Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọjọ́ Tí Ọ̀sán Dòru

Ọjọ́ Tí Ọ̀sán Dòru

Ọjọ́ Tí Ọ̀sán Dòru

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ÀǸGÓLÀ ÀTI ZAMBIA

‘Ọ̀SÁN dòru kẹ̀? Àgbẹdọ̀, kò lè ṣẹlẹ̀ láé!’ lohun táwọn kan máa wí. Àmọ́ kì í ṣe pé èyí lè ṣẹlẹ̀ nìkan ni, ó tiẹ̀ tún níye ìgbà tó fi máa ń ṣẹlẹ̀ lọ́dún mẹ́wàá-mẹ́wàá—ìyẹn nígbà tí òṣùpá bá bo ojú oòrùn pátápátá ní ọ̀sán gangan. Kí ló máa ń mú kí ọ̀sán dòru, kí nìdí tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sì fi máa ń jẹ́ ìran àpéwò fún àwọn èèyàn? Àfi ká kọ́kọ́ mọ̀ nípa òṣùpá ná, ká tó lè dáhùn ìbéèrè yìí.

Ǹjẹ́ o mọ bí òṣùpá ṣe máa ń yí ìrísí rẹ̀ padà bó ṣe ń rìn yí po ayé? Nígbà tí òṣùpá àti oòrùn bá wà ní ìhà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lójú òfuurufú la máa ń rí ohun tá à ń pè ní òṣùpá àrànmọ́jú, èyí tó máa ń rọra yọ ní ìlà oòrùn bí oòrùn bá ṣe ń wọ̀ ní ìwọ̀ oòrùn. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, òṣùpá yìí á máa gòkè díẹ̀díẹ̀ lálaalẹ́, tí yóò sì máa rọra rìn lọ síhà ibi tí oòrùn ti ń yọ wá lójú sánmà. Apá ibi tí ìmọ́lẹ̀ tàn sí lára òṣùpá yìí á wá máa kéré sí i díẹ̀díẹ̀ títí yóò fi fara hàn bí ìgbà tí oṣù bá ṣẹ̀ṣẹ̀ lé. Kódà ìwọ̀nba tó hàn yìí yóò pòórá nígbà tí òṣùpá bá wà lójú òfuurufú pẹ̀lú oòrùn látàárọ̀ ṣúlẹ̀, kì í sì sábà ṣeé ṣe láti rí òṣùpá náà nítorí pé apá ibi tó ṣókùnkùn lára rẹ̀ ló máa kọjú sí ilẹ̀ ayé. Èyí la máa fi ń sọ pé oṣù ṣẹ̀ṣẹ̀ lé. Lẹ́yìn náà, òṣùpá náà á tún bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò rẹ̀ padà, tí yóò máa rìn kúrò lápá ibi tí oòrùn wà títí tí yóò fi tún padà di òṣùpá àrànmọ́jú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Bí òṣùpá ṣe máa ń rìn-lọ rìn-bọ̀ yìí máa ń wáyé ní nǹkan bí ọjọ́ méjìdínlọ́gbọ̀n síra wọn.

Ohun tó máa ń pinnu ìgbà tí ọ̀sán bá máa dòru ni òṣùpá àṣẹ̀ṣẹ̀yọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, ńṣe ni òṣùpá máa ń wulẹ̀ kọjá lára oòrùn ní ọ̀sán gangan, tí a ò sì ní rí i, nítorí pé ipa ìrìnnà wọn kì í ṣe ọ̀kan náà. Àmọ́ ṣá o, nígbà míì, oòrùn, òṣùpá, àti ayé máa ń wà ní ọ̀gban-anran ìlà kan náà. Nírú ìgbà yìí ni òjìji òṣùpá máa ń ṣíji bo ilẹ̀ ayé, èyí á sì mú kí ọ̀sán dòru.

