Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Burú Nínú Tẹ́tẹ́ Títa?

Kí Ló Burú Nínú Tẹ́tẹ́ Títa?

Kí Ló Burú Nínú Tẹ́tẹ́ Títa?

“Àwọn ará Ọsirélíà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rùn-ún lé rúgba [290,000] ni tẹ́tẹ́ títa ti di bárakú fún, wọ́n sì ń pàdánù owó tó lé ní bílíọ̀nù mẹ́ta lọ́dọọdún. Kì í ṣe àwọn tí tẹ́tẹ́ títa ti di bárakú fún yìí nìkan ni àdánù náà ń bá, àmọ́ ó tún ń ṣàkóbá fáwọn èèyàn tó tó mílíọ̀nù kan ààbọ̀ nítorí irú àwọn nǹkan bíi gbèsè, ìkọ̀sílẹ̀, ìpara-ẹni, àti pípàdánù àkókò lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́.”J. Howard, olórí ìjọba ilẹ̀ Ọsirélíà ló sọ ọ̀rọ̀ yìí lọ́dún 1999.

JOHN, tá a mẹ́nu kan nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, di ẹni tó sọ tẹ́tẹ́ títa di bárakú. a Ó ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, níbi tó ti ṣègbéyàwó pẹ̀lú Linda, tí òun náà jẹ́ atatẹ́tẹ́. Ńṣe ni àṣà bárakú John yìí túbọ̀ wá ń jingíri sí i. Ó sọ pé: “Mi ò dá a dúró sórí ríra tíkẹ́ẹ̀tì tẹ́tẹ́ lọ́tìrì nìkan, àmọ́ mo tún tẹ̀ síwájú dórí kíkọ́ iyàn lórí ẹni tó máa borí nínú ìdíje fífi ẹṣin sáré, mo sì máa ń lọ ta tẹ́tẹ́ nílé tẹ́tẹ́. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni mò ń ta tẹ́tẹ́. Nígbà míì, màá fi gbogbo owó oṣù mi ta tẹ́tẹ́, tí kò sì ní sí owó kankan láti fi sanwó ilé àti láti fi bọ́ ìdílé mi. Kódà bí mo bá jẹ owó tó pọ̀ gan-an pàápàá, ńṣe ni màá ṣì tún máa ta tẹ́tẹ́ lọ ràì. Ìmóríyá tí jíjẹ tẹ́tẹ́ máa ń fúnni ló dẹkùn mú mi.”

Irú àwọn ẹ̀dá bíi ti John pọ̀ lọ jàra. Ńṣe ló dà bíi pé gbogbo àwùjọ èèyàn ni ìgbónára tẹ́tẹ́ títa ti bò mọ́lẹ̀. Ìwé ìròyìn USA Today sọ pé láàárín ọdún 1976 sí 1997, iye táwọn èèyàn ná sórí tẹ́tẹ́ títa tó bófin mu ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ sókè lọ́nà tó kàmàmà, nítorí pé iye tí wọ́n ná fi ìlọ́po méjìlélọ́gbọ̀n ga ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

Ìwé ìròyìn The Globe and Mail ti ilẹ̀ Kánádà sọ pé: “Láyé àtijọ́, ohun tí kò bójú mu láwùjọ làwọn èèyàn ka tẹ́tẹ́ títa sí. Àmọ́, ó ti di ohun àfipawọ́ tí tọmọdé tàgbà ń dunnú sí lóde òní.” Ìwé ìròyìn yìí wá sọ ọ̀kan lára àwọn kókó tó fà á, ó ní: “Àwọn ìpolówó tẹ́tẹ́ tí ìjọba gbé kalẹ̀, èyí tó tíì ná ìjọba lówó jù lọ, tí wọ́n sì ṣe fún àkókò tó tíì pẹ́ jù lọ nínú ìtàn orílẹ̀-èdè Kánádà, ló jẹ́ kí àwọn èèyàn máa fojú tó dára wo tẹ́tẹ́ títa.” Ipa wo làwọn akitiyan lóríṣiríṣi láti gbé tẹ́tẹ́ títa lárugẹ ti ní lórí àwọn àwùjọ kan?

