Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ètò Sayé Dọ̀kan Lè Yanjú Àwọn Ìṣòro Wa Lóòótọ́?

Ṣé Ètò Sayé Dọ̀kan Lè Yanjú Àwọn Ìṣòro Wa Lóòótọ́?

Ṣé Ètò Sayé Dọ̀kan Lè Yanjú Àwọn Ìṣòro Wa Lóòótọ́?

“Bí ọ̀rọ̀ àwa tá a jẹ́ aládùúgbò ara wa ṣe rí náà ni ètò sáyé dọ̀kan ṣe rí. Ètò yìí kò mú àwọn ìrètí wa ṣẹ; bẹ́ẹ̀ ló sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àbùkù. Kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń gbé inú ẹ̀ ni nǹkan dára fún; wọn ò jọ jẹ irú àǹfààní kan náà. Ìṣẹ́ ń fi ojú àwọn kan rí màbo débi pé, wọn ò gbà pé apá kan ìlú làwọ́n jẹ́.”—“OUR GLOBAL NEIGHBOURHOOD.”

FATIMA, tó ń gbé ìlú ńlá kan ní ilẹ̀ Áfíríkà ka ara rẹ̀ sí ẹni tó rí já jẹ. Ó ṣe kò ṣe, ó ní ẹ̀rọ amómitutù kan. Àmọ́ páànù ni wọn fi gbá ilé jagara táwọn òbí rẹ̀ ń gbé pọ̀ mọ́ àwọn sàréè mẹ́ta kan tí wọ́n fi mábìlì ṣe. Itẹ́ òkú fífẹ̀ kan ló ń gbé bíi tàwọn èèyàn mìíràn tí wọ́n tó ìdajì mílíọ̀nù. Kódà, èrò ti bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ jù ní itẹ́ òkú ọ̀hún pàápàá. Ó sọ pé: “Àwọn èèyàn tó ń kó wá ti pọ̀ jù, àgàgà lápá ibi tí sàréè pọ̀ sí níbí.”

Ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún síbi tí Fatima ń gbé yìí, àwọn ilé mèremère kan wà níbẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́. Kò sóhun tí kò pé síbẹ̀ tán, ilé àrójẹ wà, ó sì ní ibì kan tó fẹ̀ lọ salalu tí wọ́n ti ń gbá bọ́ọ̀lù àfọ̀págbá. Iye tí wọ́n fi ń gbá bọ́ọ̀lù yìí lẹ́ẹ̀kan ju gbogbo owó tó ń wọlé fún ẹnì kan ní orílẹ̀-èdè Áfíríkà yìí lóṣù. Kì í ṣòní kì í ṣàná tí ìṣẹ́ ti ń han àwọn ará ìlú yìí léèmọ̀, síbẹ̀ wọ́n mọ̀ pé olówó làwọn tó ń gbá bọ́ọ̀lù àfọ̀págbá yìí, èyí sì máa ń jẹ́ kí inú bí wọn. Nínú ayé tá à ń gbé yìí, òṣì pọ̀ rẹpẹtẹ, ọrọ̀ náà sì pọ̀ jaburata.

Ní àárín gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé, kọ́lọkọ̀lọ ni ọ̀nà Wadi Hadhramaut rí, ó sì gba àgbègbè Yemen tó gbẹ táútáú kọjá. Ibẹ̀ làwọn oníṣòwò máa ń gbà láyé ọjọ́un, àwọn ìlú àtayébáyé sì wà káàkiri ojú ọ̀nà yìí. Téèyàn bá kọ́kọ́ wo àgbègbè tó jìnnà tó sì kún fún àfonífojì yìí gààràgà, ńṣe ló máa rò pé kò yí padà kúrò sí bó ṣe wà látìgbà láéláé. Àmọ́ ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀ o. Nílùú Saywūn tó wà nítòsí ibẹ̀, àwọn tó ń bójú tó ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ti gba ọmọ yunifásítì kan pé kó bá wọn gbé gbogbo ìṣúra tí wọ́n ní níbẹ̀ jáde lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ìlú náà ni akẹ́kọ̀ọ́gboyè yìí, ìlú Ohio ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ló ti kàwé. Níbi táyé dé lónìí, kò síbi tí wọn ò ti lè gbọ́ nípa àwọn èèyàn àti èrò wọn.

