Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Àgbáálá Ayé àti Ìwàláàyè Ṣe Bẹ̀rẹ̀?

Báwo Ni Àgbáálá Ayé àti Ìwàláàyè Ṣe Bẹ̀rẹ̀?

Báwo Ni Àgbáálá Ayé àti Ìwàláàyè Ṣe Bẹ̀rẹ̀?

“Sáyẹ́ǹsì ò lè dá ohunkóhun ṣe láìsí ìsìn, ìsìn náà ò lè ta pútú láìsí sáyẹ́ǹsì.”—Albert Einstein.

ÀKÓKÒ tá a wà yìí làwọn ohun àràmàǹdà tí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí ń ṣẹlẹ̀. Àwọn àwárí tuntun táwọn onímọ̀ nípa sánmà ń ṣe nípa gbalasa òfuurufú ti mú kí wọ́n máa yí èrò tí wọ́n ní nípa bí ọ̀run òun ayé ṣe pilẹ̀ṣẹ̀ padà. Ayé òun ọ̀run tó wà létòlétò ń wú ọ̀pọ̀ èèyàn lórí púpọ̀, ìdí rèé tí wíwà tá a wà láàyè fi mú kí wọ́n máa béèrè ìbéèrè ọlọ́jọ́ pípẹ́ náà pé: Báwo la ṣe dá ayé òun ọ̀run, kí ló sì fà á tá a fi dá wọn?

Ó dáa, ẹ jẹ́ ká pa ti ayé òun ọ̀run tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan ná, ká wá wo ara àwa ẹ̀dá èèyàn. Àwárí kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí nípa ohun tó pilẹ̀ àbùdá èèyàn ti mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí béèrè pé: Báwo la ṣe dá ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ohun tó ń mú kí ohun ẹlẹ́mìí lè wà láàyè? Tó bá sì jẹ́ pé ẹnì kan ló ṣẹ̀dá wọn, ta lẹni ọ̀hún? Dídíjú tí èròjà inú àbùdá wa díjú púpọ̀ yìí ló mú kí ààrẹ kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé “a ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ nípa àwọn èròjà inú àbùdá tí Ọlọ́run fi dá àwọn ohun alààyè.” Ọ̀kan lára àwọn ọ̀gá onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó wà lára àwọn tó ń ṣàwárí ohun tó pilẹ̀ àbùdá fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ sọ pé: “A ti ṣàwárí ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn ìsọfúnni tó dà bí ẹnà nínú àbùdá wa tó jẹ́ pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló mọ èyí tẹ́lẹ̀.” Àmọ́ ìbéèrè náà ṣì wà nílẹ̀ o, pé báwo la ṣe dá àwọn ohun alààyè kí sì nìdí tá a fi dá wọn?

“Fèrèsé Méjì”

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sọ pé èèyàn kàn lè dìde fùú kó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé gbogbo nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ayé òun ọ̀run láìfi ti ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ṣe. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn, tó fi dórí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì pàápàá ni kò fara mọ́ yẹn. Wọ́n ń sapá láti mọ ohun tó jẹ́ ògidì òtítọ́, èyí ló mú kí wọ́n máa ṣàyẹ̀wò ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìsìn. Èrò wọn ni pé sáyẹ́ǹsì ní tirẹ̀ ń ṣàlàyé nípa bí ìwàláàyè, ayé àti ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀, nígbà tí ìsìn ń ṣàlàyé ìdí tá a fi dá àwọn nǹkan wọ̀nyí.

Nígbà tí onímọ̀ físíìsì náà, Freeman Dyson, ń ṣàlàyé nípa ọ̀nà méjèèjì yìí, ó sọ pé: “Sáyẹ́ǹsì àti ìsìn jẹ́ fèrèsé méjì táwọn èèyàn gbà ń wo ayé òun ọ̀run láti lóye rẹ̀.”

