Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbọ́kànlé Tí Mo Ní Nínú Ọlọ́run Ló Mẹ́sẹ̀ Mi Dúró

Ìgbọ́kànlé Tí Mo Ní Nínú Ọlọ́run Ló Mẹ́sẹ̀ Mi Dúró

Ìgbọ́kànlé Tí Mo Ní Nínú Ọlọ́run Ló Mẹ́sẹ̀ Mi Dúró

GẸ́GẸ́ BÍ RACHEL SACKSIONI-LEVEE ṢE SỌ Ọ́

NÍGBÀ TÍ Ẹ̀ṢỌ́ KAN BẸ̀RẸ̀ SÍ Í KÓ Ẹ̀ṢẸ́ BÒ MÍ LÉRALÉRA NÍTORÍ PÉ MO KỌ̀ LÁTI ṢIṢẸ́ LÁRA Ẹ̀YA ARA Ẹ̀RỌ AJUBỌ́ǸBÙ TI ÌJỌBA NÁSÌ, Ẹ̀ṢỌ́ MÌÍRÀN SỌ FÚN UN PÉ: “O JẸ́ MÁ DARA Ẹ LÁÀMÚ. Ó TẸ́ ÀWỌN ‘BIBELFORSCHER’ (AKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ) YẸN LỌ́RÙN KÍ WỌ́N LÙ WỌ́N PA NÍTORÍ ỌLỌ́RUN WỌN.”

OṢÙ kejìlá ọdún 1944 ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé ní ìlú Beendorff, tí ó jẹ́ àgọ́ iṣẹ́ àṣekú ti àwọn obìnrin, nítòsí ibi tí wọ́n ti ń wa iyọ̀ ní àríwá Jámánì. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé ohun tó gbé mi débẹ̀ àti bí mo ṣe bọ́ lọ́wọ́ ikú láwọn oṣù tó kẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì.

Inú ìdílé ẹlẹ́sìn Júù ni wọ́n bí mi sí nílùú Amsterdam, lórílẹ̀-èdè Netherlands, lọ́dún 1908, èmi sì ni èkejì nínú àwa ọmọbìnrin mẹ́ta. Iṣẹ́ dídán dáyámọ́ǹdì tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó ń gbé ìlú Amsterdam ń ṣe kí Ogun Àgbáyé Kejì tó bẹ̀rẹ̀ ni bàbá mi ń ṣe. Ọmọ ọdún méjìlá ni mí nígbà tó kú, èyí sì mú kí bàbá wa àgbà wá máa gbé pẹ̀lú wa. Ògbóǹkangí ẹlẹ́sìn Júù ni bàbá àgbà, ó sì rí i dájú pé ìlànà ẹ̀sìn Júù lòún fi tọ́ wa dàgbà.

Ẹsẹ̀ bàbá mi ni mo tọ̀, èmi náà kọ́ bí wọ́n ṣe ń gbẹ́ dáyámọ́ǹdì, nígbà tó sì di ọdún 1930, mo fẹ́ ẹnì kan tóun náà ń ṣe irú iṣẹ́ yẹn. A bí ọmọ méjì, ọ̀kan ń jẹ́ Silvain, ọmọkùnrin kan tára rẹ̀ yọ̀ mọ́ni tó sì jẹ́ olófìn-íntótó. Carry ló ṣìkejì, ọmọdébìnrin kan tó fani mọ́ra tó sì jẹ́ ẹni jẹ́jẹ́. Àmọ́ ìgbéyàwó wa kò tọ́jọ́. Lọ́dún 1938, kò pẹ́ lẹ́yìn tá a jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ fúnra wa, mo fẹ́ Louis Sacksioni, tóun náà jẹ́ ẹni tó ń dán dáyámọ́ǹdì. Ní February 1940, a bí ọmọbìnrin wa, Johanna.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́sìn Júù ni Louis, kò fọwọ́ gidi mú ẹ̀sìn náà. Nígbà tó sì yá, a ò ṣayẹyẹ àwọn àjọ̀dún ẹ̀sìn Júù mọ́, èyí tí mo nífẹ̀ẹ́ sí gan-an nígbà tí mo wà lọ́mọdé. Èyí dùn mí púpọ̀, àmọ́ mò ń bá a lọ láti máa ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run nínú ọkàn mi.

