Ètò Sayé Dọ̀kan Tó Máa Ṣe Ọ́ Láǹfààní
Ètò Sayé Dọ̀kan Tó Máa Ṣe Ọ́ Láǹfààní
“Bí ètò sayé dọ̀kan bá máa yọrí sí rere, àtolówó àti mẹ̀kúnnù ló gbọ́dọ̀ jàǹfààní rẹ̀. Bó ṣe ń fúnni lẹ́tọ̀ọ́ ẹni ló gbọ́dọ̀ máa fúnni ní ọrọ̀. Kò gbọ́dọ̀ fa ojúsàájú láwùjọ, nǹkan sì gbọ́dọ̀ rọ̀ṣọ̀mù fún tẹrútọmọ. Ó tún gbọ́dọ̀ mú ètò ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ní ọ̀kúnkúndùn.”—KOFI ANNAN, Ọ̀GÁ ÀGBÀ FÚN ÌPARAPỌ̀ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ.
BÍ Kofi Annan ṣe sọ lọ̀rọ̀ rí, bí ètò sayé dọ̀kan bá máa lójútùú, ó gbọ́dọ̀ mú nǹkan dán mọ́ràn fún gbogbo èèyàn tó ń gbé orí ilẹ̀ ayé láìyọ ẹnì kankan sílẹ̀. Àmọ́ ohun tá a rí láwọn ọdún àìpẹ́ yìí jìnnà síyẹn fíìfíì. Fífúnni lẹ́tọ̀ọ́ ẹni àti pinpín ọrọ̀ inú ayé dọ́gba kò rọ́wọ́ mú rárá, bẹ́ẹ̀ kẹ̀, ìdàgbàsókè nínú iṣẹ́ ẹ̀rọ àti kíkó ọrọ̀ jọ pelemọ kò dáwọ́ dúró.
Olórí ohun tó ń fa ìṣòro yìí ni pé, ìfẹ́ owó ló wà lẹ́yìn ètò mímú kí ọrọ̀ ajé àgbáyé dọ̀kan. Ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni ìfẹ́ owó yìí kì í jẹ́ káwọn èèyàn ní ìgbatẹnirò fún àwọn tálákà àtàwọn tí kò rí bátiṣé láwùjọ, kódà kì í jẹ́ kí wọ́n ronú nípa àkóbá tó lè ṣe fún ilẹ̀ ayé wa lọ́jọ́ iwájú. Ọ̀mọ̀wé David C. Korten ṣàlàyé pé: “Ó dájú pé ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé kò lè lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, nítorí pé ìkáwọ́ àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá ló wà láìsí òfin pàtó kan tó dè wọ́n tó sì jẹ́ pé owó tí wọ́n máa rí níbẹ̀ nìkan ló jẹ wọ́n lógún . . . síbẹ̀, ìpalára tó ń ṣe fún ọmọ ẹ̀dá kọjá kèrémí.”
Ṣé àwọn ìjọba ayé lè ṣètò ọrọ̀ ajé àgbáyé lọ́nà tí àìṣègbè á fi wà láwùjọ? Kò dájú pé ìyẹn á ṣeé ṣe. Títí di bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn ìjọba kò tíì rí ojútùú sí ọ̀kankan nínú àwọn ìṣòro tó kan gbogbo ayé lápapọ̀, ì báà jẹ́ ti ìwà ọ̀daràn tó gbayé kan ni o, ti ayé tó túbọ̀ ń móoru sí i ni o tàbí ti ipò òṣì
tó ń han aráyé léèmọ̀. Annan sọ pé: “Ká tó lè bójú tó àwọn ọ̀ràn tó máa ṣe gbogbo ayé láǹfààní, gbogbo wa gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Àmọ́ nínú ayé tó lu jára yìí, àwọn ìlànà tá a ní lọ́wọ́ kò lè tu irun kankan lára àwọn ìṣòro yìí.”Bí aráyé tiẹ̀ ní àwọn ìlànà tí wọ́n nílò láti kojú àwọn ìṣòro tó ń yọ ayé lẹ́nu, ìyẹn nìkan kò tó o. Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Tó Wà fún Ètò Ìṣèjọba Lágbàáyé a sọ pé, aráyé tún nílò ìlànà ìwà rere. Ìròyìn tí wọ́n tẹ̀ jáde sọ pé: “Láìsí ìlànà ìwà rere kan gbòógì tí gbogbo ayé á máa tẹ̀ lé, wàhálà àti ìṣòro táwọn èèyàn ń kojú ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni o; tí kò bá sì sí aṣáájú, àwọn àjọ àtàwọn ètò tó dára gan-an tá ò rí irú ẹ̀ rí á máa kùnà ni.”