Òǹkọ̀wé William Rees-Mogg, sọ pé: “Àwọn nǹkan tó ṣeé díwọ̀n ni sáyẹ́ǹsì ń ṣàlàyé nígbà tí ìsìn ń ṣàlàyé àwọn ohun tí kò ṣeé díwọ̀n.” Ó sọ pé: “Sáyẹ́ǹsì kò lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ọlọ́run wà tàbí pé Ọlọ́run kò sí, lọ́nà kàn náà tí kò lè gbà sọ pé àwọn ohun kan jẹ́ àdámọ́ tàbí àtọwọ́dá. Kò sí ohunkóhun tó kan sáyẹ́ǹsì nípa pé kéèyàn nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ̀ tàbí kó bọ̀wọ̀ fún ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn . . . Bákan náà, àṣìṣe ńlá gbáà ló máa jẹ́ láti gbà pé bí sáyẹ́ǹsì kò bá ti lè fìdí ohun kan múlẹ̀, a jẹ́ pé ohun náà kò sí nìyẹn, èyí á sì túmọ̀ sí pé ká pa gbogbo ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí nígbèésí ayé tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nìyẹn. Bó bá sì rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé àfi ká pa Ọlọ́run, ọgbọ́n orí èèyàn, ìfẹ́, ewì àti orín náà ti sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.”

Ìgbàgbọ́ Sáyẹ́ǹsì

Lọ́pọ̀ ìgbà, ó dà bí ẹni pé àbá àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì máa ń dá lórí àwọn abàmì ìgbàgbọ́ kan. Bí àpẹẹrẹ, ní ti ọ̀ràn bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀, èrò ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n béèrè pé kéèyàn nígbàgbọ́ nínú àwọn “ẹ̀kọ́” kan. Ńṣe ni wọ́n lú àwọn òkodoro òtítọ́ mọ́ àbá lásánlàsàn. Bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì bá sì fi agbára tó wà níkàáwọ́ wọn fúngun mọ́ àwọn èèyàn láti gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́, ohun tí wọ́n ń sọ ni pé: ‘Ọkàn rẹ kọ́ ni ìwà rere èyíkéyìí tó wù kó o hù ti wá nítorí pé ẹni kan lásánlàsàn táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun alààyè, nípa ẹ̀kọ́ kẹ́mísírì àti ẹ̀kọ́ físíìsì mú jáde ni ọ́.’ Richard Dawkins, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ohun alààyè sọ pé tá a bá wo ayé àtọ̀run, ‘kò sí ohun kan tó fi hàn pé a ṣètò rẹ̀, kò sí ohun tó fi hàn pé ó wà fún ète kan, kò sí ibi nínú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò sí ire, kò sí ohunkóhun níbẹ̀ gbogbo rẹ̀ kàn wà bọrọgidi ni.’

Káwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan bàa lè gbé irú ìgbàgbọ́ yìí lárugẹ, ohun tí wọ́n ṣe ni pé wọ́n pa àwọn ìwádìí àṣekára táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mìíràn ti ṣe tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, nítorí pé ìwádìí táwọn yẹn ṣe nípa bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀ ta ko tiwọn. Àní, kí àìmọye ọdún kọjá pàápàá, pé ńṣe làwọn ohun kéékèèké dídíjú tó mú kí ìwàláàyè ṣeé ṣe ṣèèṣì ṣẹlẹ̀ jẹ́ ohun tí kò lè rí bẹ́ẹ̀ láéláé. a Nítorí náà, a ò gbọ́dọ̀ ka àwọn àbá nípa bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀ táwọn kan kàn ṣàdédé gbé kalẹ̀ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé sí ohun tó tọ̀nà.

Láti gbà gbọ́ pé ìwàláàyè kàn ṣèèṣì bẹ̀rẹ̀ béèrè pé kéèyàn ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ ju èyí téèyàn á ní tó bá gbà gbọ́ pé ẹnì kan ló mú ìwàláàyè ṣeé ṣe. David Block, tó jẹ́ onímọ̀ nípa sánmà sọ pé: “Ẹni tí kò bá gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá wà gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ tó ju ti ẹni tó gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá wà lọ. Bí ẹnì kan bá sọ pé Ọlọ́run kò sí, ọ̀rọ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ló ń sọ, bẹ́ẹ̀ sì rèé orí ìgbàgbọ́ kan ni èyí náà dá lé.”

