Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ààbò Táwọn Ọlọ́pàá Ń Pèsè—Ìrètí àti Ìbẹ̀rù Táwọn Èèyàn Ní Nípa Rẹ̀

Ààbò Táwọn Ọlọ́pàá Ń Pèsè—Ìrètí àti Ìbẹ̀rù Táwọn Èèyàn Ní Nípa Rẹ̀

Ààbò Táwọn Ọlọ́pàá Ń Pèsè—Ìrètí àti Ìbẹ̀rù Táwọn Èèyàn Ní Nípa Rẹ̀

Ọ̀PỌ̀ àwọn tó ń gbé nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún ló kọ̀ jálẹ̀ pé àwọn ò fẹ́ àwọn ọlọ́pàá táá máa wọṣọ. Ẹ̀rù ń bà wọ́n pé tí ìjọba àpapọ̀ bá lọ ní àwọn kan tí wọ́n ń dìhámọ́ra nígbà gbogbo, àwọn ò ní lè ṣe bó ṣe wu àwọn mọ́. Àwọn kan sì ń bẹ̀rù pé ètò náà lè wá di ti ọlọ́pàá-inú, kó dà bí irú èyí tí wọ́n ń ṣe nílẹ̀ Faransé lábẹ́ ìdarí Joseph Fouché, tó jẹ́ pé ńṣe làwọn ọlọ́pàá máa ń ṣọ́ àwọn èèyàn lọ́wọ́-lẹ́sẹ̀. Síbẹ̀, ìbéèrè kan ò yéé wá sí wọn lọ́kàn o. Ìbéèrè náà ni pé, ‘Kí là bá ṣe ká ní kò sí àwọn ọlọ́pàá?’

Nígbà yẹn, ìlú London ló tóbi jù lọ ní gbogbo ayé; òun náà ló sì tún lọ́rọ̀ jù lọ. Ńṣe ni ìwà ọ̀daràn ń fojoojúmọ́ ròkè tí èyí sì ń ṣèdíwọ́ fún òwò ṣíṣe. Kò sí ẹnì kankan tó lè dáàbò bo ẹ̀mí àwọn èèyàn àti dúkìá wọn, yálà àwọn ọlọ́dẹ alẹ́ tó yọ̀ǹda ara wọn ni o tàbí àwọn tó mọ olèé mú dáadáa, ìyẹn àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tí wọ́n ń pè ní Bow Street Runners, táwọn èèyàn kan ń sanwó fún. Clive Emsley, nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní The English Police: A Political and Social History, sọ pé: “Díẹ̀díẹ̀, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé ìwà ọ̀daràn àti rúkèrúdò kì í ṣe ohun tó bójú mu láwùjọ àwọn ọ̀làjú.” Èyí ló mú káwọn ará London fara mọ́ níní àwọn ọlọ́pàá tó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ lábẹ́ ìdarí Ọ̀gbẹ́ni Robert Peel. Ní September ọdún 1829 ni àwọn ọlọ́pàá tó ń wọṣọ, tó wà fún Ìlú Ńlá London bẹ̀rẹ̀ sí í káàkiri àwọn àgbègbè.

Àtìgbà tíṣẹ́ ọlọ́pàá òde òní sì ti bẹ̀rẹ̀ lọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́pàá ti ń kọ àwọn èèyàn lóminú, bí wọ́n ṣe ń retí pé kí wọ́n pèsè ààbò náà ni ẹ̀rù tún ń bà wọ́n pé wọ́n lè ṣi agbára wọn lò.

Iṣẹ́ Ọlọ́pàá Bẹ̀rẹ̀ Nílẹ̀ Amẹ́ríkà

Ní gbogbo ilẹ̀ Amẹ́ríkà, New York City ló kọ́kọ́ ní àjọ ọlọ́pàá tó mọṣẹ́ dunjú. Bí ọrọ̀ ìlú náà ṣe ń búrẹ́kẹ́ sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìwà ọ̀daràn ń peléke sí i. Nígbà tó fi máa di àwọn ọdún 1830, kò sí ìdílé tí kì í ka àwọn ìròyìn amúnitagìrì nípa ìwà ọ̀daràn, èyí tó ń jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn olówó pọ́ọ́kú tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣe jáde nígbà yẹn. Làwọn èèyàn bá yarí, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹ̀hónú wọn hàn, bí ìlú New York náà ṣe di èyí tó wá ní àjọ ọlọ́pàá tirẹ̀ nìyẹn lọ́dún 1845. Látìgbà yẹn làwọn ọlọ́pàá ìlú New York àti ti ìlú London ti jẹ́ ohun ìwúrí fún àwọn èèyàn ìlú kálukú wọn.