Ọ̀sán máa ń dòru nígbà tí àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ kan bá wáyé láàárín oòrùn, òṣùpá, àti ayé. Oòrùn tóbi lọ́nà tó kàmàmà, nǹkan bí irínwó ìgbà ló fi tóbi ju òṣùpá lọ. Ohun tó tún pabanbarì níbẹ̀ ni pé, oòrùn fi nǹkan bí irínwó ìgbà jìn sí wa ju bí òṣùpá ṣe jìn sí wa lọ. Látàrí èyí, lójú àwa èèyàn, ńṣe ló máa ń dà bíi pé oòrùn àti òṣùpá fẹ́rẹ̀ẹ́ jọ bára wọn dọ́gba. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè dà bíi pé òṣùpá bo ojú oòrùn tán pátápátá nígbà míì.

Kí òṣùpá tó lè bo oòrùn lójú pátápátá bẹ́ẹ̀ yẹn, kì í ṣe pé oòrùn, òṣùpá, àti ayé gbọ́dọ̀ jọ wà ní ọ̀gban-anran ìlà kan náà lọ́nà tó ṣe rẹ́gí nìkan ni, ṣùgbọ́n, ó tún gbọ́dọ̀ jẹ́ nígbà tí òṣùpá bá sún mọ́ ayé. a Láwọn àkókò tí èyí bá ṣẹlẹ̀, ńṣe ni òjìji òṣùpá náà, èyí tó máa ń wá látòkè-sísàlẹ̀ ní ìrísí òkòtó, yóò mú kí àwọn ibi díẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ṣókùnkùn.

Nígbà tí ọ̀sán dòru ní June 21, 2001, òjìji òṣùpá tó ṣíji bo ayé lọ́jọ́ náà fẹ̀ tó igba [200] kìlómítà. Ìṣẹ̀lẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí oòrùn là ní etíkun ìhà ìlà oòrùn Gúúsù Amẹ́ríkà ó sì kọjá ní Gúúsù Àtìláńtíìkì, níbi tó ti fara hàn fún nǹkan bí ìṣẹ́jú márùn-ún, èyí tó jẹ́ ìgbà tó gùn jù lọ tó lè fara hàn. Lẹ́yìn tó ti kọjá ní Àǹgólà, Zambia, Zimbabwe, àti Mòsáńbíìkì, ó parí ìfarahàn rẹ̀ nígbà tí oòrùn wọ̀ ní etíkun ìlà oòrùn Madagascar. Ẹ jẹ́ ká wo bí ìran àgbàyanu ojú sánmà yìí ṣe fara hàn fún àwọn olùwòran ní ilẹ̀ Àǹgólà àti Zambia.

Àwọn Ìmúrasílẹ̀ Tí Wọ́n Ṣe fún Ìṣẹ̀lẹ̀ Náà

Pẹ̀lú bí ara tọmọdé tàgbà ṣe wà lọ́nà, ńṣe ni àwọn ògbóǹkangí olùṣèwádìí, àwọn ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ onímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá inú sánmà, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn mìíràn ń rọ́ gìrọ́gìrọ́ lọ sí ilẹ̀ Áfíríkà láti lọ wo bí òṣùpá ṣe máa bo oòrùn lójú pátápátá fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ẹgbẹ̀rúndún tuntun. Níwọ̀n bí ìlú Lusaka, lórílẹ̀-èdè Zambia, tí jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo tó wà ní ipa ọ̀nà tí òṣùpá yóò ti bo oòrùn lójú pátápátá, ibẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn olùṣèbẹ̀wò kọrí sí láti lọ wò ó.

Àfàìmọ̀ ni kò jẹ́ pé èyí ni ìran kíkàmàmà jù lọ tó tíì fa ọ̀pọ̀ àwọn olùṣèbẹ̀wò wá sí ilẹ̀ Zambia. Ní kìkì ọjọ́ bíi mélòó kan ṣáájú kí ọ̀sán tó dòru náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùṣèbẹ̀wò ti kún ìlú Lusaka fọ́fọ́. Ọ̀pọ̀ oṣù ṣáájú ni wọ́n ti ń ṣe ìmúrasílẹ̀ fún ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún. Èèyàn ò lè rí yàrá gbà mọ́ nínú gbogbo hòtẹ́ẹ̀lì, ilé ìbùwọ̀, ibi ìpàgọ́, àtàwọn ilé aládàáni, torí pé ọ̀pọ̀ àwọn olùṣèbẹ̀wò ti sanwó sílẹ̀ láti dé síbẹ̀.