Sísọ Tẹ́tẹ́ Títa Di Bárakú Ń Tàn Kálẹ̀

Ẹ̀ka Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Àwọn Àṣà Tó Ti Di Bárakú ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn Harvard ṣe ìwádìí kan lọ́dún 1996, wọ́n sì fojú díwọ̀n rẹ̀ pé “mílíọ̀nù méje ààbọ̀ làwọn àgbàlagbà ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó ti sọ tẹ́tẹ́ títa di bárakú àtàwọn tí tẹ́tẹ́ títa ti yí lórí,” nígbà tí “àwọn ọ̀dọ́langba ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó ti sọ tẹ́tẹ́ títa di bárakú àtàwọn tí tẹ́tẹ́ títa ti yí lórí sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́jọ.” Àwọn ìṣirò wọ̀nyí wà lára ìròyìn kan tí Ìgbìmọ̀ Tí Ìjọba Àpapọ̀ Gbé Kalẹ̀ Láti Ṣàyẹ̀wò Ipa Tí Tẹ́tẹ́ Títa Ń Ní Lórí Àwùjọ ṣàkójọ rẹ̀ tí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ìròyìn náà sọ pé àfàìmọ̀ kí iye àwọn èèyàn tó ti sọ tẹ́tẹ́ títa di bárakú lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà má ju iye tí wọ́n kọ sílẹ̀ lọ.

Àwọn olùwádìí sọ pé tẹ́tẹ́ títa tó ti di bárakú ń ná ilẹ̀ Amẹ́ríkà ní ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là lọ́dọọdún, látàrí bí iṣẹ́ ṣe ń bọ́ lọ́wọ́ àwọn atatẹ́tẹ́, bí ìlera wọn ṣe ń jó rẹ̀yìn, bí wọ́n ṣe ń san owó ìtìlẹyìn fáwọn tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́, àti iye tí wọ́n fi ń tọ́jú àwọn tí tẹ́tẹ́ títa ti dá wàhálà sí lọ́rùn. Àmọ́, iye owó tí tẹ́tẹ́ títa to ti di bárakú ń ná ìjọba kò tó ìnira tó ń kó àwọn èèyàn sí—irú bí àdánù tó máa ń mú bá ìdílé, àwọn ọ̀rẹ́, àtàwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni, látàrí olè jíjà, ìkówójẹ, ìpara-ẹni, ìwà ipá inú ilé, àti híhùwà àìdáa sáwọn ọmọdé. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà fi hàn pé ẹnì kan tó sọ tẹ́tẹ́ títa di bárakú lè ṣèpalára fún ẹni mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní tààràtà. Ìròyìn kan tó wá látọ̀dọ̀ Àjọ Tó Ń Ṣèwádìí fún Ìjọba Àpapọ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé “àwọn tí tẹ́tẹ́ títa ti yí lórí ń hùwà àìdáa sí iye tó tó ìdá àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkọ tàbí aya wọn, wọ́n sì tún ń hùwà àìdáa sí iye tó tó ìdá mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ wọn.”

Àṣà Bárakú Yìí Máa Ń Gbèèràn

Bíi tàwọn àrùn kan tó máa ń gbèèràn, àwọn òbí tó sọ títẹ́ títa di bárakú lè kó àṣà yìí ran àwọn ọmọ wọn. Ìròyìn tó wá látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Tí Ìjọba Àpapọ̀ Gbé Kalẹ̀ Láti Ṣàyẹ̀wò Ipa Tí Tẹ́tẹ́ Títa Ń Ní Lórí Àwùjọ sọ pé: “Ó rọrùn gan-an fún àwọn ọmọ táwọn òbí wọn ń ta tẹ́tẹ́ láìníjàánu láti di oníwàkiwà, bíi kí wọ́n máa mu sìgá, kí wọ́n máa mu ọtí ní ìmukúmu, kí wọ́n sì máa lo oògùn líle. Àfàìmọ̀ kí àwọn náà fúnra wọn má sì di ẹni tó sọ tẹ́tẹ́ títa di bárakú tàbí ẹni tí tẹ́tẹ́ títa yí lórí bíi tàwọn òbí wọn.” Ìròyìn náà tún kìlọ̀ pé: “Ó ṣeé ṣe gan-an pé káwọn ọ̀dọ́langba tó ń ta tẹ́tẹ́ sọ ọ́ di bárakú tàbí kí wọ́n di ẹni tí tẹ́tẹ́ títa yí lórí ju àwọn àgbàlagbà lọ.”