Bí ẹ̀rù ṣe ba àwọn ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni ẹ̀rù ṣe kọ́kọ́ ba àwọn ará Amẹ́ríkà fún bí ìjọba ṣe fẹ́ ní àjọ kan táá máa dìhámọ́ra. Àmọ́, ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì yìí gbà yanjú ìṣòro wọn. Àwọn ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fẹ́ àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n á máa dé fìlà gogoro tí wọ́n á sì máa wọ aṣọ aláwọ̀ aró. Kóńdó tí kì í hàn síta nìkan ni ohun ìjà tí wọ́n ń mú dání. Títí dòní olónìí, àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kì í gbé ìbọn àyàfi tí ọ̀rọ̀ pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀. Àmọ́, ìròyìn kan sọ pé, “àwọn èèyàn túbọ̀ ń rí èyí bí ohun tí kò lè máa bá a lọ títí . . . wọ́n ní bópẹ́ bóyá, á di dandan fún àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láti máa dìhámọ́ra gidi.”

Àmọ́ nílẹ̀ Amẹ́ríkà, ìbẹ̀rù pé àwọn ọlọ́pàá lè ṣi agbára wọn lò ló mú kí ìjọba ṣe Àtúnṣe Kejì sí Òfin Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, èyí tó “gba àwọn èèyàn láyè láti ní Ohun Ìjà kí wọ́n sì máa mú un kiri.” Èyí mú kí àwọn ọlọ́pàá náà sọ pé àwọ́n fẹ́ máa gbé ìbọn. Kò pẹ́ kò jìnnà, ilẹ̀ Amẹ́ríkà di ibi táwọn ọlọ́pàá àtàwọn ọ̀daràn tí wọ́n ń lé ti máa ń yìnbọn síra wọn, ìyẹn sì di ohun táwọn èèyàn wáá mọ̀ wọ́n mọ́. Ìdí mìíràn tó tún mú káwọn ara Amẹ́ríkà máa ní ìbọn lọ́wọ́ ni pé, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n dá àjọ ọlọ́pàá àkọ́kọ́ sílẹ̀ nílẹ̀ Amẹ́ríkà yàtọ̀ gédégédé sí bí ipò nǹkan ṣe rí nílùú London. Bí àwọn èèyàn ìlú New York ṣe ń pọ àpọ̀yamùrá fa ìdàrúdàpọ̀ nínú ìlú náà. Yíya tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ń ya wọ̀lú, pàápàá láti ilẹ̀ Yúróòpù, àti bí àwọn aláwọ̀ dúdú ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣe ń pọ̀ sí i lẹ́yìn tí Ogun Abẹ́lé tó wáyé láàárín ọdún 1861 sí 1865 bẹ̀rẹ̀, dá ìjà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà sílẹ̀. Làwọn ọlọ́pàá bá rí i pé ó di dandan káwọn túbọ̀ mú ọwọ́ líle.

Èyí ló mú kí wọ́n ka àwọn ọlọ́pàá sí kò-ṣeé-rí-kò-ṣeé-fẹ́-kù lọ́pọ̀ ìgbà. Làwọn èèyàn bá kúkú gbà láti máa fara da ìwàkiwà táwọn ọlọ́pàá lè máa hù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìrètí pé ìlú á ṣáà tiẹ̀ rójú díẹ̀ àwọ́n á sì ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Àmọ́ láwọn apá ibì kan lágbàáyé lákòókò náà, iṣẹ́ ọlọ́pàá mìíràn tún ti ń yọjú.

Àwọn Ọlọ́pàá Ṣẹ̀rùbàwọ́n

Níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún, tí ewé àwọn ọlọ́pàá tá a mọ̀ lóde òní ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í rú, àwọn Olú Ọba ilẹ̀ Yúróòpù ló ti kọ́kọ́ ń ṣàkóso ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn láyé. Kò sóhun méjì tí wọ́n fi ṣètò àwọn ọlọ́pàá Yúróòpù nígbà náà ju pé kí wọ́n lè máa dáàbò bo àwọn ọba kàkà tíì bá fi jẹ́ àwọn aráàlú. Kódà, ó jọ pé àwọn ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tí wọ́n kórìíra níní àwọn ọlọ́pàá adìhámọ́ra táá máa hùwà bí ológun lórílẹ̀-èdè wọn, kò rí ohun tó burú nínú pé kí irú àwọn ọlọ́pàá yìí wà láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tó wà lábẹ́ ìṣàkóso ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, káwọn aráàlú lè gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. Rob Mawby, nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Policing Across the World sọ pé: “Ní gbogbo ọ̀rúndún táwọn ọlọ́pàá fi wà láwọn ilẹ̀ tó wà lábẹ́ àkóso ilẹ̀ òkèèrè ni wọ́n fi ń hùwà òǹrorò, ìwà ìbàjẹ́, ìwà ipá, ìpànìyàn àti ṣíṣi agbára lò.” Lẹ́yìn tí ìwé yìí kan náà ti sọ pé àjọ ọlọ́pàá ìgbà náà kò ṣàìní àǹfààní tirẹ̀, ó fi kún un pé, ìṣesí wọn máa ń jẹ́ kí “àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri ayé máa wo àwọn ọlọ́pàá pé irinṣẹ́ ìjọba ni wọ́n pé wọn kì í ṣe ìránṣẹ́ aráàlú.”

