Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó o Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí Nínú Ayé Alálòsọnù

Bó o Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí Nínú Ayé Alálòsọnù

Bó o Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí Nínú Ayé Alálòsọnù

“NÍNÚ gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá . . . kò sí èyíkéyìí tó máa ń ṣòfò.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Time ti sọ, ohun tí ó jẹ́ èrò ògbógi kan nípa ìṣàtúnlò nìyẹn. Ó ń tọ́ka sí ọ̀nà àgbàyanu tí ilẹ̀ ayé máa ń fi lo ohun kan tí kò lẹ́mìí tàbí ohun táwọn èèyàn ti gbé sọ nù láti ṣe àwọn nǹkan mìíràn láǹfààní, láìka apá ibi tí wọ́n ti wá nínú àyíká sí. Ìròyìn náà tún sọ pé ògbógi ọ̀hún ronú pé “àwa ẹ̀dá èèyàn lè fara wé ọ̀nà tí ìṣẹ̀dá ń lò láti palẹ̀ pàǹtírí mọ́, àmọ́ ká tó lè ṣe èyí, a óò nílò ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tó jẹ́ àkọ̀tun, àti ìyípadà tó pẹtẹrí nínú ìṣarasíhùwà wa.”

Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa ni kò lè hùmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ àkọ̀tun èyíkéyìí. Àmọ́ ó ṣeé ṣe fún wa láti ṣàkóso ìṣarasíhùwà wa! Fífi ọwọ́ gidi mú àwọn ìlànà pàtàkì kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìwà ọmọlúwàbí yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti lè túbọ̀ kojú àwọn ìṣòro tó wà nínú gbígbé láwùjọ táwọn èèyàn ti máa ń yára gbé nǹkan sọ nù.

Má Ṣe Ya Àpà Tó Máa Ń Fi Nǹkan Ṣòfò

Iye tó tó ìdá márùn-ún nínú gbogbo olùgbé ayé ló ń pa ebi mọ́nú sùn lálaalẹ́. Mímọ̀ tá a mọ èyí yẹ kó máa tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa lọ́kàn pé, ó yẹ ká mọrírì oúnjẹ ká má sì ṣe máa fi ṣòfò. Tọkọtaya kan tí wọ́n padà sí ilẹ̀ Yúróòpù lẹ́yìn tí wọ́n ti lo ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Áfíríkà sọ pé, ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tó mú kó nira fún wọn láti jẹ́ kí ara wọn tètè mọlé padà ní orílẹ̀-èdè wọn ni, fífarada “ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà fi oúnjẹ ṣòfò.”

Àwọn òbí tó gbọ́n máa ń kọ́ ọmọ wọn láti bu ìwọ̀nba oúnjẹ tí wọ́n lè jẹ tán lẹ́ẹ̀kan sínú àwo. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ máa ń dín pàǹtírí àti ìfiṣòfò kù. Ohun tó dára jù ni pé kí wọ́n kọ́kọ́ bu díẹ̀, lẹ́yìn náà kí wọ́n wá gbà sí i bí wọ́n bá fẹ́ jẹ sí i. Ní ti gidi, àwọn òbí gbọ́dọ̀ fi àpẹẹrẹ èyí lélẹ̀. Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún gbogbo wa nípa fífi ìmọrírì àtọkànwá hàn fún àwọn ìpèsè Ọlọ́run, nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Bíbélì sọ pé Jésù yẹra fún fífi oúnjẹ ṣòfò—bó tiẹ̀ jẹ́ pé nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu ló fi pèsè oúnjẹ ọ̀hún lọ́pọ̀ yanturu!—Jòhánù 6:11-13.