Dókítà Howard J. Shaffer, ẹni tó jẹ́ olùdarí Ẹ̀ka Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Àwọn Àṣà Tó Ti Di Bárakú ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn Harvard, sọ pé: “Ẹ̀rí tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ń fi hàn pé tẹ́tẹ́ títa láìbófinmu láàárín àwọn ọ̀dọ́ túbọ̀ ń peléke sí i lọ́nà tó dọ́gba pẹ̀lú tẹ́tẹ́ títa tí ìjọba fọwọ́ sí, àfàìmọ̀ kó má tiẹ̀ jùyẹn lọ.” Ó sọ kókó kan láti fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí àwọn tí tẹ́tẹ́ títa ti yí lórí lo ìmọ̀ ẹ̀rọ Íńtánẹ́ẹ̀tì lọ́nà tí kò bójú mu, ó ní: “Gẹ́gẹ́ bí fífa kokéènì ságbárí ṣe yí ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà lo kokéènì padà, mo rò pé àwọn ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ náà pẹ̀lú máa yí ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà ta tẹ́tẹ́ padà.”

Àwọn tó ń ṣagbátẹrù tẹ́tẹ́ títa sábà máa ń fi hàn pé ó jẹ́ eré ìdárayá kan tí kò lè pani lára. Àmọ́ tẹ́tẹ́ títa lè di bárakú fún àwọn ọ̀dọ́langba bíi ti oògùn olóró, ó sì lè mú kí ẹnì kan hùwà ọ̀daràn. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi hàn pé láàárín àwọn ọ̀dọ́langba tó ń ta tẹ́tẹ́, “ìdá mẹ́rìndínláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ló ja ìdílé wọn lólè” láti lè fi ta tẹ́tẹ́.

Láìka gbogbo òkodoro òtítọ́ tá a ti fi hàn lókè yìí sí, ẹgbẹ́ àwọn sànmọ̀rí kan tó ń ṣonígbọ̀wọ́ tẹ́tẹ́ títa ṣì ń kan sáárá sí tẹ́tẹ́ títa pé kò sóhun tó burú nínú rẹ̀, wọ́n ní: “Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ará Amẹ́ríkà tó gbádùn tẹ́tẹ́ títa kì í ní ìṣòro kankan rárá.” Kódà bó o bá rò pé tẹ́tẹ́ títa ò lè gbọ́n owó àpò rẹ gbẹ tàbí pé kò lè kó bá ìlera rẹ púpọ̀ jù, ipa wo ni tẹ́tẹ́ títa lè ní lórí ìlera rẹ nípa tẹ̀mí? Ǹjẹ́ àwọn ìdí pàtàkì wà tó o fi ní láti yẹra fún tẹ́tẹ́ títa? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e á dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpótí náà “Àbí Mo Ti Sọ Tẹ́tẹ́ Títa Di Bárakú Ni?” tó wà ní ojú ìwé 14 àti 15.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14, 15]

Àbí Mo Ti Sọ Tẹ́tẹ́ Títa Di Bárakú Ni?

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Àjọ Àwọn Oníṣègùn Ọpọlọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ, àwọn àmì tó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé yìí lọ dé 15, la fi lè mọ ẹni tí tẹ́tẹ́ títa ti yí lórí (tí wọ́n tún máa ń pè ní atatẹ́tẹ́ láìníjàánu). Ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi gbà pé bó o bá ń rí díẹ̀ lára àwọn àmì wọ̀nyí nínú ìwà rẹ, o ti sọ tẹ́tẹ́ títa di bárakú nìyẹn, bó bá sì jẹ́ èyíkéyìí lára wọn lo ní, ó ṣeé ṣe kó o di ẹni tó máa sọ tẹ́tẹ́ títa dí bárakú tó bá yá.