Sàhárà wà ní apá ìwọ̀ oòrùn ibi tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kìlómítà mélòó kan ni sí ibẹ̀. Àwọn ọkọ̀ akẹ́rù mẹ́ta kan rọra ń rìn lọ sí apá gúúsù, lójú ọ̀nà kan tó dá páropáro. Mashala, ọ̀kan lára àwọn awakọ̀ náà ṣàlàyé pé àwọn nǹkan bíi tẹlifíṣọ̀n, fídíò àti sátẹ́láìtì ni òún máa ń fi ọkọ̀ kó kiri. Gbogbo nǹkan tó ń lọ láyé ló máa ń mọ̀ nítorí pé ó máa ń wo àwọn tẹlifíṣọ̀n ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ó sọ pé, nílùú wa “gbogbo wa la ní sátẹ́láìtì.” Bẹ́ẹ̀ ni, ṣàṣà ibi ló wà láyé yìí tí wọn ò ti mọ̀ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé.

Bí àwọn èèyàn, èrò, ìròyìn, owó àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ṣe ń lọ láti ibì kan sí ibòmíràn láyé, ó ti sọ àwọn èèyàn di aládùúgbò ara wọn, ọ̀pọ̀ àǹfààní ni èyí sì lè mú wá. Ayé tó lu jára ló jẹ́ kí àṣà àwọn ará ìlú Yemen tá a mẹ́nu kàn lókè di ohun tí wọ́n ń mọ̀ lágbàáyé, òun náà ló jẹ́ kí Mashala máa rí tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta dọ́là láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tó bá fi rìnrìn àjò ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo. Àmọ́ gbogbo èèyàn kọ́ lowó ń dé ọ̀dọ̀ wọn bẹ́ẹ̀. Ojú nìkan ni Fatima àtàwọn aládùúgbò rẹ̀ fi ń rí àwọn èèyàn díẹ̀ tí adùn ayé tó lú jára ń kán sí lẹ́nu, inú òṣì paraku làwọ́n wà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun táwọn èèyàn retí kọ́ ni ètò sayé dọ̀kan mú wá, kò dájú pe wọ́n lè dáwọ́ rẹ̀ dúró mọ́. Ṣé àwọn èèyàn kò ní í wo tẹlifíṣọ̀n mọ́ ni, ṣé wọ́n á ju tẹlifóònù alágbèéká wọn sígbó ni, ṣe wọ́n máa gbé àwọn kọ̀ǹpútà wọn dànù ni àbí kẹ̀ wọn ò ní í rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́? Tá a bá sì ń sọ nípa ètò ìṣèlú àti ọrọ̀ ajé lágbàáyé, ṣé àwọn orílẹ̀-èdè lè ya ara wọn kúrò lára gbogbo ayé tó kù ni? Kò dájú pé èyí lè ṣeé ṣe. Kò sẹ́ni tí kò wù láti pọ́n lá lára adùn tó wà nínú ayé tó lu jára yìí. Àmọ́ àwọn ìṣòro tó wà níbẹ̀ ńkọ́? Ìbẹ̀rù táwọn ìṣòro yìí ń dá sílẹ̀ kì í ṣe kékeré rárá kò sì sẹ́ni tí ò kàn. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ìṣòro kàbìtìkàbìtì tí ètò sísọ gbogbo ayé dọ̀kan ti dá sílẹ̀.

