Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Làjọgbé Èmi àti Alábàágbé Mi Ṣe Lè Wọ̀?

Báwo Làjọgbé Èmi àti Alábàágbé Mi Ṣe Lè Wọ̀?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Làjọgbé Èmi àti Alábàágbé Mi Ṣe Lè Wọ̀?

“Ṣe ni mo máa ń fẹ́ kí ilé ìdáná mọ́ tónítóní. Àmọ́ kò séyìí tó kan àwọn tá a jọ ń gbénú yàrá, abọ́ oúnjẹ ì báà wà nílẹ̀ káàkiri tàbí kí ìkòkò ọbẹ̀ wà lórí sítóòfù. Àgunlá, àguntẹ̀tẹ̀.” —Lynn. a

ÀWỌN ALÁBÀÁGBÉ. Òǹkọ̀wé Kevin Scoleri sọ pé: “Bí wọn ò bá jẹ́ kòríkòsùn, wọ́n á jẹ́ ata àti ojú.” Bíbá èèyàn gbé lè má fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ nǹkan bàbàrà sí ọ, àmọ́ kò sí àní-àní pé ìpèníjà ńlá ló jẹ́ láti máa bá ẹlòmíràn gbé. b Èdè àìyedè tó sábà máa ń wáyé láàárín àwọn ọmọ yunifásítì tí wọ́n ń bára wọn gbé wọ́pọ̀ débi pé, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn U.S.News & World Report ṣe sọ, ọ̀pọ̀ yunifásítì ló ń “sapá gan an” láti lè jẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọwọ́ ara wọn. Wọ́n tún máa ń ṣe “ètò píparí aáwọ̀,” àti àwọn àpérò mìíràn lóríṣiríṣi.

Bíbá àwọn ẹlòmíràn gbénú yàrá kan náà kò rọrùn, kódà fún àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ tí wọ́n fi ilé wọn sílẹ̀ torí àtilè ṣe iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún. Ṣùgbọ́n ó dáa ká fi sọ́kàn pé tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, tá a sì ń lo “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́,” ọ̀pọ̀ ìgbà la máa lè yanjú èdèkòyedè èyíkéyìí tó bá wáyé.—Òwe 2:7.

Ẹ Sapá Láti Mọwọ́ Ara Yín

Gbàrà tí ara rẹ bá ti wálẹ̀ lẹ́yìn tó o ti kó dé ibùgbé tuntun yìí tán, àárò ilé lè máa bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ́, kó o wá máa rántí bí gbogbo nǹkan ṣe rí nílé yín lọ́hùn-ún. (Númérì 11:4, 5) Àmọ́ ṣíṣàárò ilé á túbọ̀ jẹ́ kó nira fún ọ láti mú ara rẹ bá ibùgbé tuntun yìí mu. Ìmọ̀ràn tí Oníwàásù 7:10 gbà wá nìyí: “Má sọ pé: ‘Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé àwọn ọjọ́ àtijọ́ sàn ju ìwọ̀nyí lọ?’ nítorí pé ọgbọ́n kọ́ ni ìwọ fi béèrè nípa èyí.” Bẹ́ẹ̀ ni, sapá láti jẹ́ kí àyíká tuntun yìí gbádùn mọ́ ọ.

Ohun àkọ́kọ́ tó o máa ṣe ni pé wàá gbìyànjú láti túbọ̀ mọ ẹni tẹ́ ẹ jọ ń gbénú yàrá. Lóòótọ́, kò pọn dandan pé káwọn tó ń bá ara wọn gbé jẹ́ kòríkòsùn. Kódà, ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé onítọ̀hún kì í ṣe ẹni tí ọkàn rẹ fà sí. Síbẹ̀, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìwọ àti oníyẹn lẹ ó jọ máa gbé pọ̀, ǹjẹ́ kò ní dára pé kí ẹ máa hùwà bí ọ̀rẹ́ sí ara yín?

