Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 16. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)

1. Èé ṣe tí kò fi tọ̀nà fún ẹnì kan láti gbẹ̀san ara rẹ̀ tàbí kó gbẹ̀san ẹlòmíràn? (Róòmù 12:19)

2. Kí nìdí tí Jèhófà fi fòfin de jíjọ́sìn àwòrán tàbí ère? (Aísáyà 42:8)

3. Irú ojú wo ni Jésù fi wo iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un lórí ilẹ̀ ayé? (Jòhánù 4:34)

4. Ibo la ti fi òróró yan Dáfídì bí ọba, tó sì fibẹ̀ ṣe olú ìlú kí wọ́n tó kó o lọ sí Jerúsálẹ́mù? (2 Sámúẹ́lì 2:1-4)

5. Gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ṣe sọ, òkúta iyebíye wo ni òṣùmàrè tó yí ìtẹ́ Jèhófà ká jọ? (Ìṣípayá 4:3)

6. Ìlú wo ni ẹ̀rí fi hàn pé Pọ́ọ̀lù ti dúró nígbà tí wọ́n ń mú un lọ sí Róòmù bí ẹlẹ́wọ̀n? (Ìṣe 28:13)

7. Ọ̀rọ̀ ewì wo ni Jeremáyà lò fún Jerúsálẹ́mù nígbà tó ń kẹ́dùn nípa ìparun rẹ̀? (Ìdárò 2:2)

8. Alákòóso wo ni ẹ̀rù rẹ̀ ba Dáfídì tó fi ṣe bí ẹni tí orí rẹ̀ ti dàrú? (1 Sámúẹ́lì 21:12-15)

9. Kí nìdí tó fi jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó ń yọrí sí ikú béèyàn bá fúnra rẹ̀ ṣe òróró àfiyanni tí Jèhófà ní kí Mósè máa lò tàbí kéèyàn lò ó? (Ẹ́kísódù 30:31-38)

10. Nítorí ọmọ ẹ̀yìn wo ni “ìbújáde ìbínú mímúná” fi wáyé láàárín Pọ́ọ̀lù àti Bánábà tó fi jẹ́ pé ńṣe ni olúkúlùkù rìnrìn àjò gba ọ̀nà tirẹ̀? (Ìṣe 15:36-41)

11. Níbàámu pẹ̀lú Jòhánù 3:16, kí ni ohun tó lè fún èèyàn ní ìyè àìnípẹ̀kun?

12. Báwo ni àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe ń pe àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn? (3 Jòhánù 14)

13. Ta lẹni náà tó jẹ́ pé ọ̀nà tó gbà ń sáré nígbà tó ń mú ìròyìn wá bá Dáfídì ni wọ́n fi dá a mọ̀? (2 Sámúẹ́lì 18:27)

14. Kí ló fà á tí Mósè ò fi wọ Ilẹ̀ Ìlérí? (Númérì 20:7-12)

15. Ta lẹni náà táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa pé “àsápajúdé eré” ló máa ń fi ẹṣin sá? (2 Ọba 9:20)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. Nítorí Jèhófà sọ pé: “Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san”

2. Òun nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ìjọsìn, ògo àti ìyìn

3. Ó dà bí oúnjẹ fún un

4. Hébúrónì

5. Émírádì

6. Pútéólì

7. “Ọmọbìnrin Júdà”

8. Ákíṣì, ọba Gátì

9. Nítorí ohun mímọ́ ló jẹ́, tó ń fi ìjẹ́pàtàkì àti ìjẹ́mímọ́ àwọn ọ̀ràn tí Jèhófà bá ṣètò wọn hàn

10. Máàkù

11. Lílo ìgbàgbọ́ nínú Jésù

12. Àwọn ọ̀rẹ́

13. Áhímáásì

14. Ó da ọ̀rọ̀ náà sí ìbínú kò sì gbé orúkọ Jèhófà ga nígbà tó pèsè omi fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì

15. Jéhù