Ìyàtọ̀ Àárín Olówó àti Mẹ̀kúnnù Túbọ̀ Ń Pọ̀ Sí I

Kò tíì sígbà kan tí ọrọ̀ ayé yìí tẹ gbogbo èèyàn lọ́wọ́ rí, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ètò ọ̀rọ̀ ajé àgbáyé túbọ̀ ń fa ìyàtọ̀ púpọ̀ gan-an sáàárín olówó àti tálákà. Lóòótọ́, ó jọ pé àwọn orílẹ̀-èdè díẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ti jàǹfààní látinú báwọn náà ṣe ń kópa nínú ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé. Àwọn ògbógi sọ pé, láti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, iye àwọn èèyàn tó jẹ́ òtòṣì paraku nílẹ̀ Íńdíà ti lọ sílẹ̀ látorí ìdá mọ́kàndínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún sí ìdá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún. Wọ́n sì sọ pé nǹkan ti gbé pẹ́ẹ́lí sí i nílẹ̀ Éṣíà náà. Ìwádìí kan fi hàn pé, lọ́dún 1998, kò ju ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ mọ́ nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Ìlà Oòrùn Éṣíà tó jẹ́ pé dọ́là kan péré ni owó tí wọ́n ṣì ń ná lójúmọ́. Lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn sì rèé, ìdá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ni wọ́n jẹ́ nínú ọgọ́rùn-ún. Àmọ́ tá a bá wo ipò ayé lápapọ̀, kò múnú èèyàn dùn rárá.

Ní gúúsù aṣálẹ̀ Sàhárà ní Áfíríkà àti láwọn ibi kan tí nǹkan ò ti dán mọ́rán fáwọn èèyàn, ńṣe ni iye tó ń wọlé fún wọn níbẹ̀ ń wálẹ̀ sí i láti ọgbọ́n ọdún sẹ́yìn. Kofi Annan tó jẹ́ Ọ̀gá Àgbà fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé . . . kò wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ bílíọ̀nù mẹ́ta àwọn èèyàn, ìyẹn nǹkan bí ìdajì gbogbo èèyàn tó wà láyé, tí wọ́n ń wa ìyà mu nínú ayé kan tí ọrọ̀ ti pọ̀ jaburata.” Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ohun tó ń fa ìyàtọ̀ ńláǹlà yìí láwùjọ ni ìmọtara ẹni nìkan. Larry Summers, akọ̀wé ọ̀rọ̀ ìnáwó tẹ́lẹ̀ fún orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Káàkiri ayé, àwọn tó wà nídìí okòwò jàǹkàn-jàǹkàn kì í ro tàwọn akúùṣẹ́. Àwọn báńkì kì í fẹ́ ṣí ẹ̀ka wọn síbi táwọn tálákà bá pọ̀ sí, nítorí ìyẹn kò ní jẹ́ kí owó rẹpẹtẹ wọlé fún wọn.”

Bí owó tó ń wọlé ṣe ń dá ìyàtọ̀ púpọ̀ gan-an sáàárín àwọn ọlọ́rọ̀ àti tálákà náà ló tún ń fìyàtọ̀ sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọrọ̀ tí ẹni tó lówó jù lọ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní ju àpapọ̀ iye tó ń wọlé fún iye tó lé lọ́gọ́rùn-ún mílíọ̀nù ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà bíi tiẹ̀ lọ. Sísọ ayé dọ̀kan tún ti mú kí àwọn iléeṣẹ́ ńláńlá tí wọ́n ní ẹ̀ka káàkiri ayé pọ̀ bí eéṣú, tó sì jẹ́ pé àwọn nìkan ni ká sáà sọ pé ó wà nídìí òwò oríṣi àwọn ohun èlò kan lágbàáyé. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1998, iléeṣẹ́ mẹ́wàá péré ló kó ìdá mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún owó okòwò iléeṣẹ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ onígba-bílíọ̀nù ó lé méjìlélọ́gọ́ta dọ́là. Agbára tó máa ń wà lọ́wọ́ àwọn iléeṣẹ́ àgbáyé yìí máa ń ju ti ìjọba lọ lọ́pọ̀ ìgbà. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Abẹ̀bẹ̀-fún-Ìdáríjì Lágbàáyé sì ṣe sọ, “ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti ẹ̀tọ́ òṣìṣẹ́ kò já mọ́ nǹkan kan lójú wọn.”

