Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ètò Sayé Dọ̀kan—Ohun Táwọn Èèyàn Ń Fẹ́ Àtohun Tó Ń Bà Wọ́n Lẹ́rù

Ètò Sayé Dọ̀kan—Ohun Táwọn Èèyàn Ń Fẹ́ Àtohun Tó Ń Bà Wọ́n Lẹ́rù

Ètò Sayé Dọ̀kan—Ohun Táwọn Èèyàn Ń Fẹ́ Àtohun Tó Ń Bà Wọ́n Lẹ́rù

“Ohun tó gbàfiyèsí jù lọ ní sànmánì wa yìí ni ètò sayé dọ̀kan . . . . Ó ń ṣínà àwọn àǹfààní táráyé ò rírú ẹ̀ rí fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn jákèjádò ayé.”—MARTIN WOLF, ÒǸKỌ̀WÉ ÈTÒ ÌNÁWÓ.

“Ìdílé ńlá kan ni gbogbo àwa èèyàn tá à ń gbé lórí Ilẹ̀ Ayé jẹ́. Ètò tuntun tó gbòde yìí ń mú àwọn ohun tuntun wá àmọ́ ó tún ń dá àkọ̀tun wàhálà sáyé. Àwọn ìṣòro bíi bíba àyíká jẹ́, lílo àwọn nǹkan àlùmọ́nì ilẹ̀ ayé tán yán-án-yán, àwọn ogun tó ń fẹ̀mí àwọn èèyàn ṣòfò àti òṣì.”—ÀÀRẸ GEORGIA, EDUARD SHEVARDNADZE.

LÓṢÙ December ọdún 1999, àwọn ajìjààgboro lọ dabarú ìpàdé tí Àjọ Oníkáràkátà Lágbàáyé ṣe nílùú Seattle, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Èéfín tajútajú, ọta onírọ́bà àti ohun èlò tó ń fọ́n omi ata làwọn ọlọ́pàá lò láti fi dá wọn lẹ́kun. Lópin rẹ̀, wọ́n kó ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èèyàn tó ń ṣe ìwọ́de náà sí àtìmọ́lé.

Kí ló fa gbọ́nmi-sí-omi-ò-tó tó ṣẹlẹ̀ nílùú Seattle yìí? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló fà á. Bíi kí iṣẹ́ ẹni máà láyọ̀lé, bíba àyíká jẹ́ àti ìwà ojúsàájú tó wọ́pọ̀ láwùjọ. Àmọ́, ká má déènà pẹnu, ohun tó ń bí àwọn tó ń fi ẹ̀hónú hàn náà nínú kò ṣẹ̀yìn ẹ̀rù tó ń bà wọ́n nítorí ètò sayé dọ̀kan, nítorí wọ́n ro àkóbá tó máa ṣe fún ènìyàn àti ilẹ̀ ayé wa.

Ìbẹ̀rù wọn ọ̀hún kò tíì rọlẹ̀ o. Látọdún 1999, ńṣe ni ìwọ́de ń gorí ìwọ́de, bẹ́ẹ̀ ló sì túbọ̀ ń le sí i. Láwọn ìgbà míì, ìkọ̀kọ̀ làwọn aṣáájú ayé ti ń ṣe àwọn ìpàdé wọn báyìí, níbi tí kò ti ní í rọrùn fún àwọn tó ń ṣe ìwọ́de láti da ètò náà rú.

Àmọ́ gbogbo èèyàn kọ́ ló ń wo ètò sayé dọ̀kan bí nǹkan tó léwu o. Níbi táwọn kan ti kà á sí ọ̀dádá tó dá àwọn ìṣòro ayé sílẹ̀, ibẹ̀ làwọn kan ti ń kókìkí rẹ̀ pé òun gan-an ni ojútùú sí ọ̀pọ̀ jù lọ ìṣòro tó ń yọ ayé yìí lẹ́nu. Lóòótọ́, ó lè dà bí ẹni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ̀ nípa ọ̀ràn tó ń fa awuyewuye yìí, ó ṣe tán èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ni kò fi bẹ́ẹ̀ lóye ohun tó ń jẹ́ ètò sayé dọ̀kan. Àmọ́ ohun tó wù kó jẹ́ èrò tìrẹ nípa ètò yìí, ó ń nípa lórí rẹ lọ́wọ́lọ́wọ́, àfàìmọ̀ bí kò bá sì tún ní kàn ọ́ jù báyìí lọ lọ́jọ́ iwájú.