A tún lè lo ìlànà yíyẹra fún fífi nǹkan ṣòfò bó bá dọ̀ràn aṣọ wa, àwọn ohun ọ̀ṣọ́ inú ilé wa, àtàwọn ẹ̀rọ wa. Bá a bá ń jẹ́ kí àwọn ohun èlò wà ní ipò tó dára nípa títún wọn ṣe bí wọ́n bá ti fẹ́ dẹnu kọlẹ̀, tá a sì ń gbìyànjú láti lò wọ́n fún ìgbà pípẹ́ bó bá ṣe bọ́gbọ́n mu sí, á fi hàn pé a mọyì àwọn ohun tá a ní. Kò yẹ ká jẹ́ kí àwọn tó ń polówó ọjà tàn wá jẹ débi pé àwọn ohun tá a ní báyìí ò ní tẹ́ wa lọ́rùn mọ́, tí a óò wá máa sáré àtira àwọn nǹkan ìgbàlódé tó tóbi gan-an, tó dára gan-an, tó yára gan-an, tó sì tún lágbára gan-an ju èyí tá à ń lò báyìí lọ. Lóòótọ́ o, ó lè pọn dandan pé ká pààrọ̀ àwọn ohun ìní wa tó ṣì wúlò. Ṣùgbọ́n ká tó ṣe bẹ́ẹ̀, á dáa ká kọ́kọ́ gbé ìṣarasíhùwà wa yẹ̀ wò, ká sì tún mọ ète tá a fi fẹ́ẹ́ pààrọ̀ wọn.

Yẹra fún Ìwà Ìwọra

Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rìnrìn-àjò la àárín aginjù já nígbà tí wọ́n ń lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí, Ọlọ́run pèsè mánà fún wọn gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, mánà ọ̀hún pọ̀ rẹpẹtẹ. Àmọ́, a kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n yẹra fún ìwà ìwọra; kìkì ìwọ̀nba tí wọ́n nílò lójú ẹsẹ̀ ni kí wọ́n kó. Àwọn tó kọtí dídi sí ìkìlọ̀ yìí rí i pé ìwà ìwọra kò pé, torí pé ńṣe ni èyí tó ṣẹ́ kù yọ ìdin, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rùn. (Ẹ́kísódù 16:16-20) Bíbélì kò fọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ rárá nípa ìwà ìwọra, ó tẹnu mọ́ ọn láìmọye ìgbà pé ìwà ìwọra kò bójú mu.—Éfésù 5:3.

Kì í ṣe Bíbélì nìkan ló tẹnu mọ́ kókó yìí. Bí àpẹẹrẹ, Seneca, ọmọ ilẹ̀ Róòmù kan ní ọ̀rúndún kìíní, tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí àti òǹkọ̀wé eré onítàn, gbà pé ẹni tó bá ní ìwà ìwọra kì í nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Ó sọ pé: “Gbogbo nǹkan tó wà lórí ilẹ̀ ayé kò lè tẹ́ oníwọra lọ́rùn.” Erich Fromm, tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí kan ní ọ̀rúndún ogún, dé ìparí èrò kan náà, ó sọ pé: “Ìwà ìwọra dà bí ọ̀gbun kan tí kò nísàlẹ̀, èyí tó máa ń máyé sú onítọ̀hún, torí pé ṣe ni yóò kàn máa fi torí tọrùn ṣiṣẹ́ ṣáá láti lè ní gbogbo ohun tó wù ú, àmọ́ kò ní tẹ́ ẹ lọ́rùn.” Yàtọ̀ sí yíyẹra fún ìwà ìwọra àti ìfiṣòfò, àwọn ìgbésẹ̀ rere kan wà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti fúnra wọn yàn láti gbé.

Máa Ṣàjọpín Nǹkan

Kó o tó sọ àwọn ohun èlò tó ṣì wà ní ipò tó dára nù, ronú nípa ẹni tó lè nífẹ̀ẹ́ sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, bí aṣọ àwọn ọmọdé bá ti fò wọ́n, ǹjẹ́ àwọn ọmọdé mìíràn ṣì lè jàǹfààní wọn bó bá bá wọn mu? Ṣé o lè ṣàjọpín àwọn ohun ìní rẹ mìíràn bẹ́ẹ̀ tó ṣì wúlò àmọ́ tí o kì í fi bẹ́ẹ̀ lò mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀? Jẹ́ kí àwọn ẹlòmíì náà jàǹfààní ohun kan tó o ti lò nípa fífi wọ́n tọrẹ. Mark Twain, tó jẹ́ òǹṣèwé àti aláwàdà ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, kọ̀wé nígbà kan pé: “Kéèyàn tó lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀, àfi kó wá ẹnì kan láti bá ṣàjọpín ayọ̀ rẹ̀.” Bóyá ìwọ fúnra rẹ ti rí i pé ńṣe ni ayọ̀ téèyàn bá ṣàjọpín máa ń di ìlọ́po méjì. Yàtọ̀ síyẹn, nípa ṣíṣàjọpín lọ́nà yìí, wàá lè ṣèrànwọ́ láti dènà àbájáde tí kò bára dé tó máa ń jẹ yọ nígbà téèyàn bá ń fi nǹkan ṣòfò.