Ìwé Fílípì 2:4 sọ pé ká má ṣe máa mójú tó, ‘ire ara wa nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara wa nìkan, ṣùgbọ́n ire ara àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.’ Lọ́nà tí kò fi ní dà bíi pé ìbéèrè rẹ ti pọ̀ jù, ǹjẹ́ o lè dọ́gbọ́n wádìí nípa irú ìdílé tó ti wá, àwọn ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí, àwọn ohun tó ń lépa nínú ìgbésí ayé, àti àwọn ohun tó yàn láàyò? Sọ fún un nípa ara rẹ. Bẹ́ ẹ bá ṣe mọ̀ nípa ara yín tó ni ọ̀rọ̀ yín ṣe máa yéra yín tó, torí pé ìwájọ̀wà ní í jẹ́ ọ̀rẹ́jọ̀rẹ́.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹ máa ṣètò láti jọ ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀. Ẹnì kan tó ń jẹ́ Lee, sọ pé: “Nígbà míì èmi àtàwọn alábàágbé mi lè jọ lọ jẹun níta, a sì lè jọ lọ ṣèbẹ̀wò sí ibi tí wọ́n ti ń gbéṣẹ́ ọnà yọ.” Bó bá jẹ́ Kristẹni ni yín, lílọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí pa pọ̀, irú bíi mímúra sílẹ̀ fún ìpàdé ìjọ tàbí ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù pa pọ̀, jẹ́ ọ̀nà gbígbéṣẹ́ kan láti mú kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ yín túbọ̀ lágbára sí i.

David sọ pé: “Mo máa ń lọ sí ìjọ alábàágbé mi lọ́jọ́ tó bá fẹ́ sọ àsọyé Bíbélì kí n lè fún un níṣìírí.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ lọ̀rọ̀ òun àti alábàágbé rẹ̀ bó bá dọ̀ràn eré ìdárayá tàbí orin, ìfẹ́ tí wọ́n ní sí àwọn nǹkan tẹ̀mí jẹ́ kí wọ́n mọwọ́ ara wọn. David tún sọ pé: “A jọ máa ń sọ̀rọ̀ gan-an nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí. Kódà, a lè sọ̀rọ̀ lórí rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí.”

Ìkìlọ̀ kan rèé o: Má ṣe jẹ́ kí ìwọ àti ẹni tẹ́ ẹ jọ ń gbénú yàrá di wọléwọ̀de débi pé o ò ní ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn mọ́. Bó bá jẹ́ pé gbogbo ibi tí alábàágbé rẹ bá ń lọ lo fẹ́ máa tẹ̀ lé e lọ, ó lè máa rò pé ò ń ká òun lọ́wọ́ kò, o ò jẹ́ kí òun rin ìrìn ẹsẹ̀ òun. Ìmọ̀ràn Bíbélì ni pé kó o jẹ́ kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rẹ “gbòòrò síwájú.”—2 Kọ́ríńtì 6:13.

Jẹ́ Kí Òfin Pàtàkì Náà Máa Darí Rẹ

Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, bẹ́ ẹ ṣe túbọ̀ ń mọ ara yín dunjú lẹ ó máa rí i pé àṣà tó ti mọ́ kálukú lára, ohun tí kálukú nífẹ̀ẹ́ sí àti ojú tí kálukú fi ń wo nǹkan yàtọ̀ síra. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Mark kìlọ̀ pé: “Máa fi í sọ́kàn pé aláìpé lẹni tó ò ń bá gbé.” Bó bá jẹ́ pé tinú-mi-ni-máa-ṣe tàbí onímọtara-ẹni nìkan ni ẹ́, kò sí bí gbúngbùngbún ò ṣe ní máa ṣẹlẹ̀. Bákan náà, bó o bá ń retí pé kí alábàágbé rẹ yí ìwà rẹ̀ padà kó tó lè bá ọ gbé, kò lè sí àlàáfíà.

Fernando ti kọ́ ohun kan nípa bíbá àwọn ẹlòmíràn gbé, ó sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan àti anìkànjọpọ́n.” Ohun tó sọ bá Òfin Pàtàkì tá a mọ̀ bí ẹní mowó náà mu pé: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Bí àpẹẹrẹ, kò pẹ́ tí Fernando fi kíyè sí i pé òun àti alábàágbé òun máa ń ṣaáwọ̀ lórí ọ̀rọ̀ jíjẹ́ kí yàrá tutù tàbí kó lọ́ wọ́ọ́wọ́; òun ní tiẹ̀ máa ń fẹ́ kí yàrá lọ́ wọ́ọ́wọ́ àmọ́ alábàágbé rẹ̀ gbádùn àtimáa sùn nínú yàrá tó tutù. Báwo ni wọ́n ṣe yanjú ọ̀rọ̀ ọ̀hún? Fernando dáhùn pé: “Mo wá aṣọ ìbora tí màá máa dà bora.” Òótọ́ ọ̀rọ̀ ni Mark sọ pé: “Máa mú nǹkan mọ́ra. Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kó o fi gbogbo àṣà tó ti mọ́ ọ lára sílẹ̀ o, àmọ́ ó lè béèrè pé kó o fi àwọn nǹkan kan tó o nífẹ̀ẹ́ sí du ara rẹ.”

