Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mímú Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì àti Ìsìn Ṣọ̀kan

Mímú Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì àti Ìsìn Ṣọ̀kan

Mímú Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì àti Ìsìn Ṣọ̀kan

“A ò ka sáyẹ́ǹsì àti ìsìn sí ohun tí kò bára mu mọ́.”—The Daily Telegraph, London, May 26, 1999.

ÒTÍTỌ́ kan náà ni sáyẹ́ǹsì àti ìsìn ń wá kiri. Sáyẹ́ǹsì ṣe àwọn àwárí kan nípa ayé yìí tá a ṣètò lọ́nà tó bùáyà, tó láwọn àmì tó fi hàn pé ọpọlọ pípé la fi ṣe é. Kò sì sírọ́ ńbẹ̀ pé ìsìn tòótọ́ ti túbọ̀ gbé àwọn àwárí yìí lárugẹ nípa fífi kọ́ni pé ìmọ̀ gígadabú tí Ẹlẹ́dàá náà ní ló fi ṣètò ilẹ̀ ayé wa tá a lè fojú rí.

Francis Collins tó jẹ́ onímọ̀ nípa ohun alààyè tíntìntín sọ pé: “Mo rí i pé ìsìn ló jẹ́ kí n lè lóye ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì bí mo ṣe lóye rẹ̀.” Ó sọ síwájú sí i pé: “Ẹnu máa ń yà mí mo sì máa ń ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ ní gbogbo ìgbà tí mo bá ṣàwárí ohun kan nípa ohun tó pilẹ̀ àbùdá èèyàn. Mo máa ń sọ fún ara mi pé, ‘Káàsà, Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló mọ èyí tẹ́lẹ̀ o.’ Èyíjẹ́ ìmọ̀lára tó dára púpọ̀ ó sì máa ń mára yá gágá, òun ló jẹ́ kí n túbọ̀ lóye Ọlọ́run kí n sì máa buyì fún un, ó sì ti tún jẹ́ kí n túbọ̀ gbádùn ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sí i.”

Kí ló lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti mú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìsìn ṣọ̀kan?

Ìwákiri Tí Kò Dáwọ́ Dúró

Ká fara mọ́ ibi tí òye wa mọ: Àwọn ìbéèrè tá à ń wá ìdáhùn sí nípa ilẹ̀ ayé òun ọ̀run, òfuurufú àti àkókò kò ní yéé wá sí wa lọ́kàn o. Lewis Thomas tó jẹ́ onímọ̀ nípa ohun alààyè sọ pé: “Ìwákiri wa yìí kò lè lópin, nítorí a jẹ́ ẹ̀dá tó máa ń fẹ́ mọ fìn-ín ìdí kókò, tó máa ń ṣèwádìí káàkiri tó sì máa ń gbìyànjú láti lóye àwọn nǹkan. A ò lè rí ìdáhùn sí gbogbo ìbéèrè nípa ayé òun ọ̀run láéláé. Mi ò tíì rí àkókò náà tí ara gbogbo èèyàn á rọlẹ̀ pẹ̀sẹ̀ tí wọ́n á sì sọ pé, ‘Ní báyìí o, a ti mọ gbogbo nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.’ Àwámáridìí ni á ṣì máa jẹ́ fún gbogbo ẹ̀dá èèyàn.”

Bákan náà, tó bá di ọ̀ràn ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa ìsìn, wíwá ìmọ̀ kiri kò lópin. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì, ìyẹn Pọ́ọ̀lù, sọ pé: “Nisisiyi a ń ríran [bàìbàì] bí ìgbà tí eniyan ń wo dígí . . . Nisisiyi, kò sí ohunkóhun tí mo mọ ohun gbogbo nípa rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 13:12, Ìròyìn Ayọ̀.

Bó ti wù kó rí, pé èèyàn ò tíì mọ ohun gbogbo nípa sáyẹ́ǹsì àti ìsìn kò sọ pé ká má lè lo àwọn òkodoro òtítọ́ tó wà nílẹ̀ láti dórí ìpinnu kan tó ṣe gbòógì. Ó ṣe tán, kò dìgbà tá a bá mọ tìfun-tẹ̀dọ̀ ibi tí oòrùn ti wá ká tó lè fọwọ́ sọ̀yà pé oòrùn á ràn lọ́la.