Lára ibi táwọn èèyàn ti lè wòran ni pápákọ̀ òfuurufú ìlú Lusaka, níbi táwọn olùṣèbẹ̀wò lè lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, kí wọ́n wo ìṣẹ̀lẹ̀ náà, kí wọ́n sì kúrò lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ làwọn iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n àti rédíò fi ń kéde ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tí wọ́n sì ń kìlọ̀ gbọnmọgbọnmọ pé ewu púpọ̀ ló wà nínú kéèyàn tẹjú mọ́ oòrùn o. Ńṣe làwọn èèyàn kàn ń ra àkànṣe awò ojú wìtìwìtì. Iye táwọn olùtajà tà kọjá iye tí wọ́n lérò pé àwọ́n lè tà, kódà ọ̀pọ̀ ilé ìtajà ló ta gbogbo èyí tí wọ́n ní tán.

Bó ti wù kó rí, orílẹ̀-èdè Àǹgólà ni ibi àkọ́kọ́ tí òṣùpá yóò ti bo oòrùn lójú pátápátá ní ilẹ̀ Áfíríkà, èyí sì jẹ́ ní ìlú Sumbe tó wà létíkun. Ibí làwọn olùwòran ti máa láǹfààní láti rí bí òṣùpá yóò ti bo oòrùn lójú pátápátá fún ìṣẹ́jú mẹ́rin ààbọ̀, èyí tó jẹ́ àkókò tó tíì gùn jù lọ téèyàn fi lè rí bí ọ̀sán ṣe máa dòru láti orí ilẹ̀, tí kì í bá ṣe pé èèyàn wò ó láti ojú òkun.

Ní ọ̀pọ̀ oṣù ṣáájú kí òṣùpá tó bo oòrùn lójú náà, wọ́n ti gbé àwọn pátákó ìpolówó tó ń kéde ìṣẹ̀lẹ̀ yìí àtàwọn ewu tó lè bá a rìn sí ìlú Luanda, tó jẹ́ olú ìlú Àǹgólà, àti sí àwọn ìlú ńláńlá mìíràn. Àárín orílẹ̀-èdè náà ni òjìji òṣùpá náà á gbà kọjá, nípa bẹ́ẹ̀ gbogbo ilẹ̀ Àǹgólà ló máa rí i tí òṣùpá á bo oòrùn lójú lápá kan, ó kéré tán. Àwọn olùgbé Luanda ní tiwọn á rí i tí òṣùpá bo nǹkan bí ìdá mẹ́sàn-án àbọ̀ nínú mẹ́wàá ojú oòrùn. Ìjọba, àtàwọn iléeṣẹ́ aládàáni kan ṣètò láti kó ọ̀pọ̀ jaburata àkànṣe awò ojú tó ṣeé fi wo oòrùn wọlé, káwọn èèyàn bàa lè rí wọn lò. Ọ̀pọ̀ ni wọ́n há lọ́fẹ̀ẹ́ fún àwọn tí kò lówó láti rà á.

