Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìjọba Tó Fàyè Gba Onírúurú Ẹ̀sìn Láyé Ìgbà Tí Kò Sí Òmìnira Ìsìn

Ìjọba Tó Fàyè Gba Onírúurú Ẹ̀sìn Láyé Ìgbà Tí Kò Sí Òmìnira Ìsìn

Ìjọba Tó Fàyè Gba Onírúurú Ẹ̀sìn Láyé Ìgbà Tí Kò Sí Òmìnira Ìsìn

“KÁLUKÚ LÈ ṢE Ẹ̀SÌN TÓ BÁ WÙ Ú LÁÌSÍ PÉ À Ń FIPÁ MÚ UN, Ó SÌ LÁǸFÀÀNÍ LÁTI GBÁRÙKÙ TI ÀWỌN ONÍWÀÁSÙ TÍ WỌ́N JỌ JẸ́ ẸLẸ́SÌN KAN NÁÀ.”

BÍ WỌ́N bá ní kó o sọ ìgbà tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí sílẹ̀, ìgbà wo lo máa pè é? Ọ̀pọ̀ èèyàn lè rò pé ara àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé òfin orílẹ̀-èdè kan lóde òní ni, tàbí pé ara òfin ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn kan ni.

Àmọ́ ṣá o, ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé ó ti lé ní irínwó ọdún tí wọ́n ti ṣe ìpolongo yìí, ní orílẹ̀-èdè kan tó fàyè gba onírúurú ẹ̀sìn, láàárín ẹgbàágbèje orílẹ̀-èdè tí wọn ò fàyè gba ẹ̀sìn. Orílẹ̀-èdè wo là ń sọ gan-an? Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ ká wo ibi tí gbogbo ọ̀rọ̀ ọ̀hún ti bẹ̀rẹ̀.

Àìfàyègba Ẹ̀sìn Mìíràn Gbayé Kan

Ní Sànmánì Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú, àìfàyègba ẹ̀sìn mìíràn ló gbayé kan, ó sì tún gbóná janjan ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún. Ọ̀ràn ẹ̀sìn ló tapo síná àwọn ogun bíbanilẹ́rù ọlọ́gbàrá ẹ̀jẹ̀, tó bẹ́ sílẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè bí ilẹ̀ Faransé, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Jámánì, àti Netherlands. Láti ọdún 1520 sí 1565, nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] èèyàn ni wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n jẹ́ aládàámọ̀, tí wọ́n sì pa láwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kristi ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìgbàkígbà tí ẹnikẹ́ni bá kọminú sí ìlànà tàbí àṣà àtayébáyé kan, pàápàá bó bá lọ jẹ́ lórí ọ̀ràn ẹ̀sìn, lonítọ̀hún máa rí àtakò gbígbóná janjan.

Ẹ̀kọ́ Ìjọ Kátólíìkì kan tọ́jọ́ ti pẹ́ tí wọ́n ti ń ṣàríyànjiyàn lórí rẹ̀ ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, ìyẹn ìgbàgbọ́ pé ẹni mẹ́ta ló para pọ̀ di Ọlọ́run. Àní, òpìtàn Earl Morse Wilbur ṣàlàyé pé “kékeré kọ́ ni àríyànjiyàn táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólíìkì bá ara wọn ṣe lórí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ní Sànmánì Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú, àwọn Póòpù pàápàá ò sì gbẹ́yìn nínú arukutu ọ̀hún.” Àmọ́ ṣá o, irú àwọn àríyànjiyàn bẹ́ẹ̀ kì í sábà dé sàkáání àwọn gbáàtúù èèyàn, torí wọ́n retí pé kí àwọn yẹn gba irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ gbọ́ láìṣèwádìí, gẹ́gẹ́ bí “àdììtú tó yé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo.”