Àwọn àwárí sáyẹ́ǹsì lè mú káwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀. Albert Einstein sọ pé: “Láàárín àwọn àgbà onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, ó ṣòro láti rí ẹnì kan lára wọn tí kò lẹ́mìí ìsìn. . . . Ohun tó ń mú kéèyàn ní ẹ̀mí ìsìn yìí ni bí ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn òfin àdánidá ṣe máa ń ṣèèyàn ní kàyéfì nítorí ó fi hàn pé ẹnì kan tó ní làákàyè ju ẹ̀dá lọ ló wà nídìí rẹ̀. Tá a bá sì fi irú làákàyè ẹni yìí wéra pẹ̀lú ọ̀nà tí ẹ̀dá èèyàn gbà ń ronú àti bí wọ́n ṣe ń hùwà, a óò rí i pé ẹ̀dá èèyàn kò já mọ́ ohunkóhun.” Síbẹ̀ náà, gbogbo ẹ̀mí ìsìn táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń ní yìí kò tí ì fi dandan ní kí wọ́n gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá kan wà, ìyẹn Ọlọ́run.

Ibi Tí Agbára Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Mọ

Kò dára ká kóyán ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn àṣeyọrí tó ti ṣe kéré. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa gbà pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé sáyẹ́ǹsì jẹ́ ọ̀nà kan téèyàn fi ń mọ nǹkan, kì í ṣe òun nìkan ni orísun ìmọ̀. Ohun tí sáyẹ́ǹsì wà fún ni pé kó jẹ́ ká mọ àwọn ohun àràmàǹdà tó wà láyé kó sì ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tó fa àwọn ohun àràmàǹdà yìí.

Sáyẹ́ǹsì jẹ́ ká túbọ̀ lóye tó jinlẹ̀ nípa àgbáálá ayé tá a lè fojú rí, ìyẹn gbogbo nǹkan téèyàn lè mọ̀. Àmọ́ bó ti wù kí àwọn ìwádìí sáyẹ́ǹsì jinlẹ̀ tó, kò lè dáhùn àwọn ìbéèrè nípa ohun náà gan-an tó mú ká dá ayé òun ọ̀run.

Òǹkọ̀wé Tom Utley, sọ pé: “Àwọn ìbéèrè kan wà táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò lè dáhùn láéláé. Ó lè jẹ́ pé nǹkan bíi bílíọ̀nù méjìlá ọdún sẹ́yìn ni Ìbúgbàù Ńlá tí wọ́n lóun ló mú ayé àti ọ̀run wá ṣẹlẹ̀. Àmọ́ kí ló mú kó ṣẹlẹ̀? . . . Báwo làwọn ohun tó wá bú gbàù náà ṣe débẹ̀? Kí ló wà níbẹ̀ káwọn ohun tó bú gbàù náà tó débẹ̀?” Utley parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ó dà bí ẹni pé . . . ó ti wá ṣe kedere báyìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ pé sáyẹ́ǹsì kò lè fún ẹ̀dá èèyàn ní ìdáhùn tó máa tẹ́ wọn lọ́rùn láéláé.”

Gbogbo ìmọ̀ tí irú àwọn ìbéèrè wọ̀nyí fúnni kò ti èrò náà lẹ́yìn pé kò sí Ọlọ́run o, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló túbọ̀ ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ayé tá à ń gbé yìí díjú púpọ̀púpọ̀, pé ó ṣòro láti ṣàlàyé ó sì ń múni kún fún ẹ̀rù. Àwọn èèyàn tó mọnúúrò ti rí i pé ohun tó dára ni láti parí èrò sí pé ńṣe làwọn òfin tó ń ṣàkóso àwọn ohun tá a lè fojú rí, báwọn kẹ́míkà ṣe ń yí padà, ásíìdì DNA àti onírúurú ohun alààyè tí wọ́n jẹ́ àgbàyanu ń fi hàn pé Ẹlẹ́dàá kan wà. Kò sí ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ pé kò sí Ẹlẹ́dàá.

‘Ojúlówó Ìgbàgbọ́’

Tó bá jẹ́ pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó dá ayé òun ọ̀run, kò yẹ ká ronú pé a lè mọ̀ ọ́n ká sì mọ àwọn ète rẹ̀ nípa lílo awò-awọ̀nàjíjìn, awò amúǹkantóbi tàbí àwọn ohun èlò sáyẹ́ǹsì mìíràn. Ìwọ wo amọ̀kòkò kan tó ti mọ àgé òdòdó kan kalẹ̀. Kò síye àyẹ̀wò téèyàn lè ṣe láyé yìí nípa àgé òdòdó náà tó lè mú kéèyàn mọ ìdí tí ẹni tó ṣe é fi ṣe é. Tá a bá fẹ́ mọ̀ ìdí tí wọ́n fi ṣe é, ẹni tó ṣe é gan-an la máa bi léèrè.

Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè, Francis Collins, sọ̀rọ̀ nípa bí ìgbàgbọ́ àti jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí ṣe lè ṣe àwọn ohun tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kò lè ṣe. Ó sọ pé: “Mi ò gbà pé ìsìn ni ohun tó tọ́ láti fi ṣàlàyé ohun tó pilẹ̀ àbùdá èèyàn, bẹ́ẹ̀ sì ni mi ò gbà pé sáyẹ́ǹsì ni ọ̀nà tó tọ́ láti wá ìmọ̀ nípa àwọn ohun tó ju ti ẹ̀dá lọ. Àmọ́ nípa tàwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì gan-an, irú bíi ‘Kí la wá ṣe nílé ayé?’ tàbí ‘Èé ṣe tí ẹ̀dá èèyàn fi nífẹ̀ẹ́ sí nǹkan tẹ̀mí?,’ Mo rí i pé sáyẹ́ǹsì kò ní ìdáhùn gidi kan sí àwọn ìbéèrè yìí. Ọ̀pọ̀ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán làwọn èèyàn ti ní, àwọn ìgbàgbọ́ yìí sì di ohun ìgbàgbé bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. Àmọ́ ìgbàgbọ́ kò tí ì di ohun ìgbàgbé o, èyí tó fi hàn pé ojúlówó ìgbàgbọ́ wà.”

Ṣíṣàlàyé Bí Àgbáálá Ayé àti Ìwàláàyè Ṣe Bẹ̀rẹ̀

Bí ìsìn tòótọ́ ṣe ń dáhùn ìbéèrè nípa ìdí tá a fi ṣẹ̀dá wa tó sì ń ṣàlàyé ète ìgbésí ayé náà ló tún ń sọ fún wa nípa ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere, ìwà ọmọlúwàbí, ìlànà ìwà híhù àti ìtọ́sọ́nà nínú ìgbésí ayé. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì náà Allan Sandage, sọ pé: “N kì í ka ìwé tó ń sọ nípa àwọn ohun alààyè kí n tó mọ bó ṣe yẹ kí n gbé ìgbésí ayé mi.”

Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn káàkiri àgbáyé rí i pé àwọn ti mọ ibi táwọn ti lè kọ́ nípa bó ṣe yẹ káwọn gbé ìgbésí ayé àwọn. Wọ́n tún ti rí i pé àwọn ti rí ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn sáwọn ìbéèrè bíi: Kí la wá ṣe nílé ayé? Kí ló ń bẹ fún wa lọ́jọ́ iwájú? Ìdáhùn kúkú ń bẹ sáwọn ìbéèrè yìí. Àmọ́ ibo ló wà? Inú ìwé mímọ́ tó lọ́jọ́ lórí jù lọ tá a sì tíì pín káàkiri jù lọ, ìyẹn Bíbélì ló kúkú wà.

Bíbélì sọ fún wa pé tìtorí ẹ̀dá èèyàn gan-an ni Ọlọ́run ṣe ṣètò ilẹ̀ ayé. Ìwé Aísáyà 45:18 sọ nípa ilẹ̀ ayé pé: “Ọlọ́run . . . kò wulẹ̀ dá a lásán, [ṣùgbọ́n] ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” Ó tún pèsè gbogbo nǹkan téèyàn máa nílò lórí ilẹ̀ ayé fún wọn. Ó fẹ́ kí wọ́n gbádùn ìgbésí ayé wọn dọ́ba kì í ṣe pé kí wọ́n kàn wà láàyè lásán.