Ríronú ṣáá nípa tẹ́tẹ́ Tẹ́tẹ́ títa ló máa gbà ọ́ lọ́kàn—wàá máa ronú ṣáá lórí àwọn tó o ti ta tẹ́lẹ̀, wàá máa wéwèé bó o tún ṣe máa lọ ta nígbà mìíràn, tàbí kó o máa ronú nípa àwọn ọ̀nà tó o lè gbà rí owó tó o máa fi ta tẹ́tẹ́.

Títẹramọ́ tẹ́tẹ́ títa Wàá máa fi owó tó túbọ̀ pọ̀ sí i ta tẹ́tẹ́ kí ọwọ́ rẹ lè tẹ àṣeyọrí tó ò ń lépa.

Kí jíjáwọ́ nínú tẹ́tẹ́ dìṣòro Ara rẹ kì í balẹ̀ tàbí kó o máa kanra gógó nígbà tó o bá ń gbìyànjú láti dín tẹ́tẹ́ tó ò ń ta kù tàbí tó o fẹ́ jáwọ́.

Títa tẹ́tẹ́ láti rí ìtura Wàá máa ta tẹ́tẹ́ torí àtilè bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro tàbí kí ara lè tù ọ́ nítorí bó o ṣe ń nímọ̀lára àìnírètí, ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀, àníyàn, tàbí ìsoríkọ́.

Fífẹ́ láti dí àdánù Lẹ́yìn tó o bá ti pàdánù owó nídìí tẹ́tẹ́ títa, wàá tún lọ ta á torí pé o fẹ́ jẹ owó tó o sọ nù padà. Àṣà yìí ni wọ́n ń pè ní dídí àdánù ẹni.

Irọ́ pípa Wàá máa purọ́ fún àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ, àwọn oníṣègùn, àtàwọn ẹlòmíràn kí wọ́n má bàa mọ bó o ti ṣe lọ jìnnà tó nídìí tẹ́tẹ́ títa.

Àìlèkóra-ẹni-níjàánu O ti gbìyànjú láìmọye ìgbà àmọ́ pàbó ni gbogbo akitiyan rẹ ń já sí láti jáwọ́ nínú tẹ́tẹ́ títa, láti ṣàkóso rẹ̀, tàbí láti dín in kù.

Híhu àwọn ìwà tí kò bófin mu O ti hu àwọn ìwà tí kò bófin mu, irú bíi lílu jìbìtì, olè jíjà, tàbí kíkówójẹ láti lè rówó fi ta tẹ́tẹ́.

Bíba àjọṣe pàtàkì kan jẹ́ O ti ṣàkóbá fún àjọṣe pàtàkì kan tàbí kó o ti bà á jẹ́, o ti lè pàdánù ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tàbí àǹfààní iṣẹ́ tuntun kan, tàbí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ nítorí tẹ́tẹ́ títa.

Jíjẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn dúró fún ọ O ti gbára lé àwọn ẹlòmíràn fún owó láti fi kó ara rẹ yọ nínú ìṣòro ìṣúnná owó kan tí tẹ́tẹ́ títa fà.

[Credit Line]

Orísun ìròyìn: National Opinion Research Center ní University of Chicago, Gemini Research, àti The Lewin Group.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ẹ̀kọ́ Tí Àwọn Ìpolówó Lọ́tìrì Ń Kọ́ni