Kí Ló Tiẹ̀ Ń Jẹ́ Ètò Sayé Dọ̀kan?

“Sísọ Ayé Dọ̀kan” ni ọ̀rọ̀ táwọn kan ń lò láti fi ṣàpèjúwe bí àwọn èèyàn lágbàáyé àtàwọn orílẹ̀-èdè ṣe túbọ̀ ń mọwọ́ ara wọn sí i. Ẹ̀wádún tá a lò tán yìí ni ètò ọ̀hún wá hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀, ìyẹn ò sì ṣẹ̀yìn arabaríbí ìtẹ̀síwájú tó wáyé nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ. (Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 17.) Lọ́jọ́ tòní, a ò tún fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè kan lọ ń kógun ja òmíràn mọ́, owó tí wọ́n máa ń san lórí àwọn ẹrù tí wọ́n ń kó wọlé látilẹ̀ òkèèrè ti lọ sílẹ̀ dáadáa, ọ̀pọ̀ èèyàn ń di ẹni tó ń ní lára ìpín ìdókòwò àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá lágbàáyé, bẹ́ẹ̀ ni rírìnrìn àjò kò náni lówó tàbí lani lóòógùn bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.

Onírúurú nǹkan ló ti jẹ́ àbájáde bí aráyé ṣe túbọ̀ ń mọwọ́ ara wọn yìí. Èyí kan ètò ọrọ̀ ajé, ètò òṣèlú, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti àyíká wa. Àmọ́ ohun tó dunni níbẹ̀ ni pé, àwọn kan lára àwọn àbájáde yìí lè ṣàkóbá. Ìwé kan tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè mú jáde tí wọ́n pè ní Human Development Report 1999 ṣàlàyé pé: “Àjọṣe tó wà láàárín àwọn èèyàn jákèjádò ayé ti fẹsẹ̀ rinlẹ̀ sí i, ó ti gbòòrò sí i, ó sì ń ṣẹlẹ̀ kíákíá ju bó ṣe máa ń rí tẹ́lẹ̀ lọ. Ọ̀pọ̀ àǹfààní lèyí ti ṣínà rẹ̀, ó sì ti fa àwọn ohun tó dára àtàwọn ohun tó kù díẹ̀ káàtó.” Ńṣe ni ètò sayé dọ̀kan dà bí ọ̀pọ̀ àṣeyọrí yòókù tí ènìyàn ti ṣe, bó ṣe níbi tó dára sí náà ló níbi tó kù sí.

Àwọn Èèyàn Ń Fẹ́ Ayé Kan Tí Nǹkan Á Túbọ̀ Rọ̀ṣọ̀mù

Amartya Sen, tó gba Ẹ̀bùn ẹ̀yẹ Nobel nínú ètò ọrọ̀ ajé sọ pé, ètò sayé dọ̀kan “ti ṣe ayé láǹfààní púpọ̀ ní ti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti àṣà, ó sì ti mú ipò ìṣúnná owó ọ̀pọ̀ èèyàn gbé pẹ́ẹ́lí sí i.” Ìwé Human Development Report 1999 náà mẹ́nu kan ohun tó jọ bẹ́ẹ̀, ó ní ètò sayé dọ̀kan “ń ṣí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní sílẹ̀ kí ipò òṣì lè di ohun àwátì ní ọ̀rúndún kọkànlélógún.” Ohun tó jẹ́ káwọn èèyàn màá wo ètò yìí tìdùnnú-tìdùnnú ni aásìkí rẹpẹtẹ tó ti mú wá lẹ́yìn tí wọ́n dá a sílẹ̀. Owó tó ń wọlé fún ọ̀pọ̀ ìdílé lónìí ti fi ìlọ́po mẹ́ta ju iye tó ń wọlé fún àwọn ìdílé ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn. a

Àwọn tó ń ṣàtúpalẹ̀ ọrọ̀ ajé tún rí àǹfààní mìíràn tó wà nínú bí aráyé ṣe ń bára wọn ṣòwò: Wọ́n ní kò ní jẹ́ káwọn èèyàn fẹ́ bára wọn jagun mọ́. Thomas L. Friedman, sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní The Lexus and the Olive Tree pé, ètò sayé dọ̀kan “túbọ̀ ń ṣèrànwọ́ láti máà jẹ́ káwọn èèyàn fẹ́ jagun mọ́ ó sì ń mú kí ohun tí ogun jíjà ń náni pọ̀ ju ti ìgbàkigbà rí lọ nínú ìtàn òde òní.”