Mo Yí Ẹ̀sìn Mi Padà

Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1940, ìyẹn ọdún táwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì ṣígun wá sí orílẹ̀-èdè Netherlands, obìnrin kan wá sẹ́nu ọ̀nà wa, ó sì bá mi sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Púpọ̀ nínú ohun tó sọ ni kò yé mi, ṣùgbọ́n ìgbàkígbà tó bá ti wá ni mo máa ń gbàwé lọ́wọ́ rẹ̀. Àmọ́, n kì í ka àwọn ìwé tó ń fi sílẹ̀ náà, torí mi ò fẹ́ẹ́ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Jésù. Wọ́n ti kọ́ mi pé apẹ̀yìndà Júù ni.

Nígbà tó wá di ọjọ́ kan, ọkùnrin kan wá sí ilé wa. Mo bá da ìbéèrè bò ó, àwọn ìbéèrè bíi “Kí ló dé tí Ọlọ́run kò fi dá àwọn èèyàn mìíràn lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ti ṣẹ̀? Kí ló dé tí ìbànújẹ́ fi gbalé ayé kan? Kí ló mú káwọn èèyàn máa kórìíra ara wọn tí wọ́n sì ń bára wọn jagun?” Ó mú un dá mi lójú pé, tí mo bá lè ní sùúrù, òún á fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè mi. Ló bá ṣètò láti wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Síbẹ̀, mo kọ̀ láti gbà pé Jésù ni Mèsáyà. Àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn náà, mo gbàdúrà nípa ọ̀ràn náà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú Mèsáyà nínú Bíbélì, mo wá ń fi ojú tó yàtọ̀ wo àwọn ohun tí mò ń kà nípa Jésù. (Sáàmù 22:7, 8, 18; Aísáyà 53:1-12) Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé Jésù ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ sí lára. Ọkọ mi kò nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí mò ń kọ́, àmọ́ kò dí mi lọ́wọ́ pé kí n má di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Mò Ń Sá Pa Mọ́, Síbẹ̀ Mi Ò Yéé Wàásù

Àkókò ewu gbáà ni àkókò táwọn ọmọ ogun Jámánì ṣígun ti Netherlands jẹ́ fún mi. Kì í ṣe torí pé mo jẹ́ ẹ̀yà Júù nìkan ni, ìyẹn ẹ̀yà táwọn ará Jámánì ń kó dà sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, àmọ́ mo tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ètò ẹ̀sìn kan tí ìjọba Násì ń wá ọ̀nà láti pa run. Síbẹ̀, mi ò yéé wàásù, mo máa ń lò tó ọgọ́ta wákàtí ní ìpíndọ́gba lóṣooṣù, ní sísọ fún àwọn èèyàn nípa ìrètí tí mo ṣẹ̀sẹ̀ ní gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni.—Mátíù 24:14.

Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ní December ọdún 1942, ọkọ mi kò darí wálé láti ibi iṣẹ́. Àṣé wọ́n ti mú un níbi iṣẹ́, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Mi ò fojú mi rí i mọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ mi gbà mí nímọ̀ràn pé kí èmi àtàwọn ọmọ mi lọ wábi fara pa mọ́ sí. Mo rí àyè lọ́dọ̀ Kristẹni arábìnrin kan ní òdìkejì ìlú Amsterdam. Àmọ́ torí pé ó léwu gan-an fún àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin láti wà lójú kan, mo ní láti fi àwọn ọmọ mi sọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn.