Ṣíṣàjọpín pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn jẹ́ ìwà àtàtà kan tí Bíbélì gbé lárugẹ gan-an. (Lúùkù 3:11; Róòmù 12:13; 2 Kọ́ríńtì 8:14, 15; 1 Tímótì 6:18) Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, ẹ ò rí i pé ayé á túbọ̀ dára gan-an bí gbogbo wa bá múra tán láti ṣàjọpín!

Jẹ́ Kí Àwọn Ohun Kòṣeémánìí Tẹ́ Ọ Lọ́rùn

Aláyọ̀ lẹni tó bá nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Òótọ́ gbáà lọ̀rọ̀ yìí o, níbikíbi àti nígbàkigbà. Òwe ilẹ̀ Gíríìkì kan sọ pé: “Kò sí nǹkan kan tó lè tẹ́ ẹni tí díẹ̀ kò bá tó lọ́rùn.” Àwọn ará ilẹ̀ Japan sì máa ń pa á lówe pé: “Aláìní ni ẹni tí kò bá nítẹ̀ẹ́lọ́rùn.” Bíbélì náà kan sáárá sí ìwà ìtẹ́lọ́rùn. A kà pé: “Láìsí àní-àní, ó jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá, àní fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi. Nítorí a kò mú nǹkan kan wá sínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mú ohunkóhun jáde. Nítorí náà, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.”—1 Tímótì 6:6-8; Fílípì 4:11.

Àmọ́ ṣá o, níní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun tá a ní lè béèrè pé ká ṣe “ìyípadà tó pẹtẹrí nínú ìṣarasíhùwà wa.” Ẹnu àìpẹ́ yìí ni ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan tó ń jẹ́ Susanne mọ̀ pé òún ní láti ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Mo pinnu pé níwọ̀n bí èmi kò ti lè ní gbogbo ohun tí mo bá fẹ́, mo gbọ́dọ̀ kọ́ láti fẹ́ràn ohun tí mo ní. Nísinsìnyí, mo láyọ̀ mo sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn.”

Òótọ́ ọ̀rọ̀ ni o, pé ìtẹ́lọ́rùn máa ń ṣamọ̀nà sí ayọ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Argir Hadjihristev, ọmọ ilẹ̀ Bulgaria kan tó jẹ́ ògbógi nínú ìmọ̀ nípa ọjọ́ ogbó, sọ pé: “Lákọ̀ọ́kọ́ ná, lájorí ohun tó ń fa láburú fún ọmọ ẹ̀dá ni àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìwọ̀nba nǹkan téèyàn ní.” Nígbà tó ń tọ́ka sí àwọn àǹfààní tí ìtẹ́lọ́rùn máa ń mú bá ìlera ara, ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹni tí kò bá ń gbìyànjú láti gbé ìgbé-ayé tó sunwọ̀n ju ti aládùúgbò rẹ̀ lọ, tí kò bá ń fìgbà gbogbo gbìyànjú láti máa ra nǹkan ṣáá, yóò máa gbé ayé láìsí pé ó ń bá àwọn ẹlòmíì díje, kò sì ní máa kó ẹ̀mí ara rẹ̀ sókè. Èyí sì máa ń ṣàǹfààní fún àwọn iṣan ara.”

Dájúdájú, bí àwọn èèyàn ṣe ń gbé nǹkan sọ nù kò lè fúnni ní ojúlówó ayọ̀. Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ àṣà fífi nǹkan ṣòfò! Ó dà bí ẹni pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ti ń gbà bẹ́ẹ̀. Ṣé ìwọ náà ti gbà bẹ́ẹ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ó yẹ káwọn ọmọdé mọ béèyàn ṣe ń yẹra fún fífi oúnjẹ ṣòfò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Jésù fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nípa yíyẹra fún fífi nǹkan ṣòfò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

O ò ṣe fún àwọn ẹlòmíràn ní ohun tó ò bá lò mọ́ dípò tí wàá fi gbé e sọ nù?