Ọ̀gangan ibi tí ọ̀sán á ti dòru ní ilẹ̀ Àǹgólà ni ìlú Sumbe, èyí tó wà ní ilẹ̀ ẹlẹ́wà títẹ́jú kékeré kan ní etíkun, láàárín méjì Gúúsù Àtìláńtíìkì àti ilẹ̀ olókè tó wà láàárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Àǹgólà. Àwọn ìjà burúkú-burúkú tó ti sọ ilẹ̀ Àǹgólà dìdàkudà kò dé àgbègbè Sumbe, èyí ló jẹ́ káwọn olùṣèbẹ̀wò láǹfààní láti wá sí ìlú píparọ́rọ́ yìí tó ní àwọn olùgbé ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000], tí wọ́n jẹ́ ọlọ́yàyà, ẹni bí ọ̀rẹ́, tí ara wọn yọ̀ mọ́ èèyàn. Kí àyè lè gba gbogbo àwọn olùṣèbẹ̀wò wọ̀nyí, wọ́n ṣe ọ̀pọ̀ ibi táwọn àlejò lè sùn sí kí wọ́n sì jẹun láfikún sáwọn àyè tó ti wà nílẹ̀, wọ́n sì tún iná mànàmáná ìlú náà ṣe kó lè sunwọ̀n sí i. Wọ́n ṣètò àkànṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kúkúrú kan fún àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, àwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba, àtàwọn òṣìṣẹ́ afẹ́dàáfẹ́re tó wà nílẹ̀ Àǹgólà pẹ̀lú àwọn tó wá látilẹ̀ òkèèrè. Wọ́n ṣe pèpéle ńlá kan sí etíkun láti fi ṣe àríyá ńlá kan tó fakíki, irú èyí tí kò wáyé rí ní ìlú Sumbe.

Ọjọ́ Tí Wọ́n Ti Ń Retí Ọ̀hún Wọlé Dé

Ọ̀kan lára àwọn àǹfààní tó wà nínú wíwo bí ọ̀sán ṣe máa dòru ní orílẹ̀-èdè Àǹgólà ni pé òjò kì í sábà rọ̀ púpọ̀ níbẹ̀ lóṣù June. Àmọ́, fọkàn yàwòrán bí ìdààmú ṣe bá àwọn èèyàn nígbà tí ìkuukùu bẹ̀rẹ̀ sí í gbára jọ sí àgbègbè Sumbe ní ó ku ọ̀la kí ọ̀sán dòru! Ńṣe ni ojú sánmà ṣú dẹ́dẹ́ẹ́dẹ́ ní gbogbo alẹ́ ọjọ́ náà títí fi di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì. Ṣé kì í ṣe pé pàbó ni gbogbo bí ara àwọn èèyàn ṣe wà lọ́nà láti wo bí ọ̀sán ṣe fẹ́ dòru yìí máa já sí báyìí? Nígbà tó fi máa di ìyálẹ̀ta ọjọ́ náà, ìkuukùu tó gbára jọ ti bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ dà nù, ìgbà tí yóò sì fi di ọwọ́ ọ̀sán, ojú ọ̀run ti mọ́ kedere, láìsí ìkuukùu kankan. Ńṣe lara wá tu àwọn èèyàn pẹ̀sẹ̀! Bákan náà lara àwọn èèyàn ò ṣe kọ́kọ́ balẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Zambia, nígbà tí ojú ọ̀run ṣú ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ náà. Àmọ́, ojú sánmà tún mọ́ foo níbẹ̀ náà kó tó pẹ́ jù. Gbọ́ ohun táwọn tó fojú ara wọn rí bí ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ náà ṣe wáyé lẹ́sẹẹsẹ sọ.