Lọ́pọ̀ ìgbà, díẹ̀ báyìí ló máa ń kù kí wọ́n rí mi mú. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, Ẹlẹ́rìí kan ń fi alùpùpù rẹ̀ gbé mi lọ sí ibòmíràn tí màá lọ fara pa mọ́ sí. Àmọ́, iná alùpùpù rẹ̀ kò ṣiṣẹ́, làwọn ọlọ́pàá méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Netherlands bá dá wa dúró. Wọ́n tan tọ́ọ̀ṣì wọn sí mi lójú wọ́n sì rí i pé Júù ni mi. Ìgbà tí Ọlọ́run máa bá mi ṣe é, ńṣe ni wọ́n kàn sọ fún mi pé: “Ó yá, máa lọ kíákíá, àmọ́ ẹsẹ̀ ni kó o máa fi rìn lọ o.”

Ọwọ́ Tẹ̀ Mí, Mo sì Dèrò Ẹ̀wọ̀n

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan ní May ọdún 1944, bí mo ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi báyìí, ni wọ́n bá mú mi—kì í ṣe nítorí pé mo jẹ́ Ẹlẹ́rìí, àmọ́ torí pé Júù ni mí. Wọ́n lọ fi mí sẹ́wọ̀n kan ní ìlú Amsterdam, ibẹ̀ ni mo sì wà fún ọjọ́ mẹ́wàá. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni wọ́n fi ọkọ̀ ojú irin gbé èmi àtàwọn Júù mìíràn lọ sí àgọ́ kan ní ìlú Westerbork, èyí tó wà lápá àríwá ìlà oòrùn Netherlands, ibi tá a gbé fúngbà díẹ̀. Àtibẹ̀ ni wọ́n ti ń kó àwọn Júù lọ sí ilẹ̀ Jámánì.

Ní Westerbork, mo bá àbúrò ọkọ mi àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pàdé, wọ́n ti mú àwọn náà. Èmi nìkan ni Ẹlẹ́rìí tó wà láàárín àwọn Júù, léraléra ni mo sì ń gbàdúrà pé kí Jèhófà jọ̀ọ́ mẹ́sẹ̀ mi dúró. Ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà ni èmi, àbúrò ọkọ mi àti ọmọkùnrin rẹ̀ jókòó sínú ọkọ̀ ojú irin kan tí wọ́n fi ń kó màlúù, èyí tó fẹ́ gbéra lọ sí ìlú Auschwitz tàbí ìlú Sobibor, àwọn àgọ́ ikú tó wà lórílẹ̀-èdè Poland. Lójijì, wọ́n pe orúkọ mi, wọ́n sì mú mi lọ sínú ọkọ̀ ojú irin mìíràn—ìyẹn ọkọ̀ ojú irin gbogbo gbòò.

Mo bá àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ dáyámọ́ǹdì tẹ́lẹ̀ rí pàdé nínú ọkọ̀ ojú irin náà. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ dáyámọ́ǹdì ni wọ́n kó lọ sí ìlú Bergen-Belsen, ní àríwá ilẹ̀ Jámánì. Ẹ̀yìn ìgbà náà ni mo wá gbọ́ pé iṣẹ́ tí mò ń ṣe yìí ló dá ẹ̀mí mi sí, torí pé inú gáàsì olóró ni wọ́n kó àwọn Júù tí wọ́n kó lọ sí Auschwitz àti Sobibor lọ tààràtà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkọ mi, àwọn ọmọ mi méjì, àtàwọn ẹbí mi yòókù gan-an nìyẹn. Àmọ́ ní àkókò yẹn, mi ò tíì mọ̀ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn nìyẹn.

Inú àkànṣe bárékè ni wọ́n fi àwa tá à ń gbẹ́ dáyámọ́ǹdì sí láti máa gbé ní ìlú Bergen-Belsen. Kí ọwọ́ wa má bàa bà jẹ́ nítorí iṣẹ́ ẹlẹgẹ́ tá à ń ṣe, wọn ò fún wa ní iṣẹ́ mìíràn ṣe. Èmi nìkan ni Ẹlẹ́rìí nínú àwùjọ mi, mo sì máa ń fi ìgboyà sọ fún àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ mi nípa ẹ̀sìn tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí náà. Àmọ́, ojú apẹ̀yìndà ni wọ́n máa ń fi wò mí, irú ojú tí wọ́n fi wo àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gẹ́lẹ́ ní ọ̀rúndún kìíní.