Abájọ táwọn àjọ tó ń jà fẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn fi ń dààmú nípa bó ṣe jẹ́ pé ọ̀dọ̀ ìwọ̀nba àwọn èèyàn díẹ̀ tí nǹkan ṣẹnuure fún ni ọrọ̀ ayé yìí pọ̀ sí. Ṣé wàá fẹ́ ẹ́ gbé ládùúgbò kan tó jẹ́ pé iye tó ń wọlé fún ìdá ogún péré nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èèyàn ibẹ̀ ju tàwọn tálákà lọ ní ìlọ́po mẹ́rìnléláàádọ́rin? Pẹ̀lú bí tẹlifíṣọ̀n ṣe wà káàkiri, ìdá ogún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn akúṣẹ̀ẹ́ tó ń gbé láyé lo mọ irú ìgbádùn táwọn èèyàn bíi tiwọn tí wọ́n lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ń jẹ, nígbà táwọn ò sì rọ́gbọ́n kankan ta kí ipò tiwọn lè gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Ó dájú pé wàhálà àti ìbànújẹ́ ni irú ìwà ojúsàájú tó gogò bẹ́ẹ̀ ń dá sílẹ̀ láyé.

Mímú Àṣà Wọnú Ara Wọn

Kókó mìíràn tó tún ń fa àìbalẹ̀ ọkàn ní í ṣe pẹ̀lú bí àṣà àwọn èèyàn kò ṣe bára wọn mu àti títan ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì kálẹ̀. Fífi èrò wérò ṣe pàtàkì gan-an nínú ètò sayé dọ̀kan, Íńtánẹ́ẹ̀tì ló sì fi èyí hàn jù. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé kì í ṣe títan àwọn ìsọfúnni tó lè ṣeni láǹfààní, àṣà àti iṣẹ́ ajé kálẹ̀ nìkan ni wọ́n ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì fún. Àwọn ohun tó ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè, ẹ̀tanú ẹ̀yà àti tẹ́tẹ́ títa ló kún àwọn ibì kan lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì fọ́fọ́. Àwọn ibì kan tiẹ̀ wà níbẹ̀ tó ṣàlàyé béèyàn ṣe lè ṣe bọ́ǹbù. Thomas L. Friedman kò purọ́ nígbà tó sọ pé, “kò ṣòro rárá láti rí àwọn ìsọfúnni tó lè kó ẹ sí wàhálà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Bó o bá ṣe ń já sí ibi tí Hitler ti ń ṣe ìpàdé bó ṣe máa já ìjọba gbà, ni wàá máa já síbi táwọn nǹkan arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè pẹ̀kun sí, . . . o ò sì ní í rí ẹnì kankan nítòsí rẹ láti kì ọ́ nílọ̀ tàbí tọ́ ẹ sọ́nà.”

Iṣẹ́ kékeré sì kọ́ ni tẹlifíṣọ̀n àti fíìmù ń ṣe láti yí àwọn èèyàn lérò padà. Ìlú Hollywood ni ọ̀pọ̀ fíìmù tí wọ́n ń wò lágbàáyé ti ń wá, ibẹ̀ sì ni ọgbọ́n tí wọ́n fi ń yí èèyàn lérò padà pẹ̀kun sí. Àwọn ohun tí àwọn iléeṣẹ́ ńlá tó ń dá àwọn èèyàn lára yá yìí máa ń gbé jáde sábà máa ń gbé ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì, ìwà ipá àti ìṣekúṣe lárugẹ. Èyí sí lè jẹ́ òdìkejì pátápátá sí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè láyé. Síbẹ̀, kò ṣeé ṣe fáwọn ìjọba, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n àtàwọn òbí láti dáwọ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí dúró.

