Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọjọ́ Pẹ́ Táwọn Èèyàn Ti Ń Ṣakitiyan Láti Fòpin Sí Ìfiniṣẹrú

Ọjọ́ Pẹ́ Táwọn Èèyàn Ti Ń Ṣakitiyan Láti Fòpin Sí Ìfiniṣẹrú

Ọjọ́ Pẹ́ Táwọn Èèyàn Ti Ń Ṣakitiyan Láti Fòpin Sí Ìfiniṣẹrú

“Ohun tí jíjẹ́ ẹrú túmọ̀ sí rèé: ká hùwà ìkà síni ká sì fara dà á, ká fipá jẹni níyà láìṣẹ̀ láìrò.”—Euripides, òǹkọ̀wé eré onítàn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì ní ọ̀rúndún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Tiwa

ÀṢÀ ìfiniṣẹrú ti wà látọjọ́ pípẹ́, ohun tá à ń gbọ́ nípa rẹ̀ sì máa ń kọni lóminú. Látìgbà tí ọ̀làjú ti bẹ̀rẹ̀ ní Íjíbítì àti Mesopotámíà làwọn orílẹ̀-èdè tó lágbára ti máa ń fi àwọn orílẹ̀-èdè alámùúlégbè wọn, tí kò lágbára tó wọn ṣẹrú. Bí ọ̀kan lára àwọn ìwà ìkà bíburú jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí, ìyẹn rírẹ́ ọmọlàkejì ẹni jẹ.

Ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì ṣáájú Sànmánì Tiwa, ilẹ̀ Íjíbítì kó odindi orílẹ̀-èdè kan tí àwọn èèyàn inú rẹ̀ á tó ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù lẹ́rú. (Ẹ́kísódù 1:13, 14; 12:37) Nígbà tí Gíríìsì ń ṣàkóso lórí Mẹditaréníà, ọ̀pọ̀ ìdílé ní ilẹ̀ Gíríìsì ló ní ẹrú kan ó kéré tán—bó ṣe fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìdílé kọ̀ọ̀kan ló ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ láwọn orílẹ̀-èdè kan lónìí. Aristotle, tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì gbà pé kò sóhun tó burú nínú àṣà yìí. Ó sọ pé ọ̀nà méjì làwa ẹ̀dá pín sí, àwọn kan ọ̀gá àwọn kan ẹrú, àwọn ọ̀gá ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa pàṣẹ, àmọ́ ńṣe làwọn ẹrú kàn wáyé àtimáa gbọ́ràn síni lẹ́nu ṣáá.

Bí àwọn ará Róòmù ṣe gba ìfiniṣẹrú tún pabanbarì ju ti àwọn ará Gíríìsì lọ. Nígbà ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdajì gbogbo àwọn tó ń gbé ìlú Róòmù ló jẹ́ ẹrú, ìyẹn túmọ̀ sí pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló jẹ́ ẹrú níbẹ̀. Ó sì jọ pé ọdọọdún ni Ilẹ̀ Ọba Róòmù máa ń kó ìdajì mílíọ̀nù èèyàn lẹ́rú, láti kọ́ àwọn ọwọ̀n ìrántí, láti ṣiṣẹ́ ìwakùsà, láti ṣiṣẹ́ ọ̀gbìn lóko àti láti máa ṣiṣẹ́ láwọn ilé alágbàlá gbàràmù gbaramu táwọn ọlọ́rọ̀ ń gbé. a Ẹrú ni àwọn ará Róòmù sábà máa ń fi àwọn tí wọ́n bá mú ti ogun bọ ṣe. Ó ní láti jẹ́ pé nítorí àtilè ní ọ̀pọ̀ ẹrú ni wọ́n ṣe máa ń jagun ṣáá.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìfiniṣẹrú rọlẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn tí Ilẹ̀ Ọba Róòmù ṣubú, àṣà yìí tún ń bá a nìṣó. Ìwé náà, Domesday Book (1086 C.E.), jẹ́ ká mọ̀ pé ìdá kan nínú mẹ́wàá gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ní sànmánì tí ọ̀làjú bẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló jẹ́ ẹrú. Síbẹ̀, àwọn ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ò yéé kó àwọn ará ìlú tí wọ́n bá ṣẹ́gun lẹ́rú.

Àmọ́ ṣá o, látìgbà ayé Kristi, kò sí àgbáálá ilẹ̀ kankan tó tíì jìyà àbárèbábọ̀ òwò ẹrú tó Áfíríkà. Àní, ṣáájú àkókò Jésù pàápàá làwọn ará Íjíbítì ìgbàanì ti máa ń ra àwọn èèyàn lẹ́rú láti Etiópíà tí wọ́n á sì tún tà wọ́n. Láàárín nǹkan bí àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀fà [1,250] ọdún, àwọn ará Áfíríkà bíi mílíọ̀nù méjìdínlógún ni àwọn òpìtàn fojú díwọ̀n pé wọ́n kó lẹ́rú lọ sí Yúróòpù àti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé, láwọn ibi tí wọ́n ti nílò ẹrú gan-an. Nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní àgbáálá ilẹ̀ Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ ètò ìgbókèèrè-ṣàkóso ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, ńṣe lọ̀nà àtimáa ṣòwò ẹrú ṣí sílẹ̀ fún wọn, kò sì pẹ́ tí òwò ẹrú fi di ọ̀kan lára àwọn okòwò tó ń mówó wọlé jù lọ lágbàáyé. Àwọn òpìtàn gbéṣirò lé e pé láàárín ọdún 1650 àti 1850, àwọn ẹrú tó lé ní mílíọ̀nù méjìlá ni wọ́n kó lọ láti ilẹ̀ Áfíríkà. b Ọjà ẹrú ni wọ́n ti ta ọ̀pọ̀ lára wọn.