Mi ò ní Bíbélì, ebi tẹ̀mí sì ń pa mí gan-an. Dókítà kan tó jẹ́ Júù nínú àgọ́ náà ní ọ̀kan, ó sì gbé e fún mi ní pàṣípààrọ̀ fún awẹ́ búrẹ́dì mélòó kan àti bọ́tà díẹ̀. Oṣù méje ni mo lò pẹ̀lú ‘àwùjọ onídáyámọ́ǹdì’ yẹn ní ìlú Bergen-Belsen. Wọ́n ṣe wá dáadáa, èyí sì mú kí àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù tí wọ́n jẹ́ Júù máa bínú sí wa. Àmọ́ níkẹyìn, ó ṣẹlẹ̀ pé wọn ò rí dáyámọ́ǹdì kó wá fún wa mọ́ láti ṣiṣẹ́ lé lórí. Nítorí náà, ní December 5, 1944, wọ́n kó nǹkan bí àádọ́rin àwa obìnrin tá a jẹ́ Júù lọ sí àgọ́ iṣẹ́ àṣekú ní ìlú Beendorff.

Mo Kọ̀ Láti Ṣe Ohun Ìjà

Níbi ìwakùsà kan nítòsí àgọ́ náà, èyí tó wà nínú àjàalẹ̀ tó jìn sísàlẹ̀ ní irínwó mítà, wọ́n fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní iṣẹ́ ṣíṣe ẹ̀yà ara ẹ̀rọ tó ń yin bọ́ǹbù. Nígbà tí mo kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ yìí, wọ́n kó ẹ̀ṣẹ́ bò mí léraléra. (Aísáyà 2:4) Pẹ̀lú ìbínú ni ẹ̀ṣọ́ náà fi sọ fún mi pé kí n máa múra sílẹ̀, torí mò ń bọ̀ wá ṣiṣẹ́ níbẹ̀ lọ́jọ́ kejì.

Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, mi ò lọ sórí ìlà níbi tí wọ́n ti ń pe orúkọ, ńṣe ni mo dúró sínú bárékè. Mo ti ní in lọ́kàn pé kò sóhun méjì ju pé wọ́n máa yìnbọn pa mí, nítorí náà mo gbàdúrà pé kí Jèhófà san èrè ìgbàgbọ́ mi fún mi. Mo wá ń ka ọ̀rọ̀ Bíbélì tó wà nínú ìwé Sáàmù léraléra nínú ọkàn mi, èyí tó sọ pé: “Ọlọ́run ni mo gbẹ́kẹ̀ lé, àyà kì yóò fò mí. Kí ni ará ayé lè fi mí ṣe?”—Sáàmù 56:11.

Wọ́n wá gbogbo inú bárékè náà, wọ́n sì rí mi. Àkókò yẹn ni ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ náà kó ẹ̀ṣẹ́ bò mí léraléra, tó sì ń bi mí pé: “Ta lẹni náà tó sọ pé kó o má ṣiṣẹ́?” Bó ṣe ń bi mí ni mò ń dáhùn pé Ọlọ́run ni. Ìgbà yẹn ni ẹ̀ṣọ́ mìíràn wá sọ fún un pé: “O jẹ́ má dara ẹ láàmú. Ó tẹ́ àwọn Bibelforscher a yẹn lọ́rùn kí wọ́n lù wọ́n pa nítorí Ọlọ́run wọn.” Ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn fún mi lókun gidigidi.

Níwọ̀n bí fífọ ilé ìgbẹ́ ti jẹ́ iṣẹ́ tí wọ́n máa ń lò láti fi jẹni níyà, tó sì tún jẹ́ iṣẹ́ tó lẹ́gbin jù lọ ti mo mọ̀, mo ní kí wọ́n jẹ́ kí n lọ ṣe é. Inú mi dùn láti ṣe iṣẹ́ yìí nítorí òun ni iṣẹ́ tí mo lè ṣe tí ọkàn mi ò sì ní í dá mi lẹ́bi. Ní àárọ̀ ọjọ́ kan, olùdarí àgọ́ náà, ẹni tí gbogbo èèyàn máa ń bẹ̀rù wá sọ́dọ̀ mi. Ó dúró síwájú mi ó sì sọ pé: “Ṣé ìwọ ni Júù tí kò fẹ́ ẹ́ ṣiṣẹ́?”