Bí àwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń mọwọ́ ara wọn sí i tún lè mú ìṣọ̀kan ayé lágbára. Ó ti ṣeé ṣe fáwọn àjọ tó ń jà fẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn láti lo àǹfààní Íńtánẹ́ẹ̀tì láti mú ìgbòkègbodò wọn tẹ̀ síwájú. Bí àpẹẹrẹ, fífi lẹ́tà ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà wà lára ohun tó jẹ́ kí ìwé àdéhùn ọdún 1997 tí gbogbo orílẹ̀-èdè fọwọ́ sí ṣàṣeyọrí, èyí tó ka bọ́ǹbù àrìmọ́lẹ̀ léèwọ̀, tó sì jẹ́ kó ṣeé ṣe láti kó oríṣiríṣi ẹgbẹ́ tó fẹ́ ṣèrànwọ́ jọ láti apá ibi gbogbo lágbàáyé. Wọ́n gbóríyìn fún bí wọ́n ṣe ka àwọn aráàlú sí nínú ọ̀ràn yìí. Wọ́n ní “bí àwọn ìjọba àtàwọn aráàlú ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti yanjú ìṣòro tó ń kojú ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn jẹ́ ọ̀nà tuntun láti bojú tó àwọ́n ọ̀ràn tó kan gbogbo orílẹ̀-èdè.”

Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo àṣeyọrí dáradára tí ètò sayé dọ̀kan ti mú wá yìí, ọ̀pọ̀ ṣì ń bẹ̀rù pé àwọn aburú tó dá sílẹ̀ pọ̀ ju àwọn àǹfààní rẹ̀ lọ.

Ìbẹ̀rù Pé Ìyàtọ̀ Àárín Olówó àti Tálákà Lè Máa Pọ̀ Sí I

Ó jọ pé ohun tó túbọ̀ ń mú kí ètò sayé dọ̀kan yìí máa ba àwọn èèyàn lẹ́rù ni bó ṣe ń mú kí àwọn olówó máa lówó sí i táwọn akúṣẹ̀ẹ́ sì ń kúṣẹ̀ẹ́ sí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí àní-àní pé nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù sí i láyé, ọ̀dọ̀ ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ àti orílẹ̀-èdè díẹ̀ ni ọrọ̀ ọ̀hún pọ̀ sí. Ọrọ̀ tí igba [200] èèyàn tó lówó jù lọ lágbàáyé ní ju ká pa iye tó ń wọlé fún àwọn èèyàn tó tó bílíọ̀nù méjì àti irínwó mílíọ̀nù [2,400,000,000] lọ. Nígbà tí iye tó ń wọlé fáwọn èèyàn láwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ ń ròkè sí i, ńṣe ni iye tó ń wọlé fáwọn èèyàn tó ń gbé ní ọgọ́rin orílẹ̀-èdè tí ìṣẹ́ ń hàn léèmọ̀ ń dín kù sí i láti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn.

Ìṣòro pàtàkì mìíràn tó tún ń kó ìdààmú bá àwọn èèyàn ní í ṣe pẹ̀lú àyíká. Èrè gọbọi tí àwọn tí okòwò àgbáyé wà níkàáwọ́ wọn máa jẹ ló ń mú wọn máa tan ètò ọrọ̀ ajé ká gbogbo ayé, èyí sì jẹ wọ́n lógún ju ààbò ayé lọ. Agus Purnomo, ọ̀gá Àjọ Akówójọ fún Ìdáàbòbo Ìṣẹ̀dá Lágbàáyé ní ilẹ̀ Indonesia sọ̀rọ̀ lórí ìṣòro ńlá yìí, ó sọ pé: “Eré bí ìdàgbàsókè ṣe máa wà là ń sá. . . . Ẹ̀rù ń bà mí pé lọ́dún mẹ́wàá sígbà tá a wà yìí, gbogbo wa la máa fojú ara wa rí ọṣẹ́ tá a ti ṣe fún àyíká, àmọ́ ẹ̀pa ò ní bóró mọ́.”