Akitiyan Láti Fòpin sí Ìfiniṣẹrú

Jálẹ̀ ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti àwọn orílẹ̀-èdè lódindi ti làkàkà láti gba ara wọn sílẹ̀ lóko ẹrú. Ní ọ̀rúndún kìíní ṣáájú kí Kristi tóó wá, Spartacus léwájú ogun kan tí ẹgbàá márùndínlógójì [70,000] àwọn ẹrú ilẹ̀ Róòmù jà, àmọ́ pàbó ni ogun tí wọ́n jà láti gbòmìnira náà já sí. Ṣùgbọ́n bí àwọn ẹrú ní ilẹ̀ Haiti ṣe jìjàgbara ní nǹkan bí ọ̀rúndún méjì sẹ́yìn yọrí sí rere, èyí ló mú kí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ọ̀hún di ẹni tó bẹ̀rẹ̀ sí í dá ìjọba ara wọn ṣe láti ọdún 1804.

Ní ti gidi, àṣà ìfiniṣẹrú pẹ́ gan-an kó tó kásẹ̀ nílẹ̀ ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àwọn ẹrú kan wà tí wọ́n jà fitafita láti dá ara wọn sílẹ̀ lómìnira, tí wọ́n sì tún ṣakitiyan láti dá àwọn èèyàn wọn sílẹ̀. Àwọn èèyàn kan sì wà tí wọn kì í ṣe ẹrú àmọ́ tó jẹ́ pé tọkàntọkàn ni wọ́n fi lòdì sí ìfiniṣẹrú, wọ́n máa ń ké tantan pé kí ìjọba fòfin dè é, wọ́n sì máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹrú tó sá. Síbẹ̀, apá ìparí ọ̀rúndún kọkàndínlógún ni ìjọba Amẹ́ríkà ṣẹ̀ṣẹ̀ tó fagi lé àṣà yìí káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Àmọ́, ọjọ́ tiwa lónìí wá ńkọ́ o?

Ṣé Kì Í Ṣe Pé Pàbó Ni Gbogbo Akitiyan Wọ̀nyí Ń Já Sí?

Ohun tó wà nínú ìwé àkọsílẹ̀ Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé ni pé: “A kò gbọ́dọ̀ fi ẹnikẹ́ni ṣẹrú tàbí ká mú un sìnrú; onírúurú àṣà ìfiniṣẹrú àti ṣíṣòwò ẹrú ni a ó kà léèwọ̀.” Láìsí àní-àní, èròǹgbà wọn yìí, tí wọ́n fi tọkàntara polongo lọ́dún 1948 wúni lórí gidigidi. Ọ̀pọ̀ olóòótọ́ èèyàn ti fi tinútinú lo àkókò wọn, agbára wọn, àtàwọn ohun ìní wọn láti fi mú kí àṣà yìí kásẹ̀ nílẹ̀. Bó ti wù kó rí, àtiṣàṣeyọrí kì í yá.

Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ti fi hàn, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ṣì ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó láìgba kọ́bọ̀ nínú ipò tó ń kóni nírìíra. Ńṣe ni wọ́n sì ra ọ̀pọ̀ lára wọn tàbí tí wọ́n tà wọ́n sóko ẹrú tìpá tìkúùkù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ń làkàkà láti fòpin sí ìfiniṣẹrú, táwọn orílẹ̀-èdè kárí ayé sì ń fọwọ́ sí àwọn òfin láti fagi lé e, òmìnira tòótọ́ kò ì tíì tẹ gbogbo èèyàn lọ́wọ́. Ètò ọrọ̀ ajé jákèjádò ayé ti mú kí ṣíṣe òwò ẹrú ní bòókẹ́lẹ́ túbọ̀ di iṣẹ́ tó ń mówó gọbọi wá. Ó dà bíi pé kàkà kéwé àgbọn ìfiniṣẹrú dẹ̀, ńṣe ló ń le koko sí i, tó túbọ̀ ń fìdí múlẹ̀ ṣinṣin láàárín ẹ̀dá èèyàn. Ṣé ó wá jẹ́ pé kò sí ojútùú kankan ni? Ẹ jẹ́ ká gbé èyí yẹ̀ wò.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìròyìn àtayébáyé kan fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ará Róòmù kọ̀ọ̀kan tí wọ́n lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ní àwọn ẹrú tó tó ọ̀kẹ́ kan [20,000].

b Àwọn àlùfáà burúkú kan tiẹ̀ sọ pé inú Ọlọ́run dùn sí bí wọ́n ṣe ń ta ọmọ èèyàn, tí wọ́n ń hùwà ìkà sí wọn. Látàrí èyí, ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì ń ronú lọ́nà òdì pé Bíbélì dá irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀ láre. Irọ́ gbuu lèyí, Bíbélì kò tì í lẹ́yìn rárá. Jọ̀wọ́ wo àpilẹ̀kọ náà, “Ojú Ìwòye Bíbélì: Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fara Mọ́ Ṣíṣe Òwò Ẹrú?,” nínú ìtẹ̀jáde Jí! September 8, 2001.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]

Àwọn tí wọ́n kó wá láti Áfíríkà nínú àwọn ọkọ̀ òkun tí wọ́n fi ń kó ẹrú (òkè) ni wọ́n sábà máa ń tà ní àwọn ọjà ẹrú ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà láyé ìgbà kan

[Àwọn Credit Line]

Godo-Foto

Archivo General de las Indias