Ìròyìn kan tí àwọn olùwádìí ní Yunifásítì Duke, èyí tó wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, fi ránṣẹ́ sí Ìgbìmọ̀ Tí Ìjọba Àpapọ̀ Gbé Kalẹ̀ Láti Ṣàyẹ̀wò Ipa Tí Tẹ́tẹ́ Títa Ń Ní Lórí Àwùjọ, sọ pé: “Gbígbé tẹ́tẹ́ lọ́tìrì lárugẹ . . . lè mú kí àwọn èèyàn máa wò ó bí ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye, ohun tó sì ń kọ́ wọn ni pé tẹ́tẹ́ títa kò fi bẹ́ẹ̀ burú tàbí pé ìgbòkègbodò tó bójú mu ni pàápàá.” Ipa wo tiẹ̀ ni ìpolówó tẹ́tẹ́ lọ́tìrì ń ní lórí àwùjọ? Ìròyìn náà sọ pé: “Kì í ṣe àsọdùn bá a bá sọ pé ẹ̀kọ́ tó lè fọ́ ìlú yángá ni ìpolówó tẹ́tẹ́ lọ́tìrì ń kọ́ wa, ìyẹn ni pé mímú nọ́ńbà tó jẹ ló máa jẹ́ kéèyàn ṣe oríire. ‘Ẹ̀kọ́’ àyídáyidà táwọn iléeṣẹ́ tẹ́tẹ́ lọ́tìrì ń polongo yìí lè yọrí sí òdìkejì ohun tí ìjọba ní lọ́kàn, ńṣe ló máa jẹ́ kí ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ bópẹ́ bóyá, dípò tí ì bá fi gbé pẹ́ẹ́lí. Ní ti gidi, bí gbígbé tẹ́tẹ́ lọ́tìrì lárugẹ kò bá fún àwọn èèyàn níṣìírí láti jẹ́ kí iṣẹ́ wù wọ́n ṣe, tí kò bá ń rọ̀ wọ́n láti fowó pa mọ́, tí kò sì ń rọ̀ wọ́n láti náwó sórí ẹ̀kọ́ ìwé tàbí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tiwọn fúnra wọn, ohun tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ ni pé àwọn iléeṣẹ́ kò ní lè mú ohun púpọ̀ jáde. Lọ́rọ̀ kan, ríretí iṣẹ́ ìyanu àìròtẹ́lẹ̀ kan kì í ṣe ìlànà téèyàn fi lè ṣàṣeyọrí tá a sábà máa ń kọ́ àwọn ọmọ wa.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ilé Èyíkéyìí Lè Di Ilé Tẹ́tẹ́

Ní ìfiwéra pẹ̀lú kíkọ́ àwọn ibùdó tẹ́tẹ́ tuntun, owó díẹ̀ ṣíún làwọn tó ń ṣagbátẹrù tẹ́tẹ́ títa máa ń ná láti ṣètò Ibi Ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, èyí tó lè sọ ilé èyíkéyìí tó bá ti ní ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tó ń bá ètò Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣiṣẹ́ di ilé tẹ́tẹ́. Lágbedeméjì àwọn ọdún 1990, àwọn Ibi Ìsọfúnni bíi mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ló wà fún tẹ́tẹ́ títa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Lọ́dún 2001, wọ́n ti ju ẹgbẹ̀fà [1,200] lọ, ọdọọdún sì ni owó tó ń wọlé látinú tẹ́tẹ́ títa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ń fi ìlọ́po méjì ga sí i. Lọ́dún 1997, iye owó tó tó ọ̀ọ́dúnrún [300] mílíọ̀nù dọ́là làwọn ibùdó tẹ́tẹ́ títa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì pa wọlé. Lọ́dún 1998, wọ́n tún jèrè àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta [650] mílíọ̀nù owó dọ́là sí i. Ìròyìn kan láti iléeṣẹ́ ìròyìn Reuters sọ pé lọ́dún 2000, àwọn ibùdó tẹ́tẹ́ títa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì jèrè owó tó lé ní bílíọ̀nù méjì dọ́là, tó bá sì fi máa di ọdún 2003, iye yìí “á ti ròkè sí ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù mẹ́fà ààbọ̀ dọ́là.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Lára ìnira tí sísọ tẹ́tẹ́ títa di bárakú máa ń mú wá ni àìrí owó fi jẹun nínú ìdílé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Tẹ́tẹ́ títa lágbo àwọn ọ̀dọ́ túbọ̀ ń peléke sí i lọ́nà tó bani lẹ́rù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ọmọ àwọn atatẹ́tẹ́ láìníjàánu lè tètè di ẹni tó sọ tẹ́tẹ́ títa di bárakú