè é tí ṣọ́ọ̀ṣì fi gbógun tì í