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ìgbà kan táwọn ìjọba bóofẹ́bóokọ̀ kò ní àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tí wọ́n máa ń lò láti ṣamí àwọn èèyàn, níwọ̀n bí wọ́n ti ń bẹ̀rù pé àwọn kan láàárín ìlú lè fẹ́ dojú ìjọba dé. Ńṣe làwọn ọlọ́pàá yìí máa ń dá àwọn èèyàn lóró láti lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wọn tí wọ́n á sì pa àwọn tí wọ́n bá rò pé wọ́n fẹ́ dojú ìjọba dé tàbí kí wọ́n gbé àwọn èèyàn jù sátìmọ́lé láìtiẹ̀ gbọ́ tẹnu wọn. Gestapo ni wọ́n ń pe àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tí Ìjọba Násì ń lò nígbà yẹn, KGB lorúkọ àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ilẹ̀ Soviet Union nígbà tí ti Ìlà Oòrùn Jámánì sì ń jẹ́ Stasi. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé àwọn Stasi yìí ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àtàwọn afinisùn tó ṣeé ṣe kó tó ìdajì mílíọ̀nù láti máa ṣamí àwọn èèyàn tí wọn ò ju mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún lọ. Gbogbo wákàtí tó wà nínú ọjọ́ làwọn ọlọ́pàá yìí fi máa ń fetí kọ́ ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn bá ń sọ lórí tẹlifóònù, wọ́n sì ní àkọsílẹ̀ ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè náà lọ́wọ́. John Koehler, nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Stasi, sọ pé: “Kò sóhun táwọn ọlọ́pàá Stasi ò lè fi èèyàn ṣe bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì nítìjú. Wọ́n gba àwọn àlùfáà rẹpẹtẹ láti lè máa fún wọn ní ìsọfúnni ní kọ̀rọ̀, títí kan àwọn tó jẹ́ ògúnná gbòǹgbò nínú ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì àti ìjọ Kátólíìkì. Ńṣe làwọn irinṣẹ́ tí wọ́n fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kúnnú àwọn ọ́fíìsì wọn àtàwọn ibi tí wọ́n ti ń gbọ́ ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.”

Àmọ́ kì í ṣe kìkì ibi táwọn ìjọba bóofẹ́bóokọ̀ bá ti ń ṣàkóso nìkan làwọn ọlọ́pàá ṣẹ̀rùbàwọ́n máa ń wà o. Láwọn ìlú ńlá mìíràn, wọ́n ti fẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá pé wọ́n máa ń dá ìpayà sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń fipá mú àwọn èèyàn láti ṣe ohun tí òfin sọ, àgàgà tó bá jẹ́ pé àwọn ẹ̀yà tí kò tó nǹkan ni wọ́n dájú sọ. Nígbà tí ìwé ìròyìn kan ń sọ nípa ìwàkiwà kan tó ṣẹlẹ̀ nílùú Los Angeles, èyí tí wọ́n polongo rẹ̀ fáyé gbọ́, ó ní ìwà yìí “fi hàn pé ìwàkiwà àwọn ọlọ́pàá ti wá kọjá bó ṣe yẹ èyí sì ti mú kí wọ́n fún wọn ní orúkọ tuntun kan, orúkọ ọ̀hún ni: àwọn ọ̀daràn ọlọ́pàá.”

Ní báyìí, ìbéèrè táwọn aláṣẹ wá ń béèrè ni pé, Kí ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lè ṣe káwọn èèyàn lè máa fojú tó dára wò wọ́n? Láti lè mú kí ipa tí wọ́n ń kó nínú ṣíṣiṣẹ́ sin ìlú ṣe kedere sí i, ọ̀pọ̀ àwọn àjọ ọlọ́pàá ti gbìyànjú láti gbájú mọ́ àwọn apá tó ṣàǹfààní fún aráàlú nínú iṣẹ́ ọlọ́pàá.

