Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mímú Ara Aláìsàn Lọ́ Wọ́ọ́wọ́ Ṣáájú Iṣẹ́ Abẹ Kì Í Sábà Jẹ́ Kí Kòkòrò Àrùn Wọ Ojú Ọgbẹ́

Mímú Ara Aláìsàn Lọ́ Wọ́ọ́wọ́ Ṣáájú Iṣẹ́ Abẹ Kì Í Sábà Jẹ́ Kí Kòkòrò Àrùn Wọ Ojú Ọgbẹ́

Mímú Ara Aláìsàn Lọ́ Wọ́ọ́wọ́ Ṣáájú Iṣẹ́ Abẹ Kì Í Sábà Jẹ́ Kí Kòkòrò Àrùn Wọ Ojú Ọgbẹ́

BÍ KÒKÒRÒ ÀRÙN ṢE MÁA Ń WỌ OJÚ ỌGBẸ́ LẸ́YÌN IṢẸ́ ABẸ jẹ́ ìṣòro kan tó ti wà látọjọ́ pípẹ́. Àmọ́ ṣá o, ìwé ìròyìn The Times ti ìlú London sọ pé: “Mímú kí ara àwọn aláìsàn lọ́ wọ́ọ́wọ́ ṣáájú kí wọ́n tó ṣiṣẹ́ abẹ fún wọn kì í sábà jẹ́ kí kòkòrò àrùn wọ ojú ọgbẹ́ wọn, ó sì ju ìdá ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún tí èyí fi gbéṣẹ́ ju kí ara wọn máà lọ́ wọ́ọ́wọ́ lọ.”

Àwọn olùṣèwádìí ní ilé ìwòsàn University Hospital of North Tees tó wà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, pín àwọn aláìsàn tó lé ní irínwó sọ́nà mẹ́ta nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ ọmú, iṣẹ́ abẹ òpójẹ̀, àti iṣẹ́ abẹ ìpákè fún wọn. Wọn kò mú ara àwùjọ àkọ́kọ́ lọ́ wọ́ọ́wọ́ rárá, àmọ́ fún bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, wọ́n mú ẹnu apá ibi tí wọ́n ti fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ tàbí gbogbo ara àwùjọ kejì àti ìkẹta lọ́ wọ́ọ́wọ́ látòkèdélẹ̀. Kí ni àbájáde rẹ̀?

Lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ abẹ fún wọn tán, kìkì ìdá márùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn aláìsàn tí ara wọn lọ́ wọ́ọ́wọ́ ni kòkòrò àrùn wọ ojú ọgbẹ́ wọn tá a bá fi wéra pẹ̀lú ìdá mẹ́rìnlá nínú ọgọ́rùn-ún àwọn aláìsàn tí ara wọn kò lọ́ wọ́ọ́wọ́ rárá. Ó yẹ fún àfiyèsí pé mímú kí ara àwọn aláìsàn lọ́ wọ́ọ́wọ́ ṣáájú iṣẹ́ abẹ tún ti ṣèrànwọ́ gan-an fún àwọn aláìsàn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ abẹ ìfun fún.