Apá ibòmíràn rèé tó o ti lè fi Òfin Pàtàkì náà sílò: Sapá láti fara da àwọn ohun tí alábàágbé rẹ nífẹ̀ẹ́ sí. Bí àpẹẹrẹ ká sọ pé irú orin tó fẹ́ràn láti máa gbọ́ lo ò nífẹ̀ẹ́, kí lo máa ṣe? Á dáa kó o rántí pé òun náà lè máà nífẹ̀ẹ́ sí orin tí ìwọ náà yàn láàyò. Torí náà, bí orin tó nífẹ̀ẹ́ sí kò bá burú fún ọmọlúwàbí láti gbọ́, o lè gbìyànjú láti fàyè gbà á. Fernando sọ pé: “Ì bá wù mí kó jẹ́ pé irú orin tí mo nífẹ̀ẹ́ sí ni alábàágbé mi náà nífẹ̀ẹ́ sí. Àmọ́ mo ti ń jẹ́ kó mọ́ mi lára.” Yàtọ̀ síyẹn, èèyàn lè lo gbohùngbohùn àtẹ̀bọtí láti gbádùn orin rẹ̀ kò máà bàa ṣèdíwọ́ fún alábàágbé rẹ̀ tó ṣeé ṣe kó máa kàwé lọ́wọ́.

Fífi Òfin Pàtàkì náà sílò tún lè jẹ́ kẹ́ ẹ yẹra fún awuyewuye tí kò pọn dandan lórí àwọn ohun ìní inú ilé. Bí àpẹẹrẹ, bó bá ti mọ́ ọ lára pé kó o kàn máa mú ohun tó bá wù ọ́ nínú fìríìjì láìkọ́kọ́ tọrọ lọ́wọ́ oní-ǹkan ṣùgbọ́n tí ìwọ kì í ra nǹkan bẹ́ẹ̀ padà síbẹ̀, èyí lè fa ìkùnsínú. Bákan náà, fífa ìbínú yọ tàbí fífojú burúkú wo alábàágbé rẹ nígbàkigbà tó bá mú ohunkóhun tó o fi owó rẹ rà kò ní jẹ́ kí àjọgbé yín dán mọ́ran. Bíbélì rọ̀ wá “láti jẹ́ aláìṣahun, kí [a] múra tán láti ṣe àjọpín.” (1 Tímótì 6:18) Bó bá dà bíi pé onítọ̀hún ń rẹ́ ọ jẹ, má ṣe dákẹ́ láìsọ̀rọ̀. Rọra fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ àti ohùn jẹ́jẹ́ sọ èrò ọkàn rẹ fún un.

Ẹ máa fọwọ́ pàtàkì mú ohun ìní ara yín. Yíyá ohun ìní ẹnì kan lò láìkọ́kọ́ gbàṣẹ jẹ́ ìkọjá-àyè-ẹni. (Òwe 11:2) Bákan náà, tún fi í sọ́kàn pé alábàágbé rẹ nílò àkókò láti dá wà lóun nìkan. Máa fi ìwà ọmọlúwàbí hàn nípa kíkan ilẹ̀kùn kó o tó wọlé. Bó o bá fi ọ̀wọ̀ wọ alábàágbé rẹ, òun náà á ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọ. David sọ pé: “Èyíkéyìí nínú wa lè kàwé nínú ilé láìsí ìṣòro. Àwa méjèèjì la ti mọ ìyẹn bẹ́ẹ̀, a sì máa ń jẹ́ kí ilé parọ́rọ́ ní irú àsìkò bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà míì, mo máa ń lọ sí ibi ìkówèésí láti lọ kàwé bí mo bá rí i pé alábàágbé mi fẹ́ ṣe ohun mìíràn.”