Níní Ọlọ́pàá Àdúgbò

Ńṣe làwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Japan máa ń ṣiṣẹ́ wọn láti àdúgbò dé àdúgbò, èyí sì máa ń wú àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè lórí. Àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Japan máa ń ní àwọn ọ́fíìsì kéékèèké láti bójú tó àwọn àgbègbè kọ̀ọ̀kan, táwọn ọlọ́pàá bíi méjìlá sì máa ń gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ara wọn. Frank Leishman, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó jẹ́ olùkọ́ ìmọ̀ nípa ìwà ọ̀daràn, tó sì ti gbé ilẹ̀ Japan fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, sọ pé: “Kò sẹ́ni tí kò mọ̀ nípa iṣẹ́ afẹ́nifẹ́re táwọn ọlọ́pàá tó ń ṣiṣẹ́ ní koban, ìyẹn àwọn àgọ́ ọlọ́pàá kéékèèké, ń ṣe. Wọ́n máa ń ṣàlàyé àdírẹ́sì fáwọn èèyàn nípa àwọn òpópónà ilẹ̀ Japan tí kì í sábà lórúkọ; wọ́n máa ń yá àwọn èrò tí òjò ká mọ́ ọ̀nà ní àwọn agbòjò tí wọ́n rí he àmọ́ tí wọn kò rí àwọn tó ni wọ́n; wọ́n máa ń rí i dájú pé àwọn ọ̀mùtí alámudòru rí ọkọ̀ ojú irin tó kẹ́yìn bá délé; wọ́n sì máa ń pèsè ìmọ̀ràn lórí ‘àwọn wàhálà tí aráàlú ní.’” Bí àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Japan ṣe sún mọ́ àwọn ará àdúgbò pẹ́kípẹ́kí mú kí wọ́n gbayì fún ohun kan, ohun náà ni pé, èèyàn lè rìn láwọn ojú pópó wọn láìsí ìbẹ̀rù.

Ṣé irú ètò yìí lè ṣiṣẹ́ fún àwọn ọlọ́pàá níbòmíràn? Àwọn kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ nípa ìwà ọ̀daràn ti ń rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ètò náà. Ètò ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ òde òní tó túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú ti mú káwọn ọlọ́pàá máa jìnnà sáwọn èèyàn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ sìn. Ní ọ̀pọ̀ ìlú lónìí, ńṣe ló máa ń dà bíi pé lájorí iṣẹ́ àwọn ọlọ́pàá kò ju kí wọ́n sáré lọ síbi tí ọ̀ràn pàjáwìrì bá ti ṣẹlẹ̀. Nígbà mìíràn, ńṣe ló máa dà bíi pé iṣẹ́ dídènà ìwà ọ̀daràn tí wọ́n máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ ti di ohun ìtàn. Láti lè wá ojútùú sí ìṣòro yìí, ètò ṣíṣọ́ àdúgbò tún ti wá wọ́pọ̀ báyìí.

Ètò Ṣíṣọ́ Àdúgbò

Nígbà tí ọlọ́pàá kan tó ń jẹ́ Dewi ń sọ nípa iṣẹ́ rẹ̀ ní ilẹ̀ Wales, ó sọ pé: “Ètò yìí gbéṣẹ́ gan-an ni; ó dín ìwà ọ̀daràn kù. Ohun tí ètò ṣíṣọ́ àdúgbò túmọ̀ sí ni pé, kí àwọn èèyàn ládùúgbò máa wá ààbò ara wọn. A máa ń ṣètò àwọn ìpàdé káwọn aládùúgbò lè mọra wọn, kí wọ́n mọ orúkọ ara wọn kí wọ́n sì gba nọ́ńbà tẹlifóònù ara wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì tún gbọ́ nípa bí wọ́n ṣe lè dènà ìwà ọ̀daràn. Mo gbádùn ètò náà gan-an ni nítorí ó dá ẹ̀mí nínífẹ̀ẹ́ aládùúgbò ẹni padà. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn èèyàn kò tilẹ̀ ń mọ àwọn tí wọ́n jọ ń gbé àdúgbò. Ètò náà ṣiṣẹ́ nítorí ó ta àwọn èèyàn jí.” Ó tún jẹ́ kí àárín àwọn ọlọ́pàá àtàwọn aráàlú dán mọ́rán sí i.