Ẹnì kan tó ń gbé nílùú Havana, ní orílẹ̀-èdè Cuba sọ fún àlejò kan tó wá láti Àríwá Amẹ́ríkà pé: “A fẹ́ràn bí àwọn ará Amẹ́ríkà ṣe máa ń ṣe gan-an. Gbogbo àwọn òṣèré jànkànjànkàn yín ní Hollywood [la] mọ̀.” Àwọn òyìnbó tún máa ń nífẹ̀ẹ́ sí oúnjẹ oní-pá-pà-pá àti ọtí ẹlẹ́rìdòdò. Oníṣòwò kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Malaysia sọ pé: “Àwọn èèyàn wa níbí nífẹ̀ẹ́ sí ohunkóhun tó bá sáà ti jẹ mọ́ ti òyìnbó, pàápàá tó bá jẹ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà ló ti wá. . . . Oúnjẹ òyìnbó ni wọ́n máa ń fẹ́ jẹ wọ́n sì máa ń fẹ́ ṣe bí àwọn òyìnbó ṣe ń ṣe.” Ẹni tó jẹ́ ọ̀gá ní Yunifásítì kan ni ìlú Havana fìbànújẹ́ sọ pé: “Cuba kì í tún ṣe erékùṣù tó dá wà mọ́. Kò tiẹ̀ sóhun tó ń jẹ́ Erékùṣù mọ́. Ayé ti lu jára.”

Àṣà àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé tó ń ràn bí iná ọyẹ́ ti ń ṣàkóbá fún ìrètí àwọn èèyàn àti ohun tí wọ́n fẹ́ o. Ìwé pẹlẹbẹ náà, Human Development Report 1998 sọ pé: “‘Ọpọ́n àṣà pé káwọn èèyàn máa sáré kìràkìtà láti ní gbogbo ohun táwọn aládùúgbò wọn ní’ ti sún síwájú báyìí o, eré kí wọ́n lè dà bí àwọn olówó àtàwọn èèyàn gbígbajúmọ̀ tí wọ́n ń rí nínú sinimá àti lórí tẹlifíṣọ̀n ló kù tí wọ́n ń sá báyìí.” Àmọ́ òótọ́ tó dájú ni pé, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn èèyàn lọwọ́ wọn ò lè tẹ irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ láéláé.

Ṣé Ètò Sayé Dọ̀kan Ló Máa Yanjú Ìṣòro Wa?

Ètò sayé dọ̀kan yìí kò yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ ètò táráyé ti ń ṣe, bó ṣe ní àwọn àǹfààní ló tún ní àwọn àbùkù. Ó ti jẹ́ káwọn kan rí tajé ṣe, ó sì ti mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo ayé láti lè bára wọn sọ̀rọ̀. Àmọ́ àwọn tó lówó àtàwọn tó nípò ló ń jàǹfààní ẹ̀, kò dé ọ̀dọ̀ àwọn mẹ̀kúnnù àtàwọn akúṣẹ̀ẹ́. Àwọn ọ̀daràn àtàwọn àrùn lóríṣiríṣi kò ṣàì gbá àǹfààní ayé tó lu jára yìí mú, kódà wọ́n tiẹ̀ mọ àǹfààní ọ̀hún lò ju ìjọba lọ.—Wo àwọn àpótí tó wà lójú ìwé 20 àti 21.

Kì í ṣe ọ̀nà kékeré ni sísọ ayé dọ̀kan gbà sọ àwọn ìṣòro tó ti wà tẹ́lẹ̀ di èyí tó gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ o. Dípò kó yanjú àwọn ìṣòro inú ayé, ńṣe lòun náà tún di ara wọn. Ìpínyà tó wà láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ti fẹjú sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìbànújẹ́ sì ń pọ̀ sí i láwùjọ ẹ̀dá. Àwọn ìjọba tó wà káàkiri ayé ń jẹ adùn tí sísọ ayé dọ̀kan ń mú wá àmọ́ wọ́n ń dáàbò bo àwọn èèyàn wọn, wọn ò fẹ́ kí wọ́n fara kááṣá àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ rẹ̀. Ṣé wọ́n lè rí ìyẹn ṣe? Ṣé táráyé bá bẹ̀rẹ̀ sí í láàánú ọmọnìkejì wọn, ṣé wọ́n á ṣàṣeyọrí? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e á tú àwọn ìbéèrè yìí yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́.