Síbẹ̀, àwọn èèyàn kan ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún ta ko àwọn ìlànà àtayébáyé wọ̀nyẹn, wọ́n ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lérò àtilàdí irú àwọn àdììtú bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ṣe atọ́nà ara wọn ni sola Scriptura (Ìwé Mímọ́ nìkan la tẹ̀ lé). Àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì sábà máa ń ṣe inúnibíni gbígbóná janjan sáwọn tí kò bá fara mọ́ ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan. Wọ́n tiẹ̀ pe àwọn kan lára àwọn tí wọ́n yapa wọ̀nyí ní ẹlẹ́sìn Unitarian lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, láti fi wọ́n hàn yàtọ̀ sáwọn onígbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan. Orúkọ awúrúju ni àwọn tí kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan wọ̀nyí fi ń bojú bí wọ́n ti ń tẹ àwọn ìwé wọn jáde lóríṣiríṣi fún gbogbo èèyàn láti kà, wọ́n sì ń fara pa mọ́ kí wọ́n má bàa ṣenúnibíni sí wọn. Àwọn mìíràn tún wà tí wọn kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, òléwájú làwọn náà nínú akitiyan láti rí i pé òmìnira ìsìn wà fún gbogbo èèyàn. Kódà àwọn kan, irú bí ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ọmọ ilẹ̀ Sípéènì náà, Michael Servetus, fi ẹ̀mí ara wọn dí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. a

Òmìnira Ìsìn Ló Mú Wọn Ṣọ̀kan

Orílẹ̀-èdè kan wà, tó jẹ́ pé dípò tí ì bá fi máa jagun ẹ̀sìn tàbí kó máa ṣenúnibíni sáwọn tó yapa, ìgbésẹ̀ tó gbé yàtọ̀ gédégédé sí tàwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Orílẹ̀-èdè ọ̀hún ni Transylvania, ilẹ̀ kan tó ń dá ìjọba ṣe lásìkò yẹn àmọ́ tó ti di apá kan orílẹ̀-èdè Romania ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù báyìí. Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Hungary náà, Katalin Péter ṣàlàyé pé Ọbabìnrin Isabella ti ilẹ̀ Transylvania, ẹni tó delé fún ọkọ rẹ̀ tó di olóògbé, “gbìyànjú láti yẹra fún ìforígbárí láàárín ẹ̀sìn kan sí èkejì nípa fífàyè gba gbogbo ẹ̀sìn.” Láti ọdún 1544 sí 1574, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ilẹ̀ Transylvania, tí wọ́n tún ń pè ní Ìpàdé Àwọn Ọ̀tọ̀kùlú ṣe òfin méjìlélógún tó fàyè gba òmìnira ìsìn.

Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn Ìpàdé Àwọn Ọ̀tọ̀kùlú tí wọ́n ṣe nílùú Torda lọ́dún 1557, ọbabìnrin ọ̀hún, pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, pàṣẹ pé “kálukú [lè] máa ṣe ẹ̀sìn tó bá wù ú, bóyá ìlànà ẹ̀sìn ọ̀hún jẹ́ tuntun o tàbí ó jẹ́ ti àtayébáyé. Bákan náà ni a tún fẹ́ kí kálukú pinnu fúnra rẹ̀ ohun tó bá wù ú láti gbà gbọ́, àmọ́ ṣá o, èyí á jẹ́ kìkì bí kò bá ti fi ṣe ìpalára fún ẹnikẹ́ni.” Àwọn èèyàn sọ pé òfin yìí ni “òfin àkọ́kọ́ tó máa fún àwọn aráàlú ní òmìnira ìjọsìn tó dájú nínú gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé.” Àkókò tí ọmọ Isabella, ìyẹn ni Sigismund John Kejì, ẹni tó gorí ìtẹ́ lọ́dún 1559, ń ṣàkóso ni òmìnira ìsìn wá di ohun tó gbòde kan ní orílẹ̀-èdè Transylvania.