Ìgbésẹ̀ mìíràn tí wọ́n tún ń gbé ni pé, wọ́n ń rọ àwọn ọlọ́pàá láti túbọ̀ máa fi àánú hàn sáwọn tó kó sọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn. Jan van Dijk, ọmọ ilẹ̀ Netherlands kan tó jẹ́ ògbóǹkangí nínú ìmọ̀ nípa ìṣesí àwọn ẹni tó kó sọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn kọ̀wé pé: “Wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọlọ́pàá pé, bí ọ̀nà táwọn dókítà ń gbà bá àwọn aláìsàn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì ń bá wọn lò ṣe ṣe pàtàkì náà ni ìhùwàsí wọn sí àwọn ẹni tó bá kó sọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn ṣe ṣe pàtàkì.” Ní ibi púpọ̀, àwọn ọlọ́pàá kò tíì máa wo ìwà ipá inú ilé àti ìfipábánilòpọ̀ bí ìwà ọ̀daràn gidi. Àmọ́ Rob Mawby sọ pé: “Ọwọ́ táwọn ọlọ́pàá fi ń mú ìwà ipá inú ilé àti ìfipábánilòpọ̀ láwọn ọdún àìpẹ́ yìí ti sàn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ fíìfíì. Síbẹ̀, wọ́n ṣì tún lè ṣe dáadáa sí i.” Bí àwọn ọlọ́pàá ṣe máa ń ṣi agbára lò jẹ́ àgbègbè mìíràn tí púpọ̀ lára wọn ti nílò àtúnṣe.

Ìwà Ìbàjẹ́ Àwọn Ọlọ́pàá Kò Fọkàn Àwọn Èèyàn Balẹ̀

Àwọn èèyàn kì í sábà gbà pé ààbò ìlú làwọn ọlọ́pàá wà fún lóòótọ́, àgàgà láwọn ìgbà tí ìròyìn ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n ń hù bá gba ìlú kan. Látìgbà tí iṣẹ́ ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ lèèyàn ti ń gbọ́ irú àwọn ìròyìn bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ìwé náà, NYPD—A City and Its Police ń tọ́ka sí ọdún 1855, ó sọ pé “èrò tí ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú New York ní ni pé, ńṣe ló túbọ̀ ń ṣòro láti mọ ìyàtọ̀ láàárín àwọn ọ̀daràn àtàwọn ọlọ́pàá.” Ìwé náà, Faces of Latin America, tí Duncan Green kọ, sọ nípa àwọn ọlọ́pàá ibẹ̀ pé “ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé owó ẹ̀yìn ti bà wọ́n jẹ́, pé wọn ò kúnjú ìwọ̀n, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ò jẹ́ nǹkan kan lójú wọn.” Ọ̀gá ọlọ́pàá kan tó ń bojú tó ètò ìgbanisíṣẹ́ fún ikọ̀ kan tó ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá ọlọ́pàá ní Látìn Amẹ́ríkà sọ pé: “Kí lẹ retí ná, nígbà tí owó tí ọlọ́pàá kan ń gbà lóṣù kò tó ọgọ́rùn-ún dọ́là? Tí wọ́n bá fi owó ẹ̀yìn lọ̀ ọ́, kí ló máa ṣe?”

Báwo ni ìṣòro rìbá gbígbà ṣe wọ́pọ̀ tó? Ìdáhùn yẹn sinmi lórí ẹni tó o bá bi. Ọlọ́pàá kan láti Àríwá Amẹ́ríkà, tó fi ọ̀pọ̀ ọdún káàkiri ìlú kan tó ní àwọn olùgbé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000] dáhùn pé: “Lóòótọ́ ni àwọn ọlọ́pàá kan tó máa ń ṣàìdáa wà, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọlọ́pàá ló jẹ́ olóòótọ́. Ohun tí mo fojú ara mi rí ni.” Òdìkejì gbáà ni ohun tí ọ̀gá ọlọ́pàá kan tó jẹ́ aṣèwádìí ìwà ọ̀daràn, ẹni tó ti ṣiṣẹ́ ọlọ́pàá fún ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ní orílẹ̀-èdè mìíràn sọ, ó ní: “Lójú tèmi, kò sí ibi tí ìwà ìbàjẹ́ kò sí. Ó ṣọ̀wọ́n púpọ̀ kẹ́ ẹ tó lè rí ọlọ́pàá tó jẹ́ olóòótọ́. Bí ọlọ́pàá kan bá lọ yẹ ilé kan táwọn olè fọ́ wò tó sì rí owó, kò dájú pé kò ní í mú un. Tó bá gba àwọn nǹkan táwọn olè jí kó padà, á jí díẹ̀ pa mọ́ lára rẹ̀.” Kí ló ń sọ àwọn ọlọ́pàá kan di oníwà ìbàjẹ́ ná?