Ọkàn àwọn èèyàn ò tún balẹ̀ lórí iṣẹ́ wọn. Bí àwọn iléeṣẹ́ ṣe ń di èyí tó já pọ̀ mọ́ra tí ìbáradíje ńláǹlà sì ń fipá mú àwọn iléeṣẹ́ kan láti dín òṣìṣẹ́ kù, kò sí ọ̀kankan tó láyọ̀lé nínú iṣẹ́ àti owó tó ń wọlé fún èèyàn. Ní ti àwọn iléeṣẹ́ tó jẹ́ pé bí èrè tí wọ́n máa jẹ á ṣe túbọ̀ pọ̀ sí i lóhun tó jẹ wọ́n lógún, wọn ò rí ohun tó burú nínú gbígba òṣìṣẹ́ kí wọ́n sì tún dà wọ́n sílẹ̀ níbàámu pẹ̀lú ọjà táwọn èèyàn bá ń fẹ́. Àmọ́ àkóbá kékeré kọ́ ni èyí ń ṣe nígbèésí ayé àwọn èèyàn o.

Àwọn òwò ńláńlá táwọn èèyàn ń bára wọn ṣe lágbàáyé tún ti dá ìṣòro mìíràn sílẹ̀ tí kò jẹ́ kí ọkàn balẹ̀. Àwọn olùdókòwò lágbàáyé lè yá àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lówó ribiribi, àmọ́ wọ́n lè ṣàdédé gba owó wọn padà tí wọ́n bá rí i pé ètò ọ̀rọ̀ ajé irú àwọn orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀ ti ń dẹnu kọlẹ̀. Irú gbígba owó padà láìròtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀, tí kì í sì í ṣe owó kékeré, lè kó ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè sí ìṣòro ìnáwó. Nítorí ìṣòro àìsí owó lọ́wọ́ ìjọba tó ṣẹlẹ̀ ní Ìlà Oòrùn Éṣíà lọ́dún 1998, mílíọ̀nù mẹ́tàlá òṣìṣẹ́ niṣẹ́ bọ́ mọ́ lọ́wọ́. Nílẹ̀ Indonesia sì rèé, àwọn tí iṣẹ́ ò bọ́ lọ́wọ́ wọn rí i pé ìlàjì ohun tí wọ́n ń fi owó tí wọ́n ń san fún wọn tẹ́lẹ̀ rà ni owó wọn ká báyìí.

Ó ti wá hàn báyìí pé, bí ètò sayé dọ̀kan ṣe ń fa ìbẹ̀rù náà ló tún ń pèsè nǹkan táwọn èèyàn fẹ́. Ǹjẹ́ ó yẹ kí ètò yìí máa bà ọ́ lẹ́rù? Àbí ṣé o lè máa retí pé á túbọ̀ mú nǹkan rọ̀ṣọ̀mù fún ọ? Ṣé ètò sayé dọ̀kan ti ṣe àwọn ohun kan fún wa tá a fi lè máa wọ̀nà pé ire ń bọ̀ níwájú? Àpilẹ̀kọ wa tò tẹ́ lé èyí á dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tá a bá fojú bí nǹkan ṣe rí ní gbogbo ayé lápapọ̀ wò ó, ó lè ṣì wá lọ́nà. Lọ́pọ̀ ibi, àwọn ìdílé kò rí àlékún kankan nínú iye tó ń wọlé fún wọn láti àádọ́ta ọdún sẹ́yìn, nígbà tó sì jẹ́ pé ìlọ́po ìlọ́po ni iye owó tó ń wọlé fún àwọn mìíràn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]

Tá a bá pa ọrọ̀ tí igba [200] èèyàn tó lówó jù lọ lágbàáyé ní pọ̀, ó ju gbogbo owó tó ń wọlé fún àwọn èèyàn tó tó bílíọ̀nù méjì àti irínwó mílíọ̀nù [2,400,000,000] lọ

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

ÀWỌN ÌMỌ̀ IṢẸ́ Ẹ̀RỌ TÓ MÚ KÁYÉ LU JÁRA

Láàárín ọ̀rúndún tá a lò tán yìí, ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti yí ètò ìbánisọ̀rọ̀ padà pátápátá. Ó ti mú kó ṣeé ṣe láti bá àwọn èèyàn sọ́rọ̀ níbikíbi tó wù kó jẹ́ lágbàáyé, lọ́nà tó yá kíákíá, lówó pọ́ọ́kú, ó sì rọrùn gan-an.