Gbé àwọn ohun tó jẹ́ òkodoro òtítọ́ yẹ̀ wò: Bá a ṣe ń sapá láti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wa, ó yẹ ká jẹ́ káwọn ìlànà tó yè kooro tọ́ wa sọ́nà. A lè ṣìnà níbi tá a ti ń wá òtítọ́ nípa sáyẹ́ǹsì tàbí ìsìn kiri àyàfi tá a bá fi àwọn ẹ̀rí tó ga jù lọ ṣe atọ́nà ara wa. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kò sí èyíkéyìí nínú wa tó lè mọ nípa gbogbo ìmọ̀ àti èrò tó jẹ́ ti sáyẹ́ǹsì tó pọ̀ lọ jàra láwọn ibi ìkówèésí lóde òní. Àmọ́ ti Bíbélì kò rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé ó pèsè àwọn kókó téèyàn lè fi ṣèwádìí àwọn nǹkan tẹ̀mí fún wa. Àwọn òkodoro òtítọ́ tá a mọ̀ ti Bíbélì lẹ́yìn pé òótọ́ ló sọ. a

Àmọ́ ṣá, téèyàn bá fẹ́ ní ìmọ̀ gbogbo gbòò, yálà nípa sáyẹ́ǹsì tàbí nípa ìsìn, èèyàn gbọ́dọ̀ sapá gidi gan-an kó bàa lè mọ̀yàtọ̀ láàárín èyí tó jẹ́ òtítọ́ àti èyí tó jẹ́ ìméfò lásánlàsàn, láàárín ohun tó jẹ́ ojúlówó àti èyí tó jẹ́ ẹ̀tàn. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù òǹkọ̀wé Bíbélì ṣe sọ, a gbọ́dọ̀ yẹra fún “àwọn ìtakora ohun tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀.’” (1 Tímótì 6:20) Bá a bá fẹ́ mú sáyẹ́ǹsì àti Bíbélì ṣọ̀kan, a ní láti gbé àwọn ohun tó jẹ́ òkodoro òtítọ́ yẹ̀ wò, ká tipa bẹ́ẹ̀ yàgò fún míméfò ká sì wá wo báwọn òkodoro òtítọ́ wọ̀nyí ṣe so mọ́ra wọn.

Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a lóye pé Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà “ọjọ́” fún àwọn àkókò kan pàtó, a tipa bẹ́ẹ̀ rí i pé kò sídìí táwọn ọjọ́ mẹ́fà tí Ọlọ́run fi ṣiṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí Jẹ́nẹ́sísì sọ nípa rẹ̀ á fi tako ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé ayé yìí ti wà láti nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́rin àtààbọ̀ ọdún sẹ́yìn. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ilẹ̀ ayé ti wà fún iye àkókò kan tá ò dárúkọ kó tóó di pé àwọn ọjọ́ tí Ọlọ́run fi ṣiṣẹ́ ìṣẹ̀dá bẹ̀rẹ̀. (Wo àpótí náà “Ṣé Ọjọ́ Oníwákàtí Mẹ́rìnlélógún Làwọn Ọjọ́ Tí Ọlọ́run Fi Ṣiṣẹ́ Ìṣẹ̀dá?”) Ká tiẹ̀ wá sọ pé sáyẹ́ǹsì wá ṣàtúnṣe ara rẹ̀, kó tún sọ pé iye ọdún mìíràn la ti ṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé wa, ohun tó wà nínú Bíbélì ṣì jẹ́ òtítọ́ síbẹ̀. Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kò tako Bíbélì nínú ọ̀ràn yìí àtàwọn ọ̀ràn mìíràn o, ńṣe ló túbọ̀ ń fún wa ní òbítíbitì ìsọfúnni nípa ilẹ̀ ayé wa tá a lè fojú rí, yálà nípa àwọn àkókò tó ti kọjá tàbí èyí tá a wà yìí.

Ìgbàgbọ́ tó dúró sán-ún la nílò kì í ṣe ìgbàgbọ́ oréfèé: Bíbélì fún wa ní ìmọ̀ nípa Ọlọ́run àtàwọn ète rẹ̀. Èèyàn ò lè rí irú ìmọ̀ yìí níbòmíràn. Kí ló dé tó fi yẹ ká gbà á gbọ́? Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ fún wa pé ká ṣàyẹ̀wò bóun ṣe pé pérépéré. Ṣàyẹ̀wò ohun tí ìtàn fi hàn nípa ìjóòtítọ́ rẹ̀, bó ṣe gbéṣẹ́ tó, báwọn tó kọ ọ́ kì í ṣe é fi dúdú pe funfun àti bó ṣe péye tó. Èèyàn lè ní ìgbàgbọ́ tó dúró sán-ún nínú Bíbélì gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run téèyàn bá ṣèwádìí nípa bí Bíbélì ṣe jóòótọ́ tó, títí kan àwọn ohun tó sọ tó jẹ mọ́ ti sáyẹ́ǹsì. Kí ó tún lè dá èèyàn lójú sí i, ṣàyẹ̀wò ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti nímùúṣẹ láti ìgbà láéláé tó fi dé àkókò tá a wà yìí. Ìgbàgbọ́ nínú Bíbélì kì í ṣe ìgbàgbọ́ oréfèé o, àmọ́ ó jẹ́ ìgbàgbọ́ to dúró sán-ún nínú àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ tí kò ní àṣìṣe.

