Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Rí Alábàágbé Tó Dára?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Rí Alábàágbé Tó Dára?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Rí Alábàágbé Tó Dára?

“Ká ní kì í ṣe pé mo ní àwọn tá a jọ ń gbé yàrá ni, mi ò ní lè sìn bí alákòókò kíkún kí n sì máa sanwó ilé àtàwọn owó mìíràn tó yẹ ní sísan.”—Lynn. a

NÍGBÀ táwọn ọ̀dọ́ bá lọ gbé níbòmíràn, ìyàlẹ́nu gbáà ló sábà máa ń jẹ́ fún wọn láti rí i pé owó kékeré kọ́ lèèyàn ń ná tó bá dẹni tó ń dá gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Fún èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn, kò sí ọ̀nà mìíràn tí wọ́n lè gbà san owó gọbọi tó yẹ ní sísan ju pé kí wọ́n ní ẹnì kan tàbí méjì tí wọ́n á jọ máa gbé.

Àmọ́ o, gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó ṣáájú nínú ọ̀wọ́ yìí ti jẹ́ ká mọ̀, ìṣòro díẹ̀ kọ́ ni bíbá ẹlòmíràn gbé máa ń fà o, àgàgà tó bá lọ jẹ́ ẹni téèyàn ò mọ̀ tẹ́lẹ̀. b Kódà, ìṣòro máa ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni pàápàá, tí wọ́n jọ ń gbé pọ̀ kí wọ́n lè máa sìn bí ajíhìnrere alákòókò kíkún. Ohun yòówù kó fà á tó o fi fẹ́ máa bá èèyàn gbé, á dára kó o lo “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́” nígbà tó o bá ń yan ẹni yẹn. cÒwe 3:21.

Ewu Tí Ẹgbẹ́ Búburú Ń Kóni Sí

Ara pátákó ìsọfúnni, àwọn ìpolówó nínú ìwé ìròyìn tàbí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ máa ń yíjú sí láti wá ẹni tí wọ́n lè bá gbé. Àmọ́ ní ti àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni, irú àwọn ibi wọ̀nyí lè kó wọn sínú ewu ńláǹlà. Kò sọ́gbọ́n tí wọn ò fi ní bá àwọn èèyàn tí ìgbàgbọ́ wọn, ìwà wọn àti ìlànà wọn yàtọ̀ sí tiwọn pàdé. Ṣé pé ìwà tèmi-yé-mi tàbí yíya ara ẹni láṣo ló ń yọ ẹni kan lẹ́nu tó bá sọ pé kìkì ẹni tí wọ́n jọ wà nínú ìsìn kan náà ni òún fẹ́ bá gbé? Rárá o, ìwà tó bọ́gbọ́n mu ni. Bíbélì fúnra rẹ̀ kìlọ̀ pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”—1 Kọ́ríńtì 15:33.

Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Lee. Kò tíì di Kristẹni tó ṣèrìbọmi nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ni yàrá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni Yunifásítì kan. Ó sọ pé: “Ibẹ̀ kì í ṣe ibiire rárá. Táwọn ọmọbìnrin míì bá dé yàrá báyìí, ńṣe ni wọ́n á bá alábàágbé wọn tóun àtọkùnrin ń bára wọn sùn.” Kò pẹ́ kò jìnnà, gbígbé níbẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kó bá ipò tẹ̀mí Lee. Ó sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn ìpàdé Kristẹni jẹ.” Abájọ tí ìwà rẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí dìdàkudà. Ó ní: “Lọ́jọ́ kan, ńṣe ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣépè, ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin náà bá sọ fún mi pé: ‘Ṣé Jèhófà ní kó o máa ṣépè?’” Ẹ ò rí i pé nǹkan ìtìjú gbáà nìyẹn! Ọlọ́run bá Lee ṣe é, ó kó jáde kúrò láàárín àwọn èèyànkéèyàn tó ń bá gbé ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i yìí fi hàn bí ewu tó wà nínú gbígbé pẹ̀lú àwọn tí kò tẹ́wọ́ gba ìlànà ẹni ṣe pọ̀ tó.

Bó O Ṣe Lè Rí Alábàágbé Tó Bójú Mu

Ibo wá lo lè yíjú sí? Bẹ̀rẹ̀ látinú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ò ń dara pọ̀ mọ́. Ó dùn mọ́ni pé, àwọn tó jẹ́ ajíhìnrere alákòókò kíkún sábà máa ń bá àwọn ọ̀dọ́ mìíràn táwọn náà nífẹ̀ẹ́ sí nǹkan tẹ̀mí pàdé láwọn ilé ìwé àti láwọn ìpàdé, pàápàá àwọn ìpàdé tí wọ́n ń ṣe fún àwọn oníwàásù alákòókò kíkún. d Àwọn òbí, àwọn alàgbà nínú ìjọ, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtàwọn mìíràn lè ṣèrànwọ́; wọ́n lè mọ àwọn ọ̀dọ́ kan tó máa dára láti bá gbé.