TẸLIFÍṢỌ̀N Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹnì kankan lágbàáyé tí kò mọ ohun tó ń jẹ́ tẹlifíṣọ̀n, bí wọn ò tiẹ̀ ní in nílé. Lọ́dún 1995, tí wọ́n bá kó ẹgbẹ̀rún èèyàn jọ, òjì lé nígba ó dín márùn-ún [235] nínú wọn ló ní tẹlifíṣọ̀n, ìyẹn sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì iye àwọn tó ní in lọ́dún 1980. Àwo sátẹ́láìtì tí kò ju gbúngbú lọ lè jẹ́ káwọn èèyàn tó ń gbé láwọn ibi tó jìnnà jù lọ láyé máa gbọ́ ìròyìn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbi gbogbo kárí ayé. Francis Fukuyama, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ètò ọ̀rọ̀ ajé ìjọba sọ pé: “Lónìí, kò sí orílẹ̀-èdè kankan tó lè ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ dáńfó pé òun ò ní í gbọ́ ìròyìn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbàáyé lọ́nà kan tàbí òmíràn.”

ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] èèyàn ló ń wọ ẹgbẹ́ àwọn tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Lọ́dún 1999, wọ́n fojú bù ú pé tó bá fi máa di ọdún 2001, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] mílíọ̀nù èèyàn ló ti máa wọ agbo àwọn tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Òǹkọ̀wé Thomas L. Friedman sọ pé: “Àbájáde èyí ni pé kò tíì sígbà kankan nínú ìtàn ayé yìí tó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ láti mọ̀ nípa ìgbésí ayé àwọn èèyàn mìíràn, àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe jáde àti èrò wọn.”

TẸLIFÓÒNÙ Àwọn wáyà tín-ín-rín àtàwọn wáyà alátagbà tó ń bá sátẹ́láìtì ṣiṣẹ́ ti dín owó tẹlifóònù kù jọjọ. Iye tí wọ́n fi ń pe ìlú New York láti ìlú London tẹ́lẹ̀ ti wálẹ̀ láti igba dọ́là ó lé márùnlélógójì tó jẹ́ lọ́dún 1930 sí ohun tí kò pé dọ́là kan mọ́ lọ́dún 1999. Àwọn ẹ̀rọ alásokọ́ra tí kì í lo wáyà ti mú kí tẹlifóònù alágbèéká tí wọ́n ń pè ní sẹ́lúlà wà káàkiri bí kọ̀ǹpútà ṣe wà káàkiri. Nígbà tí ọdún 2002 yìí bá fi máa parí, àwọn tí wọ́n fojú bù pé wọ́n á máa lo sẹ́lúlà, ìyẹn fóònù alágbèéká, á wọ bílíọ̀nù kan, ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì máa lè fi fóònù wọn yìí lo Íńtánẹ́ẹ̀tì.

OHUN ÌKÓSỌFÚNNISÍ MỌ́ŃBÉ Orí ohun èlò yìí ni gbogbo ohun tá a dárúkọ lókè yìí sinmi lé, ìgbà gbogbo ní wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ lórí wọn kí wọ́n bàa lè túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i. Láti bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn, oṣù méjìdínlógún, méjìdínlógún ni wọ́n ń fi kún agbára tí ohun èlò ìkósọfúnnisí mọ́ńbé yìí ní. Kò tíì sígbà kan tó ti ìsinsìnyí tó ṣeé ṣe láti kó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìsọfúnni pa mọ́ sínú ohun kan tó kéré gan-an bẹ́ẹ̀.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 15]

Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.; àwòrán òbírí ayé tó wà lójú ewé 17, 19-22 àti 25: fọ́tò NASA