Àǹgólà: “Ibì kan tó ga sókè dáadáa lẹ́bàá òkun la pinnu láti lọ wo bí òṣùpá ṣe máa bo oòrùn lójú. Bí wákàtí ọ̀hún ti ń sún mọ́lé, àwọn èrò tó ń wọ́ bí omi ti kóra jọ ní etíkun ìlú náà, wọ́n sì ti dúró sáwọn ibi tí wọ́n ti ṣètò fún wíwo ìran náà. Ní aago méjìlá ọ̀sán, bó ṣe kù díẹ̀ kí ọ̀sán bẹ̀rẹ̀ sí í dòru, ọ̀pọ̀ ti fi awò ojú tó máa dáàbò bo ojú wọn sójú, wọ́n sì ti ń wọ̀nà láti rí apá ibi tí òṣùpá ti máa kọ́kọ́ ‘gbé’ oòrùn ‘mì.’ Kò pẹ́ lẹ́yìn aago méjìlá ọ̀sán ni ọ̀sán bẹ̀rẹ̀ sí í dòru. Nípa lílo awò awọ̀nàjínjìn àti awò asọ-nǹkan-di-ńlá, ó ṣeé ṣe láti rí àwọn àmì tó-tò-tó dúdú kọ̀ọ̀kan lójú oòrùn. Àwọn olùwòran rí i bí òjìji òṣùpá ṣe ń gbé àwọn àmì tó-tò-tó wọ̀nyí mì lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Bí ìran náà ṣe ń tẹ̀ síwájú, ojú ọjọ́ tutù lẹ́ẹ̀kan náà, ìmọ́lẹ̀ oòrùn sì bẹ̀rẹ̀ sí í yí padà sí àwọ̀ ṣíṣàjèjì kan. Níkẹyìn, bí òjìji òṣùpá tó ń sún mọ́ oòrùn náà ṣe gbé apá kékeré tó ṣẹ́ kù lára oòrùn mì, ńṣe ni òkùnkùn biribiri bolẹ̀.”

Zambia: “Àgbègbè Makeni, ní ìlú Lusaka, ni wọ́n kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Zambia sí, ọ̀gangan ibí yìí sì jẹ́ ibi tó ṣe rẹ́gí gan-an láti wo bí òṣùpá ṣe máa bo oòrùn lójú pátápátá. Ní aago mẹ́ta kọjá ìṣẹ́jú méje ọ̀sán, òṣùpá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣíji bo ojú oòrùn. Òjìji òṣùpá náà bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn bí ìlà tẹ́ẹ́rẹ́-tẹ́ẹ́rẹ́ lára àwọn ògiri ilé, ó wá dà bíi pé wọ́n ń tanná kan tó ń ṣẹ́jú wìrìwìrì sí wọn lára. Ẹ̀fúùfù tó ń fẹ́ dáwọ́ dúró, àwọn ẹyẹ tó ń kọrin sì dákẹ́ orin kíkọ. Kíá làwọn ẹ̀dá inú igbó lóríṣiríṣi ti bẹ̀rẹ̀ sí í múra àtilọ sun oorun alẹ́. Ní aago mẹ́ta kọjá ìṣẹ́jú mẹ́sàn-án, ìyẹn nǹkan bí ìṣẹ́jú àáyá díẹ̀ kí òkùnkùn biribiri bo gbogbo ilẹ̀, kìkì ìwọ̀nba ìmọ́lẹ̀ tíntìntín kan tí ń dán yanran ló wà lójú oòrùn, títí tó fi ku ẹyọ ìmọ́lẹ̀ fótóró kan ṣoṣo. Irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mérìíyìírí wọ̀nyí ni wọ́n ń pè ní Baily’s beads àti diamond ring.  b Ohun tó tún ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e ni pé a rí chromosphere, ìyẹn ní ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ kan tó ní àwọ̀ pupa àti osùn, èyí tó ṣamọ̀nà sí òkùnkùn biribiri tó bolẹ̀ náà!”