[Àwọn àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

ÌWÀ Ọ̀DARÀN ÀTI ÌPÁNILÁYÀ TI KÁRÍ AYÉ

Ó mà ṣe o, àṣé ohun tí wọ́n ní kó ṣèrànwọ́ kí ètò ọrọ̀ ajé lè tẹ̀ síwájú tún lè para dà kó di irinṣẹ́ ìwà ọ̀daràn. Ìwé pẹlẹbẹ náà, Human Development Report 1999 sọ pé: “Bí àwọn àjọ olókòwò ńláńlá tó ní ẹ̀ka ní onírúurú orílẹ̀-èdè ti ń tiraka pé kí ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé lè di ọ̀kan, àwọn ‘ẹgbẹ́ ọ̀daràn’ náà kò jáfara, kíá ni wọ́n ti gbá àǹfààní ayé tó lu jára yìí mú.” Ọ̀nà wo ni àwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn ti gbà jàǹfààní nínú ètò sayé dọ̀kan?

Àìmọye ọ̀nà tuntun làwọn tó ń ṣòwò oògùn olóró lágbàáyé ti jágbọ́n rẹ̀ báyìí láti rí i pé àwọn èèyàn kò fura sí èrè àìmọye bílíọ̀nù dọ́là tí wọ́n ń jẹ. Bí ìjọba tún ṣe gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí àwọn òfin ẹnubodè kan àti bí àwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń rìnrìn àjò láti ibì kan sí ibòmíràn ti mú kó rọrùn púpọ̀ fáwọn tó ń ṣòwò oògùn olóró láti kó àwọn oògùn tí kò bófin mú láti orílẹ̀-èdè kan lọ sí òmíràn. Tá a bá kíyè sí i, láàárín àwọn ọdún 1990, oògùn olóró kokéènì tí wọ́n ń ṣe jáde wọ ìlọ́po méjì, tí oògùn olóró tí wọ́n ń pè ní opium sì di ìlọ́po mẹ́ta. Àwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn paraku tún ti dá òwò iṣẹ́ aṣẹ́wó sílẹ̀ lágbàáyé, èyí tó ń mú owó tabua wọlé fún wọn. Lọ́dọọdún, àwọn obìnrin tí wọ́n ń kó wọ Ìwọ Oòrùn Yúróòpù láti lò fún iṣẹ́ aṣẹ́wó tó ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000], èyí tó sì pọ̀ jù lọ lára àwọn obìnrin yìí ni kì í ṣe pé ó wù wọ́n láti gbégbá aṣẹ́wó.

Bíi tàwọn àjọ olókòwò ńláńlá tí ẹ̀ka wọn wà káàkiri ayé, àwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn náà ti ń pawọ́ pọ̀ báyìí kí agbára wọn lè pọ̀ sí i. Ọ̀pọ̀ wọn ló jẹ́ pé kò síbi tí iṣẹ́ wọn kì í dé lágbàáyé. Tá a bá sì pa iye tí wọ́n ń rí lọ́dún pọ̀, ó ju àpapọ̀ owó tó ń wọlé fún orílẹ̀-èdè Faransé lọ́dún lọ. a

Irinṣẹ́ gidi ni Íńtánẹ́ẹ̀tì tún jẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó mọ̀ nípa kọ̀ǹpútà dáadáa àmọ́ tí wọ́n jẹ́ oníṣẹ́ ibi. Ní ọdún 1995, ẹnì kan tó máa ń fọgbọ́n jí ìsọfúnni nínú kọ̀ǹpútà àwọn ẹni ẹlẹ́ni jí ìsọfúnni tá a gbọ́ pé owó rẹ̀ tó mílíọ̀nù kan dọ́là, ó tún jí àwọn nọ́ńbà káàdì táwọn èèyàn fi ń rajà àwìn tó tó ọ̀kẹ́ kan [20,000]. José Antonio Soler, òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ kan ní Sípéènì sọ pé: “Olè tí wọ́n ń fi ìmọ̀ ẹ̀rọ jà kò fi bẹ́ẹ̀ la ewu lọ, èrè gọbọi ni wọ́n sì ń rí níbẹ̀.”