Bọ̀wọ̀ fún sáyẹ́ǹsì; sì tún fi í sọ́kàn pé ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn kì í ṣe òtúbáńtẹ́: Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ké sáwọn èèyàn tó mọnúúrò, ì báà jẹ́ láti agbo sáyẹ́ǹsì tàbí agbo ìsìn láti ṣèwádìí ohun tó jẹ́ òtítọ́ ní ti sáyẹ́ǹsì àti ẹ̀sìn. Nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí, wọ́n máa ń fi ọ̀wọ̀ tó yẹ fún sáyẹ́ǹsì àtàwọn àwárí tó ti ṣe. Bákan náà ni wọ́n nígbàgbọ́ tó jinlẹ̀ pé inú Bíbélì nìkan la ti lè rí òtítọ́ nípa ẹ̀sìn. Àwọn ohun tó sọ àti ẹ̀rí jaburata inú rẹ̀ sì fi hàn kedere pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ láti ọ̀dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”—1 Tẹsalóníkà 2:13.

Kò sírọ́ ńbẹ̀ pé, bí i ti sáyẹ́ǹsì, àwọn ẹ̀kọ́ èké àtàwọn àṣà tí kò dáa tó ń ṣèpalára ti wọnú ìsìn. Nítorí náà, ìsìn tòótọ́ wà, ìsìn èké náà sì wà pẹ̀lú. Ìdí rèé tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń fi ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì ń di ọmọ ìjọ Kristẹni ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí àwọn ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀ ṣe ranrí pé àwọn ò lè jáwọ́ nínú àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ẹ̀dá èèyàn àtàwọn ìtàn àròsọ kí wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ojúlówó òtítọ́ yà wọ́n lẹ́nu púpọ̀.

Kò tán síbẹ̀ o, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń rí ìjẹ́pàtàkì àti ojúlówó ète ìgbésí ayé. Èyí kò sì ṣẹ̀yìn ìmọ̀ kíkún tí wọ́n ní nípa Ẹlẹ́dàá náà tí Bíbélì sọ, àti nípa ohun tó sọ pé òun fẹ́ ṣe fún ìran èèyàn àti ilẹ̀ ayé tá à ń gbé. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn tá a gbé karí Bíbélì sáwọn ìbéèrè bí i, Kí la wá ṣe nílé ayé? Kí ló ń bẹ fún wa lọ́jọ́ iwájú? Inú wọn á dùn púpọ̀ láti fún ọ láwọn ìsọfúnni wọ̀nyí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ìwé The Bible—God’s Word or Man’s? táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]

Ṣé Ọjọ́ Oníwákàtí Mẹ́rìnlélógún—Làwọn Ọjọ́ Tí Ọlọ́run Fi Ṣiṣẹ́ Ìṣẹ̀dá?

Àwọn ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà kan sọ pé iṣẹ́ ìṣẹ̀dá ló lè ṣàlàyé nípa ìgbà tí ẹ̀dá èèyàn kò tíì sí lórí ilẹ̀ ayé, pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n kò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n ṣáà ń tẹnu mọ́ ọn pé ọjọ́ mẹ́fà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún ni Ọlọ́run fi ṣẹ̀dá gbogbo ohun tó wà lórí ilẹ̀ ayé pátá ní nǹkan bí ẹgbàáta [6,000] sí ẹgbàárùn-ún [10,000] ọdún sẹ́yìn. Pẹ̀lú ohun tí wọ́n ń sọ yìí, ńṣe ni wọ́n ń ti ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu lẹ́yìn, èyí tó sì ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn bẹnu àtẹ́ lu Bíbélì.

Tí Bíbélì bá sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ kan, ṣé ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún ló sábàá máa ń túmọ̀ sí ní gbogbo ìgbà? Jẹ́nẹ́sísì 2:4 sọ̀rọ̀ nípa “ọjọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe ilẹ̀ ayé àti ọ̀run.” Ọjọ́ kan ṣoṣo yìí kó gbogbo ọjọ́ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí Ọlọ́run fi ṣiṣẹ́ ìṣẹ̀dá pọ̀, èyí tí Jẹ́nẹ́sísì orí kìíní sọ̀rọ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe máa ń lò ó, iye àkókò kan pàtó ni ọjọ́ kan máa ń túmọ̀ sí, èyí sì lè jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún tàbí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Èèyàn ò ṣì sọ tó bá sọ pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀dá tí Bíbélì sọ jẹ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Síwájú si i, Ọlọ́run ti ṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé kó tó di pé àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀dá wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Nítorí náà, lórí kókó yìí, ohun tí àkọsílẹ̀ inú Bíbélì sọ bára mu pẹ̀lú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì.—2 Pétérù 3:8.

