Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìfiniṣẹrú—Kò Tí Ì Dáwọ́ Dúró

Ìfiniṣẹrú—Kò Tí Ì Dáwọ́ Dúró

Ìfiniṣẹrú—Kò Tí Ì Dáwọ́ Dúró

ǸJẸ́ ìfiniṣẹrú ti kásẹ̀ ńlẹ̀? Inú ọ̀pọ̀ èèyàn ni ì bá dùn ká ló lè rí bẹ́ẹ̀. Ohun tí ọ̀rọ̀ náà, ìfiniṣẹrú máa ń mú wá síni lọ́kàn ni híhùwà-ìkà-síni àti níninilára. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rò pé ayé àtijọ́ ni irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ yẹn ti wáyé. Bí àpẹẹrẹ, ọkàn àwọn kan máa ń lọ sára àwọn ọkọ̀ òkun tí wọ́n fi ń kó ẹrú ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn. Àwọn ọkọ̀ òkun tó rí hẹ́gẹhẹ̀gẹ ni wọn máa ń lò, èyí tí wọ́n máa ń kó àìmọye èèyàn tí jìnnìjìnnì ti bá sínú rẹ̀, tí wọ́n á há wọn mọ́ inú ibi ìkẹ́rùsí nísàlẹ̀ ọkọ̀, nínú òórùn àti ìdọ̀tí tó kàmàmà.

Lóòótọ́, kò tún sí pé wọ́n ń fi irú àwọn ọkọ̀ òkun bẹ́ẹ̀ kó àwọn ẹrú la agbami òkun já mọ́, àwọn àdéhùn táwọn orílẹ̀-èdè káàkiri ayé sì ń ṣe lónìí ti fagi lé irú ìfiniṣẹrú bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ìfiniṣẹrú ṣì ń bá a lọ láìdáwọ́dúró. Àjọ kan tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, ìyẹn Àjọ Tí Ń Gbógun Ti Ìfiniṣẹrú Lágbàáyé gbéṣirò lé e pé àwọn èèyàn bí igba mílíọ̀nù ló ṣì ń gbé ìgbé ayé ẹrú lọ́nà kan tàbí òmíràn. Ipò tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ kò bójú mu, kódà ó fẹ́rẹ̀ẹ́ burú ju èyí táwọn ẹrú fara dà ní àwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá. Àwọn olùṣèwádìí kan tiẹ̀ sọ pé “iye àwọn èèyàn tó ń gbé ayé bí ẹrú lónìí pọ̀ ju ti ìgbàkigbà rí lọ nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn.”

Àwọn ohun tá à ń gbọ́ nípa àwọn tí wọ́n ń lò nílò ẹrú lóde òní ń bani lọ́kàn jẹ́. Ọmọ ọdún mẹ́wàá péré ni Kanji a tó máa ń bá àwọn ọ̀gá rẹ̀ da màlúù lójoojúmọ́. Ìgbà gbogbo làwọn ọ̀gá rẹ̀ tó jẹ́ òǹrorò èèyàn yìí sì máa ń lù ú. Ó sọ pé: “Ọjọ́ tórí bá bá mi ṣé ni mo máa ń rí búrẹ́dì tó ti gan paali jẹ, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, inú ebi ni mo máa wà ṣúlẹ̀. Wọn ò san kọ́bọ̀ fún mi rí fún gbogbo iṣẹ́ tí mò ń ṣe, torí pé ẹrú ni mí, àwọn ló ni mí. . . . Ńṣe làwọn ọmọdé ẹgbẹ́ mi máa ń bá ara wọn ṣeré, ó sàn fún mi kí n kú ju bí mo ṣe ń lálàṣí yìí lọ.”

Bíi ti Kanji, àwọn ọmọdé àtàwọn obìnrin làwọn èèyàn sábà máa ń lò bí ẹrú jù lóde òní. Wọ́n máa ń fipá mú wọn ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó, àwọn iṣẹ́ bíi ṣíṣe kápẹ́ẹ̀tì, ṣíṣe ojú ọ̀nà mọ́tò, bíbẹ́ ìrèké, tàbí iṣẹ́ aṣẹ́wó pàápàá. Wọ́n sì lè tà wọ́n ní owó táṣẹ́rẹ́ kan, bóyá bíi dọ́là mẹ́wàá péré. Fúnra àwọn òbí kan tiẹ̀ ni wọ́n máa ń fi àwọn ọmọ wọn sọfà tó bá nira fún wọn láti san gbèsè tí wọ́n jẹ.

Ǹjẹ́ irú ìròyìn báwọ̀nyí kì í kó ọ nírìíra? Kì í ṣe ìwọ nìkan o. Nínú ìwé Disposable People, èyí tí òǹṣèwé Kevin Bales kọ, ó sọ pé: “Ohun ìríra gbáà ni ìfiniṣẹrú jẹ́. Kì í wulẹ̀ ṣe jíjẹ òógùn olóòógùn mọ́ tẹni nìkan ni; ó tún jẹ́ jíja ẹnì kan lólè ìgbésí ayé rẹ̀.” Bá a bá wo bí ẹ̀dá ènìyàn ṣe ń hùwà ìkà sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ṣé nǹkankan wà tó lè mú wa gbà gbọ́ pé ìfiniṣẹrú tó ń gbèèràn yìí máa dópin lọ́jọ́ kan? Ìbéèrè yìí kàn ọ́ gbọ̀ngbọ̀n ju bí ìwọ fúnra rẹ ti rò lọ.

Gẹ́gẹ́ bí a ó ṣe rí i, kì í ṣe oríṣi ìfiniṣẹrú kan ṣoṣo ló wà. Onírúurú ìfiniṣẹrú ló wà, àwọn kan lára rẹ̀ sì kan gbogbo wa tá a wà láàyè. Nítorí náà, ó yẹ kí gbogbo wa mọ̀ bóyá ìran ènìyàn lè ní òmìnira tòótọ́. Ṣùgbọ́n lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká jíròrò ní ṣókí bí ìfiniṣẹrú ṣe bẹ̀rẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kì í ṣe orúkọ rẹ̀ gangan.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ó pẹ́ táwọn èèyàn ti ń fi àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé tó tòṣì ṣe òwò ẹrú

[Àwọn Credit Line]

Fọ́tò tó wà lókè: FỌ́TÒ UN 148000/Jean Pierre Laffont

Fọ́tò U.S. National Archives