Àwọn ìlànà ìwà híhù wo ni wọ́n dámọ̀ràn pé kí aráyé máa tẹ̀ lé? Ìròyìn náà sọ pé: “Ohun tí àwọn èèyàn bá fẹ́ kí ẹlòmíràn ṣe sí wọn ni káwọn náà máa ṣe sí àwọn mìíràn.” Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, Jésù Kristi, aṣáájú dídára jù lọ tí aráyé kò rí èkejì rẹ̀ kọ́ àwọn èèyàn ní ìlànà yìí. (Mátíù 7:12) Ìlànà yìí ṣì wúlò gan-an títí dọjọ́ òní. Ó dájú pé kò sẹ́ni tí kò ní jàǹfààní nínú ètò sayé dọ̀kan tá a bá gbé karí ìlànà yẹn. Ṣé ìyẹn lè ṣẹlẹ̀ láyé ńbí?
Ojútùú Kan Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀
Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, ìjọba karí ayé kan ń bọ̀ láìpẹ́ tó máa sọ gbogbo ayé di ọ̀kan. Kò ní dá lórí owó tàbí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, kàkà bẹ́ẹ̀ orí àìmọtara ẹni nìkan la máa gbé e kà. Ó máa kẹ́sẹ járí, nítorí ó ní agbára àtàwọn ìlànà tó máa ṣe gbogbo ọmọ aráyé láǹfààní. Ìjọba kárí ayé yìí ló gba Jésù Kristi lọ́kàn nígbà tó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n gbàdúrà ‘kí Ìjọba Ọlọ́run dé kí ìfẹ́ Ọlọ́run sì ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé.’—Mátíù 6:10.
Ìjọba Ọlọ́run, èyí tá a gbé lé Jésù Kristi lọ́wọ́ yóò fi àpẹẹrẹ ìlànà ìwà híhù tuntun lélẹ̀ fún gbogbo ayé. Òun gan-an ni Jésù fúnra rẹ̀ kọ́ àwọn èèyàn nípa rẹ̀ nígbà tó wà láyé. Ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti ìfẹ́ fún aládùúgbò ẹni ló máa darí rẹ̀. (Mátíù 22:37-39) Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nínú Bíbélì to àwọn ohun tí ìjọba tuntun yìí yóò ṣe lẹ́sẹẹsẹ. Nígbà tí Bíbélì ń sọ nípa Jésù Kristi tó jẹ́ Alákòóso ìjọba náà, ó ṣèlérí pé: “Yio fi ododo ṣe idajọ talakà, yio si fi otitọ ṣe idajọ fun awọn ọlọkàn tùtu aiye.” (Aísáyà 11:4, Bibeli Mimọ) Àwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn tágbára wà lọ́wọ́ wọn kò tún ní máa kó àwọn tí kò tẹ́gbẹ́ nífà mọ́. Jésù yóò “káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì . . . Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 72:13, 14.
Ìṣòro sísọ àyíká di ẹlẹ́gbin á di èyí tá a bójú tó láìjáfara. Dípò pípa tí àwọn èèyàn ń pa igbó run, “ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná.” (Aísáyà 35:1) Dípò àìtó oúnjẹ, “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀.”—Sáàmù 72:16.
Ìjọba Ọlọ́run ń so onírúurú èèyàn pọ̀ ṣọ̀kan. Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀ ní ìṣọ̀kan, bí agbo ẹran nínú ọgbà ẹran.” ‘Èmi yóò fún wọn ní ìyípadà Míkà 2:12; Sefanáyà 3:9) “Èdè mímọ́ gaara” yìí, tó ní ìlànà ìwà rere àti ìlànà ìsìn kan náà fún gbogbo gbòò, ń so àwọn èèyàn pọ̀, kódà nísinsìnyí pàápàá.
sí èdè mímọ́ gaara, kí gbogbo wọn lè máa sìn mí ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.’ (Nítorí àǹfààní àtirìnrìn-àjò lọ síbikíbi lágbàáyé tó ṣí sílẹ̀, ìgbà gbogbo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ìpàdé àgbáyé. Èyí ń mú kí ìdè tó wà láàárín àwọn èèyàn láti onírúurú ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i. Ẹ̀rí tó ṣe é fojú rí làwọn àpéjọ yìí jẹ́ nípa ìṣọ̀kan tó tinú ọkàn wá tó sì ní í ṣe pẹ̀lú ìrònú ẹni, kì í ṣe èyí tá a gbé karí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ àti ètò ìṣòwò. (Wo àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.) Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan ní ilẹ̀ Sípéènì tó ti lọ sírú àwọn àpéjọ bẹ́ẹ̀ kọ̀wé pé: ‘Nígbà tí mo fi máa kúrò ní àpéjọ náà, ó ti gbé mi ró gan-an, kì í ṣe nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tá a gbé karí Ìwé Mímọ́ tí wọ́n sì ń lani lọ́yẹ̀ nìkan, àmọ́ nítorí ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn èèyàn yìí, ìwà rere wọn tí kò lẹ́gbẹ́ àti ìṣesí wọn tó wuyì.’
