Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fetí Sílẹ̀ kó o sì Kẹ́kọ̀ọ́

Fetí Sílẹ̀ kó o sì Kẹ́kọ̀ọ́

Fetí Sílẹ̀ kó o sì Kẹ́kọ̀ọ́

ÌRÒYÌN kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn The Toronto Star sọ pé: “Nípa fífetí sílẹ̀ la fi mọ ìdá márùnlélọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ohun tá a mọ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé púpọ̀ nínú àkókò wa la máa ń fi fetí sílẹ̀ sí nǹkan, “ìdá márùnléláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àkókò ọ̀hún ló jẹ́ pé ibòmíràn lọkàn wa máa ń wà, tá ó máa ro nǹkan mìíràn tàbí ká má tiẹ̀ rántí ohun tá a gbọ́.” Àwọn ìsọfúnni yíyanilẹ́nu wọ̀nyí jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ ṣiṣẹ́ lórí bá a ṣe ń tẹ́tí sílẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ṣe sọ, “àìmọ béèyàn ṣe ń tẹ́tí sílẹ̀ ló wà nídìí ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń bẹ láwùjọ.” Rebecca Shafir, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ọ̀rọ̀ sísọ àti ọ̀mọ̀ràn nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ sọ pé, ìṣòro yìí ló sábà máa ń fa fífọwọ́-ara-ẹni-para-ẹni, ìwà ipá ilé ẹ̀kọ́, bí ìdílé ṣe ń túká, àti lílo oògùn olóró.

Àwọn onímọ̀ nípa àwùjọ ẹ̀dá èèyàn sọ pé, ọ̀nà tí àwa èèyàn gbà ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ yàtọ̀ síra. Àwọn kan wà tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ṣe ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹlòmíràn ni wọ́n máa ń fẹ́ gbọ́, tí wọ́n á sì fẹ́ mọ gbogbo fìn-ín ìdí kókò tó wà nínú ọ̀rọ̀ náà. Àwọn kan sì rèé, ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an ni wọ́n máa ń fẹ́ mọ̀, tí wọ́n á sì máa fẹ́ kí ẹni tó ń sọ̀rọ̀ náà tètè lọ sórí kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ìwé ìròyìn Star wá sọ pé: “Ohun tá a lè sọ nípa ẹgbẹ́ méjèèjì yìí ni pé ọ̀rọ̀ wọn lè máà yéra wọn.”

Abájọ tí Jésù fi tẹnu mọ́ kókó náà pé, “ẹ máa fiyè sí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.” (Lúùkù 8:18) Títẹ́tísílẹ̀ dáadáa nígbà tí ẹlòmíràn bá ń sọ̀rọ̀ fi ìwà ọmọlúwàbí hàn. Ó sì ṣe pàtàkì gan-an nínú ìjíròrò. Lára àwọn ìdámọ̀ràn díẹ̀ tó wúlò nípa béèyàn ṣe lè tẹ́tí sílẹ̀ nígbà tí ẹlòmíràn bá ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni, ṣíṣàìjẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn ẹni níyà, títẹ orí síwájú díẹ̀, fífi ojú dáhùn padà nípa wíwo ẹni tó ń sọ̀rọ̀ náà lójú, àti mími orí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti fi hàn pé ò ń lóye onítọ̀hún. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ ohun tí à ń kọ́ ti sinmi lórí fífetísílẹ̀ dáadáa, fífiyè sílẹ̀ jẹ́ ohun tó yẹ kí gbogbo wa máa bá a lọ láti ṣiṣẹ́ lé lórí.