Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 15. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)

1. Nígbà tí Jésíbẹ́lì pàṣẹ pé kí wọ́n pa àwọn wòlíì Jèhófà, ta lẹni tó fi ọgọ́rùn-ún lára wọn pa mọ́ sínú àwọn ihò inú àpáta? (1 Ọba 18:3, 4)

2. Orúkọ oyè Jésù wo ni ẹ̀mí àìmọ́ tí Jésù lé jáde lára ọkùnrin kan nínú sínágọ́gù Kápánáúmù pàápàá mọ̀ nípa rẹ̀? (Lúùkù 4:34)

3. Kí lorúkọ ọkọ Náómì? (Rúùtù 1:3)

4. Àwọn alákòóso Róòmù márùn-ún wo ni Lúùkù dárúkọ wọn láti fìdí àkókò tí Jòhánù Oníbatisí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ múlẹ̀? (Lúùkù 3:1)

5. Ìhà ibo ni àbáwọlé àgọ́ ìjọsìn àti ti tẹ́ńpìlì kọjú sí? (Númérì 3:38)

6. Ọmọkùnrin mélòó ni Jésè bí, ipò kelòó ni Dáfídì sì wà láàárín wọn? (1 Sámúẹ́lì 17:12, 14)

7. Ìdí wo ni àwọn Farisí fi ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ Jésù? (Mátíù 22:15)

8. Ìlú àwọn ará Filísínì wo ni Sámúsìnì lọ láti wá ọgbọ̀n ẹ̀wù rí fún àwọn tó “já” àlọ́ rẹ̀? (Onídàájọ́ 14:19)

9. Nínú ìran ìtẹ́ Jèhófà tí Jòhánù rí, kí ni ẹ̀dá alààyè kejì fara jọ? (Ìṣípayá 4:6, 7)

10. Ìlú wo ni Jèhófà dá sí nígbà tí ọba ibẹ̀ àtàwọn èèyàn rẹ̀ ronú pìwà dà kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn? (Jónà 3:1-10)

11. Kí nídìí tá a fi gbà wá níyànjú láti “jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú” nínú ìjọ? (Hébérù 13:17)

12. Wòlíì wo ló sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé “àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi ni èmi yóò pè ní ‘àwọn ènìyàn mi,’” nígbà tó ń sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe kọ Ísírẹ́lì ti ara sílẹ̀ tó sì ṣojú rere sí orílẹ̀-èdè tẹ̀mí? (Róòmù 9:25)

13. Nínú ìran tí Jòhánù rí, kí ni áńgẹ́lì náà lò láti de Sátánì? (Ìṣípayá 20:1)

14. Kí ló mú kí Ákúílà àti Pírísílà ṣí kúrò ní Róòmù lọ sí Kọ́ríńtì? (Ìṣe 18:2)

15. Kí nídìí tí a kò fi lè rí àríwísí nípa ìbínú Ọlọ́run? (Jóṣúà 7:1)

16. Kí ni Aísáyà fi àwọn èèyàn burúkú tí wọ́n ti dàjèjì sí Ọlọ́run wé? (Aísáyà 57:20)

17. Ọba wo ló ṣàkóso kẹ́yìn ní Jerúsálẹ́mù lára àwọn ọba Júdà? (2 Ọba 24:18)

18. Kí lorúkọ ohun ìkọ̀wé tí wọ́n máa ń lò láti kọ nǹkan sára amọ̀ tàbí àtè? (Aísáyà 8:1)

19. Kí ni Jésù sọ fún akọ̀wé tó sọ pé ibikíbi tí Jésù bá lọ lòún máa lọ, èyí tó fi hàn pé nǹkan á nira fáwọn tó bá tẹ̀ lé Jésù? (Lúùkù 9:58)

20. Ọba burúkú wo ní ilẹ̀ Móábù ni ikùn rẹ̀ tóbi gan-an débi pé ńṣe ni idà tí Éhúdù kì bọ̀ ọ́ wọnú rẹ̀ tán pátápátá? (Onídàájọ́ 3:17-22)

21. Bí Kíléópà ti ń fi ìyàlẹ́nu rẹ̀ hàn nítorí ó dà bí ẹni pé Jésù kò mọ ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù, ìbéèrè wo ló bi Jésù? (Lúùkù 24:18)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. Ọbadáyà, ìríjú ààfin

2. “Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run”

3. Élímélékì

4. Tìbéríù Késárì, Pọ́ńtíù Pílátù, Hẹ́rọ́dù Áńtípà, Fílípì arákùnrin rẹ̀, àti Lísáníà

5. Ìlà Oòrùn

6. Mẹ́jọ; òun ni àbúrò pátápátá

7. “Láti dẹ pańpẹ́ mú un nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀”

8. Áṣíkẹ́lónì

9. “Ẹgbọrọ akọ màlúù”

10. Nínéfè

11. Kí wọ́n bàa lè ṣe ìjíhìn wọn “pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn,” èyí tí yóò ṣe “ìpalára” fún wa

12. Hóséà

13. “Ẹ̀wọ̀n ńlá”

14. Nítorí àṣẹ tí Kíláúdíù pa, èyí tó fi lé gbogbo àwọn Júù dà nù ní Róòmù

15. Ìgbà gbogbo ni ìbínú rẹ̀ máa ń tọ̀nà, ó máa ń ṣàkóso rẹ̀, ó sì máa ń wà níbàámu pẹ̀lú àwọn ànímọ́ rẹ̀ ti ìfẹ́, ọgbọ́n, àti ìdájọ́ òdodo

16. Òkun tó ń ru gùdù

17. Sedekáyà

18. Kálàmù

19. “Ọmọ ènìyàn kò ní ibì kankan láti gbé orí rẹ̀ lé”

20. Égílónì

21. “Ìwọ ha ń ṣe àtìpó ní Jerúsálẹ́mù?”