Sísọ fún àwọn mìíràn pé ò ń wá ẹni tí wàá máa bá gbé yàrá tún lè ṣèrànwọ́ púpọ̀púpọ̀. Bí àwọn tó o sọ fún bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ló máa ṣeé ṣe tó pé kó o rí ohun tó ò ń wá. (Oníwàásù 11:6) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, bẹ Jèhófà pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí ẹni tẹ́ ẹ máa lè jọ gbé yàrá, kó o sì gbára lé e pé kò ní jẹ́ kí akitiyan rẹ já sófo.—1 Jòhánù 5:14, 15.

Wádìí Àwọn Ohun Ṣíṣekókó

Tó o bá ti wá rí ẹnì kan tó ṣeé ṣe kó di alábàágbé rẹ, ara rẹ lè ti wà lọ́nà láti bẹ̀rẹ̀ sí í bá ẹni náà gbé ní kíákíá. Àmọ́ á dára kó o kọ́kọ́ wádìí àwọn nǹkan kan wò. Ṣé ẹni tí ‘àwọn ará ròyìn rẹ̀ dáadáa’ nínú ìjọ rẹ̀ ni ẹni náà? (Ìṣe 16:1, 2) Ìwọ àtàwọn òbí rẹ tiẹ̀ lè lọ bá àwọn tí wọ́n tóótun nípa tẹ̀mí tí wọ́n mọ ẹni náà dáadáa sọ̀rọ̀. O lè béèrè pé: ‘Irú èèyàn wo ni wọ́n mọ ẹni yìí sí? Ṣé ẹni tó máa ń rí ara gba nǹkan sí tó sì jẹ́ ẹni tẹ̀mí ni? Ṣé ó máa ń lọ wàásù fún àwọn mìíràn tó sì máa ń dáhùn ìbéèrè láwọn ìpàdé? Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sẹ́ni tí ìwà rẹ̀ dára?’

Rántí o, “ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.” (Òwe 13:20) David sọ pé: “alábàágbé mi gbóná gan-an nípa tẹ̀mí. Ìyẹn jẹ́ kí èmi náà lè máa ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí.” Renee, tó ti bá àwọn èèyàn bíi mélòó kan gbé yàrá rí sọ irú ohun kan náà pé: “Àwọn kan lára àwọn tí mo ti bá gbé rí máa ń sọ pé ká máa ka orí kọ̀ọ̀kan nínú Bíbélì pa pọ̀ lálaalẹ́. Nítorí pé àwọn òbí mi kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, a ò kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rí nínú ìdílé wa. Nítorí náà, mi ò lè sọ bí inú mi ṣe dùn tó pé mo lè ṣe ‘ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé’ pẹ̀lú àwọn alábàágbé mi!” Òótọ́ ni, ìbùkún ńláǹlà ló jẹ́ láti ní alábàágbé kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ohun tẹ̀mí bíi tìrẹ.