Àwọn apániláyà náà ò kẹ̀rẹ̀ nínú lílo àwọn ohun tí ètò sayé dọ̀kan mú jáde. Níwọ̀n bí kò ti síbi tí ìròyìn kì í dé láyé, tí wọ́n bá jí àwọn ará Ìwọ Oòrùn ayé kan gbé láwọn ibi jíjìnnà tí wọ́n rìnrìn àjò afẹ́ lọ, kíá ni gbogbo ayé á ti mọ̀ pé àwọn kan ń bínú sáwọn ìjọba wọn ni.

“ÀWỌN ARÌNRÌN-ÀJÒ” TÁ Ò FẸ́

Bíi ti àwọn èèyàn làwọn àrùn náà ṣe ń rìnrìn àjò kiri àgbáyé, àwọn kan lára wọn sì ń gbẹ̀mí èèyàn. Ọ̀jọ̀gbọ́n Jonathan M. Mann tó mọ̀ nípa àjàkálẹ̀ àrùn dáadáa sọ pé: “Bí àwọn èèyàn, ọjà, àti ìrònú ṣe ń lọ láti ibì kan sí ibòmíràn lọ́nà bíbùáyà ni olórí ohun tó ń jẹ́ kí àrùn tàn kálẹ̀. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ayé ti wá di ibi tí onírúurú àrùn ti ń yọjú, èyí tó sì burú jù ni bí àwọn àrùn tuntun àtàwọn tó ti pẹ́ ṣe ń pọ̀ sí i tó sì ń tàn kálẹ̀.”

Kò tún sí ohun mìíràn tó jẹ́ ká mọ̀ pé ayé ti di ibi tí àìsàn ti ń yára tàn kálẹ̀ tó àrùn Éèdì tó ti di àjàkáyé. Ní báyìí, àwọn tí àrùn náà ń gbẹ̀mí wọn lọ́dún tó mílíọ̀nù mẹ́ta. Láwọn orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà, ńṣe lẹ̀rù ń ba àwọn olùtọ́jú aláìsàn pé ìdá méjì nínú mẹ́ta gbogbo àwọn ọ̀dọ́ wọn, lọ́kùnrin àti lóbìnrin ni àìsàn yìí máa pa. Ìròyìn Ètò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Nípa Kòkòrò Tó Ǹ Fa Àrùn Éèdì sọ pé: “Yàtọ̀ sí pé ẹgbẹ̀rúndún yìí kún fún àjàkálẹ̀ àrùn, ogun àti ebi, kò tíì sígbà kan nínú ìtàn tí ikú ọ̀dọ́ pọ̀ tó báyìí.”