A fún ẹ̀dá èèyàn níṣẹ́ láti máa ṣe lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn “láti máa ro ó àti láti máa bójú tó o.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:15) Bíbélì tún sọ pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìmọ̀ àti òye jẹ́ àti pé a gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ àti àìṣègbè bá ara wa lò. (Jóòbù 28:20, 25, 27; Dáníẹ́lì 2:20-23) Nítorí náà, ohun tó lè jẹ́ kí ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn nítumọ̀ ni pé kí wọ́n mọ ohun tó jẹ́ ète Ọlọ́run fún wọn kí wọ́n sì fara mọ́ ọn. b

Báwo wá ni àwọn tó mọnúúrò ṣe lè dí àlàfo tó wà láàárín ọ̀nà táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń gbà ronú àti ìgbàgbọ́ àwọn ẹlẹ́sìn? Àwọn ìlànà atọ́nisọ́nà wo ló lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo orí 3 nínú ìwé Is There a Creator Who Cares About You?, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde, lábẹ́ àkòrí náà “What Is the Origin of Life?” [Ibo Ni Ìwàláàyè Ti Bẹ̀rẹ̀?]

b Fún ìjíròrò ní kíkún, wo ìwé pẹlẹbẹ náà Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ohun Táwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Kan Sọ

Àwọn èèyàn kan gbà pé ohun tó fà á tí ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kì í fi í fẹ́ dá sọ́ràn tó bá jẹ mọ́ nǹkan tẹ̀mí tàbí ti ẹlẹ́sìn-índé ni pé, wọn ò fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn tàbí kó jẹ́ pé wọn ò fẹ́ lọ́wọ́ nínú àríyànjiyàn nípa ọ̀rọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìsìn. Ìyẹn fi báwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ṣe rí hàn, àmọ́ kì í ṣe gbogbo wọn ló rí bẹ́ẹ̀ ṣá o. Wo ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì wọ̀nyí sọ.

“Ayé òun ọ̀run ní ìbẹ̀rẹ̀ àmọ́ ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò lè ṣàlàyé ni bó ṣe rí bẹ́ẹ̀. Ìdáhùn ibẹ̀ ni pé Ọlọ́run ló ṣe é.” “Mo ka Bíbélì sí ìwé tòótọ́ tí Ọlọ́run mí sí. Ẹnì kan tó ní làákàyè ló gbọ́dọ̀ wà nídìí ọ̀ràn ìwàláàyè, èyí tó díjú gan-an.”—Ken Tanaka, ògbógi ní ẹ̀ka Ìwádìí Nípa Ilẹ̀ Ayé àti Ohun Tó Wà Nínú Rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà

“Ẹ̀dá èèyàn ló fa ìyàtọ̀ tó wà láàárín oríṣi ìmọ̀ tó wà láyé (ti sáyẹ́ǹsì àti ti ẹ̀sìn). . . . Ìmọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá àti ìmọ̀ nípa ìṣẹ̀dá bára mu dáadáa.”—Enrique Hernández, ọ̀jọ̀gbọ́n ni, ó sì tún jẹ́ olùwádìí ní Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Físíìsì àti Kẹ́mísìrì ní Yunifásítì National Autonomous ní Mẹ́síkò.

“Àwọn ìsọfúnni [nípa ohun tó pilẹ̀ àbùdá èèyàn] tá a túbọ̀ ń wádìí rẹ̀ yìí á jẹ́ ká mọ bó ṣe díjú tó àti bí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Ó máa jẹ́ ká mọ̀ pé ọlọ́gbọ́n tó lóye lẹni tó ṣẹ̀dá rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀, pé ẹni náà lóye púpọ̀ púpọ̀.”—Duane T. Gish, onímọ̀ nípa àwọn kẹ́míkà inú ohun abẹ̀mí.

“Sáyẹ́ǹsì àti ìsìn kò kọ̀yìn síra wọn o. Òtítọ́ kan náà làwọn méjèèjì ń gbìyànjú láti mọ̀. Sáyẹ́ǹsì fi hàn pé Ọlọ́run ń bẹ.”—D.H.R. Barton, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìmọ̀ kẹ́mísìrì ní Texas.

[Àwọn Credit Line]

NASA/U.S. Geological Survey

Fọ́tò: www.comstock.com

NASA àti The Hubble Heritage Team (STScI/AURA)

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ǹjẹ́ àwọn ìwádìí tí a tipasẹ̀ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe lè dáhùn ìbéèrè nípa ohun tá a wá ṣe nílé ayé?

[Credit Line]

Lọ́lá àṣẹ Arecibo Observatory/David Parker/Science Photo Library

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn ìràwọ̀ tó wà lójú ìwé 2, 3, 5, àtèyí tó wà lókè lójú ìwé 7: National Optical Astronomy Observatories