Ẹ Sọ Ọ́ Kó Yanjú

Ohun tó wá kàn ni pé kẹ́ ẹ jọ rí ara yín sójú kẹ́ ẹ sì jọ sọ̀rọ̀. Irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ á jẹ́ kó o mọ̀ bóyá ìwà yín á bára mu. Ìwádìí kan tí wọ́n gbé jáde nínú ìwé ìròyìn Communication Research Reports yẹ fún àfiyèsí, ó fi hàn pé àwọn alábàágbé tí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà sọ̀rọ̀ jọra wọn la “gbọ́ pé ìbágbé wọn máa ń tura jù lọ wọ́n sì máa ń fẹ́ràn ara wọn gan-an.” Nítorí náà, tó bá jẹ́ ẹni tó máa ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ jáde ni ọ́, tó o kóni mọ́ra, tó o sì jẹ́ èèyàn tó máa ń sọ̀rọ̀ gan-an, wàá ko ìṣòro tó o bá lọ bá ẹnì kan tí kì í sọ̀rọ̀, tó jẹ́ èèyàn tútù tàbí tó máa ń fẹ́ láti dá wà gbé yàrá.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ò ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ dà bí ìgbà tí ọlọ́pàá ń wádìí ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu èèyàn, yóò dára kí ìwọ àti ẹni tó fẹ́ di alábàágbé rẹ jọ jíròrò àwọn ohun tó fẹ́ ṣe àtàwọn ìwéwèé rẹ̀. Ṣé ẹni tó ń lépa bó ṣe máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí ni àbí kó ṣáà lè bọ́ lọ́wọ́ wàhálà ilé ló jẹ ẹ́ lógún? Lynn sọ nípa ìṣòro mìíràn tó tún lè yọjú, ó sọ pé: “Nígbà kan alábàágbé mi ní ọ̀rẹ́kùnrin kan, gbogbo ìgbà nìyẹn máa ń wá a wá, bí ilẹ̀ kò bá sì ṣú pátápátá kò ní í lọ.” Bí wọ́n ṣe máa ń bára wọn tage kì í bá Lynn lára mu èyí sì máa ń mú kí inú bí i. Àmọ́, èèyàn lè yẹra fún irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ nígbà míì bẹ́ẹ̀ bá ti jọ fi àwọn òfin kan lélẹ̀ látìbẹ̀rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Renee sọ pé: “A ṣe òfin kan pé, ó níye aago pàtó táwọn ọkùnrin lè dúró dà níyàrá wa.” Á tún bọ́gbọ́n mu pé kí àwọn méjì tó jọ ń gbé yàrá fohùn ṣọ̀kan pé èyíkéyìí nínú wọn kò gbọ́dọ̀ dá wà nínú yàrá pẹ̀lú ẹlòmíràn tó jẹ́ ẹ̀yà kejì.

Ó tún ṣe pàtàkì pé kẹ́ ẹ jọ jíròrò ní kínníkínní àwọn nǹkan bí eré ìnàjú, ohun tí kálukú fẹ́ àti irú orin tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nífẹ̀ẹ́ sí. Mark sọ pé: “Ẹnì kan tá a jọ nífẹ̀ẹ́ irú ohun kan náà, tí ìwà wa jọra, tó sì nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣe àwọn nǹkan tí èmi náà nífẹ̀ẹ́ sí ló wù mí láti bá gbé yàrá.” Lóòótọ́, pé ẹ̀yin méjèèjì kò jọ nífẹ̀ẹ́ sí ohun kan náà kò fi gbogbo ara túmọ̀ sí pé ẹ ò lè jọ gbé yàrá pọ̀. Kókó tó kàn wà níbẹ̀ ni pé, Báwo ni ẹ̀yin méjèèjì á ṣe lè mú nǹkan mọ́ra fúnra yín tó? Ṣé ẹ ṣe tán láti fara da àwọn ìyàtọ̀ tí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín lè ní kẹ́ ẹ sì ṣe àwọn ìyípadà láti lè jọ gbé pọ̀?

Lee dá a lámọ̀ràn pé: “O tún gbọ́dọ̀ béèrè ohun tí ẹnì kejì fẹ́ nínú ìbágbépọ̀ yín. Àwọn kan á retí pé kó o di kòríkòsùn àwọn kẹ́ ẹ sì sún mọ́ra gan-an. Àmọ́ kì í ṣe torí ìyẹn ni mo ṣe ń wá ẹni tí a jọ máa gbé yàrá.” David náà sọ pé: “Mo fẹ́ alábàágbéyàrá tá a lè jọ máa ṣe nǹkan pa pọ̀ àmọ́ kì í ṣe kó wá máa rò pé ìgbàkígbà tí èmi àtàwọn mìíràn bá ti ń ṣe nǹkan, dandan ni kí òun wà níbẹ̀.” Bákan náà, tún wádìí wò bí ẹni yẹn bá nífẹ̀ẹ́ sí i pé kẹ́ ẹ jọ jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú wíwàásù ìhìn rere tàbí bóyá òun náà ní nǹkan mìíràn lọ́kàn, irú bíi sísìn ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè òkèèrè.

Ní paríparí rẹ̀, rí i dájú pé o kò gbójú fo àwọn kókó pàtàkì kan dá, irú bí àwọn tó ní í ṣe pẹ̀lú iná dídá (ṣé ẹ̀yin méjèèjì mọ oúnjẹ sè?), bẹ́ẹ̀ ṣe máa pín iṣẹ́ ilé ṣe, ọ̀nà tí ẹ ó gbà máa lo àwọn nǹkan tẹ́ ẹ ní nínú ilé, àyè ìkáṣọsí, àga, ibi ìkẹ́rùsí àti bóyá ẹ máa ní àwọn nǹkan ọ̀sìn. Tẹ́ ẹ bá jọ sọ irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ tó yanjú, ìyẹn á lè jẹ́ kẹ́ ẹ dènà aáwọ̀ àti ẹ̀dùn ọkàn tó ṣeé ṣe kó wáyé. Òwe 20:18 sọ pé: “Ìmọ̀ràn ni a fi ń fìdí àwọn ìwéwèé múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.”