Àríyànjiyàn Ìta Gbangba

Ẹlòmíràn tó tún jà fitafita lòdì sí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ní orílẹ̀-èdè Transylvania ni oníṣègùn ọmọ ilẹ̀ Ítálì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Georgio Biandrata. Iyèméjì tó ní nípa ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan túbọ̀ fìdí múlẹ̀ lásìkò tó ń gbé ní ilẹ̀ Ítálì àti Switzerland, níbi tí ọ̀pọ̀ àwọn tó sá fi orílẹ̀-èdè wọn sílẹ̀ nítorí tí wọn kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan lọ forí pa mọ́ sí. Lẹ́yìn tó ṣí lọ sí ilẹ̀ Poland, Biandrata ṣe gudugudu méje láti gbárùkù ti Minor Church (Ṣọ́ọ̀ṣì Kékeré), èyí tá a wá mọ̀ sí Àwọn Ará ní Poland lẹ́yìn náà. b Lọ́dún 1563, wọ́n yàn án sípò gẹ́gẹ́ bí oníṣègùn àti abọ́bajíròrò fún Sigismund, èyí ló mú kó ṣí wá sí Transylvania.

Ẹlòmíràn tó jẹ́ akọ̀wékọwúrà ní Transylvania, tí òun náà tún kọminú sí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ni Francis Dávid, alábòójútó Ìjọ Alátùn-únṣe àti oníwàásù láàfin ọba Sigismund. Ó kọ̀wé nípa bí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ṣe lọ́jú pọ̀, tí kò sì ṣeé ṣàlàyé, ó ní: “Bó bá jẹ́ pé gbogbo àwọn ẹ̀kọ́ tó lọ́jú pọ̀ wọ̀nyí pọn dandan fún ìgbàlà ni, ó dájú pé kò sí Kristẹni gbáàtúù kan tó máa rí ìgbàlà, torí kò ní lóye wọn páàpáà títí dọjọ́ ikú rẹ̀.” Dávid àti Biandrata pawọ́ pọ̀ tẹ ìwé kan jáde, èyí tó ní díẹ̀ lára àwọn àkọsílẹ̀ Servetus nínú; wọ́n ṣe é láti fi ṣàpọ́nlé Sigismund.

Awuyewuye lórí ọ̀ràn Mẹ́talọ́kan bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i títí tó fi di àríyànjiyàn ìta gbangba. Níbàámu pẹ̀lú ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé, ìyẹn sola Scriptura (Ìwé Mímọ́ nìkan la tẹ̀ lé), Biandrata fòté lé e pé ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ nìkan làwọ́n máa gbé ìjiyàn àwọn kà, kì í ṣe orí ìmọ̀ ọgbọ́n orí. Lẹ́yìn ìjiyàn kan tó wáyé lọ́dún 1566 àmọ́ tí wọn ò forí rẹ̀ tì síbì kan, Sigismund fún àwọn tí kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ní ilé ìtẹ̀wé kan láti fi mú èròǹgbà wọn tàn kálẹ̀, kó délé dóko.

Biandrata àti Dávid bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn ní pẹrẹu, wọ́n sì jára mọ́ ọn títí wọ́n fi ṣe ìwé náà, De falsa et vera unius Dei Patris, Filii, et Spiritus Sancti cognitione (Ìmọ̀ Èké àti Ìmọ̀ Òtítọ́ Nípa Ìṣọ̀kan Tó Wà Láàárín Ọlọ́run, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́). Ìwé náà ní ìtàn àwọn ẹni tí kò gba ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan gbọ́ nínú. Ní orí kan nínú ìwé náà, wọ́n fi àwòrán kan hàn tí wọ́n dìídì yà bẹ́ẹ̀ láti fi tàbùkù ọ̀nà tí wọ́n gbà ya àwòrán Mẹ́talọ́kan lónírúurú ṣọ́ọ̀ṣì. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún àwọn alátakò láti rí àwọn àwòrán inú ìwé ọ̀hún, wọ́n ní ó tàbùkù síni, ni wọ́n bá gbìyànjú láti run gbogbo ẹ̀dà tí wọ́n tẹ̀ jáde. Ìwé yìí ló mú kí ìjíròrò máa gorí ìjíròrò. Ìyẹn ló sì mú kí Sigismund ṣètò fún àríyànjiyàn ẹlẹ́ẹ̀kejì.