Àwọn kan máa ń hùwà ọmọlúwàbí nígbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ọlọ́pàá, àmọ́ tó bá yá, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í fara wé àwọn ẹgbẹ́ wọn kan tó ti di oníwà ìbàjẹ́ àtàwọn ọ̀daràn tí wọ́n máa ń rí nígbà gbogbo. Ìwé What Cops Know fa ọ̀rọ̀ ọlọ́pàá kan, tó jẹ́ iṣẹ́ rẹ̀ ni láti máa káàkiri ìlú Chicago yọ pé: “Tá a bá ń sọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́pàá, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìwà ibi lojú wọn máa ń rí nígbà gbogbo, ohun tí wọ́n máa ń mọ̀ náà nìyẹn. Òun ló yí wọn ká. Wọ́n ń fọwọ́ kàn án . . . wọ́n ń tọ́ ọ wò . . . wọ́n ń gbóòórùn rẹ̀ . . . wọ́n ń gbọ́ nípa rẹ̀ . . . wọ́n sì ń dì í mú.” Béèyàn bá ń rí irú nǹkan tí kò bójú mu bẹ́ẹ̀ nígbà gbogbo, èèyàn náà ò ní pẹ́ ẹ́ dìdàkudà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ ribiribi làwọn ọlọ́pàá ń ṣe, iṣẹ́ wọn ò tíì kúnjú ìwọ̀n tó. Ṣé a lè retí pé nǹkan á sàn?

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

“Àbí Ẹ Ò Rí I Pé Àwọn Ọlọ́pàá Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Fọmọ Yọ!”

Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tí apá wọn kọ́kọ́ ká a láti ní àjọ ọlọ́pàá tó mọṣẹ́ dunjú. Wọ́n fẹ́ kí àwùjọ wọn wà létòlétò, kí ó dà bí ètò ìf ìwéránṣẹ́ wọn tó já fáfá tí kì í sì í fàkókò ṣòfò. Lọ́dún 1829, Ọ̀gá Àgbà fún Ọ̀rọ̀ Abẹ́lé, Ọ̀gbẹ́ni Robert (Bobby) Peel, rọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin láti fọwọ́ sí ẹ̀ka ọlọ́pàá tí wọn yóò mọ̀ sí London Metropolitan Police, kí olú iléeṣẹ́ wọn sì wà ní àdúgbò Scotland Yard. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ò kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ sí bí àwọn ọlọ́pàá ṣe fọwọ́ líle mú ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀mùtí àtàwọn tó máa ń ta tẹ́tẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì, nígbà tó yá, àwọn ọlọ́pàá di ọ̀rẹ́ aráàlú.

Lọ́dún 1851, tayọ̀tayọ̀ ni ìlú London fi ké sí gbogbo orílẹ̀-èdè àgbáyé láti wá sí ibi Ìpàtẹ Ńlá kan, láti wáá wo itú táwọn iléeṣẹ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń pa. Ó ya àwọn àlejò lẹ́nu láti rí bí àwọn ojú pópó wọn ṣe wà létòlétò tí kò sì sí àwọn ọ̀mùtí, àwọn aṣẹ́wó àtàwọn ọmọ asùnta. Àwọn ọlọ́pàá tó já fáfá ló ń darí àwọn èrò, tí wọ́n ń bá àwọn àlejò gbé ẹrù wọn, wọ́n ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti sọdá lójú pópó, kódà wọ́n tún ń gbé àwọn obìnrin tó jẹ́ àgbàlagbà sínú takisí. Abájọ, táwọn ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àtàwọn àlejò tó wá látilẹ̀ òkèèrè fi sọ pé, “Àbí ẹ ò rí i pé àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fọmọ yọ!”

Ó jọ pé wọ́n tún mọ ọ̀nà àtikáwọ́ ìwà ọ̀daràn débi pé, ẹni tó jẹ́ ọ̀gá ọlọ́pàá ìlú Chester lọ́dún 1873 tiẹ̀ fọkàn rò ó pé ìgbà kan máa dé tí kò ní sí ìwà ọ̀daràn mọ́ rárá àti rárá! Àwọn ọlọ́pàá tún ṣètò láti ní ọkọ̀ ìtọ́jú pàjáwìrì àti ọkọ̀ panápaná tí wọ́n á máa fi ṣiṣẹ́. Wọ́n ṣètò àwọn ẹgbẹ́ aláàánú tó máa ń fún àwọn aláìní ní bàtà àti aṣọ. Àwọn kan lára àwọn ẹgbẹ́ yìí dá àwọn ẹgbẹ́ ọ̀dọ́kùnrin sílẹ̀ torí àtilè sọ wọ́n dẹni tó ní láárí, wọ́n á mú wọn gbafẹ́ lọ fúngbà díẹ̀, wọ́n á sì tún ṣètò ìrìn-àjò ráńpẹ́ fún wọn lákòókò ìsinmi.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tuntun yìí láti f ìyà jẹ àwọn òṣìṣẹ́ wọn tí wọ́n jẹ̀bi ìwà ìbàjẹ́ àti híhùwà-ìkà-síni, síbẹ̀, inú ọ̀pọ̀ jù lọ wọn dùn pé àwọ́n lè mú ìlú wà lálàáfíà láìsí pé wọ́n le koko mọ́ àwọn èèyàn jù. Lọ́dún 1853, àwọn ọlọ́pàá àgbègbè Wigan nílùú Lancashire ń wá ojútùú sọ́rọ̀ àwọn awakùsà kan tó daṣẹ́ sílẹ̀ tí wọ́n sì ń fa wàhálà. Sájẹ́ǹtì onígboyà kan, tó ń bójú tó ọlọ́pàá mẹ́wàá péré, kọ̀ jálẹ̀ láti lo àwọn ìbọn tí ẹni tó ni iléeṣẹ́ ìwakùsà náà kó fún wọn. Lẹ́tà kan tí Hector Macleod gbà lọ́dún 1886, nígbà tóun náà wọṣẹ́ ọlọ́pàá bíi ti bàbá rẹ̀, fi irú ẹ̀mí tó gbòde nígbà yẹn hàn. Ohun tí lẹ́tà náà sọ rèé gẹ́gẹ́ bí a ti fà á yọ látinú ìwé The English Police: “Tó o bá ya òǹrorò ẹ̀dá, àwọn aráàlú ò ní í tì ẹ́ lẹ́yìn . . . Ohun tó máa ṣe aráàlú láǹfààní ni mo fi ṣáájú, nítorí ìránṣẹ́ ìlú ni ọlọ́pàá jẹ́, wọ́n fi ẹ́ sí àárín wọn fún àkókò kan ni, ojúṣe rẹ sì ni láti tẹ́ wọn lọ́rùn kó o sì tún tẹ́ ọ̀gá rẹ lọ́rùn pẹ̀lú.”