“Lọ́nà Tí Ó Bójú Mu àti Nípa Ìṣètò”

A tún rí ìlànà dáradára mìíràn nínú Lúùkù 14:28, níbi tó ti sọ pé: “Gbéṣirò lé ìnáwó náà.” Ọ̀rọ̀ gidi lọ̀rọ̀ yìí o, kọ́kọ́ gbìyànjú láti mọ iye tí bùkátà rẹ máa ná ọ. Èló ni wàá máa san fún owó ilé? Oúnjẹ? Owó iná, omi, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ? Ṣé ńṣe lẹ jọ máa máa pín tẹlifóònù lò? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo lẹ́ ṣe fẹ́ máa pín owó rẹ̀ san? Lynn sọ pé: “Màá kọ́kọ́ rí i dájú pé ọmọbìnrin tí màá bá gbé lágbára àtigbé bùkátà tó kàn án kí n tó gbà ká jọ gbé.” Ìròyìn kan tó máa ń jáde lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó ń jẹ́ The Next Step tọ̀nà nígbà tó sọ pé: “Ńṣe ni àwọn alábàágbéyàrá tí kì í san èyí tó kàn wọ́n nínú owó ilé àti owó oúnjẹ . . . tàbí tí wọ́n máa jẹ gbèsè jọ á kàn máa fún ẹ ní wàhálà tí kì í ṣe tìẹ.”

Renee sọ pé: “Nígbà míì, ìṣòro yẹn kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé èló lo yẹ kí ẹnì yẹn san, àmọ́ ìgbà wo ló ń kó owó ọ̀hún sílẹ̀!” Ó sọ pé: “Ọjọ́ kẹta oṣù la gbọ́dọ̀ san owó ilé wa. Àmọ́ nígbà míì, ńṣe ni alábàágbéyàrá míì máa wábi gbà tó bá ti di òpin ọ̀sẹ̀ láìsan owó tirẹ̀, lá bá di kí n máa bẹ onílé wa.” Èyí fi bó ṣe bọ́gbọ́n mu tó hàn láti ṣe gbogbo nǹkan “lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò” kéèyàn má sì fi àwọn nǹkan dá pé tó bá ṣeé ṣe ni. (1 Kọ́ríńtì 14:40) Lọ́pọ̀ ìgbà, ó bọ́gbọ́n mu kẹ́ ẹ jẹ́ kí ohun tẹ́ ẹ fohùn ṣọ̀kan lé lórí wà lákọọ́lẹ̀.

Lílo ìṣọ́ra àti jíjẹ́ olóye á túbọ̀ jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ láti rí alábàágbéyàrá kan tá á máa múnú rẹ dùn tí kò sì ní í máa kó ẹ sí ìbànújẹ́. Àmọ́ o, tí ìṣòro bá dìde ńkọ́ tàbí tí gbọ́nmi-sí-omi-ò-tó bá ṣẹlẹ̀ láàárín yín? Àpilẹ̀kọ kan tó ń bọ̀ lọ́nà á jíròrò àwọn ìṣòro yìí.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Kí Ló Dé Tí Àjọgbé Èmi àti Alábàágbé Mi Fi Nira?” tó jáde nínú ìtẹ̀jáde wa ti May 8, 2002.

c Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń gbé pa pọ̀ lónìí láti máa ṣèṣekúṣe, àwọn alábàágbéyàrá tí wọ́n jọ jẹ́ ọkùnrin tàbí tí wọ́n jọ jẹ́ obìnrin ni àpilẹ̀kọ yìí ń bá wí o, tí wọ́n jọ ń gbé yàrá kan náà nítorí àtilè dín ìnáwó kù kí nǹkan sì lè rọrùn fún wọn.

d Àwọn ajíhìnrere alákòókò kíkún ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ kan, wọ́n máa ń lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Aṣáájú Ọ̀nà. Àwọn ìpàdé tún wà tí wọ́n máa ń ṣe pẹ̀lú wọn nígbà ìpàdé àyíká tó máa ń wáyé lọ́dọọdún.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ewu wà nínú gbígbé pẹ̀lú àwọn èèyàn tí kì í hu ìwà rere tí Bíbélì fi kọ́ni

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Kó o tó gbà pé kí ìwọ àti ẹnì kan gbé yàrá pọ̀, ẹ jọ jókòó kẹ́ ẹ jọ jíròrò àwọn kókó tó ṣe pàtàkì