Wọ́n Borí Nítorí Wọ́n Fìmọ̀ Ṣọ̀kan

Aago márùn-ún ìdájí ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ àríyànjiyàn náà ní March 3, 1568. Èdè Látìn ni wọ́n sì fi ṣe é fún ọjọ́ mẹ́wàá gbáko. Peter Melius, olùdarí Ìjọ Alátùn-únṣe nílẹ̀ Transylvania ló jẹ́ abẹnugan fún àwọn onígbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan. Òun àtàwọn tó gbà gbọ́ nínú ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan lo ìwé tó ní àkọsílẹ̀ ìgbàgbọ́ ṣọ́ọ̀ṣì nínú, àwọn ìwé tí àwọn Bàbá Ìjọ kọ, àwọn ìlànà ẹ̀kọ́ ìsìn Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, àti Bíbélì. Àmọ́ ní ìdàkejì, Dávid lo Bíbélì nìkan láti fi ti àlàyé rẹ̀ lẹ́yìn. Dávid ṣàlàyé pé Baba dúró fún Ọlọ́run, Ọmọ wà lábẹ́ Baba, ẹ̀mí sì jẹ́ agbára Ọlọ́run. Sigismund tó fẹ́ràn ọ̀ràn ẹ̀sìn bí nǹkan míì kúkú bá wọn dá sí ọ̀rọ̀ ọ̀hún, torí ó gbà pé ìjíròrò lohun tó dára jù lọ láti fi rídìí òtítọ́. Wíwà tó wà níbẹ̀ ló jẹ́ kí kálukú sọ tẹnu rẹ̀ láìfọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ariwo ń ta gèè lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nígbà tí ọ̀rọ̀ bá ká kálukú lára.

Àwọn tí kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ló borí nínú àríyànjiyàn ọ̀hún. Tìlù tìfọn làwọn aráàlú Dávid fi kí i káàbọ̀ sí ìlú Kolozsvár tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ (orúkọ ìlú náà ní báyìí ni Cluj-Napoca, ní ilẹ̀ Romania). Ìtàn fi yé wa pé nígbà tó wọ inú ìlú rẹ̀, ńṣe ló dúró sórí òkìtì àpáta kan ní igun òpópónà, tó ń fi ìdánilójú sọ àwọn ohun tó gbà gbọ́ débi pé ó ń rọ gbogbo èèyàn láti tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ rẹ̀.

Ìyípadà Sigismund sí Ẹ̀sìn Unitarian àti Ikú Rẹ̀

Ṣáájú àsìkò yìí, èdè Látìn, tó jẹ́ pé àwọn ọ̀mọ̀wé nìkan ló gbọ́ ọ ni wọ́n fi ń ṣe àwọn àríyànjiyàn náà. Àmọ́ ṣá, Dávid fẹ́ kí gbogbo èèyàn nílé lóko gbọ́ nípa èròǹgbà rẹ̀. Nítorí náà, pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Sigismund, èdè Hungary ni wọ́n fi ṣe àríyànjiyàn tó tẹ̀ lé e ní ìlú Nagyvárad (orúkọ ìlú náà ní báyìí ni Oradea, ní ilẹ̀ Romania). Àríyànjiyàn ọ̀hún wáyé ní October 20, 1569. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Sigismund ló ṣe alága fún àwùjọ méjèèjì.

Peter Melius tó gba ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan gbọ́ kéde pé ní òru ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ àríyànjiyàn náà, Olúwa ti fi irú ẹni tí ó jẹ́ lóòótọ́ han òun. Ni ọba wá dá a lóhùn pé: “Àlùfáà Peter, bó bá jẹ́ pé nínú ìran tó o rí lóru àná lo ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ìsọfúnni nípa ẹni tí Ọmọ Ọlọ́run jẹ́, jẹ́ kí n béèrè lọ́wọ́ rẹ, kí lohun tó o ti ń wàásù rẹ̀ látẹ̀yìnwá? Ó dájú pé títí di àkókò yìí, ńṣe lo kàn ń tan àwọn èèyàn jẹ!” Nígbà tí Melius sọ̀rọ̀ burúkú sí Dávid, Ọba Sigismund bá a wí, ó wá rán onígbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan ọ̀hún létí pé “ìgbàgbọ́ jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run” àti pé “wọn kì í fipá múni ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn èèyàn ò bá fẹ́ ṣe.” Nínú ọ̀rọ̀ tí ọba ọ̀hún sọ láti fi kádìí àríyànjiyàn náà, ó sọ pé: “A pa á láṣẹ pé kí òmìnira ẹ̀rí ọkàn wà káàkiri orílẹ̀-èdè wa.”

