Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Àjọ Ọlọ́pàá Lọ́jọ́ Iwájú?

Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Àjọ Ọlọ́pàá Lọ́jọ́ Iwájú?

Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Àjọ Ọlọ́pàá Lọ́jọ́ Iwájú?

KÁ NÍ kò sí àwọn ọlọ́pàá ni, ṣe ni gbogbo ayé ì bá rí rúdurùdu. Àmọ́ pẹ̀lú báwọn ọlọ́pàá ṣe wà náà, ǹjẹ́ a lè sọ pé aráyé ti bọ́ lọ́wọ́ ewu? Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ńlá lónìí, gẹ́gẹ́ bó ti rí láwọn ìgbèríko, kò sẹ́ni tí kì í ṣàníyàn lórí ọ̀ràn ààbò. Ǹjẹ́ a lè retí pé àwọn ọlọ́pàá ló máa dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn tó ń fòkùnkùn bojú àtàwọn tó ti gba ìwà ọ̀daràn bí iṣẹ́? Ǹjẹ́ a lè retí pé kí àwọn ọlọ́pàá mú kí ààbò wà láwọn ojú pópó wa? Ṣé wọ́n lè kápá ìwà ọ̀daràn?

David Bayley sọ kókó kan nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Police for the Future, ó ní: “Àwọn ọlọ́pàá kò lè ní kí ìwà ọ̀daràn má ṣẹlẹ̀. Bí aṣọ tí wọ́n fi di ọgbẹ́ lásán làwọn ọlọ́pàá wulẹ̀ rí. . . . A ò lè gbára lé wọn, kódà nígbà tí wọ́n bá ń forí ṣe tí wọ́n ń fọrùn ṣe láti gba àwùjọ sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwà ọ̀daràn.” Ìwádìí ti fi hàn pé, àwọn iṣẹ́ mẹ́ta pàtàkì táwọn ọlọ́pàá ń ṣe, ìyẹn lílọ káàkiri àwọn òpópónà, yíyára lọ síbi tí ìṣòro pàjáwìrì bá ti ń ṣẹlẹ̀ àti ṣíṣèwádìí lórí ìwà ọ̀daràn, kò lè mú ìwà ọ̀daràn kúrò. Báwo lèyí ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?

Ìnáwó ńlá tí apá ò lè ká ló máa jẹ́ láti sọ pé à ń kó ọlọ́pàá jọ rẹpẹtẹ láti mú ìwà ọ̀daràn kúrò. Ká tiẹ̀ ní apá ká dída ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọlọ́pàá síta, kò jọ pé ìyẹn á tiẹ̀ tu irun kankan lára àwọn ọ̀daràn. Ká sì tún sọ pé bí wọ́n bá ti ń pe àwọn ọlọ́pàá níbì kan ni wọ́n máa ń dìde fùú ni, ìyẹn náà ò torí ẹ̀ ní kí ìwà ọ̀daràn kásẹ̀ nílẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá ti sọ pé àyàfi tí àwọn bá lè dé ibi tí ìwà ọ̀daràn kan ti ń ṣẹlẹ̀ láàárín ìṣẹ́jú kan, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, kò dájú pé ọwọ́ àwọn á tẹ ọ̀daràn náà. Ó jọ pé àwọn ọ̀daràn ti mọ̀ pé èyí kò ṣeé ṣe. Ṣíṣèwádìí lórí ìwà ọ̀daràn pàápàá kò tu irun kankan. Kódà, tọ́wọ́ àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ bá tiẹ̀ tẹ àwọn ọ̀daràn tí wọ́n sì sọ wọ́n sẹ́wọ̀n, ó dájú pé ìyẹn ò lè fòpin sí ìwà ọ̀daràn. Kò sí orílẹ̀-èdè tó léèyàn lẹ́wọ̀n tó ilẹ̀ Amẹ́ríkà, àmọ́ ibẹ̀ gan-an ni ìwà ọ̀daràn pẹ̀kun sí láyé; nígbà tó sì jẹ́ pé ilẹ̀ Japan táwọn ẹlẹ́wọ̀n wọn kéré kò fi bẹ́ẹ̀ níṣòro ìwà ọ̀daràn. Àní, àwọn ètò bíi ṣíṣọ́ àdúgbò pàápàá kò ṣàǹfààní kan lọ títí, àgàgà láwọn àgbègbè tí ìwà ọ̀daràn ti gogò. Àwọn ìgbésẹ̀ lílágbára táwọn ọlọ́pàá ń gbé nítorí àwọn ìwà ọ̀daràn kan pàtó, irú bíi gbígbé oògùn olóró tàbí ìdigunjalè, kàn máa ń ṣiṣẹ́ fúngbà díẹ̀ ni, àmọ́ kì í rọrùn láti lè máa bá irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìwé Police for the Future sọ pé: “Bí àwọn ọlọ́pàá ò ṣe lè fòpin sí ìwà ọ̀daràn ò yẹ kó jẹ́ ìyàlẹ́nu púpọ̀ fún àwọn olóye èèyàn. Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ bá ti kọjá ohun tí apá ọlọ́pàá lè ká, tó sì tún ju ohun tí ètò ìdájọ́ tó wà fún ìwà ọ̀daràn lè ṣe ohunkóhun sí, kò sí bí ìwà ọ̀daràn ò ṣe ní pọ̀ sí i láàárín ìlú.”

Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Tí Kò Bá Sí Ọlọ́pàá Nítòsí?

Báwo lo ṣe máa ń hùwà nígbà táwọn ọlọ́pàá ò bá sí nítòsí? Ṣé o máa ń rú òfin nítorí pé wọn ò sí lárọ̀ọ́wọ́tó? Ìyàlẹ́nu gbáà ló máa ń jẹ́ láti rí bí ọ̀pọ̀ èèyàn tó rí jájẹ àtàwọn tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ, tí wọ́n kà sí ẹni pàtàkì láwùjọ, ṣe máa ń gbàgbé ìwà ọmọlúwàbí wọn, tí wọn kì í sì í ronú ẹ̀yìn ọ̀la nítorí owó tí wọ́n fẹ́ kó jẹ àti jìbìtì tí wọ́n fẹ́ lù lẹ́nu iṣẹ́. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni ìwé ìròyìn The New York Times gbé ìròyìn kan jáde nípa ‘àwọn èèyàn méjìléláàádọ́fà [112] kan tí wọ́n fẹ̀sùn èrú ṣíṣe kàn. Wọ́n ní wọ́n lọ́wọ́ nínú ètò gbájú-ẹ̀ kan, wọ́n fẹ́ lu iléeṣẹ́ kan tó jẹ́ abánigbófò ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ní jìbìtì. Lára àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn ni àwọn amòfin, àwọn dókítà, àwọn oníṣègùn tó mọ̀ nípa ìtọ́jú egungun ẹ̀yìn, oníṣègùn kan tó máa ń wọ́ ara, oníṣègùn kan tó mọ̀ nípa ìlànà akupọ́ńṣọ̀, àti igbákejì alábòójútó kan ní Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá.’

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni ẹ̀sùn jìbìtì mìíràn tó bùáyà ṣẹ̀rù ba àwùjọ àwọn tó lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ tó ń ṣe onígbọ̀wọ́ iṣẹ́ ọnà. Wọ́n fẹ̀sùn kan àwọn alábòójútó àti olùdarí tẹ́lẹ̀ rí ní àwọn iléeṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń ta ọjà gbàǹjo, ìyẹn iléeṣẹ́ Sotheby nílùú New York àti iléeṣẹ́ Christie nílùú London fún dídíyelé ọjà lọ́nà tó kọjá ààlà. Òjìlélẹ́gbẹ̀rin dọ́là ó lé mẹ́ta [843] mílíọ̀nù ni owó ìtanràn àti owó gbà-máà-bínú ti ilé ẹjọ́ ní kí àwọn onígbọ̀wọ́ ọ̀hún àtàwọn tó ni àwọn ilé ìtajà gbàǹjo náà san! Èyí fi hàn pé àtolówó àti mẹ̀kúnnù ni ìwà ojúkòkòrò ti wọ̀ lẹ́wù láwùjọ.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ nílùú Recife, lórílẹ̀-èdè Brazil lọ́dún 1997, nígbà táwọn ọlọ́pàá daṣẹ́ sílẹ̀ fi hàn pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò ní ronú lẹ́ẹ̀mejì kí wọ́n tó hùwà ọ̀daràn tí wọ́n bá rí i pé kò sẹ́ni tó lè dí wọn lọ́wọ́. Irú ẹ̀sìn yòówù kí wọ́n lè máa ṣe kì í nípa lórí ìwà wọn. Ńṣe ni wọ́n máa ń pa ìwà ọmọlúwàbí àtàwọn ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Abájọ táwọn ọlọ́pàá ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè kò fi lè kápá ìwà ọ̀daràn nínú ayé kan tí ìwà kò-sẹ́ni-tó-máa-mú-mi ti gbòde kan, ì báà jẹ́ ìwà ọ̀daràn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tàbí èyí tó ga.

Ní òdìkejì sí ìyẹn, àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n ń pa òfin mọ́ nítorí wọ́n bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó wà nílùú Róòmù pé, wọ́n ní láti máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ tí Ọlọ́run gbà láyè láti wà, níwọ̀n bí wọ́n ti ń mú kí àwùjọ wà létòlétò dé ìwọ̀n àyè kan. Ó kọ̀wé nípa irú àwọn aláṣẹ bẹ́ẹ̀ pé: “Òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni, olùgbẹ̀san láti fi ìrunú hàn sí ẹni tí ń fi ohun tí ó burú ṣe ìwà hù. Nítorí náà, ìdí tí ń múni lọ́ranyàn wà fún yín láti wà lábẹ́ àṣẹ, kì í ṣe ní tìtorí ìrunú yẹn nìkan, ṣùgbọ́n ní tìtorí ẹ̀rí-ọkàn yín pẹ̀lú.”—Róòmù 13:4, 5.