Mo dá a lóhùn pé: “O kúkú rí i pé ẹnu iṣẹ́ lo bá mi.”

“Àmọ́ oò ní ṣiṣẹ́ fún ìtìlẹ́yìn ogun, àbí wàá ṣe é?”

Mo dáhùn pé: “Rárá, Ọlọ́run kò fẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀.”

“Àmọ́ ṣebí kì í ṣe pé ò ń lọ pààyàn?”

Mo ṣàlàyé fún un pé, bí mo bá lọ́wọ́ nínú ṣíṣe nǹkan ìjà, ńṣe ni mò ń tàpá sí ẹ̀rí ọkàn mi gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni.

Ló bá gba ìgbálẹ̀ ọwọ́ mi ó sì sọ pé: “Ṣé o mọ̀ pé mo lè lo ìgbálẹ̀ yìí láti fi pa ẹ́, àbí mi ò lè lò ó?”

Mo dá a lóhùn pé: “Dáadáa, o lè lò ó, àmọ́ kì í ṣe ohun tí wọ́n ṣe ìgbálẹ̀ fún nìyẹn. Ìbọn ni wọ́n ṣe láti fi pààyàn.”

A jọ sọ̀rọ̀ lórí bí Jésù ṣe jẹ́ Júù àti lórí kókó náà pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Júù ni mí, mo ti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó lọ tán, àwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹgbẹ́ mi wá bá mi, ó yà wọ́n lẹ́nu pé mo láyà láti bá olùdarí àgọ́ náà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀. Mo sọ fún wọn pé ọ̀rọ̀ pé mo láyà kọ́, àmọ́ torí pé Ọlọ́run mi fún mi lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀ ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi.

Mó La Òpin Ogun Náà Já

Ní April 10, 1945, bí àwọn ọmọ ogun Olùgbèjà ti ń sún mọ́ ìlú Beendorff, orí ìdúró la wà ṣúlẹ̀ nínú àgbàlá, tí wọ́n ń pe orúkọ wa. Lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n fún àwa obìnrin tá a jẹ́ nǹkan bí àádọ́jọ pọ̀ mọ́ inú ọkọ̀ ojú irin kan tí wọ́n fi ń kó màlúù. Kò sí oúnjẹ, kò sí omi. A ò mọ ibi tí ọkọ̀ ojú irin náà ń forí lé, ọ̀pọ̀ ọjọ́ la sì fi ń lọ tá à ń bọ̀ láàárín ibi tí ogun ti ń gbóná janjan. Àwọn kan fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹlẹgbẹ́ wọn lọ́rùn pa kí wọ́n lè rí àyè nínú ọkọ̀ ojú irin tó há gádígádí náà, látàrí èyí, púpọ̀ nínú àwọn obìnrin náà ni ojora sọ di rádaràda. Ìgbọ́kànlé mi nínú Jèhófà pé kò jẹ́ fi mí sílẹ̀ ló jẹ́ kí n lè fara dà á.

Lọ́jọ́ kan, ọkọ̀ ojú irin wa dúró nítòsí àgọ́ kan tó jẹ́ tàwọn ọkùnrin, wọ́n sì gbà wá láyè láti sọ̀ kalẹ̀. Wọ́n kó korobá fún àwọn kan lára wa láti lọ pọnmi wá nínú àgọ́ náà. Nígbà tí mo dé ibi tí ẹ̀rọ omi náà wà, mo kọ́kọ́ mu omi dáadáa, ẹ̀yìn náà ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá pọnmi sínú korobá mi. Nígbà tí mo padà dé, bí ẹranko ẹhànnà làwọn obìnrin náà ṣe gbéjà kò mí. Ńṣe ni wọ́n sì yí gbogbo omi inú korobá náà dà nù. Ẹ̀rín làwọn SS (àwọn ẹ̀ṣọ́ fún Hitler) kàn ń fi wá rín níbi tí wọ́n dúró sí. Ọjọ́ mọ́kànlá lẹ́yìn náà, a bára wa ní Eidelstedt, àgọ́ kan tó wà ní àgbègbè Hamburg. Nǹkan bí ìdajì lára àwùjọ wa ló kú nítorí ìnira ìrìn-àjò náà.