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ń lo àwọn àǹfààní mìíràn tí ètò sayé dọ̀kan pèsè kí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n ń ṣe lè rọrùn sí i. Bí àpẹẹrẹ, ó lé ní ọgọ́rin èdè tí wọ́n ń tú ìwé ìròyìn Jí! sí báyìí. Ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà àti ètò ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ orí kọ̀ǹpútà ni ọ̀pọ̀ àwọn atúmọ̀ èdè tó ń ṣiṣẹ́ yìí sì ń lò. Ìrànlọ́wọ́ ńlá ni irú àwọn irinṣẹ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti mú kí iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn lè dé apá ibi gbogbo lágbàáyé. Èyí fi hàn gbangba pé, àwọn ohun tí ètò sayé dọ̀kan ti mú jáde lèèyàn lè lò lọ́nà tó ṣàǹfààní tàbí lọ́nà tó máa mú ìparun lọ́wọ́.
Lọ́nà kan náà, dípò kí ìjọba kárí ayé tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ yìí máa dá ìṣòro kún ìṣòro bíi ti ètò sayé dọ̀kan tí èèyàn ṣe, ńṣe ni yóò mú ojútùú wá. Kò sí ìdí kankan tí kò fi yẹ ka nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú ìṣàkóso àtọ̀runwá yìí. Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Emi o da ọrun titun ati aiye titun: a kì yio sì ranti awọn ti iṣaju, bẹni nwọn ki yio wá si aiya. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o yọ̀, ki inu nyin ki o si dùn titi lai ninu eyi ti emi o da.” (Aísáyà 65:17, 18, Bibeli Mimọ) “Aiye titun” Ọlọ́run yóò mú àǹfààní ńláǹlà wá fún gbogbo àwọn èèyàn tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe yìí, tó ní àwọn aṣáájú ayé jàǹkànjàǹkàn méjìdínlọ́gbọ̀n nínú gbé ìròyìn gígùn jàǹrànjanran kan jáde lọ́dún 1995, èyí tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní “Ayé Lu Jára.” Nínú rẹ̀, wọ́n to àwọn ohun tí wọ́n fẹ́ gbé ṣe lẹ́sẹẹsẹ kí ètò ìṣèjọba ayé lè dára sí i.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]
AYÉ TI DỌ̀KAN ÀMỌ́ ÀWỌ́N ÈÈYÀN ṢÌ PÍNYÀ
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti sọ ayé dọ̀kan, ìpínyà kò tíì wábi gbà láàárín àwọn èèyàn o. Tẹlifíṣọ̀n, fóònù alágbèéká àti Íńtánẹ́ẹ̀tì ti ṣe gudugudu méje láti mú káwọn èèyàn máa gbúròó ara wọn àmọ́ kò so àwọn èèyàn pọ̀ ṣọ̀kan. Bí ọwọ́ ṣe wọ ọwọ́ nínú ètò ọrọ̀ ajé tí àwọn alágbára ayé ò sì bára wọn ta kànǹgbọ̀n mọ́ ti mú kí ogun táwọn Orílẹ̀-èdè máa ń bára wọn jà dín kù. Àmọ́ lọ́dọọdún, ogun abẹ́lé rírorò ṣì ń gbẹ̀mí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èèyàn, kò sì yéé ṣe àwọn èèyàn báṣabàṣa.
Kí ló dé táwọn nǹkan wọ̀nyí ṣì fi ń ṣẹlẹ̀? Ìdí ni pé, ìkórìíra tó ń mú kí àwọn ìran, ẹ̀yà àtàwọn ìsìn máa bára wọn ṣorogún ṣì wà níbẹ̀ digbí, èyí sì ni olórí ohun tó ń dá ogun abẹ́lé sílẹ̀. Láìbojúwẹ̀yìn, àwọn oníṣòwò jàǹkànjàǹkàn lágbàáyé àtàwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn ṣì ń ta àwọn nǹkan ìjà kéékèèké tówó wọn kò wọ́n fáwọn ẹgbẹ́ tó ń bára wọn jà. Bẹ́ẹ̀ làwọn ohun èlò abánáṣiṣẹ́ kò sì lè mú ojúlówó ìṣọ̀kan wá. Bí ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé sì búrẹ́kẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ, kò ní kí ojúsàájú kásẹ̀ nílẹ̀ láwùjọ.
Láwọn ọ̀nà kan, ńṣe ni ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé tiẹ̀ tún ń dá kún àìsí ìṣọ̀kan. Tí ọ̀rọ̀ ajé bá dẹnu kọ́lẹ̀ lẹ́yìn tó ti gbé pẹ́ẹ́lí fún sáà kan, àwọn olóṣèlú tí àṣejù ti wọ̀ lẹ́wù lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn aláìní fún àǹfààní ara wọn. Kí wá lojútùú báyìí? Ìwé pẹlẹbẹ náà, Human Development Report 1999 sọ pé: “Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe àkóso orílẹ̀-èdè àti gbogbo ayé lápapọ̀ gbọ́dọ̀ yí padà, àjọṣe tó dán mọ́rán láàárín àwọn èèyàn àti àìsí ojúsàájú ló sì lè mú èyí ṣeé ṣe.” Ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe gan-an nìyẹn.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ńṣe ní gbogbo ayé ti ṣèrànwọ́ láti so onírúurú èèyàn pọ̀ ṣọ̀kan