Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Títọ́jú Ìkókó Bíi Ti Ẹranko ‘Kangaroo’” Ṣé Ìyẹn Ló Máa Fòpin sí Ikú Àwọn Ìkókó Tí Oṣù Wọn Kò Pé?

“Títọ́jú Ìkókó Bíi Ti Ẹranko ‘Kangaroo’” Ṣé Ìyẹn Ló Máa Fòpin sí Ikú Àwọn Ìkókó Tí Oṣù Wọn Kò Pé?

“Títọ́jú Ìkókó Bíi Ti Ẹranko ‘Kangaroo’” Ṣé Ìyẹn Ló Máa Fòpin sí Ikú Àwọn Ìkókó Tí Oṣù Wọn Kò Pé?

Ọdún 1979 kúkú ni, ní ilé ìwòsàn kan tó wà ní Bogotá, ní Kòlóńbíà. Ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn ọmọ tí oṣù wọn kò pé táwọn èèyàn ń bí ló ń yè é, ni dókítà ọmọ Kòlóńbíà kan bá ṣàwárí ojútùú kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀—“ìyẹn títọ́jú ìkókó bíi ti ẹranko ‘kangaroo’”

Iṣẹ́ ńlá gbáà ló máa ń jẹ́ fáwọn dókítà láti bójú tó àwọn ìkókó tí oṣù wọn kò pé kí wọ́n má bàa kú. Ibi tí ooru wà ni wọ́n sábàá máa ń gbé àwọn ọmọ tí wọn ò wúwo tó bó ṣe yẹ nígbà tí wọ́n bí wọn sí, ibẹ̀ sì ni wọ́n á wà títí wọ́n á fi lókun tí wọ́n á sì wúwo tó bó ṣe yẹ. Àmọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò tíì gòkè àgbà, àwọn ilé ìwòsàn tí èrò inú wọn ti pọ̀ jù, tí kò sí ìmọ́tótó tó pójú owó àti àìsí òṣìṣẹ́ àti ohun èèlò tó yẹ máa ń mú kí àrùn ran ẹlòmíràn.

Dókítà kan ní Kòlóńbíà wá hùmọ̀ ọgbọ́n kan tó rọ ìṣòro yìí lójú díẹ̀. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é? Bí oṣù ọmọ kan kò bá pé tí wọ́n fi bíi, wọ́n á bójú tó o lọ́nà tí wọ́n ń gbà bójú tó àwọn tí oṣù wọn pé títí tára rẹ̀ á fi le díẹ̀. Kó tó di àkókò yìí, ìyá ọmọ náà á máa gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ṣe lè tọ́jú ọmọ náà. Tára ọmọ náà bá sì ti le dé ìwọ̀n àyè kan, ìyá á bẹ̀rẹ̀ sí fi ooru ara tọ́jú rẹ̀ bí ìgbà tí adìyẹ bá ń sàba. Báwo ló ṣe máa ṣe èyí? Bó ṣe máa ṣe é ni pé á fi aṣọ wé ọmọ náà mọ́ àyà rẹ̀. Á wá dà bí ìgbà tí ẹranko kangaroo gbé ọmọ rẹ̀ sábẹ́, ara ọmọ náà á máa móoru á sì rọrùn fún un láti máa mu ọyàn ìyá rẹ̀. Ìdí rèé tí wọ́n fi ń pè é ní títọ́jú ìkókó bíi ti ẹranko kangaroo.

Ọ̀rọ̀ pé wọ́n á ra ohun èlò olówó gọbọi kankan kò sí níbẹ̀ o. Ẹnu pé kí ìyá wọ irú aṣọ tó bá fẹ́ràn láti wọ̀ ni. Bí ọmọ náà bá sì ti wúwo tó bó ṣe yẹ, àtìyá àtọmọ lè máa lọ sílé, wọ́n á wá máa lọ sí ilé ìwòsàn látìgbàdégbà fún àyẹ̀wò.

Àwọn ìwádìí tí wọ́n ti ṣe ṣáájú ti fi hàn pé títọ́jú ọmọ bíi ti ẹranko kangaroo gbéṣẹ́ gan-an kò sì léwu. Ìyẹn nìkan kọ́, ó tún dà bí ẹni pé ó máa ń jẹ́ kí ìyá àtọmọ túbọ̀ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ sí i. Abájọ tí kò fi yani lẹ́nu bó ṣe di pé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni wọ́n ti ń lo ọ̀nà ìtọ́jú yìí. Ní Mẹ́síkò, wọ́n máa ń kọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn bíi bàbá tàbí ìyá àgbà káwọn náà lè tọ́jú ọmọ bíi ti ẹranko kangaroo, kí wọ́n lè ran ìyá lọ́wọ́ nígbà tó bá fẹ́ sinmi. Dókítà Guadalupe Santos tó ń ṣe kòkáárí ètò títọ́jú ọmọ bíi ti ẹranko kangaroo ní Mẹ́síkò sọ fún Jí! pé: “Ọdún 1992 la ti bẹ̀rẹ̀ sí lo ọ̀nà ìtọ́jú yìí a sì ti rí i pé ó dára gan-an. A ò fi bẹ́ẹ̀ nílò àwọn ẹ̀rọ tó ń pèsè ooru kò sì sí pé èèyàn ń fi àkókò ṣòfò ní ilé ìwòsàn.”