Lẹ́yìn àríyànjiyàn náà, Sigismund àti ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀tọ̀kùlú ìjọba rẹ̀ di ẹni tá a yí lọ́kàn padà sí ìsìn Unitarian. Lọ́dún 1571, wọ́n ṣe òfin kan tí ọba fọwọ́ sí, èyí tó fìdí Ìjọ Unitarian múlẹ̀ lábẹ́ òfin. Orílẹ̀-èdè Transylvania nìkan ni ibi tí àwọn ẹlẹ́sìn Unitarian ti lè fẹsẹ̀ wọnsẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, àwọn Ọmọlẹ́yìn Luther, àtàwọn Ọmọlẹ́yìn Calvin. Àwọn èèyàn sì mọ Sigismund gẹ́gẹ́ bí ọba kan ṣoṣo tó tíì tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn èyíkéyìí tó lòdì sí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan. Ó bani nínú jẹ́ pé, kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni ọba tó jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún yìí fara pa, nígbà tó gbáfẹ́ lọ láti lọ ṣọdẹ pẹ̀lú Dávid àti Biandrata, oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà ló sì kú.

Stephen Báthory, tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ló gorí ìtẹ́ lẹ́yìn rẹ̀. Ó mú un dá àwọn aráàlú lójú pé òun náà fara mọ́ òfin tó fàyè gba onírúurú ẹ̀sìn, àmọ́ òun kò ní gbà kí wọ́n ṣe àtúnṣe èyíkéyìí sí i. Stephen ti kọ́kọ́ sọ pé àwọn èèyàn ni òun ń ṣàkóso kì í ṣe ẹ̀rí ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ tó fòfin de títẹ ìwé jáde, èyí tó jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti tan ìgbàgbọ́ kálẹ̀. Wọ́n rọ Dávid lóyè, wọ́n sì yọ àwọn ẹlẹ́sìn Unitarian mìíràn kúrò níbi iṣẹ́ wọn, láàfin àti láàárín ìlú.

Nígbà tí Dávid bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn pé ó lòdì láti máa jọ́sìn Kristi, wọ́n ṣe òfin kan pé kò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́. Láìka pé wọ́n fòfin dè é sí, ẹ̀ẹ̀mejì ni Dávid wàásù lọ́jọ́ Sunday tó tẹ̀ lé e. Wọ́n fàṣẹ ọba mú un, wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ńṣe ló ń ṣe “ìdásílẹ̀” ẹ̀sìn mìíràn, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n gbére. Àjàalẹ̀ ọba ló kú sí lọ́dún 1579. Ṣáájú kí Dávid tó kú, ohun tó kọ sára ògiri àtìmọ́lé rẹ̀ rèé: “Àwọn póòpù ò báà lo idà . . . tàbí kí wọ́n fi ikú halẹ̀, òtítọ́ ló máa lékè bópẹ́ bóyá. . . . Ó dá mi lójú pé lẹ́yìn tí mo bá kú, ẹ̀kọ́ àwọn wòlíì èké máa wó palẹ̀ ni.”