Lọ́jọ́ kan, nígbà tá a wà ní Eidelstedt, mò ń ka Bíbélì fún díẹ̀ lára àwọn obìnrin náà. Lójijì, olùdarí àgọ́ náà wá síbẹ̀, ó sì dúró sí ojú wíńdò. Jìnnìjìnnì bò wá, nítorí wọ́n ti ka Bíbélì léèwọ̀ nínú àgọ́ náà. Olùdarí náà wọlé wá, ó gba Bíbélì náà, ó sì sọ pé: “Bíbélì nìyí, àbí kínla?” Nígbà tó dá a padà fún mi tó sì sọ pé: “Bí ọ̀kan nínú àwọn obìnrin náà bá kú, wàá ka ibì kan jáde látinú rẹ̀,” ńṣe lara rọ̀ mí pẹ̀sẹ̀.

Mo Ṣalábàápàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Ẹlẹgbẹ́ Mi

Ọjọ́ mẹ́rìnlá lẹ́yìn ìgbà náà ni wọ́n dá wa sílẹ̀, Ẹgbẹ́ Alágbèélébùú Pupa sì kó wa lọ sí iléèwé kan nítòsí ìlú Malmö, ní orílẹ̀-èdè Sweden. Ibẹ̀ ni wọ́n sé wa mọ́ fúngbà díẹ̀ ká má bàa kó àrùn ran àwọn èèyàn. Mo béèrè lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń tọ́jú wa bóyá ó lè jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé mo wà ní ilé àwọn olùwá-ibi-ìsádi náà. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, wọ́n pe orúkọ mi jáde. Nígbà tí mo sọ fún obìnrin tó fẹ́ ẹ́ rí mi náà pé Ẹlẹ́rìí ni mí, ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún. Àṣé Ẹlẹ́rìí lòun náà! Lẹ́yìn tí ara rẹ̀ wálẹ̀, ó sọ pé ìgbà gbogbo làwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Sweden máa ń gbàdúrà fún àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wọn tó wà nínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Násì.

Látọjọ́ náà, arábìnrin kan máa ń wá lójoojúmọ́ tá á sì gbé kọfí àti ìpápánu wá. Lẹ́yìn tí mo kúrò ní ilé àwọn olùwá-ibi-ìsádi náà, wọ́n gbé mi lọ sí ibì kan nítòsí ìlú Göteborg. Níbẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí ṣètò àpèjẹ ńlá kan fún mi ní ọ̀sán ọjọ́ kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò gbọ́ èdè tí wọ́n ń sọ, ńṣe ni ayọ̀ kún inú mi pé mo tún wà láàárín àwọn arákùnrin mi àtàwọn arábìnrin mi lẹ́ẹ̀kan sí i.

Nígbà tí mo wà ní ìlú Göteborg, mo gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ Ẹlẹ́rìí kan ní ìlú Amsterdam tó jẹ́ kí n mọ̀ pé wọ́n ti mú àwọn ọmọ mi, Silvain àti Carry, pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹbí mi pátá, wọn ò sì rí àbọ̀ wọn látìgbà náà. Kìkì ọmọ mi obìnrin, Johanna àti àbúrò mi obìnrin tó kéré jù nìkan ló mórí bọ́. Ẹnu àìpẹ́ yìí ni mo rí orúkọ àwọn ọmọ mi lára orúkọ àwọn Júù tí wọ́n fi gáàsì olóró pa ní Auschwitz àti Sobibor.