Àǹgólà: “Bí ìmọ́lẹ̀ oòrùn ṣe fara jọ òrùka dáyámọ́ǹdì tí ń kọ mọ̀nà yìí jẹ́ káwọn èèyàn mí kanlẹ̀ kí wọ́n sì pariwo gèè. Lẹ́yìn náà, ní aago méjì ku ìṣẹ́jú méjìlá ní Àǹgólà, ńṣe ni òkùnkùn biribiri bẹ̀rẹ̀ sí í bolẹ̀. Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lohun táwọn èèyàn ṣe lásìkò yìí. Fọ́tò làwọn kan ń yà ṣáá. Àwọn mìíràn bẹ̀rẹ̀ sí í jọ kígbe nígbà náà pé, ‘Òkùnkùn biribiri! Òkùnkùn biribiri! Òkùnkùn biribiri!’ Ńṣe làwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í súfèé, tí wọ́n sì ń pariwo pẹ̀lú ìyàlẹ́nu bí oòrùn ṣe ń wọ̀ọ̀kùn ní ọ̀sán gangan. Lẹ́yìn náà, àwọn ọ̀wọ́-iná oòrùn tó dà bí ìlà tẹ́ẹ́rẹ́-tẹ́ẹ́rẹ́ tó yí oòrùn náà ká para pọ̀ láti ìhà gbogbo láti di corona, ìyẹn ìmọ́lẹ̀ róbótó kan tó yí oòrùn tí òkùnkùn ti fẹ́ ẹ́ gbé mì náà ká. A rí àwọn nǹkan tó dà bí gáàsì tó ń jó fòfò, tí wọ́n tẹ̀ kọrọdọ ní eteetí òṣùpá tó ṣú dùdù náà. Lójijì, bí ẹni pé nǹkan ti yí ọwọ́ aago síwájú, ńṣe ni òkùnkùn biribiri tó bolẹ̀ ọ̀hún pòórá, tí ọwọ́ ìmọ́lẹ̀ oòrùn kan sì mọ́lẹ̀ yóò láti ẹ̀gbẹ́ kejì òjìji òṣùpá náà.

“Bí oòrùn náà ti ń fara hàn, a rí àwọn àmì tó-tò-tó lójú oòrùn, èyí tí òṣùpá ti gbé mì tẹ́lẹ̀, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í padà wá lọ́kọ̀ọ̀kan bí oòrùn ṣe ń para dà di róbótó bó ti máa ń rí.”

Zambia: “Gbogbo àkókò tí òṣùpá fi bo oòrùn lójú pátápátá níbí jẹ́ ìṣẹ́jú mẹ́ta àti ìṣẹ́jú àáyá mẹ́rìnlá, nípa bẹ́ẹ̀, a láǹfààní láti wo ìran àgbàyanu ọ̀hún dáadáa. Òkùnkùn ṣú àmọ́ ìmọ́lẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀ kedere kan wà ní gbogbo eteetí sánmà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojú ọ̀run ṣì ní àwọ̀ búlúù, ó ṣeé ṣe láti rí àwọn pílánẹ́ẹ̀tì mìíràn tí oòrùn sábà máa ń bò mọ́lẹ̀, irú bíi Jupiter àti Saturn, kedere làwọn èèyàn sì rí wọn. Àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ohun táwọn èèyàn fẹ́ràn láti wò jù lọ nígbà tí ọ̀sán dòru ni corona oòrùn. Ó fara hàn bí ìmọ́lẹ̀ dídángbinrin kan tó ní àwọ̀ osùn àti funfun, èyí tó yí ohun dúdú róbótó kan ká. Bí ìran yìí ṣe gba àwọn èèyàn lọ́kàn tó, ńṣe ni wọ́n ń sọ pé ‘eléyìí ga jù, ó ga lọ́lá.’ Díẹ̀díẹ̀, òṣùpá tó bojú oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí sún kúrò, tí ìmọ́lẹ̀ oòrùn sì bẹ̀rẹ̀ sí í tàn sórí ilẹ̀ ayé, títí di aago mẹ́rin kọjá ìṣẹ́jú méjìdínlọ́gbọ̀n, nígbà tí ìmọ́lẹ̀ oòrùn wá mọ́lẹ̀ kedere. Bí ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú kí ọ̀sán dòru ṣe kádìí nìyẹn o!”

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tá A Lè Rí Kọ́ Látinú Ìṣẹ̀lẹ̀ Ọ̀sán Tó Dòru

Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sọ ipa tí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń wọni lọ́kàn ṣinṣin yìí ní lórí wọn. Ní orílẹ̀-èdè Àǹgólà, obìnrin kan sọ pé omijé fẹ́rẹ̀ẹ́ jábọ́ lójú òun. Ẹlòmíràn sọ pé òún ronú jinlẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà pé ó jẹ́ ẹ̀bùn ẹlẹ́wà kan tí Ọlọ́run pèsè. Síbẹ̀, ẹnì kan sọ pé kìkì Ẹlẹ́dàá kan tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ ló lè pèsè irú ìran yìí, káwọn èèyàn bàa lè mọyì ẹwà kíkàmàmà tí oòrùn ní.