Ṣíṣàtúnṣe Àwùjọ

Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ táwọn ọlọ́pàá ń ṣe ń mú kí ipò nǹkan ní àwùjọ sàn sí i. Nígbà tí kò bá sí oògùn olóró láwọn òpópónà, tí ìwà ipá kò sì wáyé, àwọn èèyàn máa ń fẹ́ láti mú ara wọn bá ipò tó túbọ̀ dára náà mu. Àmọ́ ká sòótọ́, ṣíṣe àtúnṣe àwùjọ kọjá ohun tí apá àjọ ọlọ́pàá èyíkéyìí lè ká.

Ṣé o lè fojú inú wo àwùjọ kan níbi táwọn èèyàn ti ń bọ̀wọ̀ fún òfin débi pé, wọn ò nílò ọlọ́pàá? Ṣé o lè ronú ayé kan níbi táwọn èèyàn ti bìkítà nípa ara wọn, táwọn aládùúgbò máa ń ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà gbogbo, tí kò sì sídìí kankan láti máa pe àwọn ọlọ́pàá fún ìrànlọ́wọ́? Èyí lè dà bí àsọdùn létí. Àmọ́ ọ̀rọ̀ kan tí Jésù sọ kan ohun tí à ń sọ yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kókó mìíràn ló ń ṣàlàyé rẹ̀ lákòókò náà. Ó sọ pé: “Lọ́dọ̀ ènìyàn, èyí kò ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.”—Mátíù 19:26.

Bíbélì sọ nípa àkókò kan lọ́jọ́ iwájú nígbà tí gbogbo ènìyàn yóò wà lábẹ́ ìjọba kan tí Jèhófà Ọlọ́run gbé kalẹ̀. “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ . . . Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn.” (Dáníẹ́lì 2:44) Nípa kíkọ́ gbogbo àwọn èèyàn olóòótọ́ ọkàn ní ọ̀nà Ọlọ́run ti ìfẹ́, ìjọba tuntun yìí yóò ṣe àtúnṣe sí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ tó ń fa ìwà ọ̀daràn. “Ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” (Aísáyà 11:9) Apá Jésù Kristi, Ọba tí Jèhófà ti yàn, yóò ká mímú ìwà ọ̀daràn kúrò. “On ki yio si dajọ nipa ìri oju rẹ̀, bẹni ki yio dajọ nipa gbigbọ́ eti rẹ̀; ṣugbọn yio fi ododo ṣe idajọ talakà, yio si fi otitọ ṣe idajọ fun awọn ọlọkàn tùtu aiye.”—Aísáyà 11:3, 4, Bibeli Mimọ.

Kò ní í sí àwọn ọ̀daràn àti ìwà ọ̀daràn mọ́. A ò ní í nílò àwọn ọlọ́pàá mọ́. Gbogbo èèyàn “yóò . . . jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.” (Míkà 4:4) Bó o bá fẹ́ jẹ́ apá kan “ayé tuntun” tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, àkókò yìí gan-an ló yẹ kó o ṣàyẹ̀wò ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—2 Pétérù 3:13.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]

Ṣé o lè fojú inú wo àwùjọ kan níbi táwọn èèyàn ti bọ̀wọ̀ fún òfin débi pé, wọn ò nílò ọlọ́pàá?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]

Kò ní í sí àwọn ọ̀daràn àti ìwà ọ̀daràn mọ́

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Àwọn Ọlọ́pàá Dìde Ogun Sáwọn Apániláyà

Ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹsàn-án ọdún 2001 ní New York City àti Washington, D.C fi hàn pé, àwọn tó ń fipá darí ọkọ̀ òfuurufú gba ibòmíràn, àwọn ajínigbé àtàwọn apániláyà máa ń dá ìṣòro ńlá sílẹ̀ fáwọn ọlọ́pàá nídìí iṣẹ́ ààbò ìlú tí wọ́n ń ṣe. Ní ibi púpọ̀ káàkiri ayé, wọ́n ti dá àkànṣe àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́pàá lẹ́kọ̀ọ́ láti máa já wọnú ọkọ̀ òfuurufú tí wọ́n bá rí tó balẹ̀, kí wọ́n sì yára kápá ìṣòro tó bá wà níbẹ̀. Wọ́n tún ti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè wọnú àwọn ilé láìmú ìfura lọ́wọ́, bí wọ́n ṣe lè fi okùn sọ̀ kalẹ̀ látorí àjà, bí wọ́n ṣe lè gba ojú fèrèsé fò bọ́ sílẹ̀, àti bí wọ́n ṣe lè ju àwọn bọ́ǹbù àfọwọ́jù tó ní òórùn tí ń múni pa rìdàrìdà àti afẹ́fẹ́ tajútajú. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọlọ́pàá tí wọ́n ti dá lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà yìí ti ṣàṣeyọrí nípa yíyọ sáwọn apániláyà lójijì, tí wọ́n á sì kápá wọn láìsí pé jàǹbá rẹpẹtẹ kan ṣẹlẹ̀ sáwọn òǹdè táwọn apániláyà náà mú.

[Credit Line]

James R. Tourtellotte/U.S. Customs Service

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Àwọn nǹkan tí kò ní í wúlò mọ́ nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run