Àrùn nìkan kọ́ ni “arìnrìn-àjò” tá ò ránṣẹ́ pè tó ń káàkiri ayé o. Àwọn ẹranko, irúgbìn, àtàwọn kòkòrò pẹ̀lú ti fi ibi tí Ọlọ́run dá wọn sí sílẹ̀ wọ́n sì ti forí lé àwọn kọ́ńtínẹ́ǹtì mìíràn. Irú ọ̀wọ́ ejò olóró kan láti ilẹ̀ Ọsirélíà ti lọ sọ àwọn Erékùṣù Pàsífíìkì di ibùgbé o, ó sì dájú pé ó rá pálá wọnú ọkọ̀ òfuurufú débẹ̀ ni. Lọ́wọ́lọ́wọ́, gbogbo àwọn ẹyẹ inú igbó ilẹ̀ Guam ló ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa jẹ tán. Òṣíbàtà kan tí wọ́n mú wá láti Gúúsù Amẹ́ríkà ti tàn dé àádọ́ta orílẹ̀-èdè ilẹ̀ olóoru, bó ṣe ń dí àwọn ipadò ló tún ń pa àwọn ẹja inú adágún odò run. Ìwé ìròyìn International Herald Tribune sọ pé: “Owó tí àwọn ‘àjèjì’ tó ń ṣèparun yìí ń ná aráyé kò dín sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún bílíọ̀nù dọ́là lọ́dún. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń tan àrùn kálẹ̀, òfò kékeré sì kọ́ ni wọ́n ń ṣe fún àwọn ohun alààyè àti àyíká.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Àpapọ̀ owó tó ń wọlé” túmọ̀ sí gbogbo iye tí orílẹ̀-èdè kan ń rí lọ́dún látinú ọjà tí wọ́n tà tàbí iṣẹ́ tí wọ́n ṣe.

[Àwọn àwòrán]

GBÍGBÉ OWÓ LÁTI ORÍLẸ̀-ÈDÈ KAN LỌ SÍ ÒMÍRÀN LÁÌBÓFINMU

Inú ẹrù nǹkan ìṣeré ọmọdé ni wọ́n ti rí i

ṢÍṢE FÀYÀWỌ́ OÒGÙN OLÓRÓ KOKÉÈNÌ

Kokéènì tówó ẹ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́rin dọ́là tí wọ́n rí nínú ọkọ̀ afẹ́ kan tí wọ́n gbà ní ẹnubodè

LÍLO KÒKÒRÒ ÀRÙN FÚN ÌPÁNILÁYÀ

Àwọn sójà ń wá kẹ́míkà tí wọ́n fi kòkòrò àrùn anthrax ṣe ní Òkè Capitol, ní ìlú Washington, D.C.

BỌ́ǸBÙ JÍJÙ

Ọ̀kọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan tí bọ́ǹbù wà nínú rẹ̀ bú gbàù nílẹ̀ Ísírẹ́lì

ÀRÙN ÉÈDÌ GBAYÉ KAN

Àjàkálẹ̀ àrùn éèdì ti wá kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ ní Gúúsù Áfíríkà báyìí, débi pé ńṣe làwọn ọsibítù ìjọba kan ń dá àwọn èèyàn padà nítorí àìsí àyè

ÀWỌN OHUN ABẸ̀MÍ Ń ṢÈPARUN

Irú ọ̀wọ́ ejò kan tó máa ń gbé lórí igi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ gbogbo ẹyẹ inú igbó tán ní erékùṣù Guam

OṢÍBÀTÀ

Ewéko yìí ń dí àwọn ipadò ó sì ti gba àwọn etídò mọ́ àwọn èèyàn lọ́wọ́ ní nǹkan bí àádọ́ta orílẹ̀-èdè

[Àwọn Credit Line]

Owó àti kokéènì tí wọ́n ṣe fàyàwọ́ rẹ̀: James R. Tourtellotte àti Todd Reeves/U.S. Customs Service; lílo kòkòrò àrùn fún ìpániláyà: Fọ́tò AP/Kenneth Lambert; ọkọ̀ tó ń jóná: Fọ́tò AP/HO/Àwọn Ọmọ Ogun Olùdáàbòbò ní Ilẹ̀ Ísírẹ́lì; ọmọ kékeré: Fọ́tò AP/Themba Hadebe; ejò: Fọ́tò tí T. H. Fritts yà, USGS; oṣíbàtà: Staff CDFA, California Dept. of Food & Agriculture, Integrated Pest Control Branch

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ètò ọ̀rọ̀ ajé àgbáyé ti túbọ̀ fa ìyàtọ̀ púpọ̀ gan-an láàárín àwọn olówó àtàwọn tálákà

[Credit Line]

FỌ́TÒ UN 148048/ J. P. Laffont - SYGMA

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Wọ́n ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì láti mú ìwà ìpániláyà pọ̀ sí i