Nígbà tí onímọ̀ nípa ohun alààyè tíntìntín náà Francis Collins ń sọ̀rọ̀ nípa èrò náà pé wákàtí mẹ́rìnlélógún ló wà nínú ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí Ọlọ́run fi ṣiṣẹ́ ìṣẹ̀dá, ó sọ pé: “Ìgbàgbọ́ nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀dá ti ṣèpalára púpọ̀ ju ohunkóhun mìíràn lọ fún èrò ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn tó mọnúúrò nínú ìtàn òde òní.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]

Ṣé Sáyẹ́ǹsì Ti Gbapò Iwájú Ní Ti Ìwà Rere?

Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ni ò fibì kankan fara mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn nítorí pé ìsìn kò fara mọ́ àwọn ìtẹ̀síwájú tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ní, nítorí àwọn àkọsílẹ̀ búburú tí ìsìn ti ní, ìwà àgàbàgebè rẹ̀ àti ìwà òǹrorò rẹ̀. John Postgate, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ nípa ohun alààyè tíntìntín sọ pé: “Àwọn ẹ̀sìn ayé . . . ni ọ̀dádá tó dá àwọn nǹkan ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ bíi fífi èèyàn rúbọ, ogun ẹ̀sìn, ìpakúpa rẹpẹtẹ àti ìwádìí láti gbógun ti àdámọ̀ sílẹ̀. Láyé òde òní, ńṣe ni ìwà àìdáa tí ẹ̀sìn ń hù yìí túbọ̀ ń burú sí i. Ìsìn kò dà bí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí kì í dá sọ́tùn-ún tàbí sósì.”

Nígbà tí Postgate fi èyí wéra pẹ̀lú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n sọ pé ó ń ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu, pé kì í ṣègbè, àti pé kì í hùwà jàgídíjàgan, ó ní “sáyẹ́ǹsì ti gbapò iwájú ní ti ìwà rere.”

Àmọ́ ṣé lóòótọ́ ni sáyẹ́ǹsì ti gbapò iwájú ní ti ìwà rere? Bẹ́ẹ̀ kọ́ o. Postgate fúnra rẹ̀ sọ pé “owú, ìwọra, ẹ̀tanú àti ìlara kò gbẹ́yìn lágbo sáyẹ́ǹsì.” Ó sọ síwájú sí i pé “àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mélòó kan ti sọ ara wọn di apànìyàn tí wọ́n á sì máa sọ pé ìwádìí làwọn ń ṣe, gẹ́gẹ́ bó ti ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba Násì ní Jámánì àti láwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Japan.” Nígbà tí ìwé ìròyìn National Geographic yan akọ̀ròyìn kan tó tún ń ṣèwádìí pé kó wádìí nípa bí ọ̀rọ̀ àkẹ̀kù kan tí wọ́n fi wàyó ṣe ṣe di èyí tó fara hàn nínú ìwé ìròyìn náà bí ohun kan tó jẹ́ òótọ́, akọ̀ròyìn náà tú kẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀ sílẹ̀. Ohun tí àbọ̀ rẹ̀ fi hàn nípa ohun tó fà á ni “ọ̀rọ̀ àṣírí tí wàyó kúnnú rẹ̀ àti ìgbẹ́kẹ̀lé tó já sófo, ìjà àjàkú-akátá láàárín àwọn èèyàn tí wọ́n fẹ́ kó jẹ́ pé ohun tí wọ́n bá sọ labẹ gé, àwọn tí wọn ò tó gèlètè tí wọ́n ń mí fìn-ìn, ìgbéra ẹni gẹṣin aáyán, àlá tí kò lè ṣẹ, àṣìṣe ẹ̀dá èèyàn, orí kunkun, lílo ọgbọ́n àyínìke, sísọ̀rọ̀ ẹlòmíràn lẹ́yìn, irọ́ pípa [àti] ìwà ìkówójẹ.”

Síwájú sí i, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kan náà yìí ló fún ẹ̀dá èèyàn ní irinṣẹ́ ogun tó ń kó ìpayà báni, irú bí àwọn kòkòrò àrùn tí wọ́n ń lò bí ohun ìjà ogun, gáàsì olóró, àwọn ohun ìjà, àwọn bọ́ǹbù àgbéléyìn àtàwọn bọ́ǹbù átọ́míìkì.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

“Ant Nebula” (Menzel 3) látinú Awò-Awọ̀nàjíjìn Gbalasa Òfuurufú ti Hubble

[Credit Line]

NASA, ESA àti The Hubble Heritage Team (STScI/AURA)

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Sáyẹ́ǹsì ti ṣe àwọn àwárí kan nípa ayé yìí, àwọn àwárí náà fi hàn pé ọpọlọ pípé la fi ṣe é

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi ọ̀wọ̀ tó yẹ fún ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì wọ́n sì nígbàgbọ́ nínú Bíbélì