Hayden, ọ̀gá ọlọ́pàá fún London Metropolitan Police nígbà kan rí àmọ́ tó ti fẹ̀yìn tì sọ pé: “Wọ́n kọ́ wa pé ká máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu nígbà gbogbo torí kò sí béèyàn ṣe lè ṣiṣẹ́ ọlọ́pàá láṣeyọrí láìsí ìtìlẹyìn aráàlú. Ìgbà tó bá di dandan nìkan la máa ń lo kóńdó wa, àwọn ọlọ́pàá mìíràn kì í tiẹ̀ lò ó títí tí wọ́n máa fi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ọlọ́pàá.” Ohun mìíràn tó tún jẹ́ kí wọ́n máa fi ojú tó dára wo àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà yẹn ni eré orí tẹlifíṣọ̀n kan tó gbayì tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní Dixon of Dock Green. Ọdún mọ́kànlélógún gbáko ni wọ́n fi ṣe é, ó sì dá lórí ọlọ́pàá kan tó jẹ́ olóòótọ́, ẹni tó mọ gbogbo àwọn èèyàn tó wà ní àgbègbè tó ń ṣọ́ pátá. Ó dà bíi pé eré yìí fún àwọn ọlọ́pàá níṣìírí láti máa hùwà ọmọlúwàbí, àmọ́ ó dájú pé ó tún mú kí àwọn ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ọlọ́pàá.

Nígbà tó fi máa di ọdún 1960 sí 1969, ìwà àwọn èèyàn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì bẹ̀rẹ̀ sí í yí padà. Bí wọ́n ṣe máa ń fi orílẹ̀-èdè wọn yangàn tẹ́lẹ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́, wọn ò tún fọkàn tán àwọn aláṣẹ mọ́. Ìròyìn nípa ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àwọn ọlọ́pàá tapo sí aṣọ ààlà wọn láàárín ọdún 1970 sí 1979, láìka gbogbo ìsapá wọn sí, láti máa ṣọ́ àwọn àdúgbò káwọn aráàlú bàa lè gbárùkù tì wọ́n. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀sùn tí wọ́n ti fi kàn wọ́n pé wọ́n máa ń ṣe kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti pé wọ́n máa ń purọ́ ohun tójú wọn ò tó láti fẹ̀sùn kan àwọn tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀, àwọn ọlọ́pàá ti túbọ̀ ­ṣakitiyan gan an láti mú kí ìwà wọn dára sí i.

[Credit Line]

Fọ́tò tó wà lókè: http:/⁠/⁠www.constabulary.com

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àbí Iṣẹ́ Ìyanu Ṣẹlẹ̀ Ní Ìlú New York Ni?