Ohun Tí Mo Mú Ṣe Lẹ́yìn Ogun

Nígbà tí mo padà sí Amsterdam, tí mo sì ti wà pẹ̀lú ọmọ mi Johanna, ẹni tó ti pé ọmọ ọdún márùn-ún lákòókò náà, kíá ni mo tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ padà. Nígbà míì, mo máa ń bá àwọn tó ti jẹ́ ara Ẹgbẹ́ Òṣèlú Àjùmọ̀ni Ilẹ̀ Netherlands (NSB) tẹ́lẹ̀ rí pàdé, ìyẹn ẹgbẹ́ òṣèlú tó lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Jámánì. Àwọn ló wà nídìí bí gbogbo ìdílé mi ṣe di èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ pa rẹ́ tán ráúráú. Mo ní láti ṣẹ́pá èrò òdì tí mo ní sí wọn kó bàa lè ṣeé ṣe fún mi láti sọ ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run fún wọn. Mo máa ń rò ó pé Jèhófà ló ń rí ọkàn àti pé nígbà tó bá tó àkókò, òun ló máa ṣèdájọ́ kì í ṣe èmi. Ó sì bù kún mi gan-an nítorí èyí!

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú obìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí pé ó lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú ìjọba Násì. Bí mo bá ṣe ń gòkè lọ sílé wọn, màá máa gbọ́ táwọn ará àdúgbò á máa sọ pé: “Àbí ẹ ò rí nǹkan! Obìnrin Júù yìí mà tún ti ń lọ bẹ àwọn Ẹgbẹ́ NSB yìí wò.” Àmọ́ láìka gbogbo àtakò líle koko tí ọkọ rẹ̀ tó ṣì ń ṣẹ̀wọ̀n lọ́wọ́, ẹni tó kórìíra àwọn Júù, gbé dìde sí i, obìnrin yìí, àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Inú mi dùn gan-an pé, nígbà tó yá, Johanna, ọmọbìnrin mi náà ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Èmi pẹ̀lú rẹ̀ lọ sìn ní àgbègbè tí kò sí àwọn olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run. A sì gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún tẹ̀mí. Ìlú kékeré kan ní gúúsù Netherlands ni mò ń gbé báyìí, níbi tí mo ti ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà bó bá ti lè ṣeé ṣe tó pẹ̀lú ìjọ tí mo wà. Bí mo ti ń wẹ̀yìn padà, mo lè sọ pé kò sígbà kankan tí mo nímọ̀lára pé Jèhófà fi mí sílẹ̀ rí. Ìgbà gbogbo ni mo máa ń nímọ̀lára pé Jèhófà àti Jésù, Ọmọ rẹ̀ olùfẹ́, wà pẹ̀lú mi, kódà láwọn àkókò tí nǹkan burú fún mi gan-an.

Lákòókò ogun náà, mo pàdánù ọkọ mi, àwọn ọmọ mi méjì, àti èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ẹbí mi mìíràn. Àmọ́ ṣá o, ìrètí mi ni pé màá tún rí gbogbo wọn lẹ́ẹ̀kan sí i, láìpẹ́ nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run. Láwọn ìgbà tí mo bá dá wà, tí mo sì ronú padà lórí àwọn ohun tí ojú mi ti rí, pẹ̀lú ayọ̀ àti ìmoore ni mo fi máa ń ronú lórí àwọn ọ̀rọ̀ onísáàmù náà, èyí tó sọ pé: “Áńgẹ́lì Jèhófà dó yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.”—Sáàmù 34:7.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí wọ́n ṣe ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Jámánì nígbà yẹn nìyẹn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Àwọn Júù tí wọ́n ń kó lọ sí orílẹ̀-èdè Jámánì láti àgọ́ Westerbork

[Credit Line]

Herinneringscentrum kamp Westerbork

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Èmi àtàwọn ọmọ mi, Carry àti Silvain, tí àwọn méjèèjì pa rẹ́ nígbà Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Nígbà tá a wà ní ìsémọ́ ní ilẹ̀ Sweden

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Káàdì ìdánimọ̀ onígbà kúkúrú tó ń fi hàn pé mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ogun dé ni

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Èmi àti Johanna ọmọbìnrin mi lónìí