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Lára Ọba Náà

Ọba John Sigismund gbé ètò ẹ̀kọ́, orin kíkọ, àti iṣẹ́ ọnà lárugẹ. Àmọ́, ọjọ́ díẹ̀ ló lò nílé ayé, ṣàṣà sì ni ìgbà tí àìsàn kì í dá a wólẹ̀. Ní gbogbo ìgbà tó ń ṣàkóso, ńṣe làwọn èèyàn orílẹ̀-èdè rẹ̀ ń gbógun tì í ṣáá, ó kéré tán, ìgbà mẹ́sàn-án ni wọ́n gbìyànjú láti ṣekú pa á. Bẹ́ẹ̀ sì làwọn ìjọba ilẹ̀ òkèèrè náà ò yéé súnná sí ìṣọ̀tẹ̀ tó ń wáyé láàárín orílẹ̀-èdè rẹ̀. Àwọn èèyàn sábà máa ń ṣáátá ọba tó fàyè gba gbogbo ìsìn yìí látàrí ọwọ́ tó fi mú ọ̀ràn ẹ̀sìn. Ẹnì kan tó jẹ́ alátakò ọba yìí sọ pé “ó dájú pé ọ̀run àpáàdì ló lọ.”

Bó ti wù kó rí, òpìtàn Wilbur, ṣàkópọ̀ bí gbogbo ọ̀rọ̀ ọ̀hún ṣe jẹ́, ó sọ pé: “Lọ́dún tí Ọba John [Sigismund] ṣe ìwé òfin rẹ̀ tó kẹ́yìn, èyí tó fi mú òmìnira ìsìn dá àwọn aráàlú lójú, títí kan àwọn ẹ̀ya ìsìn alátùn-únṣe, táwọn ẹlẹ́sìn mìíràn máa ń ṣàtakò gbígbóná janjan sí, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń ṣẹlẹ̀ káàkiri. Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì ṣì ń kan sáárá sí Calvin fún bó ṣe sun Servetus láàyè, Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ tí àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ṣe ṣì ń gbẹ̀mí àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì ní ilẹ̀ Netherlands, . . . ó sì máa lé ní ogójì ọdún sí i kí wọ́n tó dáwọ́ sísun èèyàn láàyè dúró ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nítorí pé ìgbàgbọ́ wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo èèyàn.”

Ní ti tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí oníròyìn kan ti sọ, “tá a bá ní ká fi ìlànà ìgbà èyíkéyìí wò ó, pàápàá ìlànà tí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ń tẹ̀ lé nígbà ayé Ọba John Sigismund—akíkanjú alákòóso ni. . . . Bó ṣe gbòmìnira ìsìn láyè ló jẹ́ káwọn èèyàn máa kan sáárá sí ìṣàkóso rẹ̀.” Níwọ̀n bó ti mọ̀ pé ìlú ò lè tòrò bí kò bá sí àlàáfíà láàárín àwọn ẹlẹ́sìn, èyí ló mú kó jà fitafita láti fìdí òmìnira ẹ̀rí ọkàn àti òmìnira ìsìn múlẹ̀ lábẹ́ òfin.

Lọ́jọ́ tiwa lónìí, táwọn èèyàn kì í fẹ́ rí ẹlẹ́sìn mìíràn sójú rárá, a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ bá a bá ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè kóńkóló ayé ọjọ́un yìí. Láàárín àkókò kúkúrú yẹn, ìjọba tó fàyè gba onírúurú ẹ̀sìn ni ilẹ̀ Transylvania jẹ́ lóòótọ́ láyé ìgbà tí kò sí òmìnira ìsìn.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Jí!, May 22, 1989, ojú ìwé 19 sí 22.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 16]

“Wọn kì í fipá múni ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn èèyàn ò bá fẹ́ ṣe . . . a pa á láṣẹ pé kí òmìnira ẹ̀rí ọkàn wà káàkiri orílẹ̀-èdè wa.”—Ọba Sigismund John Kejì

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14, 15]

Georgio Biandrata

Lára àwọn ojú ewé tó wà nínú ìwé tí Biandrata àti Dávid tẹ̀ jáde àti méjì nínú àwọn àwòrán tó ya àwọn onígbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan lẹ́nu

Francis Dávid dúró níwájú níbi Ìpàdé Àwọn Ọ̀tọ̀kùlú ìlú Torda

[Àwọn Credit Line]

Two Trinity line drawings: © Cliché Bibliothèque nationale de France, Paris; àwọn àwòrán yòókù: Országos Széchényi Könyvtár

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 16]

Ojú ìwé 2 àti 16: Országos Széchényi Könyvtár