Ó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ èèyàn nílẹ̀ Áfíríkà ló ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ẹlẹ́dàá àti fún Bíbélì. Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Sumbe ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa bí ọ̀sán ṣe dòru yìí, tí wọ́n sì ń ṣàlàyé pé ó wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wa, ńṣe làwọn olùgbé ìlú náà fi ìfẹ́ àtọkànwá wọn hàn láti túbọ̀ jíròrò lórí kókó yìí. Ọ̀pọ̀ lo fi ìháragàgà gba àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, èyí tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu wọ̀nyí.

Ìṣẹ̀lẹ̀ ojú sánmà yìí jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn gbàgbé ìṣòro wọn fún ìṣẹ́jú bíi mélòó kan, ó sì jẹ́ kí wọ́n pọkàn pọ̀ sórí ohun kan tó ń mórí ẹni wú tó sì tún ń yani lẹ́nu ní ti tòótọ́. Nígbà tí àwọn kan rí onírúurú ìran àpéwò tí oòrùn fi hàn yìí, èyí táwa èèyàn kì í sábà rí, wọ́n ronú nípa ògo àgbàyanu tá ò lè fojú rí rárá tí Jèhófà, Ẹlẹ́dàá oòrùn máa ní, ògo tó ga fíìfíì jùyẹn lọ.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Níwọ̀n bí ipa ọ̀nà òṣùpá, àti ipa ọ̀nà ayé kì í ti ṣe èyí tí ń yí po ní òbíríkítí àmọ́ tó jẹ́ pé ńṣe ní ipa ọ̀nà wọn dà bí ìrísí ẹyin, títóbi oòrùn àti òṣùpá lè yí padà níwọ̀nba, ó sinmi lórí apá ibi tí wọ́n bá wà nínú ipa ọ̀nà wọn. Nígbà tí òṣùpá bá wà ní apá ibi tí ipa ọ̀nà rẹ̀ ti jìn jù lọ sí ayé, apá ibi tó ṣókùnkùn jù lọ lára òjìji òṣùpá kò ní fi bẹ́ẹ̀ dé orí ilẹ̀ ayé. Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, àwọn olùwòran lórí ilẹ̀ ayé tó ń kíyè sí òjìji òṣùpá yìí yóò rí i tí òṣùpá bo oòrùn lójú lápá kan, ìyẹn ni ìgbà tí oòrùn bá fara hàn gẹ́gẹ́ bí òrùka dídángbinrin kan tó yí òjìji dúdú kan po.

b Ìṣẹ̀lẹ̀ mérìíyìírí tí wọ́n ń pè ní Baily’s beads máa ń wáyé nígbà tí ìmọ́lẹ̀ oòrùn bá rọra ń fara hàn bí ìlẹ̀kẹ̀ kéékèèké lábẹ́ òṣùpá tó ṣú dùdù náà ní kété kí òkùnkùn biribiri tó bolẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà “diamond ring” ní wọ́n máa ń lò láti ṣàpèjúwe ìfarahàn oòrùn ní kété kí òkùnkùn biribiri tó dé, nígbà tí apá kékeré bíńtín kan lára oòrùn bá ṣì ń hàn kedere, tí yóò fara hàn bí òrùka funfun kan tó ń tàn yinrinyinrin, tí yóò sì fara jọ òrùka dáyámọ́ǹdì kan.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

→ →

Oòrùn → Òṣùpá ⇨ Apá ibi tó ṣókùnkùn ⇨ Ayé

→ →

[Credit Line]

© 1998 Visual Language

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Baily’s beads

Òkùnkùn biribiri

Diamond ring

[Credit Line]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Juan Carlos Casado, www.skylook.net

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Àwọn tó ń wòran bí ọ̀sán ṣe dòru ní ìlú Lusaka, lórílẹ̀-èdè Zambia