Ìmọ̀ Pọ̀ Rẹpẹtẹ Àmọ́ Kò Fi Bẹ́ẹ̀ Sí Ìyípadà
Ìmọ̀ Pọ̀ Rẹpẹtẹ Àmọ́ Kò Fi Bẹ́ẹ̀ Sí Ìyípadà
“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti mú àwọn àṣeyọrí ńláǹlà wá lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, síbẹ̀, ìwà àwọn èèyàn ò tíì fi bẹ́ẹ̀ yí padà láti ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn; fún ìdí yìí, ó ṣì yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá.”—Kenneth Clark, nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Civilisation—A Personal View.
KÒ SÍ àní-àní pé, ìtẹ̀síwájú gígọntíọ ti ń wáyé lágbo ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì láti àwọn ọ̀rúndún yìí wá. Ìwé ìròyìn Time sọ pé èyí ti mú kí “ìgbésí ayé ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn sàn ju ti ìgbàkigbà rí lọ nínú ìtàn.” Inú ìmọ̀ ìṣègùn ni àwọn kan lára àwọn ìtẹ̀síwájú kíkọyọyọ yìí ti wáyé jù. Òpìtàn Zoé Oldenbourg sọ pé, nígbà ayé ojú dúdú, “àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ìṣègùn rárá, ọ̀nà tí wọ́n sì ń gbà ṣe é kò bọ́ sí i rárá. Bí àwọn dókítà ṣe lè woni sàn náà ni wọ́n ṣe lè gbẹ̀mí ẹni.”
Gbogbo Ìgbà Kọ́ Làwọn Èèyàn Máa Ń Fẹ́ Láti Kẹ́kọ̀ọ́
Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn kì í ti í fẹ́ ẹ́ gbẹ̀kọ́. Bí àpẹẹrẹ, ní apá ìparí ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ọ̀pọ̀ dókítà kọ̀ láti gbà pé àwọn fúnra wọn, lọ́nà kan ṣá, ń tan àìsàn kálẹ̀ láàárín àwọn aláìsàn tí wọ́n ń tọ́jú. Èyí ló mú kí wọ́n rinkinkin mọ́ àwọn ọ̀nà eléwu tí wọ́n ń gbà tọ́jú àwọn èèyàn, wọn kò sì ń fọwọ́ wọn bí wọ́n ti ń ti ọ̀dọ̀ aláìsàn kan dé ọ̀dọ̀ òmíràn.
Síbẹ̀, èyí kò dí ìtẹ̀síwájú tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ lọ́wọ́. Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà láti sọ pé, ó yẹ káwọn èèyàn ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, kí wọ́n bàa lè mọ ọ̀nà tí wọ́n á lè fi sọ ayé di ibi tó túbọ̀ láyọ̀ tó sì láàbò ju bó ṣe wà yìí lọ. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá.
Gbé àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ Yúróòpù ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún yẹ̀ wò. Wọ́n sọ pé àkókò ọ̀làjú ni àkókò náà, àti pé àwọn olórí pípé èèyàn pọ̀ gan-an. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí Kenneth Clark ti sọ, òótọ́ ibẹ̀ ni pé, “pẹ̀lú báwọn tí orí wọ́n pé gidi nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ọnà àti sáyẹ́ǹsì ti pọ̀ lọ bí-ilẹ̀-bí-ẹní nígbà yẹn, táráyé sì ń rí àwọn ohun tí wọn ò rírú ẹ̀ rí, inúnibíni tí kò mọ́gbọ́n dání àtàwọn ogun oníkà tó burú jáì ṣì ń wáyé.”
Lóde òní náà, àwọn èèyàn kì í fi àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá ṣàríkọ́gbọ́n láti lè yẹra fáwọn àṣìṣe táwọn èèyàn àtijọ́ ti ṣe. Látàrí èyí, ńṣe ló dà bí ẹni pé inú ewu gidi la wà. Òǹkọ̀wé Joseph Needham sọ pé, ìṣòro ọ̀hún ti burú débi pé, ‘gbogbo ohun tó kù tá a lè ṣe kò ju ká máa gbà á ládùúrà pé káwọn ayírí èèyàn má lọ ṣe ohun tó máa gbẹ̀mí gbogbo ohun alààyè tó wà lórí ilẹ̀ ayé pátá.’
Kí ló fà á tó fi jẹ́ pé pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n ńláǹlà tó kún orí èèyàn àti gbogbo ìmọ̀ tí wọ́n ní, a ò tíì rí ọ̀nà àbáyọ lọ́wọ́ ìwà ipá àti ìwà ìkà tó kúnnú ayé? Ṣé ìyípadà tiẹ̀ máa wà rárá? Àwọn àpilẹ̀kọ méjì tó tẹ̀ lé e ló máa dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
ÈPO Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Àwọn àgbá arọ̀jò ọta tí wọ́n lò nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní: fọ́tò U.S. National Archives; àwọn tó kú nígbà Ìpakúpa Rẹtẹtẹ Ogun Àgbáyé Kejì: Robert A. Schmuhl, nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda USHMM Photo Archives
Ojú ìwé 2 àti 3: Ọkọ̀ òfuurufú arọ̀jò ọta B-17: fọ́tò USAF; obìnrin: Instituto Municipal de Historia, Barcelona; àwọn olùwá-ibi-ìsádi: UN PHOTO 186797/ J. Isaac; ìbúgbàù tó jẹ́ ìdíwọ̀n 23 kiloton: fọ́tò U.S. Department of Energy