Fífi Òfin Pàtàkì náà sílò tún wé mọ́ ṣíṣe ojúṣe rẹ bó bá dọ̀ràn àwọn nǹkan bíi, sísan ìpín tìrẹ lára owó ilé lásìkò tàbí ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ilé tó kàn ọ́.

Yíyanjú Èdèkòyedè

Lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, “ìbújáde ìbínú mímúná” wáyé láàárín Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, àwọn ọkùnrin Kristẹni méjì kan táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún gidigidi. (Ìṣe 15:39) Bí irú ohun bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ láàárín ẹ̀yin méjèèjì ńkọ́? Ó lè jẹ́ pé ìwà kan tí alábàágbé rẹ ń hù ni kò bá ọ lára mu tàbí kó jẹ́ pé àṣà bárakú kan tó ní ló ń rí ọ lára, tó sì ti tán ọ ní sùúrù pátápátá. Ǹjẹ́ ó wá yẹ kẹ́ ẹ tìtorí àríyànjiyàn kan tàbí àìgbọ́ra-ẹni-yé sọ pé ẹ ò ní jọ gbé pọ̀ mọ́ bí? Kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Ó ṣe kedere pé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà yanjú aáwọ̀ wọn. Ìwọ náà lè gbìyànjú àtiyanjú èdèkòyedè yín kó o tó parí èrò sí pé ṣe ni wàá kó jáde. Àwọn ìlànà Bíbélì kan rèé tó lè ṣèrànwọ́.

● ‘Má ṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí o máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù ọ lọ.’—Fílípì 2:3.

● “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú. Ṣùgbọ́n kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.”—Éfésù 4:31, 32.

● “Nígbà náà, bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.”—Mátíù 5:23, 24; Éfésù 4:26.

Àǹfààní Wà Nínú Níní Alábàágbéyàrá

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni (àtàwọn tí kì í ṣe ọ̀dọ́) tó ń bá àwọn ẹlòmíràn gbé ti rí i fúnra wọn pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ tí ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì sọ, pé: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan.” (Oníwàásù 4:9) Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ ti rí i pé níní alábàágbé lè ṣeni láǹfààní. Mark sọ pé: “Mo ti wá mọ bí mo ṣe lè bá àwọn ẹlòmíràn lò kí n sì mú ara mi bá ipò wọn mu.” Renee fi kún un pé: “Wàá túbọ̀ mọ ohun púpọ̀ nípa ìwọ fúnra rẹ. Bákan náà, àwọn alábàágbé tún lè jẹ́ ojúgbà ẹni tó lè gbéni ró.” Lynn sọ pé: “Ìwà tinú-mi-ni-màá-ṣe ni mo máa ń hù tẹ́lẹ̀ kí n tó máa gbé pẹ̀lú àwọn alábàágbé mi. Ṣùgbọ́n mo ti mọ béèyàn ò ṣe ń wonkoko mọ́ nǹkan jù. Mo ti wá mọ̀ báyìí pé, bí ẹnì kan kò bá tiẹ̀ ṣe nǹkan lọ́nà tí mò ń gbà ṣe é, kò túmọ̀ sí pé onítọ̀hún kò mọ̀ ọ́n ṣe.”

Lóòótọ́, ó ń béèrè pé kí àwọn alábàágbé ṣe àwọn nǹkan kan, kí wọ́n sì fi àwọn ohun kan du ara wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kí ọ̀rọ̀ wọn bàa lè wọ̀. Àmọ́, bó o bá sapá gidigidi láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, kì í ṣe pé á ṣeé ṣe fún ìwọ àti ẹni tẹ́ ẹ jọ ń gbénú yàrá láti gbé ní àlàáfíà nìkan ni, wàá tún wá rí i pé níní alábàágbéyàrá máa ń gbádùn mọ́ni.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Kí Ló Dé Tí Àjọgbé Èmi àti Alábàágbé Mi Fi Nira?,” tó jáde nínú ìtẹ̀jáde wa ti May 8, 2002.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Mímú àwọn nǹkan láìkọ́kọ́ tọrọ lọ́wọ́ oní-ǹkan lè fa gbúngbùngbún

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ẹ máa gba ti ara yín rò lẹ́nì kìíní kejì