Bí àwọn ọlọ́pàá bá fi tọkàntara ṣiṣẹ́, wọ́n máa ń ṣàṣeyọrí tó pọ̀ gan an. Ó pẹ́ táwọn èèyàn ti ka ìlú New York sí ọ̀kan lára àwọn ìlú tó léwu jù lọ lágbàáyé, nígbà tó sì máa fi di apá ìparí àwọn ọdún 1980 sí 1989, ọ̀rọ̀ ọ̀hún ti sú àwọn ọlọ́pàá ó sì jọ pé apá wọn ò fẹ́ ẹ́ ká a mọ́. Ìṣòro àìlówólọ́wọ́ ni kò jẹ́ kí ìjọba ìlú náà fi kún owó oṣù àwọn ọlọ́pàá, òun náà ló sì mú kí wọ́n dín lára iye wọn kù. Àyè wá gba àwọn tó ń ṣòwò oògùn olóró bí nǹkan míì, èyí sì mú kí ìwà ipá ròkè sí i lọ́nà tó burú jáì. Bí àwọn tó ń gbé ní àárín gbùngbùn ìlú náà bá ti ń lọ sùn lálẹ́ báyìí, ìró ìbọn ni wọ́n á máa gbọ́ ṣáá. Lọ́dún 1991, ìjààgboro tó ṣẹlẹ̀ láàárín onírúurú ẹ̀yà ìran kì í ṣe kékeré. Àwọn ọlọ́pàá pàápàá ṣe ìwọ́de tiwọn, ìtagbangba báyìí ni wọ́n sì ti ń fi ẹ̀hónú wọn hàn.

Àmọ́ ṣá o, ńṣe ni ọ̀gá ọlọ́pàá tuntun kan tó gorí àlééfà bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ níṣìírí, tó ń lọ sí àwọn àgọ́ ọlọ́pàá káàkiri láti bá wọn ṣèpàdé déédéé, nípa ọ̀nà tí wọ́n lè gbà yanjú ìṣòro tó ń kojú iṣẹ́ wọn. Nínú ìwé kan tí James Lardner àti Thomas Reppetto pawọ́ pọ̀ kọ, èyí tí wọ́n pè ní NYPD, wọ́n sọ pé: “Inú ìwé ìròyìn nìkan ni àwọn ọ̀gá tó wà láwọn àgọ́ ọlọ́pàá káàkiri ti máa ń kà nípa àwọn ọ̀gá fún ẹ̀ka ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àtàwọn olùdarí Ẹ̀ka Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Tó Ń Gbógun Ti Oògùn Olóró, wọn ò bá wọn pàdé rí. Àmọ́ ní báyìí, ńṣe ni gbogbo wọ́n jọ ń ṣèpàdé fún ọ̀pọ̀ wákàtí láìdánudúró.” Ìwà ọ̀daràn tó ń ṣẹlẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù gan-an. Iye ẹ̀sùn ìpànìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù díẹ̀díẹ̀, látorí ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méjì lọ́dún 1993 sí ẹgbẹ̀ta ó lé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [633] lọ́dún 1998—iye yìí ló tíì kéré jù lọ látọdún márùndínlógójì sẹ́yìn. Bí iṣẹ́ ìyanu ló ṣe rí lójú àwọn ara ìlú New York. Láàárín ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn, ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi tó àwọn ọlọ́pàá létí fi ìdá mẹ́rìnlélọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún lọ sílẹ̀.

Báwo ni wọ́n ṣe dín ìṣòro ìwà ọ̀daràn yìí kù? Ìwé ìròyìn The New York Times ti January 1, 2002, sọ pé, ohun kan tó jẹ́ kí wọ́n ṣàṣeyọrí ni ìlànà Compstat, ìyẹn ni Fífi Kọ̀ǹpútà Ṣe Ìwádìí. “Èyí ń jẹ́ kí wọ́n mọ ibi tí ìwà ọ̀daràn ti ń ṣẹlẹ̀, nípa ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ìsọfúnni láti àdúgbò kọ̀ọ̀kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, tí wọ́n á sì yanjú àwọn ìṣòro ọ̀hún ní kíá mọ́sá bí wọ́n bá ṣe ń yọjú.” Bernard Kerik, tó ti fìgbà kan jẹ́ kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá sọ pé: “A máa ń kíyè sí ibi tí ìwà ọ̀daràn ti ń ṣẹlẹ̀ àti ohun tó ń mú kó máa ṣẹlẹ̀, lẹ́yìn náà la máa wá kó àwọn ọlọ́pàá àtàwọn nǹkan tá a nílò lọ síbẹ̀, láti rí i dájú pé a túbọ̀ gbájú mọ́ àwọn àgbègbè náà. Ọ̀nà tí ìwà ọ̀daràn fi lè gbà dín kù nìyẹn.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Bí àgọ́ ọlọ́pàá àwọn ará Japan ṣe máa ń rí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọlọ́pàá tó ń darí ọkọ̀ lójú títì ní Hong Kong

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Kíkápá àwọn èrò níbi eré bọ́ọ̀lù ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ṣíṣèrànwọ́ fáwọn tó kàgbákò jàǹbá ọkọ̀ wà lára iṣẹ́ táwọn ọlọ́pàá ń ṣe